Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Nígbànáà Ni Èmi ó Sọ Àwọn Ohun Aláìlágbára Di Alágbára”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


“Nígbànáà Ni Èmi ó Sọ Àwọn Ohun Aláìlágbára Di Alágbára”

Bí a ti nrẹ ara wa sílẹ̀ tí a sì nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, oore ọ̀fẹ́ Krístì àti ẹbọ ètùtù àìlópin Rẹ̀ nmú kí ó ṣeéṣe láti yípadà.

Ààrẹ Thomas S. Monson sọ ìtàn ọ̀gá ẹlẹ́wọ̀n Clinton Duffy ní ìgbà kan. “Láàrin àwọn ọdún 1940s àti 1950s, [Wọ́dà Duffy] jẹ́ ẹni mímọ̀ dáadáa fún àwọn akitiyan rẹ̀ láti ṣe àtúnṣe àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀. Ọlọ́fintótó kan sọ pé, ‘Ó yẹ kí o mọ̀ pé àwọn àmọ̀tẹ́kùn kìí yí àwọn àpá wọn padà!’

“Wọ́dà Duffy dáhùn pé, ‘Ó yẹ kí o mọ̀ pé èmi kò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmọ̀tẹ́kùn. Mo nṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, àti pé àwọn ènìyàn máa nyí padà ní ojojúmọ́.”1

Ọ̀kan lára àwọn irọ́ títóbijùlọ ti Satanì ni pe àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin kò le yípadà. Àìjẹ́-òtítọ́ yi ti di sísọ àti títúnsọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ bí aráyé ṣe nsọ pé a kò kan le yípadà—tàbí búburú jùlọ síbẹ̀, pé a kò gbọdọ̀ yípadà. A kọ́ wa pé àwọn ipò wa máa nṣe àlàyé wa. A níláti “gba ẹnití a jẹ́ gan mọ́ra,” ni aráyé nsọ, “kí a sì jẹ́ tòótọ́ sí àwa fúnrawa lõtọ́.”

Àwa Lè Yípadà

Nígbàtí ó dára lóòtọ́ láti jẹ́ tõtọ́, a níláti jẹ́ tõtọ́ sí ara wa lõtọ́ gan, bíi ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run pẹ̀lú àdánidá àti àyànmọ́ àtọ̀runwá láti dàbí Rẹ̀.2 Bí ìlépa wa bá ṣe láti jẹ́ tõtọ́ sí àdánidá àti àyànmọ́ àtọ̀runwá yi, nígbànáà a ó nílò láti yípadà. Ọrọ̀ ìwé mímọ́ fún ìyípadà ìrònúpìwàdà. “Àwọn ènìyàn púpọ̀jù,” ní Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni, “ro ìronúpìwàdà bíi ìbáwí—ohunkan tí a níláti yẹra fún bíkòṣe nínú àwọn ipò líle jùlọ. … Nígbàtí Jésù sọ fún ẹ̀yin àti èmi láti ‘ronúpìwàdà,’ Ó npè wá láti yípadà.”3

Àwọn Ipò Ọlọ́run

Àwọn tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ọpọlọ inú kọmpútà lo àwọn ọ̀rọ̀ àjọsọ láti sọ fún kọ̀mpútà ohun tí yío ṣe. Ìwọ̀nyí ni a ntọ́kasí nígbàmíràn bíi àwọn ọ̀rọ̀ bí-nígbànáà. Bíi nínú, bí x bá jẹ́ òtítọ́, nígbànáà yjẹ́ bẹ́ẹ̀.

Olúwa bákannáà nṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ipò: àwọn ipò ti ìgbàgbọ́, àwọn ipò ti òdodo, àwọn ipò ti ìrònúpìwàdà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ ló wà nípa gbólóhùn lórí ọ̀rọ̀ àjọsọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí irú:

ó bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́ àti tí ó forítì dé òpin [nígbànáà] ìwọ yíó ní iyè ayérayé, ẹ̀bùn èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.”4

Tàbí “ ẹ̀yin bá bèèrè tọkàn-tọkàn, pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, pẹ̀lú níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, [nígbànáà] yíò fi òtítọ́ rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.”5

Ìfẹ́ Ọlọ́run papàá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ àìlópin àti pípé, dá lórí àwọn ipo bákannáà.6 Fún àpẹrẹ:

