Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
À Sọ̀rọ̀ Nípa Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


À Sọ̀rọ̀ Nípa Krístì

Bí ayé ti nsọ̀ díẹ̀ nípa Jésù Krístì, ẹ jẹ́ kí a sọ̀ jùlọ nípa Rẹ̀ si.

Mo fi ìfẹ́ mi hàn fún yín, ẹ̀yin àyànfẹ́ ọ̀rẹ́ àti ọmọnìkejì onígbàgbọ́ wa. Mo fẹ́ràn ìgbàgbọ́ àti ìgboyà yín ní àárín àwọn oṣù tó kọjá wọ̀nyí, bí àjàkálẹ̀ àrùn gbogbo ayé ṣe nda ayé wa láàmú tí ó sì nmú àwọn iyebíye ọmọ ẹbí àti ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n lọ.

Ní ìgbà àìnídánilójú yí, mo ti ní ìmọ̀lára ìmoore àìláfiwé nítorí ìmọ̀ dídájú àti pàtó pé Jésù ni Krístì. Ṣe ẹ ti ní ìmọ̀lára lọ́nà yí? Àwọn ìṣòro tí ó tẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa mọ́lẹ̀ wà, ṣùgbọ́n nígbàgbogbo níwájú wa ni ẹni tí Ó kéde pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè.”1 Nígbàtí a farada àkokò ti jíjìnà síra wa kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, a kò nílò láti farada àkokò jíjìnà ti ẹ̀mí arawa kúrò lọ́dọ̀ Rẹ ẹnití ó fi tìfẹ́tìfẹ́ pè wá, “Wá sọ́dọ̀ mi.”2

Gẹ́gẹ́bí ìràwọ̀ tí ó ntàn kedere, ní ojú ọ̀run dúdú, Jésù Krístì nfi ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa. Ó wá sí ilẹ̀-ayé nínú ibùjẹ ìrẹ̀lẹ̀. Ó gbé ìgbé ayé pípé. Ó wo aláìsàn ó sì jí òkú dìde. Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ sí ẹni tí a gbàgbé. Ó kọ́ wa láti ṣe rere, láti gbọ́ràn, àti láti nifẹ ara wa. Ó kú lórí àgbélèbú, ó dìde nínú ọlánlá lọ́jọ́ mẹ́ta lẹ́hìnnáà, ó fàyè gba wá àti àwọn tí a nifẹ láti gbé ìgbé ayé kọjá ibojì. Pẹ̀lú àánú àti oore-ọ̀fẹ́ àìláfiwé Rẹ̀, Ó gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìjìyà wa lé orí Ararẹ, ó mú ìdáríjì wá bí a ti nronúpìwàdà ati àláfíà nínú ìjì ayé. A nifẹ Rẹ̀. À njọ́sìn Rẹ̀. À ntèlé E. Òun ni Olùmúdúró ẹ̀mí wa.

Ó dùn mọ́ni pé, nígbàtí ìdánilójú ti-ẹ̀mí yí npọ̀si ni àárín wa, àwọn kan wà ní ayé tí wọ́n mọ ohun kékeré nípa Jésù Krístì, àti ní àwọn ara ibìkan ayé níbi a tí nkéde orúkọ Rẹ̀ fún àwọn sẹ́ntúri, ìgbàgbọ́ nínú Krístì ndínkù. Àwọn akọni Ènìyàn Mímọ́ ní Europe ti ri tí ìgbàgbọ́ wọn ndínkù nínú àwọn orílẹ̀ èdè ní awọn díkédì.3 Ó baninínújẹ́, nihin ní United States ìgbàgbọ́ nrẹlẹ̀ bakannáà. Nínú ẹ̀kọ́ àìpẹ́ tí a fihàn pé ní àwọn ọdún mẹwa tó kọjá, ọgbọ̀n míllíọ́nù àwọn ènìyàn ní United States ti gbésẹ̀ kúrò ní ìgbàgbọ́ nínú àtọ̀runwá Jésù Krístì.4 Wíwo gbogbo ayé, ẹ̀kọ́ míràn sọtẹ́lẹ̀ pé nínú àwọn díkédì níwájú díẹ̀ síi ju ìlọ́po méjì bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò ṣe fi Krístẹ́nì sílẹ̀ ju àwọn tí yíò gbàá mọ́ra lọ.5

