Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ tújúka.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ẹ tújúka.

Ìgbàgbọ́ àìmikàn wa nínú ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ntọ́ àwọn ìṣísẹ̀ wa sọ́nà ó sì nfún wa ní ayọ̀.

Ní àwọn ọjọ́ ìgbé ayé ikú Rẹ̀, Jésù Krístì wí fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ nípa inúnibíni àti ìṣòrò tí wọ́n jìyà.1 Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé” (Jòhánù 16:33). Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ Olùgbàlà sí gbogbo àwọn ọmọ Baba wa Ọ̀run. Ìyẹn ni ìròhìn rere ìgbẹ̀hìn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nínú ìgbé ayé ikú wa.

“Tújúká” bákannáà ni ìnílò ìdánilójú kan nínú ayé èyí tí àjínde Krístì ran àwọn Àpóstélì Rẹ̀. “A npọ́n wa lójú níhà gbogbo,” Àpóstélì Paul later told the Corinthians, “ṣùgbọ́n ara kò ni wá; à ndàmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù; à nṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; à nrẹ̀ wá sílẹ̀, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá run” (2 Àwọn Ará Kọ́ríntì 4:8–9).

Àwòrán
Jésù sìn ní ọ̀kàn sí ọ̀kan

Ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́hìnnáà àwa bákannáà ni wọ́n “npọ́n lójú níhà gbogbo,” àwa náà sì nílò irù ọrọ̀ kannáà kìí ṣe kí a sọ ìrètí nù ṣùgbọ́n láti tújúká. Olúwa ní ìfẹ́ pàtàkì àti àníyàn fún àwọn ọmọbìnrin iyebíye rẹ̀. Ó mọ àwọn ohun ti ẹ fẹ, ìnílò yín, àti àwọn ẹ̀rù yín. Olúwa ní gbogbo agbára Ẹ gbẹ́kẹ̀lé E.

Wòlíì Joseph Smith ni a kọ́ pé “àwọn iṣẹ́, àti àwọn àgbékalẹ̀, àti àwọn èrò Ọlọ́run kò ṣeé bàjẹ́, wọn kò sì lè di asán” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 3:1). Sí àwọn ọmọ Rẹ̀ tó ntiraka, Olúwa fún wọn ní àwọn ìdánilójú nlá wọ̀nyí pé:

“Kíyèsi, èyí jẹ́ ìlérí Olúwa síi yín, áà ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi.

“Nítorínáà, ẹ tújúká, ẹ máṣe bẹ̀rù, nítorí èmi Olúwa mo wà pẹ̀lú yín èmi ó sì dúró tì yín; ẹ̀yin yíò sì jẹri mi, àní Jésù Krístì, pé èmi ni Ọmọ Ọlọ́run alààye” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 68:5–6).

Olúwa dúró nítòsí wa, àti pé Ó wípé:

“Ohun tí èmi bá wí fún ẹnìkan mo wí fún ẹni gbogbo, ẹ tújúká, ẹ̀yin ọmọ kékeré; nítorí èmi wà ní àárín yín, èmi kò aì tíì kọ̀ yín sílẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 61:36).

“Niítorínáà lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ni àwọn ìbùkún yíò wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58:4).

Ẹ̀yin Arábìnrin, Mo jẹri pé àwọn ìlérí wọ̀nyí, tí a fúnni ní àárín inúnibíni àti àjálù araẹni, ní ó wúlò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára yín ní àwọn ipò ìdàmú yín ní òní. Wọ́n jẹ́ iyebíye àti láti ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa létí láti tújúká àti láti ní ayọ̀ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere bí a ti ntẹ̀síwájú nípasẹ̀ àwọn ìpènijà ayé ikú.

Ìpọ́njú àti àwọn ìpènijà jẹ́ àwọn ìrírí tó wọ́pọ̀ ní ayé ikú. Àtakò jẹ́ apákan pàtàkì ti ètò àtọ̀runwá láti ṣèrànwọ́ fún wa láti dàgbà,2 àti pé ní àárín ètò náà, a ní ìdánilójú Ọlọ́run pé, ní ìwò pípẹ́ ti àìlópin, a kò ní gba àtakò láàyè láti borí wa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti òdodo àti ìforítì wa, a ó yege. Bí ìgbé ayé ikú ti èyí tí a jẹ́ ara rẹ̀, gbogbo àwọn ìpọ́njú jẹ́ ránpẹ́. Nínú àwọn aríyànjiyàn tí ó ṣíwájú ogun tó léwu kan, ààrẹ United States Abraham Lincoln fi ọgbọ́n rán àwọn olùwòran létí nípa ìmọ̀ àtijọ́ pé “èyí, bákannáà, yio kọjá lọ.”3

Bí ẹ ti mọ̀, àwọn ìpọ́njú ayé ikú nípa èyí tí mo sọ̀rọ̀—èyí tí ó mú kí ó ṣòrò láti tújúká—nígbàmíràn nwa sọ́dọ̀ wa ní ìwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, bíi àwọn míllíọ́nù nísisìyí tí wọ́n ntiraka nípa àwọn àbájáde ìpọ́njú àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19. Bákannáà, ni United States àwọn míllíọ́nù njìyà nípasẹ̀ àkokò ọ̀tẹ̀ àti ìjà tí ó nfi ìgbàgbogbo dàbí ó nbá ìdìbò ààrẹ lọ, ṣùgbọ́n ìgbà yí ni ó lè jùlọ tí àwọn tó dàgbà jùlọ lára wa lè rántí láé.

