Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Ìwòsàn ti Jésù Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Agbára Ìwòsàn ti Jésù Krístì

Bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì nípa lílo ìgbàgbọ́ nínu Rẹ̀, ríronúpìwàdà, àti dídá àti pípa májẹ̀mú mọ́, ìròbìnújẹ́ wa—eyikeyi ìdí rẹ̀—ni a lè wòsàn.

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yi, a ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò retí. Ìpàdánù ẹ̀mí àti owó nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kárí ayé ti kan agbègbè àti ọrọ̀ ajé gbogbo ayé.

Ìlẹ̀ ríri, iná, àti ìkún omi ní oríṣiríṣi àwọn abala ilẹ̀ ayé, ati àwọn àjálù míràn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ojú ọjọ́, ti fi àwọn àwọn ènìyàn sílẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára àìsí-ìrànlọ́wọ́, àìnírètí, àti bíi oníròbìnújẹ́, ní rírò bóyá ìgbé ayé wọn yío tún wà bákannáà mọ́ láe.

Ẹ jẹ́kí nsọ ìtàn ti ara ẹni kan fun yín nípa ìbìnújẹ́.

Nígbàtí àwọn ọmọ wa kéré, wọ́n pinnu pé àwọn ó ṣe ẹ̀kọ́ dúrù. Ọkọ mi, Rudy, àti èmi fẹ́ pèsè ànfààní yí fún àwọn ọmọ wa, ṣùgbọ́n a kò ní dùrù. A kò le ra dùrù tuntun, nítorínáà Rudy bẹ̀rẹ̀ sí wá àlòkù kan.

Ní ọdún náà fún Kérésì, ó ya gbogbo wa lẹ́nu pẹ̀lú dùrù kan, àti pé nínú àwọn ọdun, àwọn ọmọ wa kọ́ láti tẹ̀ẹ́.

Àwòrán
Dùrù gbígbó

Nígbàtí àwọn ọmọkùnrin wa dágbá tí wọ́n sì kúrò nílé, dùrù gbigbó kàn kún fún eruku lásán, nítorínáà a tà á. Àwọn ọdún díẹ̀ kọjá lọ, a sì ti fi owó díẹ̀ pamọ́. Ní ọjọ́ kan Rudy sọ pé, “Mo ro pé ó tó àkókò kí a ní dùrù tuntun.”

Mo bééré pé, “Kínniṣe tí a ó ní dùrù titun, nígbàti kò sí ẹnìkankan lára wa tó mọ̀ọ́ tẹ̀?”

Ó wípé, “Áà, ṣùgbọ́n a le ní dùrù kan tó ntẹ̀ ara rẹ̀! Nípa lílo kọ̀mpútà kékéré alágbéká, o le mú dùrù ṣe láti tẹ̀ àwọn orin tí ó ju ẹgbẹ̀rún mẹrin lọ, pẹ̀lú àwọn orin ìsìn, àwọn orin Ẹgbẹ́ Akọrin Àgọ́, gbogbo àwọn orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi.”

Rudy jẹ́ olùtajà nlá kan, láti sọ èyítí ó kéré jùlọ.

Àwòrán
Dùrù Titun

A ra píanó tuntun rírẹwà kan tí ó ntẹ ara rẹ̀, àti pé ní ìwọ̀n ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, àwọn ọkùnrin títóbi, alágbara méjì gbé e wá sí ilé wa.

Mo fi ibi tí mo fẹ́ kó wà hàn wọ́n mo sì sún kúrò ní ọ̀nà.

Àwòrán
Gbígbé dùrù

Ó jẹ́ bebi títóbi tí ó wúwo, àti pé láti mú kí ó wọlé ní ibi ìlẹ̀kùn, wọ́n yọ àwọn ẹsẹ̀ wọ́n sì dọ́gbọ́n fi ẹ̀gbẹ́ dùrù náà lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù ọlọ́wọ́ tí wọ́n mú wá pẹ̀lú wọn.

Ilé wa jókòó lé orí ibi tí ó ṣe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ díẹ̀, àti pé pẹ̀lú ẹ̀dùn, ṣaájú ní ọjọ́ náà yìnyin ti rọ̀, tí ó mú kí àwọn nkan ó tutù tí kò sì dán mọ́rán. Njẹ́ ẹ le rí ibití èyí nlọ?

Nígbàtí wọ́n ngbé dùrù náà gun orí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kékeré náà, ó yọ̀, mo sì gbọ́ ìṣubú aláriwo nlá kan. Dùrù náà ti jábọ́ kúrò ní orí kẹ̀kẹ́ ẹrù ọlọ́wọ́ náà ó sì lulẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi àpá nlá kan tẹ̀ sí orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ koríko wa.

