Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìwà-ẹ̀dá Àtọ̀runwá àti Ípin Ayérayé Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìwà-ẹ̀dá Àtọ̀runwá àti Ípin Ayérayé Yín

Mo pè yín láti fi ìgbé-ayé yín lé oókan Jésù Krístì kí ẹ sì rántí àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́ nínú Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin.

Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, e ṣe fún wíwa nihin. Mo ní ọlá láti kópa nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò abala ti àwọn obìnrin yí. Bákannàà ní ìgbà kan mo ti ní ànfàní láti lọ sí kílásì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí èmi fi àmì kedere hàn—èmi kìí ṣe ọmọdé, èmi kìí sì iṣe obìnrin kan! Mo kọ́ ẹ̀kọ́, bàkannáà, pé èmì kò ní ní ìmọ̀lára àìsí bí mo bá lè ka Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin náà. Ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ tí a kọ́ni nínú Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin1 ṣe pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, ṣùgbọ́n ó wúlò fún gbogbo ènìyàn, pẹ̀lú àwọn wọnnì lára wa tí wọn kìí ṣe ọ̀dọ́mọbìnrin.

Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin bẹ̀rẹ̀ pé, “Èmi jẹ́ olùfẹ́ Ọmọbìnrin kan ti àwọn Òbí Ọrun, pẹ̀lú ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá àti ìpín ayérayé.”2 Ẹ̀là-ọ̀rọ̀ yí wà pẹ̀lú àwọn òtítọ́ mẹ́rin. Àkọ́kọ́, ẹ jẹ́ olùfẹ́ ọmọbìnrin kan. Kò sí ohun tí ẹ ṣe—tàbí tí ẹ kò ṣe—tí ó lè yí èyí padà. Ọlọ́run fẹ́ràn yín nítorí ẹ jẹ́ ọmọbìnrin ẹ̀mí Rẹ̀. Nígbàmíràn a lè má tilẹ̀ ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ó wà níbẹ̀ nígbàgbogbo. Ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ pípé.3 Agbára wa láti ní òye pé ìfẹ́ kìí ṣe.

Ẹ̀mí nṣe ojúṣe ìdarí nínú sísọ̀rọ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa.4 Síbẹ̀síbẹ̀ okun Ẹ̀mí Mímọ́ le bonimọ́lẹ̀ “nípasẹ̀ agbára ẹ̀dùn-ọkàn, bí irú ìbínú, ìkóríra, … [tàbí] ẹ̀rù … bíi gbìgbìyànjú láti gba òórùn ẹlẹgẹ́ ti adùn gírépù kan nígbàtí à njẹ ata jalapeño. … [Òórùn ọ̀kan] bo òmíràn mọ́lẹ̀ pátápátá.”5 Nítorínáà bẹ́ẹ̀ni àwọn ìwà tí ó nmú wa jìnnà kúrò ní ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀,6 ṣe nmu ṣòro láti lóye ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa.

Bákannáà, ọgbọ́n wa nípa ìfẹ́ Ọlọ́run lè díjú nípa àwọn ipò ípéníjà àti àìlera ti-ara tàbí ti ọpọlọ, ní àárín àwọn ohun míràn. Nínú gbogbo àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, àmọ̀ràn àwọn olùgbẹ́kẹ̀lé olórí tàbí amòye lè ní èrè nígbàkugbà. Bákannáà a lè gbìyànjú láti gbèrú ìtẹ́wọ́gbà wa sí ìfẹ́ Ọlọ́run nípa bíbèèrè lọ́wọ́ arawa pé, “Ṣe ìfẹ́ mi fún Ọlọ́run wà lemọ́lemọ́, tàbí njẹ́ mo ní ìfẹ́ Rẹ̀ nígbàtí mo nni àwọn ọjọ́ rere ṣùgbọ́n tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàtí mo bá ní àwọn ọjọ́ búburú?”

