Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Títẹ̀lé Jésù: Jíjẹ́ Onílàjà kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Títẹ̀lé Jésù: Jíjẹ́ Onílàjà kan

Àwọn onílàjà kìí ṣe olùpalọ́lọ́; wọ́n ní ìyíni-lọ́kàn pada ní ọ̀nà Olùgbàlà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, bí a ṣe nní ìrírí àwọn ọjọ́ ẹ̀rù ti ìdàmú, ìjà, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìjìyà tó jinlẹ̀, ọkàn wa kún fún ìmoore bíbonimọ́lẹ̀ fún Olùgbàlà wa àti àwọn ìbùkún ayérayé ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. A nifẹ a sì gbẹ́kẹ̀lé E, a sì ngbàdúrà pé a ó tẹ̀le E títíláé.

Ìpènijà Ìròhìn Àwùjọ

Ìfaragbá alágbára ti ayélujára ní ìbùkún àti ìpènijà, tí ó yàtọ̀ sí àkokò wa.

Nínú ayé ìròhìn àwùjọ àti àlàyé òpópónà-dídárajùlọ, ohùn ẹnìkan lè dipúpọ̀si lọ́pọ̀lọpọ̀. Ohùn náà, bóyá òtítọ́ tàbí irọ́, bóyá dídára tàbí ẹ̀tàn, bóyá ìwàrere tàbí ìwàburúkú, nrìn kiri ayé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Àwọn àlẹ̀mọ́ ìròhìn àwùjọ ti níní-àníyàn àti inúrere jẹ́jẹ́ nígbàkugbà wà lábẹ́ rédà, nígbàtí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ìbínú nsán-àrá léraléra nínú etí wa, bóyá pẹ̀lú ẹ̀kọ́ òṣèlú, àwọn ènìyàn nínú àwọn ìròhìn, tàbí àwọn èrò lórí àjàkálẹ̀-àrùn. Kò sí ẹni tàbí ẹ̀kọ́, pẹ̀lú Olùgbàlà àti ìmúpadàsípò ìhìnrere Rẹ̀, kúrò nínú àwọn ohùn àríyànjiyàn asán àwùjọ yí.

Dídà onílàjà

Ìwàásù lórí Òkè kìí ṣe ọ̀rọ̀ sí gbogbo àwọn ènìyàn ṣùgbọ́n tí a fún àwọn ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà nípàtàkì, àwọn tí wọ́n ti yàn láti tẹ̀lé E.

Olúwa kọ́ni bí a ṣe níláti gbé ìgbé-ayé, nígbànáà àti ìsisìyí, nínú ayé ìjà. Ó kéde pé,“Alábùkúnfún ni àwọn onílàjà,” “nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.”1

Nípa ìṣíji ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, a di onílàjà, ní pípa—títúmọ̀sí láti tura, farabalẹ̀, tàbí pa—gbogbo iná apanirun ti ọ̀tá.2

Bí a ṣe nsa ipa wa, ìlérí Rẹ̀ ni pé a ó pè wá ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé jẹ́ “ọmọ”3 Ọlọ́run, ṣùgbọ́n láti pè ní “ọmọ Ọlọ́run” túmọ̀sí púpọ̀, púpọ̀ síi. Bí a ti nwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì tí a sì ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀, à ndi “irú-ọmọ rẹ” àti “ajogún ìjọba,”4 “àwọn ọmọ Krístì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.”5

Báwo ni onílàjà ṣe ntura tí ó sì nfarabalẹ̀ pa idá apanirun? Dájúdájú kìí ṣe nípa sísúnkì níwájú àwọn wọnnì tí wọ́n nrẹ̀wásílẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀, kí a dúró ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìgbàgbọ́ wa, ní pípín ìgbàgbọ́ wa pẹ̀lú ìdánilójú ṣùgbọ́n kí a mú ìbínú tàbí ìkóríra kúrò nígbàgbogbo.6

Láìpẹ́, lẹ́hìn rírí èrò ọ̀rọ̀ líle kan tí ó lóminú nípa Ìjọ, Ẹni-ọ̀wọ̀ Amos C. Brown, olórí ẹ̀tọ́ ìbílẹ̀ ti orílẹ̀-èdè àti olùṣọ́ ti Ìjọ Baptist Kẹta ní San Francisco, fèsì pé:

“Mo bọ̀wọ̀ fún ìrírí àti ìwò ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì. Gbígbà bẹ́ẹ̀, èmì kò rí ohun tí óun nrí.”

