Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹnìkọ̀ọ̀kan Wa Ní Ìtàn kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ẹnìkọ̀ọ̀kan Wa Ní Ìtàn kan

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá wá ẹbí yín rí, gbogbo àwọn ìran yín, kí ẹ sì mú wọn wá sílé.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́, arákùnrin àti arábìnrin, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìtàn kan. Bí a ṣe nṣe ìwákiri ìtàn wa, à nsopọ̀, à nwà pẹ̀lú, à ndà.

Orúkọ mi ni Gerrit Walter Gong. Gerrit jẹ́ orúkọ Dutch, Walter (orúkọ baba mi) jẹ́ orúkọ Amẹ́ríkà, àti pé bẹ́ẹ̀ni Gong jẹ́ orúkọ Chinese.

Àwọn amoye ṣírò bíllíọ́nù àádọ́rin sí àádọ́fà ènìyàn tí wọ́n ti gbé lórí ilẹ̀-ayé. Bóyá ọ̀kan nìkan ní a sọ lórúkọ Gerrit Walter Gong.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan Wa Ní Ìtàn kan. Mo fẹ́ràn “òjò lórí ojú mi [àti] afẹ́fẹ́ bí ó ti nyára kọjá.”1 Mo nyí-bírí pẹ̀lú àwọn pẹ́ngúìnì ní Antarctica. Mo nfún àwọn ọmọ-òrukàn ní Guatemálà, àwọn ọmọ ìgboro ní Cambodia, àwọn obìnrin Masai ní Mára Áfríkà ní fọ́tò àkọ́kọ́ ti ara wọn fúnra wọn gan.

Mo dúró ní ilé-ìwòsàn bí a ṣe nbí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wa—nígbàtí dókítà ti ràn mí lọ́wọ́.

Mo gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run. Mo gbàgbọ́ “[a] wà, kí [a] lè ní ayọ̀,”2 pé àwọn ìgbà àti àkokò wà sí ohungbogbo lábẹ́ ọ̀run.3

Ṣé ẹ mọ ìtàn yín? Ohun tí orúkọ yín túmọ̀ sí? Oye ayé gbèrú láti àwọn ènìyàn bíllíọ̀nù 1.1 ní 1820 sí bíi bíllíọ̀nù 7.8 ní 2020.4 Ọdún 1820 dàbí àmì ìkọlù kan nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí a bí lẹ́hìn 1820 ní ìrántí gbígbé àti àwọn àkọsílẹ̀ láti dá onírurú àwọn ẹbí mọ̀. Njẹ́ ẹ lè rònú nípa pàtàkì, ìrántí dídùn pẹ̀lú òbí-òbí tàbí ọmọ ẹbí míràn?

Ohunkóhun tí oye àkópọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan tí àwọn tí ó ngbé lórí ilẹ̀-ayé lè jẹ́, ó jẹ́ àìlópin, ṣíṣírò, ẹnìkan ní ìgbà kan. Ẹ̀yin àti èmi, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ṣe pàtàkì.

Jọ̀wọ́ yẹ èyí wò: bóyá a mọ̀ wọ́n, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ni a bí nípasẹ̀ ìyá àti baba. Ìyá kọ̀ọ̀kan àti baba ni a bí nípa ìyá kan àti baba.5 Nípa ìbí tàbí ìran àgbàtọ́, gbogbo wa ní ìsopọ̀ nígbẹ̀hìn nínú ẹbí ènìyàn àti ẹbí Ọlọ́run.

A bi ní 837 A.D., baba-baba mi àgbà ọgbọ̀n, Dragon Gong Àkọ́kọ́, bẹ̀rẹ̀ abúlé ẹbí wa ní gúsù China. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bẹ abúlé Gong wò, àwọn ènìyàn wípé, “Wenhan huilaile”” (“Gerrit ti dé”).

Ní ẹ̀gbẹ́ ti ìyá mi, igi ẹbí wa tó wà láàyè wà pẹ̀lú ẹgbẹẹ̀rún àwọn orúkọ ẹbí, pẹ̀lú púpọ̀ si láti wárí.6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní ẹbí si pẹ̀lú ẹnití a níláti sopọ̀. Bí ẹ bá rònú pé àùntí-àgbà ti parí gbogbo ìtàn ẹbí yín, ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá àwọn ìbátan yín àti ìbátan ti àwọn ìbátan. Ẹ so ìrántí orúkọ ẹbí alààyè yín papọ̀ pẹ̀lú bíllíọ́nù mẹwa àwọn orúkọ wíwákiri ÌwákiriẸbí nísisìyí ní orí àpapọ̀ ayélujára rẹ̀ àti ọ̀kọ̀ọ̀kan bíllíọ̀nù 1.3 nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan Igi Ẹbí rẹ̀.7

