Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ojúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ojúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀

Àwọn ìgbà àpọ́njú àti ìjákulẹ̀ kiò yí ojú ìṣọ́ni Olúwa padà bí Ó ti nfi ojúrere wò wá, tí ó nbùkún wa.

Níjọ kan ní àwọn ọdún sẹ́hìn, gẹ́gẹbí àwọnn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí ó nṣiṣẹ́ ní ẹ̀ká tínrín kan ní island Amami Oshima, Japan, inu èmi àti ojúgba mi dùn gan láti gbọ́ pé Ààrẹ Spencer W. Kimball nbọ́ wá ṣe ìbẹ̀wò ní Asia àti pé gbogbo àwọn ọmọ ìjọ àti ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Japan ni a pè sí Tokyo láti gbọ́ wòlíì ní ìpàdé àpapọ̀ agbègbè kan. Àwọn ọmọ ẹ̀ká, ojúgbà mi àti èmi fi ìdùnnú bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ètò fún ìpàdé àpapọ̀, ìrin wákàtí méjìlá ọkọ-ojú omi sọdá Òkun Ìlà-oòrùn China sí Japan, ìrìn wákàtí marundínlógún ọkọ̀ ojú-irin sí Tokyo tẹ̀le. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, bákannáà, kò wáyé. A gba ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ ààrẹ míṣọ̀n pé nítorí ọ̀nà-jíjìn àti àkokò, èmi àti ẹnìkejì mi kò ní lè lọ ibi ìpàdé àpapọ̀ ní Tokyo.

Àwòrán
Alàgbà Stevenson àti ẹnìkejì ìránṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀

Nígbàtí àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ká kékeré lọ sí Tokyo, a dúró sẹ́hìn. Àwọn ọjọ́ tó tẹ̀le dàbí kòròfo àtì jẹ́jẹ́. A dá ṣe ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ilé-ìjọsìn kékeré náà, nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti iránṣẹ́ ìhìnrere lọ sí ìpàdé àpàpọ̀.

Àwòrán
I`pàdé A`papọ̀ Agbègbè Asia

Àní ìmọ ti ara mi nípa ìjákulẹ̀ mi pọ̀si gidi bí mo ṣe nfetísílẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀ká tí wọ́n padà dé láti ìpàdé àpapọ̀ ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà tí wọ́n ròhin pé Ààrẹ Kimball ti kéde pé a ó kọ́ tẹ́mpìlì kan ní Tokyo. Wọn kún fún ìdùnnú bí wọ́n ṣe npín ìmúṣẹ àlá wọn. Wọ́n júwe bí, àwọn ọmọ ìjọ àti ìránṣẹ ìhìnrere kò ṣe lè mú ayọ̀ wọn mọ́ra tí wọ́n fi ìgbọnra bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́, lórí gbígbọ́ ìpolongo tẹ́mpìlì.

Àwòrán
Ààrẹ Kimball kéde tẹ́mpílì kan tí Tokyo

Àwọn ọdún ti kọjá, ṣùgbọ́n mo ṣi rántí ìjákulẹ̀ tí mo mọ̀ lára látinú pípàdánù ìpàdé onítàn náà.

Ní àwọn oṣù àìpẹ́ mo ti ronú lórí ìrírí yí, bí mo ti nkíyèsí àwọn míràn tí wọ́n dojúkọ ìjákulẹ àti ìkorò jíjinlẹ̀—títóbi gidi ju tèmi lọ gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ iránṣẹ́ ìhìnrere—tí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 gbogbo ayé mú wa.

Ṣíwájú ní ọdún yí, bí àjàkálẹ̀ àrùn ṣe npọ̀si, Àjọ Ààrẹ Ìkínní jẹ́jẹ́ pé “Ìjọ àti àwọn ọmọ ìjọ yíò fi òtítọ́ ṣe ìfarasìn láti jẹ́ ọmọ-ìlú rere àti aladugbo rere”1 a ó sì “lo ọ̀pọ̀ ìṣọ́ra.”2 Bayii, a ti ní ìrírí ìdádúró àwọn ìkórajọ Ìjọ ní gbogbo ayé, ìpadàbọ̀ tipátipá ju ààbọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere Ìjọ sí ilé orílẹ̀-èdè wọn, àti ìpadé gbogbo àwọn tẹ́mpìlì káàkiri Ìjọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára yín ti múrasílẹ̀ láti wọ tẹ́mpìlì fún àwọn ìlànà alààyè—pẹ̀lú èdidì tẹ́mpìlì. Àwọn ẹlòmíràn lára yín ti parí iṣẹ́-ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere yín ṣíwájú tàbí tí a ti dá wọn sílẹ̀ ránpẹ́ tí a sì tún yàn.

