Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Rẹ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Rẹ

Ní mímọ̀ pé gbogbo wa ni ọmọ Ọlọ́run nfún wa ní ìran àtọ̀runwá nípa gbogbo àwọn míràn àti ìfẹ́ àti okun láti dìde kọjá ẹ̀tanú.

Àwọn ìkọ́ni Olúwa wà fún ayérayé àti fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nínú ọ̀rọ̀ yí èmi ó fúnni ní àwọn àpẹrẹ kan láti Ìlú Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí wọ́n nkọ́ wúlò níbigbogbo.

À ngbé ní ìgbà ìbínú àti ìkóríra kan nínú àwọn ìbáṣepọ̀ òṣèlú àti àwọn ètò. A ní ìmọ̀làra rẹ̀ ní ìgbà ooru yí ní ibi tí àwọn kan ti kọjá àtakò àláfíà tí wọ́n sì nhùwà ìparun. A ní ìmọ̀lára rẹ nínú àwọn ìpolongo fún ibi-iṣẹ gbàngba tó nlọ lọ́wọ́. Láìlóríre, àwọn yí tilẹ̀ ti tànká sínú àwọn ìsọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìtọ́kasí àìnìnúrere nínú àwọn ìpàdé Ìjọ wa.

Nínú ìjọba tiwantiwa a ó ní àwọn ìyàtọ̀ nígbàgbogbo lórí ẹnití a fẹ́ àti àwọn ètò. Bákannáà, bí àwọn àtẹ̀lé Krístì a gbọ́dọ̀ pa ìbínú ti àti ìríra pẹ̀lú èyí tí a ndíje àwọn àṣàyàn òṣèlú tàbí kí a kọ̀ọ́ nínú àgbékalẹ̀ eyikeyi.

Àwòrán
Ìwàásù lórí Òkè

Nihin ni ọ̀kan lára àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà, bóyá tí a mọ̀ dáadáa ṣùgbọ́n tí a kìí lò déédé.

“Ẹ gbọ́ bí a ti wipé, Ẹ̀yin gbọ́dọ̀ fẹ́ ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì kóríra ọ̀tá yín.

“Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe õre fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò tí wọn nṣe inúnibíni sí yín” (Máttéù 5:43–44).1

Fún ìrandíran, àwọn Júù ní a ti kọ́ láti kóríra àwọn ọ̀tá wọn, nígbànáà wọ́n sì njìyà lábẹ́ ìdarí àti ìkà ti ojúṣe Ará Rome. Síbẹ̀, Jésù kọ́ wọn láti “fẹ́ àwọn ọ̀tá wọn” kí wọ́n sì “ṣe rere sí àwọn tí … o kóríra yín.”

Àwòrán
Jésù nkọ́ní nínú àwọn Amẹ́ríkà

Irú àwọn ìkọ́ni rògbòdìyàn fún àwọn ìbáṣe araẹni àti òṣèlú! Ṣùgbọ́n ìyẹn ṣì ni ohun tí Olùgbàlà pàṣẹ kí a ṣe. Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, “Nítorí lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití ó bá ní ẹ̀mí asọ̀ kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù ni ṣe, ẹnití íṣe bàbá asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú” (3 Néfì 11:29).

Fífẹ́ àwọn ọ̀tá wa àti àwọn onínúnibini kò rọrùn. “Púpọ̀ lára wa kò tíì dé ipele ti … ìfẹ́ àti ìdáríjì,” Ààrẹ Hinckley ṣe àkíyèsí, ó fikun pé, “ó fẹ́rẹ̀ gba ìkóraẹni-níjánu púpọ̀ ju bí a ṣe lágbára.”2 Ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì, nítorí ó jẹ́ ara àwọn òfin méjì gíga Olùgbàlà láti “fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ” àti láti “fẹ́ ọmọ.nìkejì bí ara rẹ” (Máttéù 22:37, 39 Ó sì gbọ́dọ̀ ṣeéṣe, nítorí Ó ti kọ́ni pé, “Bèèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí” (Máttéù 7:7).3

Báwo ni a ṣe lè pa àwọn òfin àtọ̀runwá wọ̀nyí mọ́ nínù ayé níbití wọ́n ti mú wá mọ́lẹ̀ sínù àṣẹ ènìyàn? Lóríre, a ní àpẹrẹ ti Olùgbàlà fúnrarẹ̀ àti àpẹrẹ bí á ó ṣe mú àwọn àṣe ayérayé Tirẹ̀ pẹ̀lú àwọn ṣíṣe àṣẹ àfọwọ́dá. Nígbàtí àwọn ọ̀tá bá wá láti dèé mọ́lẹ̀ pèlú ìbèèrè kan nípa bóyá ó yẹ kí àwọn Júù san owó orí sí Rómù, Ó nawọ́ sí àwòrán Ceasar lórí ẹyọ-owó wọn ó sì kéde: “Njẹ́ ẹ fi ohun tí ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run” (Lúkù 20:25).4

