Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ fún ìmúdúró.

Ẹ jọ́wọ́ e fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Kristì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè fihàn bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, bí èyíkéyi bá wá, nípa irú àmì kannáà.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ti dásílẹ̀ nínú àwọn ìfúni-níṣe wọn: Mark D. Eddy, Ryan K. Olsen, Jonathan S. Schmitt, àti Denelson Silva.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin wọn tó tayọ, jọ̀wọ́ fihàn.

A nawọ́ àwọn ìdásílẹ̀ sí Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbò láti bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹ́jọ, 2022, bí ìwọ̀nyí: Jean B. Bingham bí Ààrẹ, Sharon Eubank Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Reyna I. Aburto bí Olùdámọ̀ràn Keji.

A ti nawọ́ ìdásílẹ̀ sí Àjọ Ààrẹ Alakọbẹ̀rẹ̀ Gbogbogbò, èyí tí yíò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ, 2022, bí ìwọ̀nyí: Camille N. Johnson bí Àarẹ, Susan H. Porter bí Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Amy Wright bí Olùdámọ̀ràn Kejì.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arábìnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin olùfọkànsìn, jọ̀wọ́ fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Àádọ́rin Gbogbogbò wọ̀nyí: Mark D. Eddy, James W. McConkie III, Isaac K. Morrison, Ryan K. Olsen, Jonathan S. Schmitt, àti Denelson Silva.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A ṣe àkíyèsí pé àwọn Àádọ́rin Agbègbè marundinlaadọ́ta ni a múdúró nínú àwọn ìpàdé olórí àpapọ̀ gbogbogbò ní Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ́n Oṣù Kẹ́ta, lẹ́hìnnáà wọ́n kéde sí orí newsroom.ChurchofJesusChrist.org ṣíwájú ní ọ̀sẹ́ yí.

A pè yín láti ṣe ìmúdúró wọn nínú ìfúnni-níṣe titun wọn.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbò titun, láti bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ, 2022: Camille N. Johnson Bí Ààrẹ, Jeannie Anette Dennis bí Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Kristin Mae Yee bí Olùdámọ̀ràn Kejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba kí a ṣe ìmúdúró àwọn wọ̀nyí bí Àjọ Ààrẹ Alakọbẹ̀rẹ̀ Gbogbogbò, bákannáà láti bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ, 2022: Susan H. Porter bí Ààrẹ, Amy Eileen Wright bí Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Tracy Y. Browning bí Olùdámọ̀ràn Kejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, bí ọ̀kankan bá wà.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.

Elzimar Gouvêa de Albuquerque, Roland J. Bäck, Raúl Barrón, Bruno V. Barros, Eric Baxter, Oscar Bedregal, Joep Boom, Michael P. Brady, Randall A. Brown, Kennedy F. Canuto, Stephen K. Christensen, Nathan A. Craig, Mark Anthony Dundon, Favio M. Durán, Amândio A. Feijó, Claude R. Gamiette, Scott L. Hymas, Jason C. Jensen, Roberto G. F. Leite, John W. Lewis, Paulo Renato Marinho, Blaine R. Maxfield, Eduardo R. Mora, David Ngabizele, João Luis Oppe, Justice N. Otuonye, Emanuel Petrignani, Daniel Piros, Craig W. J. Raeside, Nelson Ramírez, Alexey V. Samaykin, Jose Antonio San Gabriel, Jose Estuardo Sazo, Steven D. Shumway, Oswaldo J. Soto, Mark G. Stewart, Scott N. Taylor, Roseveltt de Pina Teixeira, Gordon L. Treadway, Harold Truque, Nikolai Ustyuzhaninov, Carlos Ernesto Velasco, Kyle A. Vest, Sergio Villa, Min Zu Wang