Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àkàbà Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Àkàbà Ìgbàgbọ́

Àìgbàgbọ́ dí agbára wa lọ́wọ́ láti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu, nígbà tí èrò ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ṣí àwọn agbára ọ̀run sílẹ̀.

Báwo ni àwọn ìpèníjà ayé ṣe lè nípa lórí ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì? Ipa wo sì ni ìgbàgbọ́ wa máa ní lórí ayọ̀ àti àlàáfíà ti a ní ìrírí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa?

Ọdún náà jẹ́ 1977. Fóònù náà dún, ìfiránṣẹ́ náà sì fa ọkàn wa ya. Carolyn ati Doug Tebbs nmúra láti lọ sí ilé wọn titun lẹ́hìn tí wọ́n parí ilé-ìwé gíga. Àwọn iyejú alàgbà ti wá láti kó ẹrù sínú ọkọ̀ rínrìn náà. Doug, ri dájú pé ọ̀nà náà mọ́ kedere kí ó tó padà, wo ọ̀kan tí ó kẹ́hìn. Ohun tí kò lè rí ni ọmọbìrin rẹ̀ kékeré, Jennie, dart lẹ́hìn ọkọ̀ akẹ́rù ní àkokò tí kò tọ́. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jennie olùfẹ́ wọn ti lọ.

Kíni ó kàn tí yíò ṣẹlẹ̀? Njẹ́ ìrora tí wọ́n ní lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ àti ìmọ̀lára òfò tí kò ṣeé ronú kàn yíò dá ọ̀gbun àìbáradọ́gba kan láàárín Carolyn àti Doug, tàbí yíò so ọkàn wọn pọ̀ kí ó sì mú ìgbàgbọ́ wọn lágbára nínú ètò Baba Ọ̀run bí?

Ọ̀nà tó gba ìpọ́njú wọn kọjá gùn ó sì dunni, ṣùgbọ́n láti ibìkan ni àwọn ìpamọ́ ẹ̀mí ti wá láti má ṣe sọ ìrètí nù, bí kò ṣe láti “di ọ̀nà [wọn] mú.”1 Lọ́nà kan ṣáá tọkọtaya àgbàyanu yìí tún wá dà bíi ti Kristi síi. Olùfarajì díẹ̀ síi. Aláánù díẹ̀ síi. Wọ́n gbàgbọ́ pé, ní àkokò Rẹ̀, Ọlọ́run yìó yà àwọn ìpọ́njú wọn sí mímọ́ fún èrè wọn.2

Bíótilẹ̀jẹ́ pé ìrora àti àdánù náà kò lè lọ pátápátá, Carolyn àti Doug ti gba ìtùnú nípasẹ̀ ìdánilójú pé nípa dídúró ṣinṣin lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, olùfẹ́ wọn Jennie yíò jẹ́ tiwọn títíláé.3

Àpẹrẹ wọn ti fún ìgbàgbọ́ mi nínú ètò Olúwa lókun. A kò rí ohun gbogbo. Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Olúwa sọ fún Wòlíì Joseph Smith ní ẹ̀wọ̀n Liberty pé “àwọn nkan wọ̀nyí yìó fún yín ní ìrírí, àti fún rere yín. Ọmọ Ènìyàn ti sọ̀kalẹ̀ kọjá gbogbo wọn. Ṣé ìwọ tóbi jùú lọ?”4

Bí a ṣe ngba ìfẹ́ Olúwa, Ó nkọ́ wa bí a ṣe lè rìn pẹ̀lú Rẹ̀.5 Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tí ó sìn ní Tahiti, a sọ wípé kí nṣe ìtọ́jú ìkókó aláìsàn kan. A gbé ọwọ́ wa lé orí rẹ̀ a sì fun ní ìbùkún láti ní ìlera si. Ìlera rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sunwọ̀n sí i, ṣùgbọ́n lẹ́hìn náà ó tún ṣàìsàn. Ni ẹ̀ẹ̀kejì a bùkun un ṣùgbọ́n pẹ̀lú àbájáde kannáà. Ìbéèrè kẹ́ta wá. A bẹ Olúwa pé kí ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. Kò pẹ́ lẹ́hìn náà, ẹ̀mí kékeré yìí padà sí ilé rẹ̀ ọ̀run.