“Mo kà á sí ọ̀kan lára ayọ̀ títóbijùlọ ìgbé-ayé láti mọ àwọn olórí [Ìjọ], pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson. Ní ìṣirò mi, wọ́n jẹ́, ara jíjẹ́-olórí dídárajùlọ tí orílẹ̀-èdè wa ní láti fúnni.”

Àwòrán
Ààrẹ Nelson pẹ̀lú Ẹni-ọ̀wọ̀ Brown

Lẹ́hìnnáà ó fikun pé: “A lè dúpẹ́ nípa ọ̀nà tí àwọn nkan ti wà. A lè kọ̀ láti jẹ́wọ́ gbogbo ohunrere tí ó nlọ lọ́wọ́ nísisìyí. … Ṣùgbọ́n àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí kò ní wo àwọn ìyapa orílẹ̀-èdè wa sàn. … Bí Jésù ti kọ́ni, a kò lè mú ibi kúrò pẹ̀lú ibi púpọ̀. À nifẹ pẹ̀lú inúrere a sì ngbé pẹ̀lú àánú, àní síwájú àwọn wọnnì tí a rò pé wọ́n jẹ́ ọ̀tá wa.”7

Ẹni-ọ̀wọ̀ Brown jẹ́ onílàjà. Ó fi ìtura àti pẹ̀lú ọ̀wọ̀ mú idà apanirun wálẹ̀. Àwọn onílàjà kìí ṣe olùpalọ́lọ́; wọ́n ní ìyíni-lọ́kàn pada ní ọ̀nà Olùgbàlà.8

Kíni ohun tí ó nfún wa ní agbára inú láti nítura, farabalẹ̀, kí a sì pa idá apanirun tí ó njó níwájú àwọn òtítọ́ tí a fẹ́ràn? Okun náà nwá látinú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì àti ìgbàgbọ́ wa nínú àwan ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

“Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin, nígbati àwọn ènìyàn bá nkẹgan yin, … tí wọn sì nfi èké sọ onirũru ohun búburú si yin, nitori mi.

“… Nítorí títóbi ni èrè yín ní ọ̀run: nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lépa àwọn wòlíì tí wọ́n wà ṣíwájú yín.”9

Pàtàkì Agbára Òmìnira

Àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ méjì pàtàkì tí ó ntọ́ àwọn ìfẹ́-inú wa sọ́nà làti jẹ́ onílàjà.

Àkọ́kọ́, Baba wa Ọ̀run ti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ọkùnrin tàbí obìnrin ni ìwà agbára òmínira, pẹ̀lú okun láti yan ipa-ọ̀nà ti ara ẹnìkan.10 Agbára òmìnira yí ni ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn títóbijùlọ ti Ọlọ́run.

Èkejì, pẹ̀lú agbára òmìnira yí, Baba wa Ọ̀run fi ààye gba “àtakò nínú ohun gbogbo.”11 Àwa “tán ìkorò wò, kí [a] lè mọ̀ láti díyelé rere.”12 Àtakò kò níláti yà wá lẹ́nu. À nkọ́ láti mọ ìyàtọ̀ rere àti ibi.

A yọ̀ nínú ìbùkún agbára òmìnira, níní-òye pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò wà tí kò gbàgbọ́ nínú ohun tí a gbàgbọ́. Nítòótọ́, díẹ̀ ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn yíò yàn láti mú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ oókan gbogbo ohun tí wọ́n nrò tí wọ́n sì nṣe.13

Nítorí àwọn ẹgbẹ́ ìròhìn àwùjọ, ohùn àìgbàgbọ́ kan lè hàn bí ọ̀pọ̀ ohùn àìdára,14 ṣùgbọ́n àní bí ó ti jẹ́ ọ̀pọ̀ ohùn, a yàn ipa-ọ̀nà onílàjà.

Àwọn Olórí ti Olúwa

Àwọn kan wo Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá bí níní àwọn ìgbèrò ayé, bíiti òṣèlú, ọrọ̀-ajé, àti àwọn olórí ọ̀làjú.