Àwòrán
Àwọn nìránṣẹ́ ìhìnrere padà ní àárín COVID

Ní ìgbà yí, ìjọba àti àwọn olórí ẹ̀kọ́ ti ilé-ìwé—èyí tí àbájáde rẹ̀ yọrísí da ìgboyè rú ó sì fa píparẹ́ àwọn eré-ìdálárayá àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbámu-ilé-ìwé míràn àti àwọn ìṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín múrasílẹ̀ fún ìṣeré àti ìdíje tí a kò gbọ́ tàbí àkokò olùṣeré tí a kò ṣe.

Àní púpọ̀ si ni dídunni èrò àwọn ẹbí tí wọ́n pàdánu àwọn olólùfẹ́ wọn ní ìgbà yí; ọ̀pọ̀ kò lè ṣe ìsìnkú tàbí àwọn ìkórajọ ìrọ́nú míràn bí wọ́n ṣe ní ìrètí.

Ní kúkurú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti kojú ìjákulẹ̀ tó wọnilọ́kàn, ìkorò, àti ìrẹ̀wẹ̀sì tòótọ́ gan. Nítorínáà báwo ni a ó ṣe wòsàn, faradà, kí a sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́?

Wòlìí Néfì bẹ̀rẹ̀ fínfín àwo kékeré nígbàtí ó ndàgbà bí ọkùnrin. Bí ó ti wo ẹ̀hìn lórí ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó fúnni ní àwọn ìrònú pàtàkì, ní ẹsẹ ìkínní Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ẹsẹ yí ṣe ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì fún wa láti yẹ̀wò ní ìgbà wa. Títẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a dámọ̀, “Èmi, Néfì, tí a bí nípa àwọn òbí dídára … ,” o kọ wí pé, “àti nítorí pé mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní ìgbà àwọn ọjọ́ mi, bí o tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítori tí mo ti rí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ mi.”3

Bí àwọn akẹkọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpọ́njú èyí tí Néfì ntọ́ka sí. Síbẹ̀síbẹ̀ títẹ̀lé jíjẹ́wọ́ àwọn ìpọ́njú rẹ̀ ní ìgbà àwọn ọjọ́ rẹ̀, Néfì fúnni ní ìrísí ìhìnrere ti gbígba ojúrere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ̀. Àwọn ìgbà àpọ́njú àti ìjákulẹ̀ kiò yí ojú ìṣọ́ni Olúwa padà bí Ó ti nfi ojúrere wò wá, tí ó nbùkún wa.

Àwòrán
Ìpàdé míṣọ̀n lórí afẹ́fẹ́
Àwòrán
Ìpàdé míṣọ̀n lórí afẹ́fẹ́ pẹ̀lú Alàgbà àti Arábìnnrin Stevenson
Àwòrán
Ìpàdé míṣọ̀n lórí afẹ́fẹ́ pẹ̀lú Alàgbà àti Arábìnnrin Stevenson

Láìpẹ́ mo pàdé pẹ́lù bíi ọgọrunmẹfa àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Australia, púpọ̀ ju àwọn tó wà lábẹ́ àwọn ìwọ̀n ti ìtìmọ́lé tàbí ìdádúró tó wà pẹ̀lú COVID-19, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nṣiṣẹ́ látinú yàrá wọn. Lápapọ̀ a nyẹ àwọn olúkúlùkù nínú Májẹ̀mú Titun, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti Ẹ̀kọ̀ àti àwọn Májẹ̀mu tí Olúwa ti bùkún láti ṣe àṣeyege nlá jùlọ nínú ìpọ́njú wo. Gbogbo wọn nítumọ̀ si nípasẹ̀ ohun tí wọ́n lè ṣe pẹ̀lú ìránlọ́wọ́ Olúwa ju nípasẹ̀ ohun tí wọ́n kò lè ṣe gẹ́gẹ́bí ayọrísí ìsémọ́lé àti ìdádúrí wọn.