Òtítọ́ kejì ni pé a ní àwọn òbí ọ̀run, baba kan àti ìyá kan.7 Ẹ̀kọ́ nípa Ìyá Ọ̀run nwa nípasẹ̀ ìfihàn ó sì jẹ́ ìgbàgbọ́ àràọ̀tọ̀ ní àárín àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ààrẹ Dallin H. Oaks ṣe àlàyé pàtàkì òtítọ́ yí: “Idanilẹkọ-ẹ̀sìn wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn óbí ọ̀run. Ìlépa wa gígajùlọ ni láti dàbíi tiwọn.”8

Díẹ̀ an ni a ti fihàn nípa Ìyá ní Ọ̀run, ṣùgbọ́n ohun tí a mọ̀ ni a kékúrú nínú Àròkọ Àkọlé Ìhìnrere tí a rí nínú àmúlò Yàrá-ìkàwé Ìhìnrere.9 Nígbàkan tí ẹ bá ti ka ohun tí ó wà níbẹ̀, ẹ ó mọ gbogbo ohun tí mo mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ náà. Mo fẹ́ láti mọ̀ síi. Ẹ̀yin náà ṣì lè ní àwọn ìbèèrè kí ẹ sì fẹ́ láti wá àwọn ìdáhùn si. Wíwá òyè títóbijù ni apákan pàtàkì ti ìgbèrú ti-ẹ̀mí wa, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ẹ gba ìkìlọ̀. Èrèdí kò lè rọ́pò ìfihàn.

Lílérò kìí darí lọ sí ìmọ̀ títóbijù ti-ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ó lè darí sí ẹ̀tàn tàbí yí ìdojúkọ wa kúrò ní ohun tí a ti fihàn.10 Fún àpẹrẹ, Olùgbàlà kọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, “Ẹ gbàdúrà sí Baba ní orúkọ mi nígbàgbogbo.”11 Àwa tẹ̀lé àwòṣe yí a sì ndarí ìjọ́sìn wa sí Baba wa Ọ̀run ní orúkọ Jésù Krístì a kìí gbàdúrà sí Ìyá Ọ̀run.12

Láti ìgbà tí Ọlọ́run ti yan àwọn wòlíì, a ti fún wọ́n láṣẹ láti sọ̀rọ̀ ní ìtìlẹhìn Rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọn kò pè àwọn ẹ̀kọ́ àsọdùn “nípa inú ti ara [wọn] ”13 tàbí kọ́ ohun tí a kò fihàn. Yẹ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Balaamu ti Májẹ̀mú Láéláé wò, ẹnti ó fúnni ní rìbá láti fi àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ré láti mú Móábù jèrè. Balaamu wípé, “Bí [Ọba Móábù] yíò bá fún mi ní ilé rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmì kò lè rékọjá ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run mi, láti ṣe ohun kékeré tàbí nlá.”14 Àwọn wòlíì Ọjọ́-ìkẹhìn ni a dálẹ́kun bákannáà. Bíbèèrè ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ méjèèjì ìgbéraga àti àìlérè. Dípò bẹ́ẹ̀, a dúró dé Olúwa àti aago-àkókò láti fi àwọn òtítọ́ hàn nípasẹ̀ ohun tí Ó ti gbékalẹ̀.10

Òtítọ́ Kẹ́ta nínú gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìṣíwájú ti Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ni pé a ní “ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá kan.” Èyí jẹ́ ojúlówó sí ẹni tí a jẹ́. Ó jẹ́ ti-ẹ̀mí “jíìnì,” tí a jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ọ̀run15 kò sì ní ìtiraka kankan ní ara wa. Ẹ̀yí ni ìdánimọ̀ wa pàtàkì jùlọ, láìka bí a ṣe yàn láti fi ìdánimọ̀ arawa hàn. Níní ìmọ̀ jíjinlẹ̀ òtítọ́ yí ṣe pàtàkì fún gbogbo ènìyàn ṣùgbọ́n nípàtàkì fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tí a ti ṣátì, nilára, tàbi tẹ̀mọ́lẹ̀ nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn. Ẹ rántí pé ìdánimọ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún yín bá ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá yín mu bí ọmọ Ọlọ́run.

Òtítọ́ kẹ́rin ni pé a ní “ìpín ayérayé kan.” Irú ìpín kan tí a kò ní fi ipá mú lé wa lórí. Lẹ́hìn ikú, a ó gba ohun tí a yege fún a ó sì “gbádùn ohun èyí tí [a] ní ìfẹ́ láti gbà [nìkan],”16 Dídá àyànmọ́-ìpín ayérayé wa mọ̀ dálé orí àwọn àṣàyàn wa. Ó gba dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́. Májẹ̀mú yí ni ọ̀nà tí a ó fi wá sọ́dọ̀ Krístì ó dì dá lé òtítọ́ ayérayé àti pátápátá, òfin àìyípadà. A kò lè dá ipá-ọ̀nà ti ara wa sílẹ̀ kí a retí àwọn àbájade ìlérí Ọlọ́run. Láti retí àwọn ìbùkún Rẹ̀ nígbàtí a kò tẹ̀lé àwọn àṣẹ ayérayé lórí èyí tí wọ́n dálé17 jẹ́ ìṣìnà, bíi ríronú pé a lè fọwọ́kan ìdáná gbígbóná kì a sì “pinnu” pé kò ní jó wa.

