Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìròhìn Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò Ohun-ìní Ìjọ, Ọdún 2021
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìròhìn Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò Ohun-ìní Ìjọ, 2021

Sí Àjọ Ààrẹ Kínní ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Ẹ̀yin Arákùnrin Ọ̀wọ́n: Ní dídarí nípa ìfihàn, bí a ṣe kọ́sílẹ̀ nínú ipín 120 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Ìgbìmọ̀ lórí Lílo àwọn Idamẹwa—tí ó jẹ́ àkópọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, àti Àjọ Bíṣọ́pù Alákòóso—fi àṣẹ sí níná àwọn owó Ìjọ. Àwọn ẹka Ìjọ ngbé owó jáde ní ìbámu sí àwọn ìṣúná tí a fi ọwọ́ sí, àwọn ìṣètò, àti àwọn ìlànà.

Jíjẹ́rí Ìṣírò Ohun-ìní Ìjọ, èyí tí ó ní àkópọ̀ àwọn akọ́ṣẹmọṣẹ tí wọ́n ní ìwé ẹ̀rí, tí ó sì wà ní òmìnira kúrò ní gbogbo àwọn ẹ̀ka Ìjọ míràn àti ile-iṣẹ àdáwà, ní ojúṣe láti ṣe ìjẹ́rìí ìṣírò ohun-ìní fún èrò ti pípèsè ìdánilójú tó nítumọ̀ nípa àwọn ìdáwó tí a gbà, ìnáwó tí a ṣe, àti dídá-ààbò bo àwọn ohun ìní Ìjọ.

Ní dídá lórí ìjẹ́rí ìṣírò ohun-ìní tí a ṣe, Ẹka Jíjẹ́rí Ìṣírò Òhun-ìní ti Ìjọ ní èrò pé, ní gbogbo ọ̀nà tí ó ṣe kókó, ìdáwó tí a gbà, ìnáwó tí a ṣe, àti àwọn ohun-ìní Ìjọ fún ọdún 2021 ní a ti kọ sílẹ̀ tí a sì ti lò ní ìbámu sí àwọn ìṣúná Ìjọ tí a fi ọwọ́ sí, àwọn ìṣètò, àti àwọn ìṣesí ìṣírò síṣe. Ìjọ tẹ̀lé àwọn ìṣesí tí a kọ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ti gbígbé ní ààrin ìṣúná-owó, yíyẹra fún gbèsè, àti fífi-pamọ́ fún ìgbà àìní kan.

Ní gbígbé kalẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀.

Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò Ohun-ìní Ìjọ

Jared B. Larson

Olùdarí Àgbà