Àwa, bẹ́ẹ̀náà, bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan láti yàn, síbẹ̀ Baba wa Ọ̀run wí tán pé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi: gbọ́ tirẹ̀.”5 Mo jẹri pé ọjọ́ yíò dé tí gbogbo eékún yíò wólẹ̀ tí gbogbo èdè yíò jẹ́wọ́ pé Jésù ni Krístì.7

Báwo ni a ó ti fèsì sí ayé wa tó nyípadà? Nígbàtí àwọn kan npa ìgbàgbọ́ wọn ti, àwọn míràn nwá òtítọ́ kiri. A ti gba orúkọ Olùgbàlà sórí ara wa. Kíni a lè ṣe si?

Imímúrasílẹ̀ ti Ààrẹ Russell M. Nelson

Àra ìdáhùn wa lè wá bí a ti nrántí bí Olúwa ti nkọ́ Ààrẹ Russell M. Nelson ní àwọn oṣù ṣíwájú ìpè rẹ̀ bí Ààrẹ Ìjọ. Sísọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ àgbà ní ọdún kan sí ìpè rẹ̀, Ààrẹ Nelson pè wá láti ṣe àṣàrò àwọn ìtọ́nisọ́nà ẹgbẹ̀rúnméjìlénígba jinlẹ̀jinlẹ̀ si nípa orúkọ Jésù Krístì tí a dárúkọ nínú Ìtọ́nisọ́nà Agbègbè.8

Àwòrán
Ààrẹ Nelson nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́

Oṣù mẹta lẹ́hìnnáà, nínú ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹrin, àní pẹ̀lú àwọn díkédì ipò-àpóstélì rẹ̀, ìjìnlẹ̀ àṣàrò ti Jésù Krístì yí ti kàn án lára gidi. Arábìnrin Wendy Nelson bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ipá tí ó ní lori rẹ̀. Ó fèsì pé, “Èmi jẹ́ ọkùnrin tó yàtọ̀.” Ó ti jẹ́ ọkùnrin tí ó yàtọ̀? Ní ọjọ́ orí àádọ́rúnléméjì, ṣé ó jẹ́ ọkùnrin kan tó yàtọ̀? Ààrẹ Nelson ṣàlàyé

“Bí a ṣe dókòwò ìgbà ní kíkọ́ nípa Olùgbàlà àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, à nsúnmọ [Ọ]. …

“… Ìfojúsùn wa [di] ìsomọ́ Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀.”9

Olùgbàlà wípé, “Wo mí nínú gbogbo èrò.”10

Nínú ayé iṣẹ́, ìdàmú, àti ìtiraka yíyẹ, tí a npamọ́ sínú ọkàn wa, inú wa, àti èrò wa lórí Rẹ̀ ẹnítí ó jẹ́ ìrètí àti ìgbàlà wa.

Bí àtúnṣe àṣàrò nípa Olùgbàlà bá ṣèrànwọ́ láti múra Ààrẹ Nelson sílẹ̀, ṣé kò ní ṣèrànwọ́ láti múra wa sílẹ̀ bákannáà?

Àwòrán
Alàgbà Russell M. Nelson

Ní títẹnumọ́ orúkọ Ìjọ, Ààrẹ Nelson kọ́ni pe: “Tí àwà … bá ní ààyè sí agbára Ètùtù Jésù Krístì—láti wẹ̀ àti láti wò wá sàn, láti gbéga àti láti fún wa ni ókun, àti nígbẹ̀hìn láti gbé wa ga—a gbọ́dọ̀ dá A mọ̀ dáadáa bí orisun agbára náà.”11 Ààrẹ Nelson kọ́ wa pé lílo orúkọ tòótọ́ Ìjọ léraléra ohun kan tí ó dàbí ó kéré, kò kéré rárá àti pé yíò sì tún ọjọ́-ọ̀la ayé wa ṣe.

