Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kíkọ́ Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni sí Àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Kíkọ́ Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni sí Àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́

Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé Olùgbàlà wa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ nípa dída olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ní gbogbo ayé wa kí a sì kọ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ní èyí.

Èmi yíò sọ̀rọ̀ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni àti bí a ṣe lè fi kọ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́. A lè rò ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni bíi jíjẹ́ ẹ̀kọ́ kan tí ó pọndandan fún àwọn àgbà. Mo ti mọ̀ pé àwọn àgbà lè wà ní ipá-ọ̀nà dídárajùlọ síwájú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni nígbàtí a bá ti kọ́ wọ́n ní ìhìnrere Jésù Krístì tí wọ́n sì mú ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́-ìpìnlẹ̀ rẹ̀ lò látigbà èwe àti ọ̀dọ́ ní ilé.

Ìjúwe dídárajùlọ ni àpẹrẹ nlá ti ìgbé-ayé òtítọ́. Wilfried Vanie, àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò méje rẹ̀, àti ìyá rẹ̀ darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní Abidjan, Ivory Coast, nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà. Ó ṣe ìrìbọmi ní ọdún mẹ́jọ. Baba rẹ̀, olùpèsè àkọ́kọ́ nínú ẹbí, kú nígbàtí Wilfried wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ní ìbànújẹ́ nípa ipò ẹbí, Wilfried pinnu lati tẹ̀síwájú ní ilé-ìwé pẹ̀lú ìgbani-níyànjú ìyá rẹ̀ àti pẹ̀lú àtìlẹhìn Ìjọ. Ó ṣetán láti ilé-ìwé gíga ó sì sìn ní míṣọ̀n ìgbà-kíkún ní míṣọ̀n Ghana Cape Coast, níbití ó ti kọ́ Èdè-gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́hìn mísọ̀n rẹ̀, ó lọ sí unifásítì ó sì gba dípúlọ́mà nínú ìṣirò àti ìṣúná. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó le láti rí iṣẹ́ nínú ẹ̀kọ́ yí, ó rí iṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìgbafẹ́ àti ìgbàlejò.

Ó bẹ̀rẹ̀ bí onídúró ní ilé-ìtura 5-star, ṣùgbọ́n ìfẹ́ rẹ̀ láti gbèrú si tì í láti kẹkọ síi títí tí ó fi di agbàlejò elédèméjì níbẹ̀. Nígbàtí ilé-ìtura titun ṣí sílẹ̀, wọ́n gbà á bí ajẹ́ri ìwé ìṣirò owó alẹ́. Lẹ́hìnnáà, ó forúkọ sílẹ̀ ní BYU–Pathway Connect ó sì nka ẹ̀kọ́ kan lọ́wọ́lọ́wọ́ láti gba iwé-ẹ̀rí nínú ìgbafẹ́ àti Ilé-ìtura. Ìfẹ́ rẹ̀ ni láti di olùṣàkóso ti ilé-ìtura high-end ní ọjọ́ kan. Wildried lè pèsè fún ojúgbà ayérayé rẹ̀ àti ọmọ méjì, bákannáà bí ríran ìyá rẹ̀ àti àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò rẹ̀ lọ́wọ́. O nsìn nínú Ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ bí ọmọ ìgbìmọ̀ gíga ti èèkàn.

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ni a túmọ̀ sí bí “agbára, ìfọkànsìn, àti ìtiraka láti pèsè àwọn kòṣemáàní ìgbé-ayé fún araẹni àti ẹbí níti-ẹ̀mí àti níti-ara.”1 Títiraka láti jẹ́ olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ni ara iṣẹ́ wa ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú tí ó ndarí wa lọ sọ́dọ̀ Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Òun yíò fún ìgbàgbọ́ wa nínuí Jésù Krístì lókun yíò si so wá pọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ sí I nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga. Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ni ẹ̀kọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì kan, kìí ṣe ètò. Ó jẹ́ ìṣètò tí ó dúró títí-ayé, kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀.

A ndi olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni nínú ìgbé-ayé wa nípa dídàgbà nínú okun ti-ẹ̀mí, gbígbèrú nípa ti-ara àti ìlera ẹ̀dùn-ọkàn, lílépa ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ wa, àti mímúrasílẹ̀ níti-ara.2 Njẹ́ iṣẹ́ yí parí nínú ayé wa láéláé bí? Rárá, ó jẹ́ ìṣètò ikẹkọ, ìdàgbà, àti iṣẹ́ títí-ayé. Kò dópin láéláé, ó jẹ́ ìṣètò ojojúmọ́, tó nlọ-lọ́wọ́.

