Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Má Bẹ̀rù: Gbàgbọ́ Nìkan!
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Má Bẹ̀rù: Gbàgbọ́ Nìkan!

Ẹ bẹ̀rẹ̀ síí wá ìdùnnú yín nípa gbígbà-mọ́ra ohun púpọ tí a ti gbà tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ olùfúnni ní gbogbo ẹ̀bùn rere.

Mo darí àwọn ọ̀rọ̀ mi lónìí sí àwọn ọ̀dọ́ nínú Ìjọ, tí ó túmọ̀ sí ẹnikẹ́ni bí ọjọ́ orí Ààrẹ Nelson tàbí kéré jubẹ́ẹ̀. Èmi kìí sábà lo àwọn ohun ìwòran, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàì pín èyí.

Àwòrán
Ìwe kíkọ láti ọwọ́ Marin Arnold

Cri de couer yí wá láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi ọmọ-ọdún-mẹ́jọ Marin Arnold, tí ó kọ nígbàtí ó wà ní ọdún méje. Èmi ó túmọ̀ àtúnṣe ìbẹ̀rẹ̀ èdè Egíptì rẹ̀ fún yín:

“Bíṣọ́pù ọ̀wọ́n

Generle confrins

jẹ́ àìládùn kínìdí

Tí a sé ìdajì láti

Ṣe é? sọ ìdí rẹ̀ fún mi

Sinserlie, Marin

Arnold.1

Ó dára, Marin, ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yíò já ọ kulẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi láìṣiyèméjì. Ṣùgbọ́n nígbàtí o kọ̀wé sí Bíṣọ́pù rẹ láti ṣàròyé, ó ṣe pàtàkì kí o sọ fún un pé orúkọ mi ni “Kearon. Alàgbà Patrick Kearon.”

Fún bí ọdún méjì àjàkálẹ̀ àrùn kan bíi ti inú Bíbélì ti bo pílánẹ́ẹ̀tì wa, àti pé nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni àjàkálẹ̀ àrùn náà mú òpin bá láwùjọ, ó ṣe kedere pé kò mú òpin bá ìwà òǹrorò, ìwà ipá, àti ìwà ìtara ìkà nínú ìṣèlú—ní orílẹ̀ èdè tàbí ní òké òkun. Bí ẹni pé èyíinì kò tó, a ṣì ndojú kọ àwọn ìpèníjà àwùjọ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó ti wà fún ìgbà pípẹ́, látorí àìnító nínú ètò ọrọ̀ ajé sí ìbàjẹ́ àyíká sí àìdọ́gba àwọn ẹ̀yà àti púpọ̀ sí i.

Irú àwọn ẹ̀fúùfù líle àti àwọn ọjọ́ dúdú bẹ́ẹ̀ lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàrin wa, àwọn wọnnì tí à nwò fún ìrètí àti ìtara nípa àwọn ọjọ́ ọ̀la ìgbésí ayé wa. Wọ́n ti sọ pé “agbára ọ̀dọ́ ni ọrọ̀ àjùmọ̀ní fún gbogbo ayé. Àwọn … ọ̀dọ́ … ni àwọn ìwò ojú … ọjọ́ iwájú wa.”2 Síwájú sí i, àwọn ọmọ wa ni àwọn alábòójútó tí a ó gbé kádàrá Ìjọ yìí lé lọ́wọ́.

Ní ti àwọn àkokò lọwọlọwọ, ó yẹ kí ó yéni bí ìbójúmu àwọn ọ̀dọ́ bá ndínkù díẹ̀. Dókítà Laurie Santos, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Yale, ṣẹ̀dá kíláàsì kan láìpẹ́ yi tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ọ̀rọ̀ Ìrònú àti Ìgbésí Ayé Rere.” “Ní ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe kíláàsì náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ [ìdá mẹ́rin] ti ẹgbẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ [gbogbo àwọn] onípele àkọ́kọ́ ni wọ́n forúkọ sílẹ̀.”3 Ju àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lẹ́hìnnáà ṣe àbẹ̀wò sí pọ́díkàstì rẹ. Ní kíkọ̀wé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, akọ̀ròyìn kan ṣe àkíyèsí bí ó ti dunni tó láti rí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n lóye, àwọn ọ̀dọ́—àti àwọn àgbà—tí wọ́n “nwá ohun kan tí wọ́n ti pàdánù” tàbí, ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n nlàkàkà fún ohun kan tí wọn kò ní rí.4