Ìlérí kan fún Mímúrasílẹ̀ Yín

Mo ṣe ìlérí fún yín pé bí a ṣe nmúra ara wa sílẹ̀, bí Ààrẹ Nelson ti ṣe, àwa bákannáà yíò yàtọ̀, ní ríronú nípa Olùgbàlà, àti ní sísọ̀rọ̀ nípa Rẹ̀ léraléra si àti pẹ̀lú ìdínkù iyèméjì. Bí a ṣe nwá láti mọ̀ àti láti nifẹ Rẹ̀ jinlẹ̀ si, àwọn ọ̀rọ̀ yín yíò ṣàn tààrà si, bí wọ́n ti nṣe nìgbàtí ẹ bá sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín tàbí ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan. Àwọn tí ó nfetísílẹ̀ sí yín yíò ní ìdínkù ìmọ̀lára bíi ìdíje tàbí pípa yín ti sẹgbẹ àti kíkọ́ ẹ̀kọ́ si látọ̀dọ̀ yín.

Ẹ̀yin àti èmi nsọ̀rọ̀ nípa Jésù Krístì, ṣùgbọ́n a lè ṣe dáradára díẹ̀ si nígbàgbogbo. Bí ayé yíò bá sọ̀rọ̀ dínkù nípa Rẹ̀, tani yíò sọ̀rọ̀ nípa Rẹ̀ jù? Àwa ni! Lẹgbẹ pẹ̀lú àwọn olùfọkànsìn Krìstẹ́nì míràn!

Sísọ̀rọ̀ nípa Krístì nínú Ilé Wa

Ṣé àwọn àwòrán Olùgbàlà wa ní ilé wa? Njẹ́ à nsọ̀rọ̀ léraléra sí àwọn ọmọ wa nípa àwọn òwe Jésù? “Àwọn ìtàn Jésù [dàbí] ìyára afẹ́fẹ́ káàkiri éérú-ìgbóná ìgbàgbọ́ nínú ọkàn àwọn ọmọ wa.”12 Nígbàtí àwọn ọmọ yín bá bèèrè ìbèèrè lọ́wọ́ yín, ẹ fi taratara ronú nípa ìkọ́ni ohun tí Olùgbàlà kọ́. Fún àpẹrẹ, tí ọmọ yín bá bèère pé, “Baba, kínídí tí a fi ngbàdúrà ní ọ̀nà tí à ngbàdúrà?” Ẹ lè fèsì, “Ìyẹn ni ìbèère nlá. Ṣe ẹ rántí ìgbàtí Jésù gbàdúrà? Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Ó fi gbàdúrà àti bí Ó ti gbàdúrà.”

“À nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, … pé kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”13

Sísọ̀rọ̀ nípa Krístì nínú Ìjọ

Ìwé mímọ́ yí kannáà fikun pé a “wàásù nípa Krísti.”14 Nínú iṣẹ́-ìsìn ìjọ́sìn wa, ẹ jẹ́ kí a fi ìgbàgbogbo dojúkọ Olùgbàlà Jésù Krístì àti ẹ̀bùn ètùtù ìrúbọ Rẹ̀. Èyí kò túmọ̀sí pé a kò lè sọ ìrírí kan látinú ayé ara wa tàbí ṣe àbápín èrò kan látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nígbàtí ẹ̀kọ́ wa bá lè jẹ́ nípa àwọn ẹbí tàbí iṣẹ́-ìsìn tàbí tẹ́mpìlì tàbí míṣọ̀n àìpẹ́, gbogbo ohun tó wà nínú ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ nawọ́ sí Olúwa Jésù Krístì.

Ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn, Ààrẹ Dallin H. Oaks sọ̀rọ̀ nípa lẹ́tà tí o gbà “látọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tí o sọpé lílọ sí ìpàdé [oúnjẹ Olúwa kan] àti fìfi etí sílẹ̀ sí àwọn ẹ̀rí mẹ́tàdínlógún láì gbọ́ kí a darúkọ Olùgbàlà.”15 Ààrẹ Oaks nígbànáà ṣe àkíyèsí, “Bóyá a sọ àsọdùn ìjúwe náà [ṣùgbọ́n] mo ṣe àyọsọ rẹ̀ nítorí ó pèsè ìrántí híhàn gidi fún gbogbo wa.”16 Nígbànáà Ó pè wá láti sọ̀rọ̀ si nípa Jésù Krístì nínú àwọn ọ̀rọ̀ wà àti kíláàsì ìbárasọ̀rọ̀. Mo ṣe àkíyèsí pé a ní ìdojúkọ púpọ̀ àti púpọ̀ si lórí Krístì nínú àwọn ìpàdé Ìjọ wa. Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú taratara pẹ̀lú àwọn ìtiraka dídára wọ̀nyí.