Báwo ni a ṣe lè kọ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ní ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni? Ọ̀nà kan pàtàkì ni láti lo ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ déédé. Àwọn òbí àti ọmọ nkọ́ ìhìnrere Jésù Krístì, kópa nínú iṣẹ́-ìsìn àti àwọn ìṣeré, àti ṣiṣẹ́ papọ̀ ní agbègbè mẹ́rin ti ìdàgbàsókè araẹni tí ó yàtọ̀ fún ọmọ kọ̀ọ̀kan. Kìí ṣe irú ètò kannáà tí a júwe fún gbogbo ènìyàn mọ́.

Ìwé-ìtọ́nisọ́nà àwọn ọmọdé wípé, “Nígbàtí Jésù wà ní ọjọ́ orí yín, Ó kẹkọ Ó sì dàgbà. Ẹ̀ nkẹkọ ẹ sì ndàgbà pẹ̀lú. Ìwé-mímọ́ wípé: ‘Jésù pọ̀si ní ọgbọ́n àti dídágbà, àti ní ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn’ (Luku 2:52).”3 Ìwé-mímọ́ yí tọ́ka sí dídàgbà àti ikẹkọ nínú ìṣe ti-ẹ̀mí, ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run; ìṣe ìbákẹ́gbẹ́, ojúrere pẹ̀lú ènìyàn; ìṣe ti-ara, ìdàgbà; àti iṣe ìmọ̀, ọgbọ́n. Àwọn agbègbè ìdàgbàsókè wọ̀nyí wúlò sí gbogbo wa bí ó ti wù kí ọjọ́ orí wa tó. Nígbàwo ni a nkọ́ wọn? Nínú Deuteronomy 6:6–7 a ka pé:

“Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo paláṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ:

“Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ ìsọ nígbàtí ìwọ bá joko nínú ilé rẹ, àti nígbàtí ìwọ bá nrìn ní ọ̀nà, àti nígbàtí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbàtí ìwọ bá dìde.”

A nkọ́ àwọn ọmọdé ní àwọn ohun wọ̀nyí nípa àpẹrẹ rere wa, nípa ṣíṣe iṣẹ́ àti sísìn pẹ̀lú wọn, ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, àti títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì bí a ti kọ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì.

Mo ti dàrùkọ ìyẹn nínú ètò ìdàgbàsókè àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́, àwọn ọmọdé nyàn àwọn àfojúsùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbègbè mẹ́rin ìdàgbàsókè. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n dá àwọn àfojúsùn ti ara wọn sílẹ̀ ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Àwọn òbí àti olórí lè kọ́ni, gbàni-nímọ̀ràn, àti tini-lẹ́hìn.

Fún àpẹrẹ, ọmọ-ọmọ wa Miranda ní ìwúrí gidi láti dàgbà níti-ẹ̀mí nípasẹ̀ kíkópa nínú àwọn kílásì sẹ́mínárì òwúrọ̀-kùtùkùtù. Ó ní ìfẹ́ si nípa gbígbọ́ àwọn ìfèsì dídára láti ọ̀dọ̀ àwọn akẹkọ sẹ́mínárì míràn nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀. Ìyá rẹ kò ní láti jí i dìde fún kílásì. Níti ara rẹ̀, ó wà lókè ó sì sopọ̀ nípasẹ̀ fídíò-ìpàdé-àpapọ̀ ní àkokò yíyàn ti aago mẹ́fà-kọjá ogún ìṣẹ́jú ní òwúrọ̀ nítorí òun ti dàgbàsókè nínú ìwà rere tí ó nràn án lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn òbí mi wí fún mi láìpẹ́ wípé Miranda nsọ̀rọ̀ sí i nísisìyí nígbàtí ó bá nbẹ̀ wọ́n wò, bí ó ṣe ndàgbà nínú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni. Àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí wà fún ìgbé-ayé àti ìgbèrú pẹ̀lú àwọn àbájáde tó ṣeérí.