Ẹ lè mọ̀ pé mo máa ntọ́jú àwọn aláìsàn pẹ̀lú ọkàn kíkùnà. Àbájáde wọn dídárajùlọ ni a gbà nípasẹ̀ títẹ̀lé àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìtọ́jú, dídálé-ẹ̀rí. Pẹ̀lú mímọ èyí, àwọn aláìsàn kan gbìyànjú láti dúnádúrà ètò ìtọ́jú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n wípé, “Èmi kò fẹ́ láti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egboogi” tàbí “Èmi kò fẹ́ láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdánwò léraléra.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn aláìsàn nifẹ láti ṣe ìpinnu ti ara wọn, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá yà kúrò nínú àwọn ètò ìtọ́jú pípéye, ìjìyà ni àyọrísí wọn yíò jásí. Àwọn aláìsàn pẹ̀lú ọkàn ìkùnà kò lè yàn ọ̀nà ayédèrú kí wọ́n sì dá ẹ̀bi fún olùtọ́jú-ọkàn wọn fún ayédèrú àbájáde.

Ọ̀kannáà jẹ́ òtítọ́ fún wa. Baba Ọ̀run júwe ipá-ọ̀nà tí ó darí sí àbájádé ayérayé dídarajùlọ. A ní òmìnira láti yan, ṣùgbọ́n a ko lè yan àyọrísí àìtẹ̀lé ipá-ọ̀nà tí a fihàn.18 Olúwa ti wípé, “Èyí tí ó rú òfin kan, tí ko pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n tí ó nwa ọ̀nà láti jẹ́ òfin fún ara rẹ̀, … kì yíò lè jẹ́ yíyàsímímọ́ nípa òfin, bóyá nípa àánú, òdodo, tàbí ìdájọ́.”19 A kò lè yà kúrò ní ọ̀nà Baba Ọ̀run kí a sì dá A lẹ́bi fún ayédèrú àbájáde.

Gbólóhùn ọ̀rọ̀ kejì nínú Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin kà pé: “Gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, mo ntiraka láti dà bíi Rẹ̀. Mo wá láti ṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn míràn ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀.” A lè mú ẹ̀rí nípa Jésù Krístì dàgbà nípa ṣíṣe ìṣe ìgbàgbọ́.20 A lè gba ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí “láti mọ̀ pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé òun ni a kàn mọ́ àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.” Tàbí a lè gba ẹ̀bùn láti gbàgbọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn tì ó mọ̀ọ́,21 títí tí a ó fi mọ̀ọ́ fúnra wa. A lè tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà kí a sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ní ọ̀nà yí, a ndarapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ Rẹ̀.22

Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìrnin tẹ̀síwájú, “Èmi yíò dúró bí ẹlẹri kan ti Ọlọ́run ni gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo.” Gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ ni a nílò bí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run,23 bíótilẹ̀jẹ́pé a yà àwọn Àpóstélì àti àwọn Àádọ́rin sọ́tọ̀ bí àwọn ẹlẹri pàtàkì ti orúkọ Krístì.24 Ronú nípa ere họ́kì nínú èyí tí adelé nìkan ndá ààbò bo oju-ile. Láìsí ìrànlọ́wọ́ ti àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́lù míràn, adelé kò ní lè dá ààbò bò ojú-ilé dáadáa, àti pé àwọn ẹgbẹ yíò máa kùnà nígbàgbogbo. Nítorínáa, gbogbo ènìyàn gan an ni a nílò nínú ẹgbẹ́ ti Olúwa.