Àwòrán
Igi ààyè pẹ̀lú àwọn gbòngbò àti ẹ̀ká

Ní kí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí ya igi ẹbí. Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, igi ààyè ní àwọn gbòngbò àti àwọn ẹ̀ká.8 Bóyá ẹ jẹ́ àkọ́kọ́ tiyín tàbí ìran mímọ̀ kẹwa, tí a sopọ̀ ní àná fún ọ̀la. So àwọn gbòngbò àti ẹ̀ká nínú igi ẹbí alààyè yín pọ̀.9

Ìbèèrè náà “Níbo ni ẹ ti wá?” ẹ bèèrè ìran, ibi-ìbí, ilẹ̀ orílẹ̀-èdè tàbí ìlú. Káàkiri, ìdá marundinlogun lára wa nwá ìlú wa lọ sí China, ìdá mẹ́tàlélógún sí India, ìdá mẹ́tàdínlógún sí àwọn Asia Pacific míràn, ìdá méjìdínlógún sí Europe, ìdá mẹwa sí Africa, àti ìdá méje sí àwọn America.10

Ìbèèrè náà “Níbo ni ẹ ti wá?” bákannáà ni ó pe wá láti ṣe àwárí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá tiwa àti ti èrèdí ti-ẹ̀mí nínú ayé.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìtàn kan.

Ẹbí kan tí mo mọ̀ so ìran ẹbí marun pọ̀ nígbàtí wọ́n bẹ ilé wọn àtijọ́ wò ní Winnipeg, Canada. Níbẹ̀ babanlá wì fún àwọn ọmọ-ọmọkùnrin rẹ̀ nípa ọjọ́ tí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere (ó pè wọ́n ní ángẹ́lì láti ọ̀run) mú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì wá, tí ó yí ẹbí wọn padà títíláé.

Ìyá kan tí mo mọ̀ pè àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìbátan wọn láti bèèrè ìyá-ìyá-nlá wọn nípa àwọn ìrírí ìgbà èwe rẹ̀. Àwọn ṣeréṣeré ìyá-ìyá-àgbà àti àwọn ẹ̀kọ́ ayé ti ìwé ẹbí tí a pọ́nlé nísisìyí nda àwọn ìràn mẹrin pọ̀.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí mo mọ̀ nto “Ìwé-ìròhìn Baba papọ̀.” Ní àwọn ọdún ṣẹ́hìn, ọkọ̀ kan kọlu ó sì pa baba rẹ̀. Nísisìyí, láti mọ baba rẹ̀, akọni ọ̀dọ́mọkùnrin yí ndá ààbò bo ìrántí ìgbà èwe àti àwọn ìtàn láti ọ̀dọ̀ ẹbí àti ọ̀rẹ́.

Nígbàtí a bèèrè ibití ìtumọ̀ ti nwá, púpọ̀ àwọn ènìyàn fi ẹbí sí ipò àkọ́kọ́.11 Èyí pẹ̀lú ẹbí alààyè àti àwọn tí wọ́n ti lọ ṣíwájú. Bẹ́ẹ̀ni, nígbàtí a ba kú, a kò ní dáwọ́ wíwà dúró. A tẹ̀síwájú láti gbé ní ẹ̀gbẹ́ òdìkejì ti ìkelè.

Síbẹ̀síbẹ̀ wíwà láàyè gan an, àwọn babanlá wa lẹtọ jíjẹ́ rírántí.12 A nrántí ogún wa nípasẹ̀ àwọn àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹnu, àkọsílẹ̀ àwọn ìdílé àti ìtàn ẹbí, àwọn ìrántí tàbí ibi rírántí, ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn fọ́tò, oúnjẹ, tàbí àwọn ohun èlò èyí tí ó nránwalétí nípa àwọn olólùfẹ́.