Àwọn òbí, òbi-òbí, olórí, àti ọ̀rẹ́ nṣe ìrànlọ́wọ́ nínú ìgbèrú àti ìdàgbàsókè àwọn ọmọ. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní kíkún, papọ̀ pẹ̀lú oyèàlùfáà àti ìṣètò àwọn olórí wọ́ọ̀dù, npèsè àtìlẹhìn. “Ẹbí: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé” wípé: “Nípa ètò àtọ̀runwá, àwọn baba níláti ṣe àkóso lórí ẹbí wọn nínú ìfẹ́ àti òdodo àti pé wọ́n ní ojúṣe láti pèsè àwọn ohun àìgbọdọ̀-máni ìgbé-ayé àti ààbò fún àwọn ẹbí wọn. Àwọn ìyá ní àkọ́bẹ̀rẹ̀ ojúṣe fún títọ́ àwọn ọmọ wọn. Nínú àwọn ojúṣe mímọ́ wọ̀nyí, ó jẹ́ dandan fún àwọn baba àti ìyá láti ran ara wọn lọ́wọ́ bíi àwọn alábáṣepọ̀ dídọ́gba. … Àwọn ìbátan níláti ṣe àtìlẹhìn nígbàtí ìnílò bá wà.”4 Ìlà tó kẹ́hìn tọ́ka sí àwọn òbí-òbí, ní àárín àwọn míràn.

Bí a ṣe nsìn ní Ìwọ̀-oòrùn Áfríkà, ìyàwó mi Nuria, ti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ alámì ó sì dúró ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí wa àti ọmọ-ọmọ ní òkè òkun. Ó nṣe èyí nípa ẹ̀rọ-ìgbàlódé. Ó nka àwọn ìwé sí àwọn ọmọ-ọmọ kékeré ní lílo àwọn ohun-èlò oríṣiríṣi. Ó nkọ́ àwọn ọmọ-ọmọ obìnrin àgbà ní ẹ̀kọ́ lórí ìtàn ẹbí wa, sáyẹ́nsì, àkọọ́lẹ̀-ìtàn ti Puerto Rico, Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́, àti ìhìnrere Jésù Krístì. Àwọn ọ̀nà jíjìn òde-òní kò dáwọ́ ìsopọ̀, wíwàpẹ̀lú, ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí, àti kíkọ́ ìran àwọn ẹbí wa tó ndìde dúró. Bákannáà mo darapọ̀ mọ́ Nuria nígbàtí mo bá lè ṣé láti kọ́ àwọn ọmọ-ọmọ wa oníyebíye, láti fẹ́ràn wọn, àti láti bà wọ́n jẹ́ kí nsì mú wọn rẹrin.

Ẹ níláti ṣe àkíyèsí àwọn ìbámu ìmísí ní àárín ìdàgbàsókè àti gbígbé ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ ga. Àwọn agbègbè mẹ́rin ìdàgbàsókè nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ irúkannáà. . Okun ti-ẹ̀mí nínú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni wání-ìbámu sí ìṣe ti-ẹ̀mí nínú àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́. Ìlera ti-ara àti ẹ̀dùn-ọkàn nínú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni sopọ̀ pẹ̀lú ti-ara àti ìṣe ìbákẹ́gbẹ́ nínú àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́. Ẹ̀kọ́, iṣẹ́, àti ìmúrasílẹ̀ ti-ara nínú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ṣe pàtàkì sí iṣe ìmọ̀ nínú ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́.

Ní ìparí, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé Olùgbàlà wa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ nípa dída olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni nínú ayé wa àti kíkọ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ní èyí. A lè ṣe èyí didárajùlọ nípa

  1. Jíjẹ́ àpẹrẹ rere ti sísin àwọn ẹlòmíràn.

  2. Gbígbé àti kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, àti

  3. Gbígbọ́ran sí òfin láti gbé ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ga bí ara ìhìnrere Jésù Krístì.

Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 104:15-16 wípé:

“Ó sì jẹ́ ìpinnu mi láti pèsè fún àwọn ènìyàn mi, nítorí ohun gbogbo jẹ́ tèmi.

“Ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ níláti jẹ́ ṣíṣe ní ọ̀nà tèmi; sì kíyèsi èyí ni ọ̀nà náà tí èmi, Olúwa, ti pàṣẹ láti pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́ mi, pé kí a lè gbé àwọn ọlọ́rọ̀ sílẹ̀.”

Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì. Ìhìnrere Rẹ̀ nbùkún àwọn ẹbí nihin lórí ilẹ̀-ayé àti ní gbogbo àìlópin. Ó ntọ́ wa sọ́nà nínú ìgbé-ayé wa bí a ṣe ntiraka láti di àwọn ẹbí ayérayé. Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni èyí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn ninú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 22.0, ChurchofJesusChrist.org.

  2. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 22.1.

  3. Ìgbèrú Ti Araẹni: Ìwé Ìtọ́nisọ́nà àwọn Ọmọdé (2019], 4.

  4. Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” ChurchofJesusChrist.org.