A ka Páùlù àti Silas, nígbàtí a tì wọ́n mọ́ inú ìkójọ, wọ́n gbàdúrà, kọrin, jẹ́ ẹ̀rí—àní wọ́n ṣe ìrìbọmi onítúbú.4

Lẹ́ẹ̀kansi nípa Páùlù, ní Rómù, lábẹ́ ìtìmọ́lé ilé fún ọdún méjì. nínú ìgbà èyí tí ó tẹ̀síwájú láti sọ “àsọyé ó sì jẹri nípa ìjọba Ọlọ́run,”5 ó nkọ́ni ni àwọn ohun tí iṣe ti Olúwa Jésù Krístì,”6

Nípa Néfì àti Léhì, àwọn ọmọkùnrin Hẹ́lámánì, lẹ́hìn ìlòkulò àti àtìmọ́lé ni iná ààbò yíká rẹ̀ bí Olúwa ní “ohùn pẹ̀lẹ́ dídákẹ́ rọ́rọ́ … tí ó wọ inú ọkàn [àwọn akónilẹ́ru] lọ àní dé ìsàlẹ̀ ẹ̀mí wọn gan.”7

Nípa Álmà àti Amúlẹ́kì ní Amoníhà, ẹnití ó rí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ “gbàgbọ́ … wọ́n sì bẹ̀rẹsí ronúpìwàdà, àti láti ṣe àṣàrò ìwé mímọ́,”8 àní bíótilẹ̀jẹ́pé a kẹ́gàn wọn lẹ́hìnnáà àti láìsí oúnjẹ, omi, tàbí ẹ̀wù, ní ìdè nínú ẹ̀wọ̀n,9

Àwòrán
Joseph Smith nínú Ẹ̀wọ̀n Liberty

Àti ní òpin nípa Joseph Smith, ẹnití ó, ní ìmọ̀lára ìpatì àti ìgbàgbé, nínú ìrora ní Ẹ̀wọn Liberty, lẹ́hìnnáà gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa:“Àwọn ohun wọ̀nyí … yíò wà fún rere rẹ”10 àti pé “Ọlọ́run yíò wà pẹ̀lú rẹ títíláé.”11

Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára ìwọ̀nyí mọ ohun tí Néfì mọ̀: pé bí o tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní ọ̀nà àwọn ọjọ́ wọn, síbẹ̀ wọ́n rí ojúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀.

Àwa bákannáà wa ní ìbámu gẹ́gẹbí olúkúlùkù àwọn ọmọ ìjọ ní ọ̀nà èyí tí a ti rí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àwọn ìgbà àwọn ìpènijà tí a ti dojúkọ fún àwọn oṣù púpọ̀ tó kọjá. Gẹ́gẹ́bí mo ti sọ àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí wọ́n fún ẹ̀rí ipo-aríran wòlíì alààyè yín lókun bákannáà, ẹnití ó múra wa sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àtúntò ṣíwájú ìfura àjàkálẹ̀ àrùn kankan, tí ó jẹ́ kí a farada àwọn ìpènijà tí ó wá.

Ìkínní, dída àtìlẹhìn Ìjọ àti gbùngbun ilé.

Ọdún méjì sẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ wípé: “Ó ti mọ́ wá lára láti máa ronú nípa ‘ìjọ’ bí ohunkan tí o n ṣẹlẹ ní àwọn ilé ìjọsìn, pẹ̀lú àtìlẹ́hìn nípasẹ̀ ohun tí ó n ṣẹlẹ̀ nílé. A nílò àtúnṣe sí àwòṣe yí. … Gbùngbun-ilé Ìjọ kan, tí a tìlẹ́hìn nípasẹ̀ ohun tí ó nṣẹlẹ̀ nínú ilé … wa.”12 Irú àtúntò wòlíì tí ó jẹ́! Ìkọ́ni ìhìnrere gbùngbun ilé ní a ti múlò pẹ̀lú títì ránpẹ́ àwọn ilé-ìpàdé. Àní bí ayé ṣe bẹ̀rẹ̀ sí npadàsípò tí a sì npadà sí ilé-ìjọsìn, a ó fẹ́ láti mú àwọn àwòṣe àṣàrò ìhìnrere gbùngbun ilé dúró àti ìkọ́ni tí a kọ́ nígbà àjàkàlẹ̀ àrùn.

Àpẹrẹ èkejì ni pé rírí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀lọpọ̀ ni ìfìhàpn ní ìkàsí ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ọ̀nà gíga jùlọ àti mímọ́ si.