Àwòrán
Fi Fún Caesar

Nítoríanáà, a níláti tẹ̀lé àwọn àṣẹ ènìyàn (fi fún Késárì) láti gbé pẹ̀lú àláfíà lábẹ́ àṣẹ ìbílẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé àwọn àṣẹ Ọlọ́run láti tẹ̀síwájú òpin àjò ayérayé wa. Ṣùgbọ́n báwo ni a ó ti ṣe èyí—nípàtàkì báwo ni a ó ti kọ́ láti fẹ́ àwọn ọ̀tá àti onínúnibíni wa?

Ìkọ́ni Olùgbàlà kí a máṣe “ja pẹ̀lú ìbínú” ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Èṣù ni baba ìjà, òun sì ni ẹnití ó ndán àwọn ènìyàn wo láti jà pẹ̀lú ìbínú. Láti gbé ọ̀tẹ̀ àti ìbáṣepọ̀ ìríra ga ní àárín olúkúlùkù àti àárín ẹgbẹ́. Ààrẹ Thomas S, Monson kọ́ni pé ìbínú ni “Irinṣẹ́ Sátánì,” nítorí “láti bínú ni láti juwọ́lẹ̀ sí agbára Sátánì. Kò sí ẹnikan tí ó lè wa bínú. Àṣàyàn wa ni.”5 Ìbínú ni ọ̀nà sí ìyapa àti ọ̀tẹ̀. À nrìn síwájú fífẹ́ àwọn ọ̀tá nígbàtí a bá yẹra fún ìbínú tí a sì kúró nínú ìkanra sí àwọn tí a kò bárẹ́. Bákannáà ó nṣèrànwọ́ àní tí a bá nfẹ́ láti kẹkọ látinú wọn.

Ní àárín àwọn ọ̀nà míràn láti gbèrú agbára láti fẹ́ àwọn ẹlòmíràn ni ọ̀nà ìrọ̀rùn tí a júwe nínú àwọn ọ̀rọ̀ olórin kan tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn. Nígbàtí a ngbìyànjú láti ní ìmọ̀ àti láti bá àwọn ènìyàn àṣà ọ̀tọ̀tọ̀ ṣe, ó yẹ kí a gbìyànjú láti mọ̀ wọ́n. Nínú àwọn ipò àìlónkà, ìfura àwọn àlejò àní bíburú nfi ọ̀nà fún ìbádọ́rẹ̀ tàbí àní fẹ́ràn nígbàtí àwọn ìbaṣe araẹni bá mú níní ìmọ̀ àti ọ̀wọ̀ irúkannáà jáde.6

Àní ìrànlọ́wọ́ tó ga jùlọ ní kíkọ́ láti fẹ́ àwọn ọ̀tá wa àti àwọn onínunibíni ni láti wá àti láti ní ìmọ̀ agbára ìfẹ́. Nihin ni mẹ́ta lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìkọ́ni ti wòlíì nípa èyí.

Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé “ó jẹ́ òwe ìgbà tí a bú-ọlá fún pé ìfẹ́ nmú ìfẹ́ jáde. Ẹ jẹ́ kí a tú ìfẹ́ jade—kí a fi inúrere hàn sí gbogbo ènìyàn.”7

Àarẹ Howard W. Hunter kọ́ni pé: “Inú ayé èyí tí à ngbé yíò mú èrè nlá wá tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin níbigbogbo yíò lo ifẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Krístì. Kìí ṣe láìsí owú tàbí ìgbéraga. … Kìí wá ohunkóhun ní ìọ́pò. … Kò ní ààyè fún ìtara, ìríra, tàbí ìwà-ipá. … Ó ngba onírurú àwọn ènìyàn níyànjú láti gbé papọ̀ nínú ìfẹ́ Krìstẹ́nì láaìka ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn, ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, dídúró ìṣúná-owó, ẹ̀kọ́, tàbí ọ̀làjú.”8

Ààrẹ Russell M. Nelson ti rọ̀ wá “ẹ mú agbo wa nípa ìfẹ́ gbòòrò láti gba gbogbo ẹbí ẹlẹ́ran-ara mọ́ra.”9

Apákan pàtàkì ti fífẹ́ àwọn ọ̀tá wa ni láti fi fun Késárì nípa pípa àwọn àṣẹ ti onírurú àwọn orílẹ̀-èdè wa mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìkọ́ni Jésù jẹ́ rògbòdìyàn, Kò kọ́ rògbòdìyàn tàbí kọ kíkọ-ẹ̀hìn sí òfin. Ó kọ́ni ní ọ̀nà dídára si. Ìfihàn òde-òní kọ́ni bákannáà:

“Ẹ máṣe jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni kọ ẹ̀hìn sí àṣẹ ilẹ̀, àṣẹ ìfihàn òde-òní nítorí ẹni tí ó bá pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ kò nílò láti kọ ẹ̀hìn sí òfin ilẹ̀.