Ẹ̀bẹ̀ mi lóni sí àwon ọ̀dọ́ wa, àti ẹ̀yin òbí àti àgbà tó ngbà wọ́n nímọ̀ràn, ni kí ẹ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí yín fún ìdùnnú nípasẹ̀ gbígbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí a ti gbà tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ olùfúnni ní gbogbo ẹ̀bùn rere mọ́ra.5 Ní ọ̀gangan àkokò tí ọ̀pọ̀ nínú ayé nbéèrè àwọn ìbéèrè jíjinlẹ̀ ti ọkàn, ó yẹ kí a máa dáhùn pẹ̀lú “ìròhìn rere”6 ti ìhìnrere Jésù Kristi. Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, tí ó gbé iṣẹ́ àti ọ̀rọ̀ Olùgbàlà aráyé sókè, npèsè ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ láti rí rere àti láti ṣe rere ní irú àkokò tí ó nílò rẹ̀.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ pé ìran ti àwọn ọ̀dọ́ yìí ní agbára láti ní “ipá púpọ̀ sí i [fún rere] lórí ayé ju èyíkéyìí tó ti kọjá lọ.”7 Àwa, nínú gbogbo ènìyàn, gbọ́dọ̀ máa “kọ orin ìfẹ́ tí nrànipadà,”8 ṣùgbọ́n èyí gba ìkóraẹni-níjanu—“jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn,” bí ẹ bá fẹ́— irú èyí tó nṣọ́ra fún àwọn ìwà òdì àti àwọn àṣà apanirun tí yíò fà wá kúrò bi a ti ngbìyànjú láti kọ orin ìgbàlà ayérayé náà.

Àní bí a ti dúró ní “ẹ̀gbẹ́ ibi ti oòrùn wà ní òpópónà,”9 a nṣe alábãpàdé ẹni náà láti ìgbà dé ìgbà, tí ó ti pinnu láti wá ohun kan tí ó ṣókùnkùn àti àìbìkítà nípa ohun gbogbo. Ẹ mọ àkọmọ̀nà rẹ: “Ó maa nṣókùnkùn jùlọ ṣaájú kí ó tó dúdú gidi.” Ó ti jẹ́ irú ìwòran èro burúkú àti ìwàláàyè tí ó bani nínú jẹ́ tó! Bẹ́ẹ̀ni, nígbàmíràn a lè fẹ́ sá kúrò níbi tí a wà, ṣùgbọ́n ó dájú pé a kò gbọ́dọ̀ sá fún irú ẹni tí a jẹ́ láé—àwa ọmọ Ọlọ́run alààyè tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó ṣetán nígbà gbogbo láti dárí jì wá, tí kì yíò sì fi wá sílẹ̀ láé, láé Ìwọ ni ohun-ìní Rẹ̀ tó ṣeyebíye jùlọ. Iwọ ni ọmọ Rẹ̀, ẹni tí Ó ti fi àwọn wòlíì àti àwọn ìlérí, àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí àti ìfihàn, àwọn iṣẹ́ ìyanu àti àwọn ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́ fún, àti àwọn ángẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú náà.10