Ṣùgbọ́n a wà ní àlááfìà. A fẹ́ kí ìkókó wà láàyè, ṣùgbọ́n Olúwa ní àwọn ètò míràn. Gbígba ìfẹ́ Rẹ̀ ní ààyè tiwa jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí wíwá ayọ̀ láìbìkítà àwọn ipò wa.

Ìgbàgbọ́ rírọrùn tí a ní nínú Jésù Krístì bí a ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Rẹ̀ lè dúró nínú ọkàn wa bí a ti nkojú àwọn ìpèníjà ìgbésí-ayé. Ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ lè àti pé Yíò ṣe amọ̀nà wa nípasẹ̀ àwọn dídíjú ìgbésí-ayé. Ní tòótọ́, a ó rí i pé ìrọ̀rùn wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì àwọn dídíjú ìgbésí-ayé6 bí a ṣe dúró “[ṣinṣin] nínú Kristi, ní níní ìmọ́lẹ̀ pípé ìrètí.”7

Ara èrèdí ìgbésí-ayé ni láti jẹ́ kí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ wọ̀nyí lè di àtẹ̀gùn bí a ṣe ngun ohun tí mo pè ní “àkàbà ìgbàgbọ́”—àkàbà kan nítorí ó daba pé ìgbàgbọ́ kò dúró lójúkan. Ó lè lọ sókè tàbí ìsàlẹ̀ ní ìbámu sí àwọn yíyàn wa.

Bí a ṣe nlàkàkà láti gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Olùgbàlà, a lè má lóye kíkún ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa kí a sì ṣègbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀ láti inú ìmọ̀lára ojúṣe. Ẹ̀bi pàápàá lè di ẹni àkọ́kọ́ tí nsún wa lọ́kàn ju ìfẹ́ lọ. A lè ma ti ní ìrírí àsopọ̀ gidi kan pẹ̀lú Rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀.

Bí a ṣe ngbìyànjú láti mú kí ìgbàgbọ́ wa pọ̀ sí i, ohun tí Jákọ́bù kọ́ni lè dà wá láàmú. Ó rán wa létí pé “ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ òkú ni.”8 A lè kọsẹ̀ tí a bá rò pé ohun gbogbo dá lórí wa. Gbígbẹ́kẹ̀lé ara wa jù lè ṣe ìdíwọ́ agbára wa láti rí ààyè sí àwọn agbára ọ̀run.

Ṣùgbọ́n bí a ṣe nlọ sí ọ̀nà ìgbàgbọ́ òtítọ́ nínú Jésù Krístì èrò inú wa bẹ̀rẹ̀ síí yípadà. A mọ̀ pé ìgbọràn àti ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ṣe wa ní yíyẹ láti ní Ẹ̀mí Rẹ̀ nígbàgbogbo láti wà pẹ̀lú wa.9 Ìgboràn kìí ṣe ìbínú mọ́ ṣùgbọ́n ó di ìbéèrè.10 A mọ̀ pé ìgbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run jẹ́ kí á ní ìgbẹ́kẹ̀lé lọ́dọ̀ Rẹ̀. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ npọ̀ si. Ìmọ́lẹ̀ yí ṣe ìtọ́sọ́nà ìrìn-àjò wa o sì gbàwá láàyè láti ri ní kedere ní ipa-ọ̀nà tí ó yẹ kí á gbà.

Ṣùgbọ́n díẹ̀ wa síi. Bí ìgbàgbọ́ wa nínú Olùgbàlà ṣe npọ̀ sí i, a nṣàkíyèsí ìyípadà àrékérekè kan tí ó ní òye tọ̀run nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run—ìyípadà dídúró ṣinṣin kúrò ní “Kí ni mo fẹ́?” sí “Kini Ọlọrun fẹ?” Gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, a fẹ́ láti ṣe “kìí ṣe bí mo ṣe fẹ́, ṣùgbọ́n bí ìwọ ṣe fẹ́.”11 A fẹ́ láti ṣiṣẹ́ Olúwa, kí a sì jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Rẹ̀.12