“Nítorínáà, ẹ wà lábẹ́ agbára tí ó wà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58:21–22).

Àti pé nkan ìgbàgbọ́ wa, tí a kọ́ látọwọ́ Wòlíì Joseph Smith lẹ́hìn tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣíwájú ti jìyà inúnibíni líle látọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Míssouri, wọ́n kéde pé: “A gbàgbọ́ ní wíwà lábẹ́ àwọn ọba, ààrẹ, aláṣẹ, àti adájọ́, ní gbígbọ́ràn, bíbuọlá-fún, àti mímúdúró àṣẹ” (Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:12).

Èyí kò túmọ̀ sí pé a wà ní ìbámu pẹ́lú gbogbo ohun tí à nṣe pẹ̀lú ìmúṣẹ ti àṣẹ. Ó túmọ̀ sí pé a gbọ́ran sí àṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti kí a lo ìtumọ̀ àláfíà láti ṣe ìyípadà rẹ̀. Bákannáà ó túmọ̀ pé a ó fi àláfíà tẹ́wọ́gba àbájáde ìdìbò. A kò ní kópa nínú ìjà-ipá nípasẹ̀ ìbẹ̀rù àwọn tí kò faramọ́ àyọrísí. Ní àwùjọ tiwatiwa à nfi ìgbàgbogbo ní ànfàní àti ojúṣe láti ní ìtẹramọ́ àláfíà títí di ìdìbò tó nbọ̀.

Ìkọ́ni Olùgbàlà láti fẹ́ àwọn ọ̀tá wa ni ó dá lórí òdodo pé gbogbo àwọn ara ayé ikú jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ayérayé náà àti àwọn kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àṣẹ ní a dánwò nínú àtakò àìpẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá Ará Amẹ́ríkà.

Àwòrán
Àtakò Alálàfíà

Ní òpin kan, ó dàbí àwọn kan ti gbàgbé pé àtúnṣe Àkọ́kọ́ sí Ìwé-òfin United States fi ààyè gba “ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn láti kórajọ ní àláfíà àti láti kọ́wémọ́ Ìjọba fún títúnṣe àwọn ohun ìbànújẹ́.” Ìyẹn ni ọ̀nà àṣẹ láti mú ìfura gbangba wá kí wọ́n sì dojúkọ àìní-ìdáláre nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣàkóso àwọn àṣẹ. Àti pé àìníìdáláre ti wà. Nínú àwọn iṣe gbangba àti nínú àwọn ìwà araẹni, a ti ní ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti àwọn ohun ìbànùjẹ́. Nínú àròkọ ìrọni araẹni kan, Ẹni-ọ̀wọ̀ Theresa A. Dear ti Ìṣepọ̀ Gbogbogbò fún Ìlọsíwájú àwọn Ènìyàn Aláwọ̀ (IGIEA) ti rán wa létí pé a “ngbìlẹ̀ lórí ìríra, ìrẹ́jẹ, ìpalọ́lọ́, ììpàdíàpòpọ̀, yàtọ̀, àti ìdákẹ́jẹ́jẹ́.”11 Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ ìlú àti ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a gbọ́dọ̀ ṣe dáadáa si láti ṣèrànwọ́ láti fa gbogbo ẹlẹ́yàmẹ̀yá tu.