Ní orí araẹni, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ntiraka ní olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpọ́njú ayé ikú, bí irú òṣì, ẹlẹ́yàmẹ̀yà, àìní-ìlera, ìpàdánù iṣẹ́ tàbí àwọn ìjákulẹ̀, àwọn ọmọ ìpánlè, ìgbeyàwó búburú tàbí àìsí ìgbeyàwó, àti àbájáde ẹ̀ṣẹ̀—ara wa tàbí àwọn míràn’.

Síbẹ̀, ní àárín gbogbo èyí, a ní àmọ̀ràn tọ̀run láti tújúká àti láti ní ayọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ìlérí ìhìnrere àti èso àwọn iṣẹ́ wa.4 Àmọ̀ràn náà ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn wòlíì nígbàgbogbo, àti fún gbogbo wa. A mọ èyí látinú àwọn ìrírí ti àwọn aṣíwájú wa àti ohun tí Olúwa wí fún wọn.

Àwòrán
Arákùnrin Joseph

Ẹ rántí àwọn ipò Wòlĩ Joseph Smith. Ẹ woo nínú jigi ìpọ́njú, bí ìgbé ayé rẹ̀ yi jẹ́ ọ̀kan ti oṣì, inúnibíni, ìpinilẹ́mí, ìkorò ẹbí, àti pípa nígbẹ̀hìn. Bí ó ti jìyà àtìmọ́lé, ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ àti àwọn Ènìyàn Mímọ́ míràn jìyà ìṣòro líle bí a ṣe lé wọ́n kúrò ní Missouri.

Nígbatí Joseph bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa dáhùn:

“Ọmọ mi, àláfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀;

“Àti pé nígbànáà, tí o bá fi ara dàá dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga sókè; ìwọ yíò borí gbogbo ọ̀tá rẹ” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:7–8).

Èyí jẹ́ àmọ̀ràn ayèrayé ti arẹni, tí ó ran Wòlíì Joseph lọ́wọ́ láti mú ìtújúká àdánidá níní-sùúrù rẹ̀ dúró àti ìfẹ́ àti òótọ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ìwa dáadáa wọ̀nyí fún àwọn olórí àti olùlànà tí ó tẹ̀le lókun ó sì lè fún yín lókun bákannáà.

Àwòrán
Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ìṣíwájú rìn nínú yìyín tó jìnlẹ̀

Ẹ ronú nípa àwọn ọmọ ìjọ ìṣíwájú! Lẹ́ẹkàn àti lẹ́ẹ̀kansi, a lé wọn láti ibìkan sí ibìkan. Ní òpin wọ́n dojúkọ àwọn ìpènijà ti gbígbé ilé wọn àti Ìjọ kalẹ̀ nínú àginjù.5 Ọdún méjì lẹ́hìn ti ẹgbẹ́ àkọ̀kọ́ àwọn olùlànà dé àfonífojì Nlá Salt Lake, àwọn olùlànà di wíwà láìléwu wọn mú nínú ìkanra agbègbè náà tí ó ṣì burú síbẹ̀. Púpọ̀ jùlọ àwọn ọmọ ìjọ ṣì wà nínú ìrìn sọdá àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí ntiraka láti gba àwọn ohun èlò láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ àwọn olórí àti ọmọ ìjọ ṣì ní ìrètí wọ́n sì tújùka.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò gúnlẹ̀ nínú ilé titun wọn, ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 1849 àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere titun kan ni a rán jáde lọ sí Scandinavia, Rance, Germany, Italy, àti Gúsù Pacific.6 Nínú ohun tí a lè rò pé ó jẹ́ ipele kíkéré jùlọ ni, àwọn olùlànà ti dìde sí ìgbésẹ̀ titun. Àti pé ní ọdún mẹta péré lẹ́hìnnáà, àwọn ọgọrundínméjì míràn ni a pè bákannáà láti bẹ̀rẹ̀ láti kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ. Ọ̀kan lára àwọn olórí Ìjọ ṣàlàyé nígbànáà pé àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ “lápapọ̀, kò yẹ kó jẹ́ pípẹ́ gan an; bóyá ọdún mẹta sí méje yíò pẹ́ bí ọkùnrin kankan yíò bá kúrò lọ́dọ̀ ẹbí rẹ.”7

Ẹ̀yin arábìnrin, Àjọ Ààrẹ Ìkínní ní àníyàn nípa àwọn ìpènijà yín. A nifẹ yín a sì ngbàdúrà fún yín. Ní ìgbà kannáà, a nṣọpẹ́ pé àwọn ìpènijà ti ara wa—yàtọ̀ sí ìsẹ́lẹ̀, ina, àgbàrá, àti ìjì-líle—ti dínkù ní ìwọpọ̀ sí èyí tí àwọn àṣíwájú wa dojúkọ.

