Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìsisìyí Ni Wákàtí Náà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìsisìyí Ni Wákàtí Náà

Ìsisìyí ni àkókò tí a lè kọ́ ẹ̀kọ́. Ìsisìyí ni àkókò tí a lè ronúpìwàdà. Ìsisìyí ni àkókò tí a lè kọ́ ẹ̀kọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ìpàdé àpapọ̀ nlá yí ti jẹ́ ohun ìtàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. A ti di alábùkúnfún nípa àwọn àdúrà, àwọn ọ̀rọ̀, àti orin tí wọ́n ti fifúnni. A ti gba ìmísí lati ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa.

A ti gba àwọn ìtọ́ni pàtàkì fún ọjọ́ iwájú. Àdúrà mi ni pé Ẹ̀mí ti báa yín sọ̀rọ̀ tààrà nípa àwọn ohun tí Olúwa yío fẹ́ kí ṣe.

Ọjọ́ iwájú máa nfi ìgbà gbogbo jẹ́ àìdánilójú. Ojú ọjọ́ nyípadà. Àwọn ìyípo ètò ọrọ̀ ajé kò ṣeé sọ-tẹ́lẹ̀. Àwọn àmúwá àdánidá àjálù, ìjàmbá, àti àìsàn le yí ìgbé ayé padà kíákíá. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kọjá ìṣàkóso wa. Ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà tí a le ṣe àkóso, nínú rẹ̀ ni bí a ti nlo àkókò wa ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Mo fẹ́ràn ewì yí láti ọwọ́ Henry Van Dyke, tí a gbé sórí ònkà wákàtí nípa òjìji òòrùn kan ní Wells College ní New York. Ó kà pé:

Òjìji tí ó jáde nípa ìka mi

Pín ọjọ́ iwájú kúrò lára ìkọjá:

Ṣaájú rẹ̀, ni wákàtí tí a kò tíì bí nsùn,

Nínú òkùnkùn, àti ìkọjá agbára rẹ.

Lẹ́hìn ìlà rẹ̀ tí kìí padà,

Wákàtí tó ti pòórá náà, kì í ṣe tirẹ mọ́:

Wákàtí kan nìkan ni ó wà ní ọwọ́ rẹ,—

ÌSISÌYÍ náà lórí èyítí òjìji dúró lé.1

Bẹ́ẹ̀ni, a le kọ́ a sì níláti kọ́ ẹ̀kọ́ láti ara èyí tó ti kọjá, àti pé bẹ́ẹ̀ni, a le múra a sì níláti múra fún ọjọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n nísisìyí nìkan ni a lè ṣe é. Ìsisìyí ni àkókò tí a lè kọ́ ẹ̀kọ́. Ìsisìyí ni àkókò tí a lè ronúpìwàdà. Ìsisìyí ni àkókò tí a lè bùkún àwọn ẹlòmíràn kí a sì “gbé àwọn ọwọ́ tó rọ sókè.”2 Bí Mọ́mọ́nì ṣe gba ọmọ rẹ̀ Mórónì nímọ̀ràn, “Jẹ́kí a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú aápọn; …nítorítí a ní iṣẹ́ láti ṣe [nígbàtí] a wà nínú àgọ ara amọ̀ yĩ, kí àwa ó lè ṣẹ́gun ọ̀tá sí gbogbo ohun tí í ṣe òdodo, kí a sì fún ẹ̀mí wa ni ìsimi nínú ìjọba Olọ́run.”3

Ọ̀tá kò kì í sùn rárá. Báyi, àtakò yío ma fi ìgbàgbogbo wà sí òtítọ́. Mo ṣe àtúnsọ ẹ̀bẹ̀ mi láti òwúrọ̀ yí láti ṣe àwọn ohun wọnnì tí yío ṣe àlékún ìyára yín dáradára níti ẹ̀mí, ìgbéra èyí tí Alàgbà Dieter F. Uchtdorf nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, tí yíò mú yín sún síwájú la èyíkéyi àwọn ìpèníjà àti àwọn ànfàní tí ó bá wá já.

Ìyára dáradára ti-ẹ̀mí máa npọ̀ síi bí a ti njọ́sìn nínú tẹ́mpìlì tí a sì ndàgbà nínú òye wa nípa títóbi fífẹ̀ àti jíjìn àwọn ìbùkún tí a ngbà níbẹ̀. Mo rọ̀ yín láti tako àwọn ọ̀nà ti ayé nípa fífojú sùn sórí àwọn ìbùkún ayérayé ti tẹ́mpìlì. Àkókò yín níbẹ̀ nmú àwọn ìbùkún wá fún ayérayé,

Bí Ìjọ ti ndàgbà, a ntiraka láti tẹ̀lé ìgbésẹ̀ náà pẹ̀lú àwọn tẹ́mpìlì síi. Àwọn tẹ́mpìlì titun mẹ́rìnlélógójì ní wọ́n wà ní abẹ́ ànkọ́lé nísisìyí Àwọn púpọ̀ ni a ntúnṣe. Mo gbàdúrà fún àwọn ènìyàn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n nṣiṣẹ́ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ wọ̀nyí ní gbogbo àgbáyé.

Nínú ẹ̀mí àdúrà ìmoore, inú mi dùn láti kéde àwọn ètò wa láti kọ́ tẹ́mpìlì titun ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ibi wọ̀nyí: Wellington, New Zealand; Brazzaville, Republic of the Congo; Barcelona, Spain; Birmingham, United Kingdom; Cusco, Peru; Maceió, Brazil; Santos, Brazil; San Luis Potosí, Mexico; Mexico City Benemérito, Mexico; Tampa, Florida; Knoxville, Tennessee; Cleveland, Ohio; Wichita, Kansas; Austin, Texas; Missoula, Montana; Montpelier, Idaho; àti Modesto, California.

Àwọn tẹ́mpìlì mẹ́tàdínlógún wọ̀nyí yíò bùkún àìníye ìgbésí ayé ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkele. Mo fẹ́ràn yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n. Ní pàtàkì jùlọ, Olúwa fẹ́ràn yín. Òun ni Olùgbàlà yín àti Olùràpadà yín. Ó ndarí ó sì ntọ́ Ìjọ Rẹ̀. Njẹ́ kí àwa le jẹ́ ènìyàn tí ó yẹ fún Olúwa, ẹnití ó sọ pé, “Ẹ̀yin ó jẹ́ ẹnìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín.”4

Fún èyí ni mo gbàdúrà ni orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.