Àwòrán
Rògbòdìyàn tí kò bá ófin mu

Ní òpin míràn, díẹ̀ lára àwọn olùkópa àti alátìlẹhin àwọn alátakò wọ̀nyí àti àwọn iṣe àìbòfinmu tí ó ti tẹ̀lé wọn ní ó dàbí a ti gbàgbé pé àwọn alátakò náà tí Ìwé-òfin dà ààbò bo ni àwọn àtakò àláfíà . Àwọn Alátakò kò ní ẹ̀tọ́ láti parun, bàjẹ́, tàbí jí ohun ìní tàbí rẹ ìlófin ètò agbára ìjọba sílẹ̀. Ìwé-òfin àti àṣẹ kò fàyè gba ìpè sí rògbòdiyàn tàbí ìwà-rúdurùdu. Gbogbo wa—ọlọpa, alatako, alátìlẹhìn, àti olùwòran—yẹ kí a ní ìmọ̀ pé òpin wa sí ẹ̀tọ́ wa àti pàtàkì ojúṣe wa láti dúró ní àárín ààlà àṣẹ tó wà. Abraham Lincoln sọ ọ́ bi ó ti tọ́ nígbà tí ó wípé: “Kò si ohun ìbàjẹ́ tí ó jẹ́ dídára fún títúnṣe nípasẹ̀ àṣẹ ẹni-ibi.”12 Títúnṣe ohun ìbàjẹ́ nípasẹ̀ àwọn ẹni-ibi ni títúnṣe nípasẹ̀ ọ̀nà àìbòfinmu. Ìyẹn ni ìwà-rúdurùdu, ipò kan tí kò ní àwọn ìjọba tó dára àti ọlọpa dídára, èyí tí ó nmú àwọn ẹ̀tọ́ olúkúlùkù rẹlẹ̀ sànju kí ó dá ààbo bòó.

Ìdí kan fún àwọn àtàkò àìpẹ́ ní United States tí ó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rù gidi ni ìkanra àti àìbófinmu tí a ní ìmọ̀lára ní àárín ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn ẹ̀yà àti ẹgbẹ́ míràn ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí kò yẹ kí a ti nímọ̀lára rẹ̀ ní United State. Orílẹ̀-èdè yí yẹ kí ó dara ju bí ó ti wà ní mímú ẹlẹ́yàmẹ̀yà kúrò kìí ṣe ní ìlòdi sí Àwọn Amẹ́ríkà Dúdú nìkan, tí wọ́n hàn gan an nínú àwọn àtàkò àìpẹ́, ṣùgbọ́n bákannáà ní ìlòdì sí àwọn Latino, Asia, àti àwọn ẹgbẹ́ míràn. Ìtàn orílẹ̀-èdè yí nípa ẹlẹ́yàmẹ̀yà kìí ṣe ọ̀kan tí ó dùn mọ́ni nínú, a sì gbọ́dọ̀ ṣe dídára si.

Àwòrán
Island Ellis
Àwòrán
Àwọn Olùkólọ

United States ni a dá sílẹ̀ nípasẹ àwọn tó nkólọ sí àwọn orílẹ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ẹ̀yà ọ̀tọ̀tọ̀. A kò ṣe èrèdí ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ láti gbé ẹ̀sìn kan pàtó kalẹ̀ tàbí láti ṣe eyikeyi onírurú ọ̀làjú tàbí ẹ̀yà tó dúróti àwọn orílẹ̀-èdè àtijọ́. Olùdásílẹ̀ ìran wa wá láti ní ìrẹ́pọ̀ nípa ìwé-òfin titun àti àṣẹ. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àwọn ìwé ìrẹ́pọ̀ wa tàbí ìmọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nígbànáà nípa àwọn ìtumọ̀ wọn jẹ́ pípé. Ìtàn àwọn sẹ́ntùrì àkọ́kọ́ méjì ti United States fi ìnilò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe hàn, bí irú ẹ̀tọ́ ìdìbò fún àwọn obìnrin àti, ní pàtó fún, mímúkúrò òwò-erú pẹ̀lú àwọn àṣẹ láti mu dánilójú pé àwọn tí wọ́n fi ṣẹrú yíò ní gbogbo àwọn ipò òmìnira.

Àwọn akẹkọ méjì ti Unifásitì Yale ránwalétí láìpẹ́:

“Fún gbogbo àṣìṣe rẹ̀, United States ni ó ní ìpèsè àìláfiwé láti mú onírurú àti ìyapa àwùjọ kan ní ìrẹ́pọ̀. …

“… Àwọn ọmọ ìlú kò ní láti yàn ní àárín ìdánimọ̀ orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀-àṣà. Àwọn Ará Amẹ́ríkà lè ní méjèèjì. Ṣùgbọ́n kókó náà ni ìwé-òfin ti ọmọ ìlú rere. A ti wà ní ìrẹ́pọ̀ nípa àti nípasẹ̀ Ìwé-òfin, láìka àwọn àgbàrò àti àìrẹ́ sí.”13

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, akọ̀wé Òyìnbó ilúọba fúnni ní àmọ̀ràn nlá yí nínú ìdíje ní Ilé ti Ìwọpọ̀: “A kò ní ará ayérayé rárá a kò sì ní àwọn ọ̀tá tó wà títí Àwọn Ìfẹ́ wa jẹ́ ti ayérayé tó wà títí, àti pé ìfẹ́ wọ̀nyí ni tiwa láti tẹ̀lé.”14