Bákannáà, a wá lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ láti ṣe àwọn ojúṣe. A kò dìbò-yàn wá tàbí yàn wá látinú ìbèèrèfúnṣẹ́. Láìsí kókó ìmúrasílẹ̀ amòye kankan, a pè wá a sì yàwásọ́tọ̀ láti jẹ́ ẹ̀rí ti orúkọ Jésù Krístì káàkiri ayé títí mímí ìgbẹ̀hìn wa. A máa nsapá láti bùkún àwọn aláìsàn, àwọn tó dá wà, àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì, àti àwọn òtòṣì àti láti fún ìjọba Ọlọ́run lókun. À nwá láti mọ ìfẹ́ Olúwa àti láti kéde rẹ̀, nípàtàkì sí a`wọn wọnnì tí wọ́n nwá ìyè ayérayé.15

Bíótilẹ̀jẹ́pé ìfẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ wa ni kí gbogbo ẹ̀nìyàn bu ọlá fún ẹ̀kọ́ Olùgbàlà, àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ sábà máa nlòdì sí ìrònú àti ìṣísẹ̀ ayé. Ó ti rí bẹ́ẹ̀ nígbàgbogbo.16

Olùgbàlà wí fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀:

“Bí ayé bá [korira] yín, ẹ̀yin mọ̀ pé ó korira mi ṣíwájú kí ó tó kórira yín. …

“… Àwọn ohun wọ̀nyí ni wọn yíò ṣe … nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.”17

Títọ́jú Gbogbo Ènìyàn

A ní ìfẹ́ òdodo a sì nṣètọ́jú fún gbogbo àwọn aladugbo wa, bóyá tàbí wọn kò gbàgbọ́ bí a ti ṣe. Jésù kọ́ wa nínú òwe ti Samaria Rere pé àwọn wọnnì ti wọ́n jẹ́ ti ìgbàgbọ́ tó yàtọ̀ níláti nawọ̀ jáde lododo láti ran gbogbo àwọn tí ó wà nínú àìní lọ́wọ́, jíjẹ́ onílàjà, lílépa àwọn èrò rere àti akọni.

Ní oṣù kejì, àkọlé kan nínú Arizona Republic sọ pé “òfin Bipartisan tí àwọn Ènìyàn Mìmọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ṣe àtìlẹhìn dá ààbò bo géè àti lákọlábo àwọn Arizonan.”18

Àwa, bí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, ní “inúdídùn láti jẹ́ ara ìṣọ̀kan ti ìgbàgbọ́, ọrọ̀-ajé, àwọn ènìyàn LGBTQ àti olórí ìletò tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ẹ̀mí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ọ̀wọ̀ kannáà.”19

Ààrẹ Russell M. Nelson nígbàkan fi níní-àníyàn bèèrè, “Ṣé ìlà ààlà lè wà láìsí dída ìlà ìjà?”20

A ngbìyànjú láti jẹ́ “ọmọlẹ́hìn àlááfíà Krístì.”21

Àwọn Àkokò Láti Máṣe Fèsì

Àwọn àtakò díẹ̀ lórí Olùgbàlà jẹ́ ìríra gidi pé Òun kò sọ ohunkan. . “Àwọn olórí àlùfáà àti akọ̀wé … fi ìgbóná-ara fẹ̀sùn kàn … wọ́n sì fi ṣẹ̀sín,” ṣùgbọ́n Jésù “kò dá [wọn] lóhùn.”22 Àwọn ìgbà kan wà nígbàtí jíjẹ́ onílàjà túmọ̀ sí pé à nkọ ìrọ́lù láti dáhùn àti dípò bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìwàtítọ́, dúró jẹ́jẹ́.23

Ó jẹ́ ìbaninínújẹ́ fún gbogbo wa nígbàtí wọ́n bá nsọ̀rọ̀ líle tàbí ìyọkúrò nípa Olùgbàlà, àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀ tàbí tẹ̀jáde nípasẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ti dúró pẹ̀lú wa nígbàkanrí, jẹ oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú wa, tí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wa nípa iṣẹ́ àtọ̀runwá Jésù Krístì.24

Èyí ṣẹlẹ̀ bákannáà lákokò iṣẹ́-ìránṣẹ́ Olùgbàlà.

Àwọn díẹ̀ lára ọmọẹ̀hìn Jésù tí wọ́n wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́-ìyanu ọlọ́lá jùlọ pinnu láti máṣe “[rìn] pẹ̀lú rẹ̀ mọ́.”25 Pẹ̀lú ìbànújẹ́, kìí ṣe gbogbo ẹni ni yíò dúró ṣinṣin nínú ìfẹ́ wọn fún Olùgbàlà àti ìpinnu wọn láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.26

Jésù kọ́ wa láti kúrò nínú agbo ìbínú àti ìjà. Nínú àpẹrẹ kan, lẹ́hìn tí àwọn Farisí dojúkọ Jésù tí wọ́n sì dámọ̀ràn bí wọ̀n ti lè pa Á run, ìwé-mímọ́ wí pé Jésù mú Ararẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ wọn,27 iṣẹ́-ìyanu sì ṣẹlẹ̀ bí “ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ṣe ntẹ̀le, ó sì wo gbogbo wọn sàn.”28

Bíbùkún Ìgbé-ayé àwọn Ẹlòmíràn

Àwa pẹ̀lú lè rìn kúrò nínú ìjà kí a sì bùkún àwọn ayé ẹlòmíràn,29 nígbàtí a kò bá ya arawa sọ́tọ̀ nínú igun ti arawa.

