Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣé Ètò Náà Nṣiṣẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ṣé Ètò Náà Nṣiṣẹ́

Mo jẹri pé ètò ìdùnnú nṣiṣẹ́. A dasílẹ̀ nípasẹ̀ Baba wa Ọ̀run, ẹnití ó mọ̀ tí ó fẹ́ràn yín.

Ṣé ètò náà nṣiṣẹ́?

Láìpẹ́ mo ní ibáranisọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgbà kan tí ó sìn míṣọ̀n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn tí ó sì wà nínú ìpè iṣẹ́ amòye rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ní àwọn ọ̀nà kan, igbé-ayé rẹ̀ dàbí ó nlọ dáadáa. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ rẹ̀ wà ní ìdínkù. Ó nrì sínú òkun ìyèméjì nípa Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀. Ó ṣe àlàyé pé òun kìí gba àwọn ìbúkún tí òun nretí látinú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere. Òun kò sì ní ìmọ̀lára pé ètò ìdùnnú nṣiṣẹ́ nínú ayé òun.

Ọ̀rọ̀ mi ní òní ni fún gbogbo àwọn ẹnití wọ́n lè ní irú àwọn ìmọ̀lára kannáà. Mo sọ̀rọ̀ sí àwọn ẹnití wọ́n “nímọ̀lára láti kọ orin ìfẹ́ ìràpadà” ní ìgbàkan tí wọn kò “nímọ̀làra bẹ́ẹ̀ nísisìyí.”1

Baba wa Ọ̀run ti múra ètò ìyanu sílẹ̀ fún ìdùnnú ayérayé wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí ayé kò bá jáde ní ọ̀nà tí a nretí, ó lè dàbí pé ètò Baba Ọ̀run kò ṣiṣẹ́.

Ó yà mí lẹ́nu bí a bá nní ìmọ́lára ọ̀nà tí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì fi ní ìmọ̀lára nígbàtí wọ́n wà nínú ọkọ̀ “ní àárín òkún, tí ìjì njà: nítorí afẹ́fẹ́ náà le.”2

Lẹ́hìnnáà, ní òwúrọ̀ kùtùkùtù:

“Jésù tọ̀ wọ́n lọ, ó nrìn lórí òkun.

“Nígbàtí àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ ri tí ó nrìn lórí òkun,ẹ̀rú bà wọ́n, … wọ́n fi ìbẹ̀rù kígbe sókè.

“Ṣùgbọ́n lójúkannáà ni Jésù wí fún wọn pé Ẹ tújúká; èmi ni, ẹ má bẹ̀rù.

“Pétérù sì dá a lóhùn wí pé, Olúwa, bí ìwọ bá ni, pàṣẹ kí èmi tọ̀ ọ́ wá lórí omi.

Ó sì wí pé, Wá. Nígbàtí Pétérù sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀, ó rìn lórí omi, láti lọ sọ́dọ̀ Jésù.

“Ṣùgbọ́n nígbàtí ó rí tí afẹ́fẹ́ le, ẹ̀rù bá á; ó sì bẹ̀rẹ̀sí írì, ó kígbe sókè, … Olúwa, gbà mi.

“Lójúkanáà Jésù sì na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú, ó sì wí fun pé, Ìwọ onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì?”3

Ṣe mo lè ṣe àbàpín ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ mẹ́ta tí mo kọ́ láti ọ̀dọ̀ Pétérù? Mo gbàdúrà pé àwọn ẹ̀kọ́-ìpìnlẹ̀ wọ̀nyí lè ran ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìmọ̀lára pé ètò ti ìdùnnú náà kìí ṣiṣẹ́ nínú ìgbé-ayé wọn.

Àkọ́kọ́, ṣe ìṣe ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.

Mo ní ọ̀wọ̀ ti ìgbàgbọ́ Pétérù. Ní ìpé ìrọ̀rùn ti Jésù láti “wá,” ó fi ọkọ̀-ojú omi tí ìjì-nyíká sílẹ̀. Ó dàbí i pé ó mọ̀ pé bí Jésù Krístì bá pè é láti ṣe ohunkan, ó lè ṣe é.4 Pétérù ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olùgbàlà síi ju bí ó ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọkọ-ojú omi rẹ̀. Àti pé ìgbàgbọ́ náà fún un ní agbára láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ìgboyà ní ìgbà ipò ìnilára, ìdẹ́rùbà

Ìgbàgbọ́ Pètérù rán mi létí nípa ìrírí kan tí mo gbọ́ láti ẹnu Alàgbà José L. Alonso. Láìpẹ́ lẹ́hìn tí ọmọkùnrin Alàgbà Alonso kọjá lọ, ní fífi ẹbí kan sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ kékèké, Alàgbà Alonso gbọ́ tí àwọn ọmọ náà nsọ̀rọ̀.