Sísọ̀rọ̀ nípa Krístì pẹ̀lú àwọn Ẹlòmíràn

Pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àyíká wa, ẹ jẹ́ kí a fetísílẹ̀ si, ní ìfẹ́ sí láti sọ̀rọ̀ Krístì. Ààrẹ Nelson wípé, “Àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tóótọ́ nfẹ́ láti dúró gbọingbọin, sọ̀rọ̀ síta, kí wọ́n sì yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn ayé.”17

Nígbàmíràn à nronú pé ìbarasọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan nílò láti yọrísí wíwá sí ìjọ wọn tàbí rírí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ẹ jẹ́ ki Olúwa tọ́ wọn sọ́nà bí wọ́n ti fẹ́, nígbàtí à nronú si nípa ojúṣe wa láti jẹ́ ohùn kan fun Un, ní ìrònú kí a sì la ẹnu wa nípa ìgbàgbọ́ wa. Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti kọ́ wa pé nígbàtí ẹnìkan bá bèèrè lọ́wọ́ wa nípa òpin ọ̀sẹ̀ wa, ó yẹ kí a rẹrin kí a sì wípé a nifẹ láti gbọ́ orin àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ, “Èmi ngbìyànjú láti dàbí Jésù.”18 Ẹ jẹ́ kí a finúrere jẹri ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì. Bí ẹnìkan bá sọ̀rọ̀ nípa wàhálà kan tí ọkùnrin tàbí obìnrin náà ti ní ní ayé araẹni wọn, a lè wípé, “Jòhánnù, Màríà, ẹ mọ̀ pé mo gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Mo ti nronú nípa ohun kan tí Ó sọ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́.”

Ẹ fi etísílẹ̀ lórí ìròhìn àwujọ ní sísọ̀rọ̀ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú Krístì. Ọ̀pọ̀ yíò bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa, ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ngbójú kúrò nígbàtí ẹ̀ nbá wọn sọ̀rọ̀ nípa Olùgbàlà, ẹ ní ìgboyà látinú ìlérí Rẹ̀: “Alábùkúnfún ni ẹ̀yín, nígbàtí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín … nítorí èmi. … Nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run.”19 À nṣìkẹ́ jíjẹ́ àtẹ̀lé Rẹ̀ ju kí àwọn àtẹ̀lé ara wa ní “fífẹ́ràn” àwọn atẹ̀lé ara wa. Pétérù fúnni ní àmọ̀ràn pé: “Kí a ṣetán láti fúnni ní ìdáhùn [fún] ìrètí tí ó wà nínú yín.”18 Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ Krístì.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí alágbára nípa Jésù Krístì. Gbogbo ojú-ewé rẹ̀ ni ó jẹri nípa Olùgbàlà àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àtọ̀runwá rẹ̀.21 Níní ìmọ̀ Ètùtù Rẹ̀ àti oore-ọ̀fẹ́ nmú ìdàpọ̀ àwọn ojú-ewé rẹ̀ wá. Gẹ́gẹ́bí ojúgbà sí Májẹ̀mú Titun, Ìwé ti Mọ́mọ́nì nràn wá lọ́wọ́ dáradára si láti ní ìmọ̀ ìdí tí Olùgbàlà nwá láti gbà wá là àti bí a ṣe lè wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìjìnlẹ̀.