Ìlọsíwájú wa jẹ́ ayérayé. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé púpọ̀ ni ohun tí Baba Ọ̀run fẹ́ kí a mọ̀.13 Bí a ṣe ntẹ̀ síwájú, a túbọ̀ lóye ohun tí Olúwa kọ́ Joseph Smith: “Nítorí bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò gba nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, a ó sì yin yín lógo nínú mi; … Mo wí fún yín, ẹ̀yin yíò gba oore-ọ̀fẹ́ fún oore-ọ̀fẹ́.”14

Bí a ṣe ngun àkàbà ìgbàgbọ́ sókè sí jẹ́ ìpinnu wa. Alàgbà Niel L. Andersen kọ́ni, “ìgbàgbọ́ yín kìí ṣe nípa àìròtẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n nípa yíyàn.”15 A lè yàn láti ṣe àwọn yíyàn tí ó nílò láti mú ìgbàgbó wa pọ̀ si nínú Olùgbàlà.

Ro ipa àwọn yíyàn ṣíṣe nígbàtí Lámánì àti Lémúẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ ní àkàbà ti ìgbàgbọ́ nígbàtí Néfì gun sókè síi. Njẹ́ ìṣojú kedere ju ìyàtọ̀ láàárín ìdáhùn Néfì ti “Èmi yio lọ ṣe”16 ní ìbámu pẹ̀lú Lámánì àti Lémúẹ́lì, nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí áńgẹ́lì kan, tí wọ́n dáhùn pẹ̀lú “Báwo ni ó ṣe ṣe é ṣe pé Olúwa yíò gbàlà?”17

Àìgbàgbọ́ ndí agbára wa lọ́wọ́ láti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu, nígbà tí èrò ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ṣí àwọn agbára ọ̀run sílẹ̀.

Pàápàá nígbàtí ìgbàgbọ́ wa ṣàìlágbára, ọwọ́ Olúwa yìó jáde nígbàgbogbo.18 Ọ̀pọ̀ àwọn ọdún sẹ́hìn mo gba iṣẹ́ àyànfúnni náà láti tún èèkàn kan tò ní Nigeria. Ní ìṣẹ́jú ìkẹhìn, ìyípadà wà ní ọjọ́ náà. Ọkùnrin kan wà ní èèkàn náà tí ó ti pinnu láti kúrò ní ìlú ní ọjọ́ ìpàdé àpapọ̀ àkọ́kọ́. Kò fẹ́ kí wọ́n pe òun gẹ́gẹ́bì ààrẹ èèkàn.

Nígbàtí ó lọ ó ní ìjàmbá ọkọ̀ nla, ṣùgbọ́n kò ní ìpalára. Èyí mú kí ó ronú ìdí tí a fi dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Ó tún ìpinnu rẹ̀ ṣe. Ó ronú pìwàdà ó sì fi ìrẹ̀lẹ̀ lọ síbi ìpàdé àpapọ̀ titun náà. Àtipé bẹ́ẹ̀ni, a pè é láti jẹ́ ààrẹ èèkàn titun.

Alàgbà Neal A. Maxwell kọ́ni: “Kìkì nípa mímú ìfẹ́ wa wà pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ni a rí ayọ̀ kíkún. Ohunkóhun tí ó dínkù ní àbájáde ní ìpín tí ó kéré.”19

Lẹ́hìn ṣíṣe “ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ agbára wa,” nígbà náà ó tó àkókò láti “dúró jẹ́ẹ́ … láti rí ìgbàlà Ọlọ́run.”20 Mo rí èyí nígbà tí mo nsìn gẹ́gẹ́ bí arákùnrin tó nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ìdílé McCormick. Ó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mọ́kànlélógún, Mary Kay fi ìṣòtítọ́ sìn nínú àwọn ìpè rẹ̀. Ken kìí ṣe ọmọ ìjọ kò sì nífẹ̀ẹ́ sí dídi ọ̀kan, ṣùgbọ́n nínífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ, ó yàn láti lọ sí ìjọ pẹ̀lú rẹ̀.

Ọjọ́ Ìsinmi kan, mo ní ìmọ̀lára ìwúrí láti ṣàjọpín ẹ̀rí mi pẹ̀lú Ken. Mo bèère lọ̀wọ́ rẹ̀ bí mo bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfèsì rẹ̀ rọrùn ó sì jẹ́ kedere: “Rárá o ṣeun.”