Bákannáà Ó ti fún ọ ní Ìjọ kan tí nfún àwọn ẹbí lókun fún ayé ikú, tí ó sì nso wọ́n pọ̀ fún ayérayé. Ó npèsè ju àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ka ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n níbití àwọn ènìyàn ti npéjọ, àti tí wọ́n nkọrin, tí wọ́n sì ngbàwẹ̀, àti àdúrà fún ara wọn tí wọ̀n sì nfi ohun ìní wọn fún àwọn tálákà. Èyí ni ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ní orúkọ, ṣe ìṣirò fún, àti tí a ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún, àti níbití àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládúgbò ti nsìn ara wọn láìfipaṣe ninú àwọn ìpè tí ó bẹ̀rẹ̀ láti iṣẹ́ ìkọ̀wé sí ojúṣe àbojútó. Àwọn ọ̀dọ́ àgbà—àti àwọn tọkọtaya àgbà bákannáà—tó nsin ní àwọn míṣọ̀n ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní nínáwó apò ara wọn láìlè ṣe ìpinnu rárá nípa ibi tí wọn yíò ti ṣiṣẹ, àti àwọn ọmọ ìjọ ọ̀dọ́ àti àgbà tí wọ́n nlọ sí àwọn tẹ́mpìlì láti ṣe àwọn ìlànà mímọ́ tí ó ṣe dandan láti so ẹbí ènìyàn papọ̀—iṣẹ ìgboyà kan nínú irú ayé pípín bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó kéde pé irú ìyapa bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nìkan. Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára ​​àwọn èrèdí tí a nsọ fún “ìrètí tí ó wà nínú [wa].”11

Dájúdájú, ní ọjọ́ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ yí, àwọn ọ̀ràn tó ṣòro púpọ̀jù ndojú kọ èyíkéyìí ọmọẹ̀hìn Jésù Kristi. Àwọn olórí nínú Ìjọ yí nfi ẹ̀mí wọn gan-an lélẹ̀ fún wíwá ìtọ́sọ́nà Olúwa nínú wíwá ìyanjú sí àwọn ìpèníjà wọ̀nyí. Bí àwọn kan kò pinnu láti tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, bóyá wọ́n jẹ́ apá kan àgbélébùú tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ gbé kí á lè baà tẹ̀lé E.12 Ó jẹ́ pàtó nítorípé àwọn ọjọ́ dúdú àti àwọn ọ̀ràn síṣòro yíò wà ni Ọlọ́run fi ṣe ìlérí pé Òun yíò, láti inú àwọ̀sánmọ̀ ní ọ̀sán àti ọ̀wọ́n iná ní òru, tọ́ àwọn wòlíì, fúnni ní ọ̀pá irin kan, ṣí ẹnu-ọ̀nà tóóró sílẹ̀ tí ó lọ sí ipa-ọ̀nà híhá, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ fún wa lágbára láti parí ipa náà.1377

Nítorínáà jọ̀wọ́, jọ̀wọ́, dúró fún gbogbo àpèjẹ nàá àní bí o kò tilẹ̀ ní ìdánilójú nípa búrókólì náà. Gbé nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ kí o sì fi fìtílà rẹ yá sí iṣẹ́ náà.14 Wọ́n ní i dáradára ní Alákọ̀bẹ̀rẹ̀: Jésù nítòótọ́ “[fẹ́ ọ] fún ìtànṣán oòrùn kan.”15

Nígbàtí Jáírù olórí àwọn Júù bẹ Jésù pé kó wo ọmọbìnrin rẹ̀ ẹni ọdún méjìlá sàn tó nkú lọ sílé, àwọn èrò tó wà láyìíká rẹ̀ dí Olùgbàlà lọ́nà pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìránṣẹ́ kan fi wa sọ láìpẹ́ fún baba tó nṣàníyàn yìí pé, “Ọmọbìnrin rẹ ti kú; maṣe yọ Olúwa lẹ́nu.”

“Ṣùgbọ́n nígbàtí Jésù gbọ́, o da a lohùn, wípé, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nìkan, a ó sì mú u láradá.”16

Ó sì wòsàn. Bẹ́ẹ̀ ni yío sì rí fún ẹ̀yin. “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ gbàgbọ́ nìkan.”

Nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan yín nínú ipéjọpọ̀ yìí jẹ́ iyebíye sí Ọlọ́run àti sí Ìjọ yìí, mo parí pẹ̀lú ìkéde pàtàkì ti àpọ́sítélì yìí. Kí ẹ to gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ láé, ẹ ti ní Ìmọ́lẹ̀ Krístì tí a gbìn sínú ọkàn yín,17 “ìmọ́lẹ̀ náà tí ó wà nínú ohun gbogbo, … fi ìyè fún ohun gbogbo,”18 àti pé ó jẹ́ ipá fún rere nínú ọkàn gbogbo ènìyàn tí ó ti gbé ní ayé tàbí tí yíò gbé ní ayé. Ìmọ́lẹ̀ náà ni a fi fúnni láti dáàbòbò yín àti láti kọ yín. Ọ̀kan nínú gbùngbùn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé ìyè jẹ́ iyebíye jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn, ẹ̀bùn kan tí a gbà ní ayérayé nípasẹ̀ Ètùtù Olúwa Jésù Krístì nìkan. Bí Ìmọ́lẹ̀ àti Ìyè Ayé,19 Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Ọlọ́run wá láti fún wa ní ìyè nípa ṣíṣẹ́gun ikú.

A gbọ́dọ̀ fi ara wa lélẹ̀ ní kíkún fún ẹ̀bùn ìyè náà kí a sì sáré lọ sí ìrànwọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ewu láti fi ẹ̀bùn mímọ́ yìí sílẹ̀. Ẹ̀yin olórí, ẹ̀yin agbanimọ́ràn, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹbí—ẹ wò fún àwọn àmì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, àìnírètí, tàbí ohunkohun tí ó tọ́ka sí ìpa ara ẹni lára. Ṣètò ìrànlọ́wọ́ rẹ. Fetísílẹ̀. Ṣe irú ìdásí díẹ̀ bí ó ṣé yẹ.

Sí èyíkéyí àwọn ọ̀dọ́ wa tí ó wà níta níbẹ̀ tó ntiraka, ohunkohun ti àwọn àníyàn tàbí àwọn ìṣòro rẹ le jẹ́, ikú nípa ìgbẹ̀mí ara ẹni kíì ṣe ìdáhùn. Kì yíò mú ìtura wá fún ìrora tí ẹ nmọ̀lára tàbí tí ẹ rò pé ẹ nfà. Nínú ayé tí ó nílò gbogbo ìmọ́lẹ̀ tí ó lè rí kíkankíkan, jọ̀wọ́ máṣe dín ìmọ́lẹ̀ ayérayé tí Ọlọ́run fi sínú ọkàn rẹ kí ayé yìí tó wà kù. Bá ẹnikan sọ̀rọ. Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́. Máṣe pa ìyè ti Krístì fi ẹ̀mí Rẹ̀ fúnní láti tọ́jú run. Ẹ lè farada àwọn ìjàkadì tí ayé ikú yí nítorí a ó ràn yín lọ́w/\ láti farada wọn. Ẹ lágbára ju bí ẹ ti rò lọ. Ìrànlọ́wọ́ ní àrọ́wọ́tó, láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn àti pàápàá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A nífẹẹ́ a mọyì a sì nílò yín. A nílò yín! “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ gbàgbọ́ nìkan.”

Ẹnìkan tí ó dojúkọ àwọn ipò àìnírètí tó jìnnà púpọ̀ ju èyítí ẹ̀yin ati èmi le dojúkọ láé, kígbe nígbà kan pé: “Ẹ tẹ̀síwájú [ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀dọ́ mi olùfẹ́]. Ìgboyà, … àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun naa! Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín kí ó yọ̀, kí ẹ sì ní ìdùnnú tí ó tayọ.”20 A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun láti dunnú nípa. A ní ẹni kọ̀ọ̀kan wa, a sì ní Òun. Máṣe dùn wá ní ààyè láti ní ọ, mo bẹ̀bẹ̀, ni orúkọ ọ̀wọ̀ àti mímọ́ Olúwa wa Jésù Krístì, Olùkọ́ni wa, àmín.