Àwọn kan lára àwọn ọmọlakeji Krìstẹ́ni wa, nígbàmíràn, kò ní ìdánilójú nípa àwọn ìgbàgbọ́ wa àti gbígbọ̀ nípa àwọn ìgbèrò wa. Ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ yayọ̀ pẹ̀lú wọn ní pípín ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì àti nínú ìwé-mímọ́ Májẹ̀mú Titun tí a nifẹ. Nínú àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì yíò nílò ìbáṣọ̀rẹ́ àti àtìlẹhìn ara wa.22

Àwòrán
Ìmọ́lẹ̀ Ayé

Bí ayé ti nsọ̀ díẹ̀ ní ti Jésù Krístì, ẹ jẹ́ kí a sọ̀ jùlọ nípa Rẹ̀ si. Bí ìwà òtítọ́ wa gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àyíká wa yíò múrasílẹ̀ láti fetísílẹ̀. Bí a ti nṣe àbàpín ìmọ́lẹ̀ tí a gbà látọ̀dọ̀ Rẹ, ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ àti agbára títayọ ìgbàlà Rẹ̀ yíò tàn sórí àwọn tí ó nfẹ́ láti ṣí ọkàn wọn. Jésù wípé, “Èmi … wá [bí] ìmọ́lẹ̀ kan sí ayé.”23

Gbígbé Ìfẹ́-inú Wa Ga láti Sọ̀rọ̀ nípa Krístì

Kò sí ohun tí ó ngbé ìfẹ́ mi láti sọ̀rọ̀ Krístì ga ju bí mo ṣe nrí ìpadàbọ̀ Rẹ̀ si. Nígbàtí a kò mọ ìgbàtí yíò dé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìpadàbọ̀ Rẹ̀ yíò wọni lọ́kan! Òun yíò wá nínú ìkukù ọ̀run nínú ọlánlá àti ògo pẹ̀lú gbogbo àwọn ángẹ́lì Rẹ̀. Kìí ṣe àwọn ángẹ́lì díẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí kìí ṣe cherry-cheeked kérúbù tí a kùn láti ọwọ́ Raphael, tí a rí lórí káàdì Àyájọ́-olólùfẹ́ wa. Ìwọ̀nyí ni àwọn ángẹ́lì ti sẹ́ntúrì, a rán àwọn ángẹ́lì láti pa ẹnu àwọn kìnìún dé,24 láti ṣí ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n,25 láti polongo ibí Rẹ̀ tí a ti dúró dè tipẹ́tipẹ́,26 láti tu U nínú ní Gẹ́thsémánì,27 láti mú ìgòkère-ọ̀run Rẹ̀ dá àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ lójú,28 àti láti ṣí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ológo.29

Àwòrán
Ìpadabọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì

Ṣe ẹ lè ro jíjẹ́ wíwà pẹ̀lú Rẹ̀, bóyá ní ẹ̀gbẹ́ yí tàbí ní ẹgbẹ́ kejì ìbòjú?30 Ìyẹn ni ìlérí Rẹ̀ sí olódodo. Ìrírí náà yíò sàmì sí ẹ̀mí wa títíláé.

Bí a ti ní ìmoore fún àyànfẹ́ wòlíì wa tó, Ààrẹ Russell M. Nelson, ẹnití ó gbé ìfẹ́ wa ga láti fẹ́ràn Olùgbàlà àti láti kéde àtọ̀runwá Rẹ̀. Èmi ni olujẹri sí ọwọ́ Olúwa lórí rẹ̀ àti ẹ̀bùn ìfihàn tí ó ntọsọ́nà. Ààrẹ Nelson, a nfi ìtara dúró de àmọ̀ràn yín.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi káàkiri ayé, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ Krístì, ríretí ìlérí ológo Olùgbàlà: “Ẹnikẹ́ni … tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn … níwájú Baba mi.”31 Mo mọ̀ pé Òun ni Ọmọ Ọlọ́run. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jòhánnù14:6.

  2. Matteu 11:28.

  3. Wo Niztan Peri-Rotem, “Ẹ̀sìn àti Ìrọyin ní Gúsù Europe: Wà káàkiri Cohorts ní Britain, France àti ní Netherlands,” Ará Europe Ìrohin Olùgbé, May 2016, 231–65, ncbi.nlm.nih.gov/pmc/articles/PMC4875064.