Ní àárín àwọn ìṣòro, ìdánilójú àtọ̀runwá ní ìgbàgbogbo ni “ẹ tújúká, nítorí Èmi ó darí yin lọ. Ìjọba náà jẹ́ tiyín àti pé àwọn ìbùkún èyínì jẹ́ tiyín, àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé jẹ́ tiyín” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 78:18). Báwo ni èyí fi ṣẹlẹ̀? Báwo ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùlànà? Báwo ni yíò ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin Ọlọ́run ní òni? Nípa títẹ̀lé ìtọ́nisọ́nà ti wòlíì, “àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run-àpáàdì kò ní borí [wa],” ni Olúwa wí nínú ìfihàn Oṣù Kẹrin1830. “Bẹ́ẹ̀ni,” Ó wípé, “… Olúwa Ọlọ́run yíò tú gbogbo agbára òkùnkùn ká ní iwájú yín, àti pé yíò mú kí ọ̀run mì tìtì fún ìre yín, àti nítorí ògo rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 21:6). “Ẹ máṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin agbo kékeré; ẹ ṣe rere; ẹ jẹ́ kí ayé àti ọ̀run jùmọ̀ takò yín, nítorí bí ẹ̀yin bá jẹ́ kíkọ́ lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 6:34).

Pẹ̀lú àwọn ilérí Olúwa, a “a gbé [àwọn] ọkàn [wa] sókè a sì yọ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:13), àti pé “pẹ̀lú ọkàn ìdùnnú àti ìwò ìtújúká” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:15), a lọ síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Púpọ̀ jùlọ lára wa kò dojúkọ ìpinnu ìwọ̀n títóbi, bíi kíkúrò ní ilé wa láti lànà sí ilẹ̀ àìmọ̀. Àwọn ìpinnu wa jùlọ jẹ́ nínú ìṣe ìgbé ayé ojojúmọ́, ṣùgbọ́n Olúwa ti wí fún wa pe, “Ẹ máṣe káàárẹ̀ ní ṣíṣe rere, nítorí ẹ̀yin nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ títóbi lélẹ̀. Àti pé nínú àwọn ohun kékeré ni èyíinì tí ó tóbi yíò ti jáde wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:33).

Agbára àìní-ààlà wà nínú ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ àìmikàn wa nínú ẹ̀kọ́ náà ntọ́ àwọn ìṣísẹ̀ wa sọ́nà ó sì nfún wa ní ayọ̀. Ó nfún inú wa ní òye ó sì nfi okun àti ìgbẹ́kẹ̀lé fún àwọn ìṣe wa. Ìtọ́sọ́nà yí àti lílóye àti agbára ni àwọn ẹ̀bùn tí a gbà látọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Nípa ìmọ̀ àti ìbáramu ìgbé ayé wa sí ẹ̀kọ́ náà, pẹ̀lú ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà àtọ̀runwá, a lè tújúká kí a sì pa arawa mọ́ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú síwájú àyànmọ́ ayérayé wa—àtúnṣe-ìrẹ́pọ̀ àti ìgbéga pẹ̀lú olùfẹ́ni àwọn òbí ọ̀run.

“Ẹ lè dojúkọ àwọn ìpènijà tí ó bonimọ́lẹ̀,” ni Alàgbà Richard G. Scott kọ́ni. “Nígbàmíràn wọ́n jẹ́ fífọ́kànsí, àìláánú gidi, tí ẹ fi lè rò pé wọ́n kọjá agbára yín láti darí. Ẹ máṣe da nìkan dojúkọ ayé. ‘Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; másì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ’ [Proverbs 3:5]. … A ti lérò pé ìgbé ayé yíò jẹ́ ìpènijà, kìí ṣe kí a lè ní ìjákulẹ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ lè yege nípa bíborí.”8

Gbogbo rẹ̀ jẹ́ apákan ètò Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì, nípa èyí tí mo jẹri, bí mo ti gbàdúrà pé gbogbo wa yíò tẹramọ́ lílọ sí òpin àjò lọ́run, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Jòhánù 13–16.

  2. Wo 2 Néfì 2:11.

  3. Abraham Lincoln, sọ̀rọ̀ sí Wisconsin State Agricultural Society, Milwaukee, Sept. 30, 1859; in John Bartlett, Bartlett’s Familiar Quotations 18th ed. (2012), 444.

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:31.

  5. Wo Lawrence E. Corbridge, “Surviving and Thriving like the Pioneers,” Ensign, July 2020, 23–24.

  6. Wo “Minutes of the General Conference of 6 October 1849,” General Church Minutes Collection, Historical Department, The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints, Salt Lake City.

  7. George A. Smith, nínú Ìròhìn Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, Aug. 28, 1852, 1, Church History Library, Salt Lake City.

  8. Richard G. Scott, Rírí àláfíà, Ìdùnnú, àti Ayọ̀ (2007), 248–49.