Gbólóhún ọ̀rọ̀ ìparí ti Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin bẹ̀rẹ̀ pé, “Bí mo ti ntiraka láti yege fún ìgbéga, mo ṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà mo sì nwá láti gbèrú ní ojojúmọ́.” Nítorí ti ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà, a lè ronúpìwàdà, kẹkọ látinú àwọn àṣìṣe wa, kí a sì máṣe gba ìdálẹ́bí nípa wọn. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, “Púpọ̀jù àwọn ènìyàn nyẹ ìrònúpìwàdà wò bí ìjìyà. … Ṣùgbọ́n ìmọ̀lára ti gbígba ìjìyà yí ni Sátánì nmúwá. Ó ngbìyànjú láti dènà wa ní wíwo Jésù Krístì, ẹnití ó dúró pẹ̀lú ọwọ́ ṣíṣí sílẹ̀, ní ìrètí àti ìfẹ́ láti wòsàn, dáríjì, wẹ̀mọ́, fúnlókún, sọdi-ọ̀tun. àti yà wá símímọ́.”4

Nígbàtí a bá ronúpìwàdà lódodo, kò sí àpá ti-ẹ̀mí tí ó kù, ohun yíòwú kí a ti ṣe, bí ó ti wù kí ó le tó, tàbí ìgbà mélò tí a ti túnṣe.27 Léralérá bi a ti nronúpìwàdà tí a sì nwà ìdàrìjì pẹ̀lú ọ̀kan òtítọ́, a lè gba ìdáríjì.28 Irú ẹ̀bùn alámì láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Krísti eyí jẹ́!29 Ẹ̀mí Mímọ́ lè mu dá wa lójú pé a ti gba ìdáríjì. Bí a ti nní ọgbọ́n ayọ̀ àti àlááfíà,30 a ó gbá ẹ̀bí kúrò,31 a kò sì nì rí ìdálóró nípa ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́.32

Àní lẹ́hìn ìrònúpìwàdà òdodo, bákannáà, a lè kọsẹ̀. Kíkọsẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ìrònúpìwàdà kò kún ojú-ìwọ̀n ṣùgbọ́n ó kàn lè fi àìlera ẹlẹ́ràn-ara hàn ni. Báwo ni ó ti tuninínú tó láti mọ̀ pé “Olúwa nrí àwọn àìlera yàtọ̀ ju bí Ó ti [nrí] oríkunkun.” A kò gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì sí agbára Olùgbàlà láti rànwálọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àìlera wa nítorí “nígbàtí Olúwa bá nsọ̀rọ̀ àwọn àìlera, o jẹ́ pẹ̀lú àánú.”33

Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin parí pé, “Pẹ̀lú ìgbàgbọ́, èmi yíò fún ilé àti ẹbí mi ní okun, dá àti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, àti láti gba àwọn ìlànà àti àwọn ìbùkún ti tẹ́mpìlì mímọ́.” Fífún ilé àti ẹbí lókun lè túmọ̀ sí mímú ìsopọ̀ àkọ́kọ́ nínú okùn òdodo dúró, gbígbé ogún ìgbàgbọ́ síwájú, tàbí mímu u padasípò.34 Ní ìkàsí, okun nwá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti nípa dídá àwọn májẹ̀mú mímọ́.

Nínú tẹ́mpìlì, a lè kọ́ ẹni tí a jẹ́ àti ibití a ti dé. Amòye Roman Cicero wípé, “Àìnì ìmọ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣíwájú kí a to bí wa ni láti dúró bí ọmọdé.”35 Bẹ́ẹ̀ni, Òun ni, ní títọ́ka sí ikẹkọ àkọọ́lẹ̀-ìtàn, ṣùgbọ́n àkíyèsí ìmòye rẹ̀ lè gbòòrò si. A ngbé bí ọmọdé títí-lọ bí a bá jẹ́ aláìmọ̀kàn nípa ìrísí ayérayé tí a jèrè nínú tẹ́mpìlì. Níbẹ̀ ni a ti dàgbà sókè nínú Olúwa, “gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́,”36 a sì di olùfarajìn kíkún síi bí àwọn ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà.37 Bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, a ngba agbára Ọlọ́run sínú ayé wa.38

Mo pè yín láti fi ìgbé-ayé yín lé oókan Jésù Krístì kí ẹ sì rántí àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́ nínú Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin. Bí ẹ bá nfẹ́, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò tọ́ yín sọ́ná. Baba wa Ọ̀run nfẹ́ kí ẹ di ajogún Rẹ̀ kí ẹ sì gba gbogbo ohun tí Ó ní.39 Òun kò lè fún yín púpọ̀si. Òun kò lè ṣe ìlérí fún yín púpọ̀si. Òun ní ìfẹ́ yín púpọ̀si ju bí ẹ ṣe mọ Ó sì nfẹ́ kí ẹ ní ìdùnnú ní ayé yí àti ní ayé tó nbọ̀, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.