Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Títẹ̀ Síwájú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Títẹ̀ Síwájú

Iṣẹ́ Olúwa ntẹ̀síwájú lemọ́lemọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, irú ayọ̀ kàn ni ó jẹ́ láti wà pẹ̀lú yín bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Àpapọ Gbogbogbò Àádọ́wa Ìlàjì-ọlọ́dọọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. Mo fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ yín nínú ilé yín tàbí ibikíbi tí ẹ wà, láti fetísílẹ̀ papọ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti àwọn olórí míràn.

Bí ọpẹ́ wa ti pọ̀ tó fún ẹ̀rọ tí ó fàyè gbà wá láti sopọ̀ bí gbogbo ayé nlá kan ti àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹrin tó kọjá ni a wò pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn si ju eyikeyi tó síwájú rẹ̀, a sì ní gbogbo ìrètí pé yíò ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi.

Ní àwọn oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, ajàkálẹ̀ àrùn àgbáyé kan, nja ìgbóná-kankan, àti pé àwọn àjálù àdánidá míràn yí ayé wa po. Mo ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan lára yín tí ó ti pàdánù olólùfẹ́ kan ní àsìkò yí. Mo sì gbàdúrà fún gbogbo ẹni tí ó njìyà lọ́wọ́lọ́wọ́.

Síbẹ̀, iṣẹ́ Olúwa ntẹ̀síwájú lemọ́lemọ́. Ní àárín ìjìnasíra àwùjọ, ohun ìbòjú, àti àwọn ìpàdé súmùù, a ti kọ́ láti ṣe àwọn ohunkan yatọ̀ àní a tún ṣe àwọn kan dáradára si. Àwọn ìgbà àìròtẹ́lẹ̀ lè mú àwọn èrè àìròtẹ́lẹ̀ wá.

Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa àti àwọn olóró míṣọ̀n ti jẹ́ ohun èlò, dídùró-gbọingbọin, àti alápẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ jùlọ lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nílàti wá àwọn ọ̀nà titun, àtinúdá láti ṣiṣẹ́ wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míṣọ̀n ti ròhìn ṣíṣe púpọ̀ si ní ìkọ́ni ju àtẹ̀hìnwá lọ.

A níláti ti àwọn tẹ́mpìlì fún ìgbà kan, àti pé àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé ní ìdádúró ránpẹ́, ṣùgbọ̀n nísisìyí gbogbo wọn ntẹ̀síwájú. Ní ìgbà ọdún 2020, à bá ti fọ́ ilẹ̀ fún àwọn ogun tẹ́mpìlì titun!

Iṣẹ́ ìtàn ẹbí ti npọ̀si lọ́pọ̀lọpọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wọ́ọ̀dù titun àti èèkàn ni a ti dá sílẹ̀. A sì ní inúdídùn láti ròhìn pé Ìjọ ti pèsè ìrànlọ́wọ́ ohun-ìtura fún iṣẹ́ ọgọrunmẹ́jọ̀ àti ọgọ́rinléméjì ní orílẹ̀-èdè mọ́kandínláàdọ́fà.

Àṣàrò ìhìnrere púpọ̀si ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé tí yọrísí àwọn ẹ̀rí àti ìbáṣepọ̀ tó lágbára. Ìya kan kọ pé: “A nímọ̀lára sísún mọ àwọn ọmọ wa àti ọmọ-ọmọ nísisìyí tí à nkórajọ lórí súmùù ní gbogbo Ọjọ́-ìsinmi. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ngba ìyípo ní fífúnni ní àwọn èrò lórí Wá, Tẹ̀lé Mi. Àwọn àdúrà fún àwọn ọmọ ẹbí wa ti yípadà nítorí a ní ìmọ̀ si ohun tí wọ́n nílò.”

Mo gbàdúrà pé àwa bí ènìyàn kan á lo ìgbà àìlékejì láti dàgbà níti ẹ̀mí. Àwa wà nihin lórí ilẹ̀-ayé láti gba ìdánwò, láti ri bóyá a ó yàn láti tẹ̀lẹ́ Jésù Krístì, láti ronúpìwàdà léraléra, láti kẹkọ, àti láti ní ìlọsíwájú. Àwọn ẹ̀mí wa nwá láti ní ìlọsíwájú. A ó sì ṣe èyí dídára jùlọ̀ nípa dídúróṣinṣin ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Nínú gbogbo rẹ̀, Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì nifẹ wa! Wọ́n nṣìkẹ́ wa! Àwọn àti angẹ̀lì mímọ́ Wọn nṣọ́ wa.1 Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni.

Bí a ti kórajọ láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti nísí àwọn iránṣẹ́ Rẹ̀ láti fúnni, mo pè yín láti jíròrò ìlérí kan tí Olúwa ti ṣe. Ó kéde pé “ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú, èyí tí ó ye tí ó sì ní agbára, tí yíò sì pín gbogbo ẹ̀tàn … àti ọgbọ́n arékérekè èṣù nnì, tí yíò sì darí [ọmọẹ̀hìn] Krístì sí ipá ọ̀nà èyí tí ó há tí ó sì ṣe tóóró.”2

Mo gbàdúrà pé ẹ ó yàn láti di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú bí a ti kéde nínú ìpàdé àpapọ̀ yí. Mo sì gbàdúrà pé kí ẹ lè ní ìmọ̀lára pípé Olúwa fún yín,3 ní orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.