Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fídíò: “Ẹ̀yin ni Àwọn Obìnrin tí Ó Rí Ṣíwájú”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Fídíò: “Ẹ̀yin ni Àwọn Obìnrin tí Ó Rí Ṣíwájú”

Ní 1979 Ààrẹ Spencer W. Kimball wà ní ilé-ìwòsàn ó sì bèèrè lọ́wọ́ ìyàwó rẹ, Camilla, láti ka ọ̀rọ̀ rẹ sí ìpàdé gbogbogbo àwọn obìnrin.

Arábìnrin Camilla Kimball: “Púpọ̀ nínú ìdàgbàsókè pàtàkì tí nbọ̀ sí Ìjọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn yíò dé nítorí pé ọ̀pọ̀ lára ​​àwọn obìnrin rere ayé (nínú àwọn tí irú ìmọ̀lára inú ti ẹ̀mí sábà máa nwà) ni a ó fà sínú Ìjọ náà ní iye púpọ̀. Èyí yío ṣẹlẹ̀ tó bí àwọn obìnrin Ìjọ bá ṣe fi ìrísí òdodo àti sísọ àsọyé hàn tó nínú ìgbé ayé wọn àti tó bí a bá ti rí àwọn obìnrin Ijọ bíi ẹni ọ̀tọ̀ àti yíyàtọ̀ sí—ní àwọn ọ̀nà ìdùnnú—kúrò nínú àwọn obìnrin ti ayé.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson: “Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ pàtàkì wa ní àkókò ìran tí nyí padà yìí, ọjọ́ tí Ààrẹ Kimball ti rí tẹ́lẹ̀ jẹ́ òní Ẹ̀yin ni àwọn obìnrin tí ó rí ṣíwájú! Ìwà rere, ìmọ́lẹ̀, ìfẹ́, ìmọ̀, ìgboyà, ìwà, ìgbàgbọ́, àti ìgbé ayé òdodo yín yíò fa àwọn obìnrin rere ti ayé, pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn, sí Ìjọ ní iye tí a kò rí rí!

“A … nílò okun yín, ìyípadà ọkàn yín, ìdánilójú yín, agbára yín láti darí, ọgbọ́n yín, àti àwọn ohùn yín. Ìjọba Ọlọ́run kò sì lè pé láìsí àwọn obìnrin tí wọ́n dá májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n sì pa wọ́n mọ́, àwọn obìnrin tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ Ọlọ́run! …

“… Eyikeyi ìpè yín, eyikeyi àwọn ipò yín, a nílò àwọn ìkúnnu yin, àwọn ìmọ̀ yín, àti àwọn ìmísí yín. A nílò yín lati sọ̀rọ̀ sókè àti sọ̀rọ̀ síta ninú àwọn ìgbìmọ́ wọ́ọ̀dù àti ti èèkàn. A nílò arábìnrin kọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣègbéyàwó láti sọ̀rọ̀ bí ‘ alájọṣepọ̀ kan àti ní kíkún ’ bí ẹ ti darapọ̀ pẹ̀lú ọkọ yín nínú ìṣàkóso ẹbí yín. O ṣe ìgbéyàwó tàbí o dáwà, ẹ̀yin obìnrin ni àwọn agbára ti o yàtọ̀ àti ìmọ̀ inú pàtàkì ti ẹ ti gbà bí àwọn ẹ̀bún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwa arakùnrin ko le ṣe ẹ̀dà ipa àrà ọ̀tọ̀ yín.

“A mọ̀ pé ìparí ìṣe ti gbogbo ìṣẹ̀dá ni ìṣẹ̀dá obìnrin! A nílò okun yín! …

“… Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yin, ẹ̀yin arabìnrin mi ọ̀wọ́n, mo sì bùkún yín láti dìde si kíkún ojú ìwọ̀n yín, láti mú ìwọ̀n ìṣẹ̀dá yín ṣẹ, bí a ṣe nrìn ní apá nínú apá nínú iṣẹ́ mímọ́ yí. Lápapọ̀ a ó ṣèrànwọ láti pèsè ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa.”2

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball (2006), 222–23.

  2. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” Ensign tàbí Liahona, Nov. 2015, 96, 97.