ẹ bá pa àwọn òfin mi mọ̀, [nígbànáà] ẹ ó gbé nínú ìfẹ́ mi; àní bí èmi ti pà àwọn òfin Bàbá mi mọ́, tí mò sì ngbé nínú ìfẹ́ rẹ̀.”7

Alàgbà D. Todd Christofferson ṣe àlàyé síwájú síi lórí òtítọ́ ìhìnrere yí nígbàtí ó kọ́ni pé: “Àwọn kan fẹ́ sọ pé, ‘Olùgbàlà fẹ́ràn mi bí mo ti wà,’ èyí sì jẹ́ òtítọ́ dájúdájú. Ṣùgbọ́n Òun kò lè mú ẹnikẹ́ni lára wa lọ sínú ìjọba Rẹ̀ bí a ti wà, ‘nítorí ohun àìmọ́ kankan kò lè gbé níbẹ̀, tàbí gbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀’[Moses 6:57]. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yànjú.”8

Àwọn Ohun Aláìlágbára Le Di Alágbára

Ìbùkún ti gbígba agbára Ọlọ́run láti rànwa lọ́wọ́ yípadà jẹ́ lórí ipò bákannáà. Olùgbàlà, ní sísọ̀rọ̀ nípasẹ̀ wòlíì Mórónì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, kọ́ni pé: “Bí àwọn ènìyàn bá wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi ó fi àìpé wọn hàn sí wọn. Mo fún àwọn ènìyàn ní àìlera kí wọn ó lè rẹ̀ ara wọn sílẹ̀; õre-ọ̀fẹ́ mi sì tó fún gbogbo ẹ̀nìti ó bá rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi; nítorí tí wọ́n bá rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi nígbànã ni èmi yio mú àwọn ohun aláìlágbára dì alágbára fún wọn.”9

Ní wíwò ohun tí Olúwa nkọ́ wa níhin fínní-fínní, a ríi pé Ó kọ́kọ́ sọ pé Òun fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ní àìlágbára, ti ẹnikan, èyítí ó jẹ́ ara ìrírí ti ara kíkú wa bíi ẹ̀dá síṣubú tàbí ti ara. A ti di àdánidá ọkùnrin àti obìnrin nítorí Ìṣubú Adámù. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, a lè borí àìlágbára wa, tàbí àwọn àdánidá ìṣubú wa.

Lẹ́hìnnáà ó sọ pé oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó àti pé a bá rẹ ara wa sílẹ̀ tí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, nígbànáà Òun yío “mú kí àwọn ohun aláìlágbára [ju ẹyọ kan lọ] di alágbára sí [wa].” Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, bí a ti kọ́kọ́ nyí àwọn àdánidá ìṣubú wa, àìlágbára wa padà, nígbànáà yío ṣeéṣe fúnwa láti yí àwọn ìhùwàsí wa, àwọn àìpé wa padà.

Àwọn Ìkàyẹ ti Ìyípadà

Ẹ jẹ́kí a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìkàyẹ sí ìyípadà ní ìbámu sí ìlànà ti Olúwa:

Ìkínní, a gbọdọ̀ rẹ ara wa sílẹ̀. Ipò ti Olúwa fún ìyípadà ni ìrẹ̀lẹ̀. “ wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi,”10 ni Ó sọ. Ìdàkèjì ìrẹ̀lẹ̀ ni ìgbéraga. Ìgbéraga nwà nígbàtí a bá rò pé a mọ̀ dárajù—nígbàtí ohun tí a nrò tàbí ní ìmọ̀lára rẹ̀ bá gba ipò àkọ́kọ́ lórí ohun tí Ọlọ́run rò tàbí mọ̀lára.