Ẹ ronú nípa ibi tí ẹ ngbé—njẹ́ èyí kìí ṣe ìyanilẹ́nu bí orílẹ̀-èdè yín àti ìletò nrántí wọ́n sì nbu-ọlá fún àwọn babanla, ẹbí, àwọn míràn tí wọ́n ti sìn tí wọ́n sì rúbọ? Fún àpẹrẹ, ní ìgbà ìrántí ìkórè ní Gúsù Moulton, Devonshire, England, Arábìnrin Gong àti èmi fẹ́ràn wíwá ìjọ kékeré àti ìletò níbití àwọn ìran àwọn ẹbí Bawden wa ngbé. A nbu-ọlá fún àwọn bàbànlá nípa ṣíṣí àwọn ọ̀run nípasẹ̀ tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ àkọọ́lẹ-ìtàn ẹbí13 àti nípa dída ẹ̀dà ìsopọ̀14 nínú ẹ̀gbà àwọn ìran wa.15

Ní ìgbà yí ti “Mo yan èmi,” àwọn àwùjọ njèrè nígbàtí àwọn ìran nsopọ̀ ní àwọn ọ̀nà onítumọ̀. A nílò àwọn gbòngbò láti ní ìyẹ́—àwọn ìbáṣepọ̀ gidi, iṣẹ́-ìsìn onítumọ̀, igbé-ayé kíkọjá títóbi ẹ̀hìn ìròhìn àwùjọ.

Sísopọ̀ pẹ̀lú àwọn bàbànlá lè yí àwọn ìgbé-ayé wa padà ní àwọn ọ̀nà ìyanu. Láti inú àwọn àdánwò àti àṣeyọrí, à njèrè ìgbàgbọ́ àti agbára.16 Látinú ìfẹ́ wọn àti ìrúbọ, a kọ́ láti dáríjì àti láti tẹ̀síwájú. Àwọn ọmọ wa di fífaradà. A njèrè ìdá-ààbò-bò àti agbára. Síso pẹ̀lú àwọn babanla nmú sísúnpọ̀ ẹbí, ìmoore, iṣẹ́-ìyanu pọ̀si. Irú síso bẹ́ẹ̀ lè mú ìrànlọ́wọ́ láti òdikejì ìbòjú wá.

Gẹ́gẹ́bí ayọ̀ ṣe nwá nínú àwọn ẹbí, bẹ́ẹ̀ni ìbànújẹ́. Kò sí ẹnìkankan tí ó pé, tàbí ẹbí kankan. Nígbàtí àwọn tí ó yẹ kí wọ́n nifẹ́, tọ́, àti dá ààbò bò wá bá kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, à nní ìmọ̀lára ìpatì, ìdójútì, ìpalára. Ẹbí lè di ìkarahun òfo. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀run, a lè wá láti mọ ẹbí wa kí a sì wà ní àláfíà pẹ̀lú arawa.17

Nígbàmíràn ìfarasìn àìyẹsẹ̀ sí ìbáṣepọ̀ ìbágbé ẹbí nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí àwọn ohun líle. Ní àwọn ọ̀ràn kan, ìletò ndi ẹbí. Ọ̀dọ́mọbìnrin olókìkí kan ẹnití ẹbí rẹ̀ tí ó ndàmú nkólọ lemọ́lemọ́ nrí olùfẹ́ni ẹbí Ìjọ níbikíbi tí ó bá wà láti tọ́ àti láti fún un ní ààyè rẹ̀. Àwòṣe ẹbí àti ìbátan nfúnni-lágbára ṣùgbọ́n kò pinnu wa.

Ọlọ́run nfẹ́ kí inú àwọn ẹbí dùn àti títíláé. Títíláé ti gùn jù bí a kò bá nmú inú arawa dùn. Ìnúdídùn kúrú jù bí ìṣìkẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀ bá dúró ní ayé yí. Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́, Jésù Krístì fúnni ní ìfẹ́, àti oore-ọ̀fẹ́ láti yí wa padà18 àti láti wo àwọn ìbáṣepọ̀ wa sàn. Iṣẹ́-ìsìn àìní-ìmọtaraẹni-nìkan tẹ́mpìlì fún àwọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n nmú Ètùtù Olùgbàlà wa jẹ́ òtítọ́ fún wa àti fún wọn. Ní yíyàsímímọ́, a lè padà sílé sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹbí ní ìrẹ́pọ̀ ayérayé.21

Ìtàn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni ìrìnàjò tí ó ṣì wà ní ìlọsíwájú, bí a ti nṣe àwárí, dásílẹ̀, kí a sì di ìṣeéṣe pẹ̀lú kíkọjá òye.

Wòlíì Joseph Smith wípé, “ó lè dàbí ẹ̀kọ́ híhàn gidi tí à nṣọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn kan nípa—agbára èyí tí ó nkọsílẹ̀ tàbí sopọ̀ lórí ilẹ̀-ayé tí ó sì nsopọ̀ ní ọ̀run.”22 Àwùjọ tí à ndásílẹ̀ nihin lè wà pẹ̀lú ògo ayérayé níbẹ̀. Nítòótọ́, “àwà láìsí [àwọn ọmọ ẹbí wa] kò lè di pípé; bẹ́ẹ̀ni wọn ko lè di pípé láìsí wa,” ìyẹn ni, nínú “gbogbo ìrẹ́pọ̀ ìparí àti pípé.”24

Kíni a lè ṣe nísisìyí?