Ní Mbuji-Mayi, Ìjọba Olómìnira Tiwantiwa ti Congo, tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn díẹ̀ lominú nípa Ìjọ, láì ní òye ìgbàgbọ́ wa tàbí mímọ̀ àwọn ọmọ ìjọ.

Ìgbà díẹ̀ sẹ́hìn, Kathy àti èmi lọ sí ìsìn Ìjọ kan pàtàkì ní Mbuji-Mayi. Àwọn ọmọdé ni ó múra dáadáa, pẹ̀lú àwọn ojú dídán àti ẹ̀rín púpọ̀. Mo ti nírètí láti sọ̀rọ̀ sí wọn nípa ẹ̀kọ́ wọn ṣùgbọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò lọ sí ilé-ìwé. Àwọn olórí wa, pẹ̀lú oye owó aranilọ́wọ́ gidi, ti rí ọ̀nà kan láti ṣèrànwọ́.30 Ní báyìí, ju àwọn akẹkọ irínwó—àwọn ọmọdébìrin àti ọmọdékùnrin, àwọn ọmọ ìjọ ati àwọn tí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa—ní a kí káábọ tí a sì kọ́ nípasẹ̀ àwọn olùkọ́ mẹ́rìndílógún tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì.

Àwòrán
Kalanga Muya

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá Kalanga Muya wípé, “[Níní owó kékeré,] mo lo ọdún mẹ́rin láì lọ sí ilé-ìwé. … Mo fi ìmoore hàn fún ohun tí Ìjọ ti ṣe. … Nísisìyí mo lè ka, kọ, àti sọ French.”31 Sísọ̀rọ̀ nípa ìfilọ́lẹ̀ yí, alága Mbuji-Mayi wípé, “Èmi ní ìmísí nípasẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nítorí nígbàtí àwọn ìjọ [míràn] ọ̀kọ̀ọ̀kan nyapa ní igun rẹ̀ … [ẹ n ṣe iṣẹ́] pẹ̀lú [àwọn míràn] láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìletò nínú àìní.”32

Ẹ Nífẹ́ Ara Yín

Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá ka d John orí kẹtàlá, a rán mi létí nípa àpẹrẹ pípé Olùgbàlà bí onílàjà. Jésù wẹ ẹsẹ̀ àwọn Àpóstélì pẹ̀lú ìfẹ́. Lẹ́hìnnáà a kà pé “ó dàmú nínú ẹ̀mí rẹ̀,”33 bí Ó ti ronú nípa ẹnití Ó fẹ́ràn tí ó nmúrasílẹ̀ láti fi Í hàn. Mo ti ro àwọn èrò àti ìmọ̀lára Olùgbàlà bí Júdásì ti kúrò. Ní ìdùnmọ́ni, ní àkokò rírọlẹ̀, Jésù kò sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára “ìdàmú” tàbí nípa ìsẹ́ni. Ṣùgbọ́n, Ó sọ̀rọ̀ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ nípa ìfẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní la àwọn sẹ́ntúrì kọjá.

“Òfin titun kan ni mo fi fún yín, Pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́bí èmi ti fẹ́ràn yín. …

“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”34

Njẹ́ kí a nifẹ Rẹ̀ kí a sì nifẹ arawa. Njẹ́ kí a jẹ́ onílàjà, kí a lè pè wá ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run,” ni mo gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Máttéù 5:9.

  2. Wo Ephesians 6:16; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 3:8.

  3. Acts 10:28.

  4. Mòsíàh 15:11.

  5. Mòsíàh 5:7.

  6. Ààrẹ Dallin H. Oaks said: “Followers of Christ should be examples of civility. We should love all people, be good listeners, and show concern for their sincere beliefs. Bíótilẹ̀jẹ́pé a lè ṣe àìgbà, a kò níláti jẹ́ aláìgbà. Our stands and communications on controversial topics should not be contentious” (“Loving Others and Living with Differences,” Liahona, Nov. 2014, 27).

  7. “Amos C. Brown: Follow the LDS Church’s Example to Heal Divisions and Move Forward,” Salt Lake Tribune, Jan. 20, 2022, sltrib.com.

  8. Alàgbà Dale G. Renlund said, “When love of Christ envelops our lives, we approach disagreements with meekness, patience, and kindness” (“The Peace of Christ Abolishes Enmity,” Liahona, Nov. 2021, 84).