Eléyi jẹ́ ìdí ikẹkọ rere fún títẹ̀lẹ́ àwọn ìfẹ́ “ayérayé àti pípẹ́” nínú àwọn ọ̀ràn òṣèlú. Ní àfikún, ẹ̀kọ́ Ìjọ Olúwa nkọ́ni pé àwọn ìfẹ́ ayérayé míràn ni láti tọ́ wa sọ́nà, àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà wa, tí ó nmísí Ìwé-òfin United States àti àwọn kókó àṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wa. Ìṣòótọ́ sí ìgbékalẹ̀ àṣẹ—kìí ṣe ìṣòótọ́ sí “ará” ni ọ̀nà dídárajùlọ láti fẹ́ àwọn ọ̀tá wa àti àwọn onínùnibíni bí a ṣe nwá ìrẹ́pọ̀ àní nínú ìpọ́njú.

Ní mímọ̀ pé gbogbo wa ni ọmọ Ọlọ́run nfún wa ní ìran àtọ̀runwá nípa gbogbo àwọn míràn àti ìfẹ́ àti okun láti dìde kọjá ìríra àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ti gbígbé ní ipò ìyàtọ̀ ní orílẹ̀-èdè yí, Olúwa ti kọ́ mi pé ó ṣeéṣe kìí ṣe láti gbọ́ran nìkan àti láti wá láti tún àwọn àṣẹ orílẹ̀ èdè ṣe àti bákannáà láti fẹ́ àwọn ọ̀tá àti onínúnibíni sí wa. Nígbàtí kò rọrun, ó ṣeéṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa wa, Jésù Krístì. Ó fúnni ní àwọn àṣẹ wọ̀nyí láti fẹ́ni, Ó sì ṣe àwọn ìlérí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ bí a ṣe nwá láti gbọ́ran. Mo jẹri pé a ní ìfẹ́ àti ìdarí látọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Bákannáà wo Lúkù 6:27–28, 30.

  2. Gordon B. Hinckley, “Agbára Ìwòsàn Krístì,” Ensign, Nov. 1988, 59; see also Àwọn Ìkọ́ni Gordon B. Hinckley (1997), 230.

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:5.

  4. Bákannáà wo Máttéù 22:21; Marku 12:17.

  5. Thomas S. Monson, “Tún Ìmọ̀lára Rẹ Ṣe, Áà Arákùnrin mi,” Liahona, Nov. 2009, 68.

  6. Wo Becky and Bennett Borden, “Rínrìn Súnmọ́: Fífẹ́ni Bí Olùgbàlà Ti Ṣe,” Ensign, Sept. 2020, 24–27.

  7. Joseph Smith, nínú Ìtàn Ìjọ, 5:517. Bákannáà, Martin Luther King Jr. (1929–1968) wípé: “Returning violence for violence multiplies violence, adding deeper darkness to a night already devoid of stars. Òkùnkùn kò le òkùnkùn jade; ìmọ́lẹ̀ nìkan ni o le ṣeé. Ìkóríra ko lè lé ìkóríra jáde; ìfẹ́ nìkan ni o le ṣe yẹn” (Where Do We Go from Here: Chaos or Community? [2010], 64–65).

  8. Awọn ìkọ́ni Awọn Ààrẹ ti Ìjọ: Howard W. Hunter (2015), 263.

  9. Russell M. Nelson, “Alábùkúnfún ni àwọn Olùlàjà,” Liahona, Nov. 2002, 41; see also Àwọn Ìkọ́ni Russell M. Nelson (2018), 83.

  10. Wo “Ilé Kan tí ó Yapa,” The Economist, Sept. 5, 2020, 17–20.

  11. Theresa A. Dear, “America’s Tipping Point: 7 Ways to Dismantle Racism,” Deseret News, June 7, 2020, A1.

  12. Abraham Lincoln, address at the Young Men’s Lyceum, Springfield, Illinois, Jan. 27, 1838, in John Bartlett, Bartlett’s Familiar Quotations (2012), 444.

  13. Amy Chua and Jed Rubenfeld, “Ẹ̀rù Ẹlẹ́yàmẹ̀yà,” Atlantic, Oct. 2018, 81, theatlantic.com.

  14. Tẹ́mpìli Henry John, Viscount Palmerston, ọ̀rọ̀ nínú ile Ìwọpọ̀, Mar. 1, 1848; in Bartlett, Bartlett’s Familiar Quotations, 392; àfikún àtẹnumọ́.