Àwòrán
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Ní 2018, Ààrẹ Nelson fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ hàn bí àtúntò ní “ọ̀nà tí a fi ntọ́jú ara wa.”13 Àjàkàlẹ̀ àrùn ti fi onírurú àwọn ànfàní hàn láti tún ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa ṣe. Arákùnrin àti arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́, ọ̀dọ́mọbìnrin àti ọ̀dọ́mọkùnrin, àti àwọn ẹlòmíràn ti nawọ́ jáde láti pèsè ìtọ́jú ọgbà, oúnjẹ, ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rọ, àti ìlànà oúnjẹ Olúwa láti bùkún àwọn tí ó wà nínú àìní. Ìjọ fúnrarẹ̀ ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn ní ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn pẹ̀lú àìmúrasílẹ̀ ìpínkiri àwọn ohun èlò sí ìkópamọ́ oúnjẹ, ibùgbé aláìnílé-lórí, àti àwọn gbàgede àtìlẹhìn aṣípòpadà àti pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ti a darí sí àwọn ipò ẹbí líle ayé jùlọ. Àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti àwọn ẹbí wọn dáhùn sí ìpènijà ti ṣíṣe ìbojú fún àwọn òṣìṣẹ́ ìtọ́jú-ìlera.

Àwòrán
Àwọn iṣẹ́ Àánú
Àwòrán
Ṣíṣe ìbòjú

Àpẹrẹ tó kẹ́hìn ti jíjẹ́ alábùkúnfún ní ìgbà ìpọ́njú ni rírí ayọ̀ gíga ní ìpadàbọ̀ àwọn ìlànà tẹ́mpìlì.

Àwòrán
Arábìnrin Kaitlyn Palmer

Èyí ni a júwe dáradára jùlọ pẹ̀lú ìtàn kan. Nígbàtí arábìnrin Kaitlyn Palmer gba ìpè míṣọ̀n rẹ̀ ní Oṣù Kẹrin tó kọjá, inú rẹ̀ dùn láti gba ìpè bí ìránṣẹ́ ìhìnrere ṣùgbọ́n ó ní ìmọ̀lára pé ó ṣe pàtàkì bákannáà àti kókó láti lọ sí tẹ́mpìlì láti gba agbára ẹ̀bùn àti láti dá májẹ̀mú mímọ́. Láìpẹ́ lẹ́hìn tí ó ti pinnu agbára ẹ̀bùn rẹ̀, ìpolongo wá pé gbogbo àwọn tẹ́mpìlì ti tì nítorí àjàkàlẹ̀ àrùn ní gbogbo ayé. Lẹ́hìn tí ó gba àlàyé bíbanilọ́kanjẹ́ yí, lẹ́hìnnáà ó kọ́ pé òun lè lọ sí gbàgede idanilẹkọ ìránṣẹ́ ìhìnrere (MTC) lórí afẹ́fẹ́ láti ilé rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ìjákulẹ̀ wọ̀nyí, Kaitlyn fojúsí pípa ẹ̀mí ìyárí rẹ̀ mọ́ ní gíga.

Àwòrán
Arábìnrin Kaitlyn Palmer ati ilé MTC

Ní àwọn oṣù náà, Arábìnrin Palmer ko sọ ìrètí ti lílọ sí tẹ́mpìlì nù. Ẹbí rẹ̀ gbàwẹ̀ wọ́n sì gbàdúrà pé kí àwọn tẹ́mpìlì ṣí ṣíwájú kíkúrò rẹ̀. Kaitlyn yíò bẹ̀rẹ̀ òwúrọ̀ MTC ilé rẹ̀ nípa sísọ pé, “Ṣé òní ni ọjọ́ tí a ó gba iṣẹ́ ìyanu kan tí tẹ́mpìlì yíò ṣí padà?”

Ní Ọjọ́ Kẹwa Oṣù Kẹjọ, Àjọ Ààrẹ Ìkínní polongo pé tẹ́mpìlì Kaitlyn yíò ṣí fún àwọn ìlànà alààye ní ọjọ gan an tí wọ́n ṣe ọkọ òfúrufú rẹ òwúrọ̀ lọ sí míṣọ̀n rẹ̀. Òun kò ní lè lọ sí tẹ́mpìlì kí ó sì bá ọkọ̀ òfúrufú. Pẹ̀lú ìrètí kékeré fún àṣeyege, ẹbí rẹ̀ pe ààrẹ tẹ́mpìlì Michael Vellinga láti ri bóyá ọ̀nàkọnà wà tí iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ti ngbàdúrà fún yíò ṣẹlẹ̀. A dáhùn àwẹ̀ àti àdúra wọn!