“Kíni ohun tí àwa ó ṣe?” wọ́n bèèrè.

Ọmọdébìnrin ọdún mẹsan dáhùn, “Baba ó dára. Òun nwàásù ìhìnrere Jésù Krístì.”

Bíiti Pétérù, ọmọdébìnrin rẹ̀ rí kọ́ja àwọn ìpènijà rẹ̀ ó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà nmú àlááfìà àti okun wá láti rìn síwájú.

Bí ẹ bá wo ẹ̀hìn wò lórí ìgbé ayé yín, mo gbàgbọ́ pé ẹ ó ri pé ẹ ti lo ìgbàgbọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Dídarapọ̀ mọ́ Ìjọ ni ìṣe ti ìgbàgbọ́. Sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba Ọrun nínú àdúrà ni ìṣe ti ìgbàgbọ́. Kíka àwọn ìwé-mímọ́ ni ìṣe ti ìgbàgbọ́ Fífetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí ni ìṣe ìgbàgbọ́. Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ, “Ẹ máṣe dín ìgbàgbọ́ tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ kù.”5

Ẹ̀kọ́ míràn tí mo kọ́ láti ọ̀dọ̀ Pétérù ni èyí:

Ní àwọn àkokò ìdàmú, yípadà sí Jésù Krístì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Bí ó ti nrìn síwájú Olùgbàlà, Pétérù bẹ̀rù nítorí ìjì ó sì bẹ̀rẹ̀ sì rì. Ṣùgbọ́n nígbàtí Pétérù mọ ohun tí ó nṣẹlẹ̀, kò gbìyànjú láti tẹ omi mọ́lẹ̀ funrarẹ̀ tàbí kí ó wẹmi padà lọ síbi ọkọ̀-ojú-omi. Dípò kí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Krístì sílẹ̀, ó dìí mú daindain, ó kígbe, “Olúwa, gbà mí.”

“Lójúkanáà Jésù sì na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú.”10

Gbogbo wa ndojúkọ àwọn ìjì líle tí ó lè mi ìgbàgbọ́ wa kí ó sì mú kí ó rì. Nígbàtí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé ètò ìdùnnú Baba Ọ̀run ní orúkọ míràn—ètò ìràpadà. Ètò náà kìí ṣe fún wa láti yíká ní ìrọ̀rùn nínú ayé, láì ṣubú láéláé, láì rì láéláé, pẹ̀lú ẹ̀rín ní ojú wa nígbàgbogbo. Baba Ọ̀run mọ̀ pé àwa yíò nílò láti di ríràpadà. Èyí ni ìdí tí Òun fi múra ètò ìràpadà sílẹ̀.7 Èyí ni ìdí tí Òun fi rán Olùràpadà kan. Nígbàtí a bá ntiraka—fún èrèdí kankan—ìyẹn kò túmọ̀sí pé ètò náà kò ṣiṣẹ́. Ìyẹn ni ìgbàtí a nílò ètò náà jùlọ!

Ní àwọn àkokò wọnnì, tẹ̀lé àpẹrẹ Pétérù. Yípada sí Olùgbàlà lọ́gán.

“Ìsisìyí ni àkokò àti ọjọ́ ìgbàlà yín. … Ẹ máṣe fi ọjọ́ ìrònúpìwàdà yín dọ̀la.”8

Ibi yíówù kí a wà àti ibi tí a ti wà, ìrònúpìwàdà ni ọ̀nà síwájú. Ààrẹ Nelson ti kọ́ni:

“Kò sí ohunkóhun tó ntúnisílẹ̀ si, níyì si, tàbí ṣe pàtàkì sí ìlọsíwájú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ju bí ó ti ṣedéédé, ìdojúkọ lórí ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́. …

“Bóyá ẹ láápọn ní rírìn lẹgbẹ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, ti ìyọ̀lulẹ̀ tàbí gbígbésẹ̀ kúrò nínú ipá májẹ̀mú, tàbí ẹ kò lè rí ipá ọ̀nà láti ibi tí ẹ wà nísisìyí, mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti ronúpìwàdà. Ẹ ní ìrírí agbára ìfúnnilókun ti ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́—ti ṣíṣe àti jíjẹ́ dáradára si díẹ̀díẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.”9

Wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì túmọ̀ sí jù ríronú nípa Rẹ̀ lásán tàbí sísọ̀rọ̀ nípa Rẹ̀ tàbí níní-ìfẹ́ Rẹ̀. Ó túmọ̀ sí tún tẹ̀lé E. Ó túmọ̀ sí gbígbé ní ọ̀nà tí Ó fi kọ́ wa láti gbé. Àti fún gbogbo wa, ìyẹ́n túmọ̀ sí ríronúpìwàdà, láìsí ìdádúró.

Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin mi nṣiṣẹ́ ní gbàgede idanilẹkọ iṣẹ́-ìránṣẹ́. Ó wí fún mi nípa alàgbà kan tí òun kọ́ ẹnití ó farapamọ́ nínú rẹ̀ pé kò dá òun lójú pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́. Ó ti gbàdúrà ó sì gbàdúrà fún ẹ̀rí ti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n òun kò gba ìdáhùn.

Ọmọbìnrin mi gbàdúrà láti mọ ohun tí òun gbọ́dọ̀ ṣe láti ran òjíṣẹ́ ìhìnrere yí lọ́wọ́. Ìwọnilọ́kàn tí ó gbà pé a fún wa ní àwọn ìwè-mímọ́ kìí ṣe kí a lè kà wọ́n kí a sì gba ẹ̀rí nìkan; bákànnáà a fún wa láti kọ́ wa láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ọmọbìnrin mi ṣe ábápín èrò yí pẹ̀lú òjíṣẹ́ ìhìnrere.

Lẹ́hìnáà, ó rí ojíṣẹ́ ìhìnrere yí lẹ́ẹ̀kansi, ní ìwò ìdùnnú síi. Ó wí fú un pé òun ti gba ẹ̀rí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́ nígbẹ̀hìn. Ó mọ̀ pé ẹ̀rí yí wá nítorí òun nṣe ìtiraka títóbijù láti ṣe ohun tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni.

Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé àpẹrẹ Pétérù nípa yíyí sí Olùgbàlà ní ìgbà ìdàmú wa. Tẹ̀lé Jésù Krístì dípò gbígbára lé ọgbọ́n àti okun ti arayín. Bí ó ti wù kí ó pẹ́ tó tí ẹ ti ngbìyànjú láti tẹ omi láìsí Rẹ̀, kò pé jù rárá láti nawọ́ jáde sí I. Ṣé ètò náà nṣiṣẹ́!

Ìpìnlẹ̀-ẹ̀kọ́ kẹta tí mo kọ́ látinú ìrírí Pétérù ni èyí:

Ẹ rẹ arayín sílẹ̀ níwájú Olúwa, Òun yíò sì gbé yín sókè sí àwọn ohun gígajù.

Pétérù ti fi ìgbàgbọ́ hàn, ní rínrìn lórí omi àti ní nínawọ́ jáde sí Olùgbàlà nígbàtí ó nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Àní bẹ́ẹ̀ náà, Olùgbàlà rí agbára fún ọ̀pọ̀ síì nínú Pétérù. “Ìwọ onìgbàgbọ́ kékeré,” Ó wípé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì?”10

Pétérù ti lè kórira ìbáwí yí. Ṣùgbọ́n ó tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Ó tẹ̀síwájú láti wá ìgbàgbọ́ títóbijù nínú Jésù Krístì. Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àníkún ìrírí gbígbéga-ìgbàgbọ́—díẹ̀ lára wọn ṣòrò gidi gidi—Pétérù nígbẹ̀hìn di olórí àpáta-daindain tí Olúwa fẹ́ kí ó jẹ́. Ó ṣe àṣeyọrí àwọn ohun nlá ínú iṣẹ́-ìsìn Olúwa.

Kíni àwọn ohun nlá tí Olúwa nfẹ́ kí ẹ ṣe ní àṣeyọrí? Nínú Ìjọ àti ìjọba Rẹ̀, àwọn ànfàní wà lọ́pọ̀lọpọ̀ láti sìn àti láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti ṣe. Ó nfẹ́ kí ẹ jẹ́ ara iṣẹ́ nlá Rẹ̀. Ètò ìdùnnú kì yíò di òtítọ́ si fùn yín láéláé ju ìgbàtí ẹ̀ bá nran àwọn míràn lọ́wọ́ láti gbé e.

Nínú ìrìnàjò ìgbágbọ́ ti ara mi, àwọn ọ̀rọ̀ ti Álmà wọ̀nyí jẹ́ yíyípadà-ìgbé ayé: “Alábùkúnfún ni àwọn tí ó rẹ arawọn sílẹ̀ láìmúnípá láti nírẹ̀lẹ̀.”11 Ẹ jẹ́ kí a fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbé arawa sí ipò kan níbití Jésù Krístì ti lè gbé wá sókè, darí wa, kí Ó sì ṣe dídárajùlọ nípa agbára wa.12

Mo jẹri pé ètò ìdùnnú nṣiṣẹ́. A daásílẹ̀ nípasẹ̀ Baba wa Ọ̀run, ẹnití ó fẹ́ràn yín. Ó nṣiṣẹ́ nítorí Jésù Krístì borí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nípasẹ̀ Ètùtù. Wá sọ́dọ̀ Rẹ̀, Tẹ̀lé E, àti “lọ́gán ni a ó mú ètò nlá ìràpadà wá sọ́dọ̀ yín.”13 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.