  4. “[Ìpín ọgọ́talémarun] ti àgbàlagbà Amẹ́ríkà júwe arawọn bí Krìstẹ́nì nígbàtí a bi wọ́n nípa ẹ̀sìn wọn, sílẹ̀ sí ìpín àmì méjìlá lórí díkéèdì tó kọjá. Meanwhile, the religiously unaffiliated share of the population, consisting of people who describe their religious identity as atheist, agnostic or ‘nothing in particular,’ now stands at 26%, up from 17% in 2009” (Pew Research Center, “In U.S., Decline of Christianity Continues at Rapid Pace,” Oct. 17, 2019, pewforum.org).

  5. Wo Pew Research Center, “The Future of World Religions: Population Growth Projections, 2010–2050,” Apr. 2, 2015, pewforum.org.

  6. Mark 9:7; Luke 9:35; see also Matthew 3:17; Joseph Smith—History 1:17.

  7. Wo Àwọn Ará Fílíppì 2: 9– 11.

  8. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Wòlíì, Jíjẹ́ Olórí, àti Àṣẹ Àtọ̀runwá” (worldwide devotional for young adults, Jan. 8, 2017), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org.

  9. Russell M. Nelson, “Fífa Agbára Krístì Sínú Ayé Wa,” Liahona, May 2017, 41.

  10. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36.

  11. Russell M. Nelson, “TorúkọTOrúkọ Títọ́ Ìjọ,” Liahona, Nov. 2018, 88.

  12. Neil L. Andersen, “Sọ a`wọn Ìtàn Jésù fún Mi,” Liahona, May 2010, 108.

  13. 2 Néfì 25:26.

  14. 2 Néfì 25:26.

  15. Dallin H. Oaks, “Ẹ̀rí Jésù Krístì Míràn” (Brigham Young University fireside, June 6, 1993), 7, speeches.byu.edu.

  16. Dallin H. Oaks, “Ẹ̀rí Krístì,” Ensign, Nov. 1990, 30.

  17. Russell M. Nelson, “Fífa Agbára Krístì Sínú Ayé Wa,” 40.

  18. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Missionary Work: Sharing What Is in Your Heart,” Liahona, May 2019, 17; “I’m Trying to Be like Jesus,” Children’s Songbook, 78.

  19. Máttéù 5:11–12.

  20. 1 Pétérù 3:15.

  21. Bí [the Book of Mormon prophetic scribes] wrote their testimonies of the [Beloved Son of God], they mentioned some form of his name on an average of every 1.7 verses. [They] referred to Jesus Christ by, literally, 101 different names. … Nígbàtí we realize that a verse usually consists of one sentence, it appears that we cannot, on the average, read two sentences in the Book of Mormon without seeing some form of Christ’s name” (Susan Easton Black, Finding Christ through the Book of Mormon [1987], 5, 15).

    “While the words atone or atonement, in any of their forms, appear only once in the King James translation of the New Testament, they appear 35 times in the Book of Mormon. Gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí Jésù Krístì míràn, ó tan ìmọ́lẹ̀ iyebiye lórí Ètùtù Rẹ̀” (Russell M. Nelson, “Ètùtù Náà; Ensign, Nov. 1996, 35).

  22. Those leaving Christianity in the United States are younger. “More than eight-in-ten members of the Silent Generation (those born between 1928 and 1945) describe themselves as Christians (84%), as do three-quarters of Baby Boomers (76%). In stark contrast, only half of Millennials (49%) describe themselves as Christians; four-in-ten are religious ‘nones,’ and one-in-ten Millennials identify with non-Christian faiths” (“In U.S., Decline of Christianity Continues,” pewforum.org).

  23. Jòhànnù 12:46.

  24. Wo Daniel 6:22.

  25. Wo Ìṣe Àwọn Àpóstélì 5:19.

  26. Wo Lúkù 2:2–14.

  27. Wo Lúkù 22:42–43.

  28. Wo Iṣe àwọn Àpóstélì 1: 9– 11.

  29. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 13; 27:12–13; 110:11–16; Joseph Smith—History 1:27–54.

  30. Wo 1 Thessalonians 4:16-17; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:96–98.

  31. Máttéù 10:32.