Ó yàmí lẹ́nu. Mo ti ní ìmọ̀lára kan mo sì gbìyànjú láti tẹ̀lé e. Ó jẹ́ ìdánwò láti pinnu pé mo ti sa ipá mí. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn àdúrà àti ìrònú, mo rí i pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ète mi tọ̀nà, mo ti gbẹ́kẹ̀ lé ara mi lọ́pọ̀lọpọ̀ àti kékeré jù lọ nínú Olúwa.

Lẹ́hìnnáà, mo padà, ṣùgbọ́n pẹ̀lú èrò tí ó yàtọ̀. Èmi yíò lọ ní ìrọ̀rùn bí ohun èlò ní ọwọ́ Olúwa, láìsí ìfẹ́ miràn ju láti tẹ̀lé Ẹ̀mí náà. Paapọ̀ pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ mi olóòótọ́, Gerald Cardon, a wọ ilé McCormick.

Láìpẹ́ lẹ́hìn náà, mo ní ìmọ̀lára ìwúrí láti ké sí Gerald láti kọrin “Mo Mọ̀ Pé Olùràpadà Mi Wà Láàyè.”21 Ó wò mí pẹ̀lú ìbéèrè, ṣùgbọ́n níní ìgbàgbọ́ nínú ìgbàgbọ́ mi, ó ṣe é. Ẹ̀mí ẹlẹ́wà kan kún yàrá náà. Ìmọ̀lára náà wá láti pe Mary Kay ati Kristin, ọmọbìnrin wọn, láti pín àwọn ẹ̀rí wọn. Bí wọ́n ṣe ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹ̀mí náà túbọ̀ lágbára sí i. Ní òtítọ́, lẹ́hìn ẹ̀rí Kristin, omijé nṣàn lójú Ken.22

Ọlọ́run ti gbàkóso. A kò fọwọ́ kan àwọn ọkàn nìkan ṣùgbọ́n wọ́n yípadà láéláé. Ọdún mọ́kànlélógún ti àìgbàgbọ́ ni a fọ̀ kúrò nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìnáà, Ken ṣe ìrìbọmi. Ọdún kan lẹ́hìn náà, Ken àti Mary Kay ni a fi èdìdì dì nínú ilé Olúwa fún àkókò àti títí ayérayé.

Lápapọ̀ a ti nírìírí ohun tí ó túmọ̀ sí láti fi ìfẹ́ Olúwa rọ́pò ìfẹ́-inú wa, ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ sì pọ̀ síi.

Ẹ jọ̀wọ́ gbé àwọn ìbéèrè díẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì mímọ́ Ọlọ́run bí ẹ ṣe nlàkàkà láti gun àkàbà ìgbàgbọ́ yín:

Ṣé mo gbé ìgbéraga kúrò bí?23

Njẹ́ mo fi àyè sìlẹ̀ ní ọkàn mi fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí?24

Njẹ́ mo gba àwọn ìpọ́njú mi lááyè láti​​di mimọ́ fun ere mi bí?25

Njẹ́ èmí fẹ́ ki ìfẹ́ mi di gbígbémì ní ìfẹ́ Baba bí?26

Bí mo bá ti nímọ̀lára láti kọ orin ìràpadà ìfẹ́, ṣé mo nímọ̀lára rẹ̀ bayi?27

Njẹ́ mo jẹ́kí Ọlọ́run borí láyé mi?28

Bí ẹ bá ríi pé ipa-ọ̀nà yín lọ́wọ́lọ́wọ́ ṣe ìlòdì sí ìgbàgbọ́ yín nínú Olùgbàlà, lẹ́hìnnáà ẹ jọ̀wọ́ wa ọ̀nà yín padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ìgbéga rẹ àti ti ìran rẹ gbáralé e.

Njẹ́ kí á gbin àwọn irúgbìn ìgbàgbọ́ jinlẹ̀ nínú àwọn ọkàn wa. Njẹ́ kí á bọ́ irúgbìn wọ̀nyí bí a ṣe nso ara wa pọ̀ mọ́ Olùgbàlà nípasẹ̀ bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a ti bá A ṣe. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.