Ọba Bẹ́njámin kọ́ni pé “ènìyàn ẹlẹ́ran ara jẹ ọ̀tá sí Ọlọ́run, … yíò sì jẹ́ bẹ̃, láé àti títí láéláé, bíkòṣepé ó … gbé ìwà ti ara sílẹ̀, tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa, tí ó sì dà bí ọmọdé, onítẹríba, oníwá-tútù, [àti] onírẹ̀lẹ̀.”11

Kí a ba lè yípadà, a nílò láti gbé ìwà ti ara sílẹ̀ tí a sì di onírẹ̀lẹ̀ àti onítẹríba. A gbọdọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó láti tẹ̀lé wòlíì alààyè kan. Onírẹ̀lẹ̀ tó láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́. Onírẹ̀lẹ̀ tó láti máa ronúpìwàdà lójoojúmọ́ A gbọdọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó láti fẹ́ láti yípadà, láti “yí ọkàn [wa] sí Ọlọ́run.”12

Èkejì, a gbọdọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà náà pé “Bí wọ́n bá rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,”13 Òun yío fúnwa ní agbára láti borí àwọn aláìlágbára wa. Ìrẹ̀lẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, yío gbà wá láàyè láti gbà nínú agbára ìgbéniró ti oore ọ̀fẹ́ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìbùkún Rẹ̀ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó nítorí Ètùtù Rẹ̀.

Ǎàrẹ Nelson ti kọ́ni pé “ìrònúpìwàdà òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Jésù Krístì ní agbára lati wẹ̀nùmọ́, wosàn, àti láti fún wa lókun. … Ìgbàgbọ́ wa ni yíò ṣí agbára Ọlọ́run nínu ayé wa .”14

Ìkẹta, nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Ó lè mú àwọn ohun aláìlágbára dì alágbára. a bá rẹ ara wa sílẹ̀ tí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristì, nígbànáà oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ yío jẹ́kí ó ṣeéṣe fúnwa láti yípadà. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Òun ó ró wa lágbára láti yípadà. Èyí ṣeéṣe nítorípé, bí Ó ti sọ. “ore-ọfẹ mi tó fún gbogbo ènìyàn.”15 Oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó nfúnni lókun, tó nmú kó ṣeéṣe nfún wa ní agbára láti borí gbogbo àwọn ìdènà, gbogbo àwọn ìpèníjà, àti gbogbo àwọn àìlera bi a ti nlépa láti yípadà.

Àwọn àìlera wa títóbi jùlọ le di àwọn okun wa títóbi jùlọ. A lè di yíyípadà kí a sì “di ẹ̀dá titun,”16 Àwọn ohun aláìlágbára bí ó ti rí le “di alágbára sí [wa].”17

Olùgbàlà ṣe iṣẹ́ Ètùtù àìlópin àti ti ayérayé Rẹ̀ jáde kí a le ba yípadà, ronúpìwàdà, kí a sì di dídára síi nítòótọ́ A le di àtúnbí nítòótọ́ lẹ́ẹ̀kansíi. A le borí àwọn ìwà, àwọn bárakú, àti papàá “ìfarahàn láti ṣe ibi.”18 Àwa bíi ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin olùfẹ́ni Baba ní Ọrun, a ní agbára ní inú wa láti yípadà.

Àwọn Àpẹrẹ Ìyípadà

Àwọn ìwé mímọ́ kún fún àwọn àpẹrẹ ti àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n yípadà.

Saulù, Farisí kan àti onínúnibíni ti ìjọ Krístíẹnì ìbẹ̀rẹ̀,19 di Paulù, Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì.

Almà jẹ́ àlùfáà nínú yàrá ìgbẹ́jọ́ ti Ọba Nóà búburú. Ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Abinádì, ó ronúpìwàdà ní kíkún, ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nlá ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Ọmọkùnrin rẹ̀ Almà lo ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ní lílépa lati pa Ìjọ náà run. Ó wà láàrin “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó burú jùlọ”20 títí ó fi ní ìyípadà ọkàn tí ó sì di alágbára ìránṣẹ́ ìhìnrere nínú ẹ̀tọ́ tirẹ̀,

Mosè ni a gbà tọ́ sínú ẹbí Fáraò tí a sì tọ́ ọ nínú ọlá bí ọmọ ọba ara Egíptì kan. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó wá ní òye ẹnití ó jẹ́ gan tí ó sì kọ́ nípa àyànmọ́ àtọ̀runwá rẹ̀, ó yípadà ó sì di wòlíì nlá afúnnilófin ti inú Májẹ̀mú Laelae.21

Bàbá àgbà ìyàwó mi, James B. Keysor, ti fi ìgbà gbogbo wù mí pẹ̀lú ìyípadà ọkàn nlá tirẹ̀.22 A bí i nípasẹ̀ àwọn olódodo olùlànà Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní àfonífojì Salt Lake ní 1906, ó pàdánù ìyá rẹ̀ ní ọjọ́ orí ọ̀dọ́ ó sì tiraka jákèjádò ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀. Àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́ àgbà ni ó lò ní àìsí nínú Ìjọ; ní àkókò tí ó gba àwọn ìwà burúkú tí ó níye díẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó pàdé ó sì fẹ́ obìnrin olódodo kan níyàwó àti pé lápapọ̀ wọ́n jọ tọ́ àwọn ọmọ márũn.