Mo wí pé, “Áà, inúrere mi o. Ṣe ẹ wà dáadáa?

Pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn ọkùnrin méjèèjì wá dáadáa.

Ojú wọn fẹ̀ bí wọ́n ti wo ara wọn, lẹ́hìnnáà wọ́n wò mí wọ́n sì sọ pé “A bẹ̀bẹ̀ má binú. A ó gbé e padà sí ilé ìtajà a ó sì mú kí mọ́níjà wa ó pè ọ́.”

Láìpẹ́ ni mọ́níjà náà nbá Rudy sọ̀rọ̀ láti ṣe ètò gbígbé dùrù tuntun kan wá. Rudy jẹ́ aláànú àti ẹnití ndáríjì ó sì sọ fún ọ̀gá náà pé ó dára bí wọ́n bá kàn tún ìbàjẹ́ náà ṣe kí wọn ó sì gbé dùrù kannáà padà wá, ṣùgbọ́n ọ̀gá-iṣẹ́ náà takú pé titun kan ni a ó gba.

Rudy fèsì, ó wípé, “Kò le burú tó bẹ́ẹ̀. Ẹ kàn túnṣe kí ẹ sì gbé e wá.”

Mọ́níjà náà sọ pé, “Igi ti kán, àti pé níwọ̀n ìgbàtí igi bá ti kán, kò le dún bákannáà mọ́. Ìwọ ọ́ gba dùrù titun.”

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, njẹ́ gbogbo wa kò ha rí bíi pianó yìí bí, ní kíkán díẹ̀, lílanu, àti bíbàjẹ́, pẹ̀lú ìmọ̀lára pé a kò ní rí bákannáà mọ́ láe? Bákannáà, Bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì nípa lílo ìgbàgbọ́ nínu Rẹ̀, ríronúpìwàdà, àti dídá àti pípa májẹ̀mú mọ́, ìròbìnújẹ́ wa—eyikeyi ìdí rẹ̀—ni a lè wòsàn. Ètò yí, èyí tí ó npè agbára ìwòsàn Olùgbàlà sínú ayé wa, kìí mú wa padàbọ̀sípò sí ohun tí a jẹ́ tẹ́lẹ̀ lásán ṣùgbọ́n mú wa dára si ju bí a ti wà rí. Mo mọ̀ pé nípasẹ̀ Olùgbàlà, Jésù Krístì, gbogbo wa le di títúnṣe, sísọ di pípé, kí a sì mú èrédí wa ṣẹ, bíiti ìró-rírẹwà kan, ẹ̀yà-titun dùrù.

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Nígbàtí àwọn àdánwo líle bá wá sí orí wa, àkókò tó láti mú ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run jinlẹ̀ síi, láti ṣiṣẹ́ kára, àti láti sin àwọn ẹlòmíràn. Nígbànáà Òun yío wò ìròbìnújẹ́ wa sàn. Òun yío fi àlàáfíà àti ìtùnú ti ara ẹni lé wa lórí. Àwọn ẹ̀bùn nlá wọnnì ni a kì yío le bàjẹ́, àní nípasẹ̀ ikú.”1

Jésù wí pé:

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́” (Matteu 11:28–30).

Àwòrán
Olùgbàlà wa, Jes´ù Krístì

Láti wo ìbìnújẹ́ sàn nípa wíwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, a níláti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. “Níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì túmọ̀ sí gbígbé ọ́kàn lé E pátápátá—níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára àìlópin … àti ìfẹ́Rẹ̀. Nínú rẹ̀ ni gbígbà àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ gbọ́. Ó túmọ̀ sí gbígbàgbọ́ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa kò ní oye ohun gbogbo, òun ní. Nítorípé Ó ti ní ìrírí gbogbo àwọn ìrora wa, ìpọ́njú wa, àti àwọn àìlera wa, Ó mọ bí yío ti ràn wá lọ́wọ́ láti ga sókè tayọ àwọn ìṣòro wa ojojúmọ.”2

Bí a ṣe nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, “a le kún fún ayọ̀, àlàáfíà, àti ìtùnínú. Gbogbo ohun tí ó le tí ó sì npeniníjà nípa ìgbé ayé ni a le sọ di títọ́ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”3 Ó ti gbani níyànjú pé, “Ẹ máa wò ọ̀dọ̀ mí nínú gbogbo èrò inú; ẹ má ṣe iyèméjì, ẹ má bẹ̀rù” (Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36).