Àkọ́kọ́, ẹ wo àwòràn yín ní ríronú sẹ́hìn àti síwájú ní àárín àwọn jígí méjì ti àìlópin. Ní ìdarí kan, ẹ wò àwòrán ara yín bí ọmọbìnrin, ọmọ-ọmọbìnrin, ọmọ-ọmọ-ọmọbìnrin; ní ìdarí míràn, rẹrin sí ararẹ̀ bí àùntí, ìyá, ìyá-ìyá. Àkokò sì nlọ kíákíá Ní ìgbà àti ojúṣe kọ̀ọ̀kan, ẹ ṣe àkíyèsí ẹni tí ó wà pẹ̀lú yín. Ẹ kó àwọn fọ́tò àti ìtàn wọn jọ; àwọn ìwé ìròhìn, mú àwọn ìrántí jẹ́ òdodo. Ẹ kọ àwọn orúkọ wọn, ìrírí, kókó ọjọ́ sílẹ̀. Wọ́n jẹ́ ẹbí yín—ẹbí tí ẹ ní àti ẹbí tí ẹ fẹ́.

Bí ẹ ti nṣe ìlànà tẹ́mpìlì fún àwọn ọmọ ẹbí, ẹ̀mí Èlíjàh, “ìfihàn Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó njẹ́ ẹ̀rí nípa ìwà-ẹ̀dá ẹbí,”25 yíò so ọkàn baba, ìyá, àti ọmọ yín papọ̀ nínú ìfẹ́.26

Ìkejì, ẹ jẹ́ kí ṣeréṣeré ti àkọ́ọlẹ̀-ìtàn ẹbí jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ àti kíákíá. Ẹ pe ìyá-ìyá yín. Wò jinlẹ̀-jinlẹ̀ sínú ojú ọmọ titun náà. Mú àkokò—ẹ ṣe àwárí àìlópin—ní ipele kọ̀ọ̀kan ti ìrìnàjò ayé yín. Ẹ kọ́ kí ẹ sì jẹ́wọ́ pẹ̀lú ogún ìmoore àti ìwà-mímọ́ ẹbí yín. Ẹ ṣe ayẹyẹ kí ẹ sì di dídára àti, níbí ìnílò, fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe gbogbo ohun tí ó ṣeéṣe láti máṣe sún àìdára síwájú. Ẹ jẹ́ kí àwọn ohun rere bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú yín.

Ìkẹ́ta, ẹ bẹ FamilySearch.org wò. Gba àwọn áàpù àgbéká tí ó wa sílẹ̀. Wọ́n jẹ́ ọ̀fẹ́ àti ìṣeré. Ṣe àwárí, sopọ̀, wà pẹ̀lú. Ẹ wo bí ẹ ti bá àwọn ènìyàn mu nínú yàrá kan, bí ó ti rọrùn àti fífi-èrè fun láti fikún àwọn orúkọ sí igi ààyè ẹbí yín, láti wá àti bùkún àwọn gbòngbò àti ẹ̀ká yín.

Ìkẹ́rin, ṣèrànwọ́ láti da ẹbí pọ̀ fún ayérayé. Rántí àwọn àdámọ̀ ti ọ̀run. Àwọn púpọ̀ si ní ẹ̀gbẹ́ míràn ti ìkelè ju ní ẹ̀gbẹ́ yí. Bí àwọn tẹ́mpìli ṣe nsúnmọ́ wa si, ní ibi púpọ̀ si, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún àwọn tí wọ́n ndúró fún àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ní ànfàní láti gba wọn.

Ìlérí ní ìgbà àjínde àti nígbàgbogbo ni pé, nínú àti nípasẹ̀ Jésù Krístì, a lè di ìtàn dídárajù tiwa àti pé àwọn ẹbí wa sì lè di onínúdídùn àti títíláé. Nínú gbogbo àwọn ìran wa, Jésù Krístì nwò àwọn oníròbìnújẹ́ ọkan sàn, ó ngba olùgbẹ̀kùn là, ó ntú àwọn tí a palara sílẹ̀.27 Májẹ̀mú tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run àti ara wa28 wà pẹlú mímọ pé ẹ̀mí àti ara wa yíò dàpọ̀ ní àjìnde àti pé àwọn ìbàṣepọ̀ oníyelórí jùlọ wa lè tẹ̀síwájú kọjá ikú pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀.29

Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìtàn kan. Ẹ wá ṣe àwárí tiyín. Ẹ wá rí ohùn yín, orin yín, ìbámu yín nínú Rẹ̀. Èyí ni èrèdí gangan fún èyí tí Ọlọ́run fi dá àwọn ọ̀run àti ilẹ̀-ayé tí Ó sì ri pé ó dára.30

Ẹ yin ètò ìdùnnú Ọlọ́run, Ètùtù Jésù Krístì, ìtẹ̀síwájú ìmúpadàbọ̀sípò nínú ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá wá ẹbí yín rí, gbogbo àwọn ìran yín, kí ẹ sì mú wọn wá sílé. Ní orúkọ ọ̀wọ̀ àti mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Baba Mi Ọ̀run Nifẹ Mi,” Children’s Songbook, 228–29.

  2. 2 Nephi 02:25.

  3. Wo Ecclesiastes 3:1.

  4. Based on United Nations Secretariat, The World at Six Billion (1999), 5, table 1; “World Population by Year,” Worldometer, worldometers.info.

  5. Many are blessed to have parents who did not physically bear them, yet they are joined as family through bonds of affection and adoption and sacred sealing covenants.

  6. I express appreciation to those who are piloting ways to organize large numbers of family names into family trees.

  7. In 2021, some 99 million names were added to public family trees. And recently, digitization was completed of 2.4 million rolls of microfilm containing approximately 37 billion names (with some duplications). These individual name records can now be prepared to be searched, found, and added to the family tree of humanity.

  8. Wo Russell M. Nelson, “Roots and Branches,” Liahona, May 2004, 27–29.

  9. Bẹ́ẹ̀ni, as we discover and build our living family tree, please maintain 100 percent respect for the privacy and volunteer participation of family members, living and deceased.

  10. David Quimette extrapolated these numbers, based on Angus Maddison, The World Economy: A Millennial Perspective (2001), 241, table B-10.

  11. Wo Laura Silver, et al., “Kíni Ó Nmú Ìgbé Ayé Nítumọ̀? Views from 17 Advanced Economies,” Pew Research Center, Nov. 18, 2021, pewresearch.org.

  12. 1 Nephi 9:5; 1 Nephi 19:3; Words of Mormon 1:6–7; and Alma 37:2 speak of keeping records and remembering “for a wise purpose,” including to bless future generations.

  13. Wo Russell M. Nelson and Wendy W. Nelson, “Ṣíṣí Ọ̀run nìpasẹ̀ Tẹ́mpìlì àti Iṣẹ́ Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí,” Ensign, Oct. 2017, 34–39; Liahona, Oct. 2017, 14–19; see also “RootsTech Family Discovery Day—Opening Session 2017” (video), ChurchofJesusChrist.org.

  14. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:18.

  15. Wo Gordon B. Hinckley, “Keep the Chain Unbroken” (Brigham Young University devotional, Nov. 30, 1999), speeches.byu.edu. Ààrẹ Hinckley is also quoted in David A. Bednar, “A Welding Link” (worldwide devotional for young adults, Sept. 10, 2017), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org.

  16. Fún àpẹrẹ nínú ẹbí wa, Henry Bawden, from Devonshire, England, married Sarah Howard, who emigrated with her family after they joined the Church. While Sarah was in St. Louis as a young teenager, her father, mother, and five siblings died. Henry and Sarah had 10 children. Sarah also raised six children of Henry’s first wife, Ann Ireland, after she died. Sarah was also mother to two young granddaughters after her (Sarah’s) daughter-in-law passed away. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpènijà ayé, Sarah was warm, loving, compassionate, and of course very hard working. Òun jẹ́ affectionately known as “Little Grandma.”

  17. Bí ó ti wù kí ó le tó, as we forgive ourselves and each other with Christ’s help, we become “the children of God” (Matthew 5:9).

  18. Fún àpẹrẹ, wo, Mosiah 3:19.

  19. Wo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” ChurchofJesusChrist.org.

  20. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128:9.

  21. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 130:2.

  22. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128:18.

  23. Russell M. Nelson, “A New Harvest Time,” Ensign, May 1998, 34; see also Russell M. Nelson and Wendy W. Nelson, “Open the Heavens through Temple and Family History Work,” 16–18.

  24. Wo Mòsíàh 18:21.

  25. Wo Lúkù 4:18.

  26. A sọ ọ̀rọ̀ Hébérù fún ẹbí fún mi—mishpachah—comes from a Hebrew root word (shaphahh) meaning “to join or bind together.” Gbogbo ojúṣe nínú ẹbí ni designed to strengthen family bonds.

  27. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:15–16, 34; 93:33, 138:17.

  28. Wo Gẹ́nẹ́sísì 1:4, 31.