Àwòrán
Ẹbí Palmer ní tẹ́mpìlì

Ní aago méjì òwúrọ̀, wákàtí ṣíwájú kíkúrò rẹ̀, Arábìnrin Palmer àti ẹbí rẹ̀, nínú omijé, ni ààrẹ tẹ́mpìlì kí ní ẹnu ọ̀nà tẹ́mpìlì nínu ẹ̀rín, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀, “Ẹ káàárọ̀, Ẹbí Palmer. Ẹ káàbọ̀ sí tẹ́mpìlì!” Bí ó ti parí agbára ẹ̀bùn, a gbà wọ́n níyànjú láti kúrò kíákíá, bí àwọn ẹbí tó kàn ti ndúró ní ẹnu ọ̀nà. Wọ́n wakọ̀ tààrà lọ sí pápá ọkọ̀ òfúrufú ni àkokò láti bá fífò lọ sí míṣọ̀n rẹ̀.

Àwòrán
Arábìnrin Palmer ní pápá ọkọ̀-òfúrufú

Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì tí a ti pàdánù ní ọ̀pọ̀ oṣù dàbí ó dùn ju ríronú àtẹ̀hìnwá bí àwọn tẹ́mpìlì káàkiri ayé ṣe nṣí ni ipele.

Bí mo ti nparí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbani-níyànjú, ìwúrí, ìgbéga Wòlíì Joseph Smith. Ẹnìkan ko lè ṣe àròsọ láé pé ó mú wọn mọ́lẹ̀ nínú ìpọ́njú àti ìpatì, nínú ìdárdúró àti ìdènà nínú ilé ní Nauvoo, ó nsápamọ́ fún àwọn tí ó fẹ́ mu láìlófin:

Nísisìyí, kíni kí à ngbọ́ nínú ìhìnrere èyí tí a ti gbà? Ohùn ìdùnnú kan! Ohùn àánú láti ọ̀run; ohùn òtítọ́ látinú ilẹ̀-ayé; ìdùnnú ayọ̀ fún àwọn okú; ohùn ti ìdùnnú kan fún alààyè àti òkú; ìdùnnú ayọ̀ nlá. …

“… Njẹ́ a kì yío ha tẹ̀síwájú ninu iṣẹ́ nlá yi? Ẹ lọ síwájú àti pé kì ẹ máṣe rẹ̀hìn. Ìgboyà … àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun naa! Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín kí ó yọ̀, kí ẹ sì ní ìdùnnú tí ó tayọ. Ẹ jẹ́ kí ilẹ́-ayé kún fún orin kíkọ.”15

Ẹ̀yin Arákùnrin àti arábìnrin, mo gbàgbọ́ pé ní ọjọ́ kan, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yíò wẹ̀hìn wo ní píparẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀, àti àdáwà àti wíwà ìgbà ìpènijà tí à nlà kọjá láti rí wọ́n pé àwọn àṣàyàn ìbùkún àti ìgbàgbọ́ púpọ̀si àti ẹ̀rí ti borí rẹ̀. Mo gbàgbọ́ pé nínú ayé yí, àti ní ayé tó nbọ̀, àwọn ìpọ́njú yín, àwọn Ammonihah yín, ẹ̀wọ̀ Liberty yín, yíò di èrè fún yín.15 Mo gbàdúrà pé, lẹgbẹ pẹ̀lú Néfì, a lè jẹ́wọ́ àwọn ìpọ́njú ní ọ̀nà ti àwọn ọjọ́ wa nígbàtí a bá damọ̀ nígbà kánnáà pé a ri ojúrere Olúwa Lọ́pọ̀lọpọ̀.

Mo parí ẹ̀rí mi nípa Jésù Krístì, ẹni tí òun Fúnrarẹ kìí ṣe àlejo sí ìpọ́njú àti bí ara Ètùtù àìlópin Rẹ̀ o sọ́kalẹ̀ kọjá gbogbo nkan.16 Ó ní ìmọ̀ ìbànújẹ́ wa, ìrora, àti ìtara. Òun ni Olùgbàlà, Olùràpadà wa, ìrètí wa, olútùnú wa, àti Olùdándè. Nípa èyí ni mo jẹri ní orúkọ mímọ́ Rẹ, Jésù Krístì, àmín.