  9. Máttéù 5:11–12.

  10. Wo 2 Néfì 10:23.

  11. 2 Nefi 2:11..

  12. Mósè 6:55.

  13. Wo 1 Néfì 14:12.

  14. Data àìpẹ́ fuhàn pé bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn npín àkọlé fún ìtàn tí wọn kò tíì kà (woCaitlin Dewey, “6 in 10 of You Will Share This Link without Reading It, a New, Depressing Study Says,” Washington PostJune 16, 2015, washingtonpost.com; Maksym Gabielkov and others, “Social Clicks: What and Who Gets Read on Twitter?” [paper presented at the 2016 ACM Sigmetrics International Conference on Measurement and Modeling of Computer Science, June 14, 2016], dl.acm.org).

  15. Don’t be surprised if at times your personal views are not initially in harmony with the teachings of the Lord’s prophet. These are moments of learning, of humility, when we go to our knees in prayer. We walk forward in faith, trusting in God, knowing that with time we will receive more spiritual clarity from our Heavenly Father.

  16. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:14-16.

  17. Jòhánnù 15:10–11; àfikún àtẹnumọ́.

  18. “Bipartisan Bill Supported by Latter-day Saints Would Protect Gay and Transgender Arizonans,” Arizona RepublicFeb. 7, 2022, azcentral.com.

  19. Why the Church of Jesus Christ Supports a New Bipartisan Religious Freedom and Non-discrimination Bill in ArizonaFeb. 7, 2022, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  20. Russell M. Nelson, “Teach Us Tolerance and Love,” Ensign, May 1994, 69.

  21. Mórónì 7:3. Ààrẹ Gordon B. Hinckley wípé: “Not only must we be tolerant, but we must cultivate a spirit of affirmative gratitude for those who do not see things quite as we see them. A kò níláti gbàbọ̀dé ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn wa ní ọ̀nàkọnà, àwọn ìdánilójú wa, òye wa nípa òtítọ́ ayérayé bí a ti fihàn nípasẹ̀ Ọlọ́run Ọ̀run. We can offer our own witness of the truth, quietly sincerely, honestly, but never in a manner that will give offense to others. … A gbọ́dọ̀ kọ́ láti accord appreciation and respect for others who are as sincere in their beliefs and practices as are we” (Teachings of Gordon B. Hinckley16).

  22. Wo Lúkù 23:9–11.

  23. Alàgbà Dieter F. Uchtdorf said: “As followers of Jesus Christ, we follow [His] example. We do not shame or attack others. We seek to love God and serve our neighbors. À nwá láti tayọ̀tayọ pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ kí a sì gbé ìgbé ayé nípa ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ìhìnrere” (“Five Messages That All of God’s Children Need to HearBrigham Young University Education Week devotional, Aug. 17, 2021], 5, speeches.byu.edu).

  24. Alàgbà Neal A. Maxwell said: “Church members will live in this wheat-and-tares situation until the Millennium. Some real tares even masquerade as wheat, including the few eager individuals who lecture the rest of us about Church doctrines in which they no longer believe. They criticize the use of Church resources to which they no longer contribute. They condescendingly seek to counsel the Brethren whom they no longer sustain. Confrontive, except of themselves, of course, they leave the Church, but they cannot leave the Church alone” (“Becometh As a Child,” Ensign, May 1996, 68).

  25. Jòhánnù 6:66.

  26. “The pleasures of sin [are only] for a season” (wo Hebrews 11:24–26).

  27. Matteu 12:1–15.

  28. Máttéù 12:15.

  29. Wo 3 Néfì 11:29–30.

  30. With the help of the Don Bosco Foundation, the school program received valuable expertise in teaching and materials.

  31. Muleka, a parent, said, “I love this program because it has provided my daughter … the chance to … learn to read and write and hope for a better future. I could not send her to school because I am just selling corn flour in the market earning … enough only for food. I greatly thank the Church for this.” Arábìnrin Monique, a teacher, said, “This program came as a great blessing for these children. In my class … most of them are orphans. Wọ́n jẹ́ olùfẹ́ni rẹ̀, regularly attending classes and doing their homework” (comments and photos supplied by Elder Joseph W. Sitati, Feb. 24, 2022).

  32. Mayor Ntumba Louis d’or Tshipota, sọ̀rọ̀ ní ìpàdé gbangba nípa ètò idanilẹkọ Mbuji-Mayi tí a dá sílẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, Oct. 10, 2021.

  33. Jòhánù 13:21.

  34. Jòhánnù 13:34–35.