Ní 1943, ní àtẹ̀lé àwọn ọdún líle ti Ìrẹ̀wẹ̀sì Nlá àti ní àkókò Ogun Àgbáyé Kejì, Bud, bí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí ti í pè é, fi Utah sílẹ̀ ó sì kó lọ sí Los Angeles, Callifornia, láti lọ wá iṣẹ́. Ní àkókò tí ó kúrò ní ilé yi, ó gbé pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀, ẹnití nsìn bíi bíṣọ́pù ti wọ́ọ̀dù wọn.

Pẹ̀lú ìfẹ́ àti ipá arábìnrin rẹ̀ àti arákùnrin-nínú-òfin, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìwuni rẹ̀ jí nínú Ìjọ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní alaalẹ́ kí ó tó lọ sùn.

Ní alẹ́ kan, bí ó ti nkà nínú Almà orí 34, a fi ọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀ bí ó ti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

“Bẹ́ẹ̀ni, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó jáde wá kí ẹ má sì sé ọkàn yín le mọ́. …

“Nítorí ẹ kíyèsĩ, ìgbésí-ayé yĩ jẹ́ àkókò fún ènìyàn láti múra sílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; bẹ́ẹ̀ni, ẹ kíyèsĩ ọjọ́ ayé yĩ ni ọjọ́ fún ènìyàn láti ṣe àwọn iṣẹ́ wọn.”23

Bí ó ti nka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, ìmọ̀lára tó lágbára kan wá sí ara rẹ̀, ó sì mọ̀ pé òun níláti yípadà, láti ronúpìwàdà, ó sì mọ ohun tí ó gbọdọ̀ ṣe. Ó dìde kúrò ní orí ibùsùn rẹ̀ ó sì kúnlẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà, ní bíbẹ̀bẹ̀ sí Olúwa láti dáríjì í àti láti fún un ní okun tí ó nílò láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó nílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àdúrà rẹ̀ jẹ́ dídáhùn. Àti pé láti ìgbà náà lọ síwájú, kò bojú wẹ̀hìn rárá. Bud tẹ̀síwájú láti sìn nínú Ìjọ ó sì dúró bí olódodo, olùfọkànsìn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn títí dé òpin ayé rẹ̀. A yí i padà ní gbogbo ọ̀nà. Ìyè rẹ̀, ọkàn rẹ̀, àwọn ìṣe rẹ̀, wíwà rẹ̀ gan di yíyípadà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àyànmọ́ àtọ̀runwa àti èrèdí wa ni láti dàbí Baba wa Ọrun àti Olùgbàlà Jésù Krístì ní ìgbẹ̀hìn. A nṣe èyí bí a ti nyípadà tàbí ronúpìwàdà. A ngba “àwòrán ti Olùgbàlà nínú ìwò ojú [wa].”24 A ndi titun, mímọ́, yàtọ̀, a sì nfi ìrọ̀rùn tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́. Nígbà míràn ó le dàbí ìgbésẹ̀ méjì síwájú àti ìgbésẹ̀ kan sẹ́hìn, ṣùgbọ́n a ntẹ̀síwájú láti lati fi ìrẹ̀lẹ̀ sún síwájú nínú ìgbàgbọ́.

Bí a sì ti nrẹ ara wa sílẹ̀ tí a sì nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, oore ọ̀fẹ́ Krístì àti ẹbọ ètùtù àìlópin Rẹ̀ nmú kí ó ṣeéṣe fúnwa láti yípadà.

Mo ṣe ẹlẹ́ri mo sì jẹ́ ẹ̀ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa ní tòótọ́. Ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó ní tòótọ́. Mo kéde pé Òun ni, “ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè.”25 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.