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì nígbàtí Alma àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ dí títẹ̀ mọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹrù tí a gbé lé wọn, àwọn ènìyàn náà bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Olúwa kò bú àwọn ẹrù wọn kúrò; dípò bẹ́ẹ̀, Ó ṣe ìlérí fún wọn pé:

“Èmi yíò sì dẹ ìnilára tí a gbé lée yín ní éjìká, àní kí ẹ̀yin kò lè mọ̀ ọ́ lórí ẹ̀hìn yín, bí ẹ̀yin tilẹ̀ wà nínú oko-ẹrú; èyí yíi ni èmi yíò ṣe kí ẹ̀yin kí ó lè dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ̃rí fún mi ní ọjọ́ tí mbọ̀, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ dájúdájú pé èmi, Olúwa Ọlọ́run nbẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú ìpọ́njú wọn.

Àti nísisìyí ó ṣì ṣe tí ìnira tí a gbé ru Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ di fífúyẹ́; bẹ̃ni, Olúwa fún wọn ní okun kí wọ́n ó lè gbé ẹrù náà pẹ̀lú ìrọ̀rùn, wọ́n sì jọ̀wọ́ ara sílẹ̀ fún gbogbo ìfẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀yàyà àti sùúrù” (Mosiah 24:14–15).

Nípa agbára Olùgbàlà láti wòsàn àti láti sọ àwọn ìnilára di fífúyẹ́, Alàgbà Tad R. Callister ti kọ́ni pé:

“Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún ti Ètùtù náà ni pé a le gba nínú àwọn agbára ìtùnilára ti Olùgbàlà. Isaiah sọ léraléra nípa ìmísí ìwòsàn, àti ìtunilára ti Olúwa. Ó jẹ́rìí pé Olùgbàlà jẹ́ ‘okun sí aláìní nínú ìrora rẹ̀, ààbò kúrò nínú ìjì, òjìji kúrò nínú ooru’ (Isaiah 25:4). Ní ti àwọn wọnnì tí nbanújẹ́, Isaiah kéde pé Olùgbàlà ní agbára láti ‘tu gbogbo ẹni tí nṣọ̀fọ̀ nínú’ (Isaiah 61:2), àti láti ‘nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn’ (Isaiah 25:8; bákannáà wo Ìfihàn 7:17); ‘láti mú ẹ̀mí àwọn onírẹ̀lẹ̀ sọjí’ (Isaiah 57:15); àti láti ‘ṣe ìwòsàn fún àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn’ (Isaiah 61:1; bákannáà wò Luku 4:18; Psalm 147:3). Títóbi tóbẹ́ẹ̀ ni agbára ìtunilára rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ó le pààrọ̀ ‘ẹ̀wà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, ẹ̀wù ìyìn dípò ẹ̀mí ìwúwo’ (Isaiah 61:3).

“Áà, ìrèti ha ti pọ̀ tó nínú àwọn ìlérí wọnnì! … Ẹ̀mí Rẹ̀ nwòsàn; ó ntúnṣe; ó ntuni nínú; ó nmí èémí ìyè sí àwọn ọkàn àìnírètí. Ó ní agbára lati ṣe àyípadà gbogbo ohun tí kò lẹ́wà àti ti ẹ̀gàn àti ti àìníláárí nínú ìgbé ayé sí ohun kan tí ó ga tayọ àti ti ológo títóbi. Ó ní agbára láti yí àwọn eérú ti ayé kíkú sí àwọn ẹwà ti ayérayé.”4

Mo jẹri pé Jésù Krístì ni olùfẹ́ni Olùgbàlà, Olùràpadà, Oníwosàn Nlá, àti ọ̀rẹ́ tòótọ́ wa. Bí a bá yí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Òun yío wò wá sàn yío sì mú wa jẹ́ pípé lẹ́ẹ̀kansíi. Mo jẹ́ri pé èyí ni Ìjọ Rẹ̀ àti pé Ó nmúrasílẹ̀ láti padà lẹ́ẹ̀kansíi sí orí ilẹ̀ ayé yi láti jọba pèlú agbára àti ògo. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì—Oníwòsàn Nlá,” Liahona, Nov. 2005, 87.

  2. Ìgbágbọ́ nínú Jésù Krístì“, Àwọn Àkòrí Ìhìnrere, topics.churchofjesuschrist.org

  3. Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà Kan sí Iṣẹ́ Ìsìn Iránṣẹ́ Ìhinrere, rev. ed. (2018), 52, ChurchofJesusChrist.org.

  4. Tad R. Callister, Ètùtù Àìlópin Náà (2000), 206–7.