Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọlọ́run Yíò Ṣe Ohun Àìlerò Kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ọlọ́run Yíò Ṣe Ohun Àìlerò Kan

Ọlọ́run ti múra àwọn ọmọ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀ sílẹ̀ fún àkokò yí.

Kò pẹ́ lẹ́hìn tí wọ́n dé àfonífojì Salt Lake, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹ́mpìlì mímọ́. Wọ́n nímọ̀lára pe wọn de ibi tí wọ́n ti lè jọ́sìn Ọlọ́run nínú àláfíà àti nínú òmìnira kúrò nínú inúnibíni.

Bákanáà, ní kété tí ìpìnlẹ̀ tẹ́mpìlì nsúnmọ́ ìparí, ọmọ-ogun United States kan dé láti fi tipátipá gbé gómìnọ̀ titun lé wọn lórí.

Nítorí àwọn olórí Ìjọ kò mọ̀ bí àwọn ogun ṣe burú tó, Brigham Yound pàṣẹ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti kúrò kí wọ́n sì sin ìpìnlẹ̀ tẹ́mpìlì síbẹ̀.

Ó dá mi lójú pé ó ya àwọn ọmọ Ìjọ kan lẹ́nu ìdí tí ìtiraka wọn láti kọ́ ìkọba Ọlọ́run fi nní ìjákulẹ̀ léraléra.

Ní ìgbẹ̀hìn, ewu kọjá, wọ́n sì gbẹ́ ìpìnlẹ̀ tẹ́mpìlìì àti pé wọ́n sì ṣe ìbẹ̀wò rẹ̀ Ìgbànáà ni àwọn akọ́lé olùlànà ṣàwárí pé àwọn kan lára àtilẹ̀bá yanrì-òkúta ti fọ́, tí kò mú wọn wúlò bí ìpìnlẹ̀ kan.

Nítorínáà, Brigham ní kí wọ́n tún ìpìlẹ̀ náà ṣe kí ó lè ti yanrìn-òkúta1 àwọn ògiri ọlánlá Temple Salt Lake náà lẹ́hìn dáadáa.2 Ní òpin, àwọn Ènìyàn Mímọ́ lè kọrin “Bí Ìpìnlẹ̀ kan ṣe Fẹsẹ̀múlẹ̀ Gbọingbọin”3 wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n kọ́ tẹ́mpìlì mímọ́ wọn sórí ìpìnlẹ̀ líle tí yíò pẹ́ fún ìrandíran.

Àwòrán
Ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake

Ìtàn yí kọ́ wa bí Ọlọ́run ṣe lo ìpọ́njú láti fi mú èrèdí Rẹ̀ wá.

Àjàkálẹ̀ Àrùn Gbogbo-ayé Kan

Bí èyí bá dàbí ohun mímọ̀ ní ipò tí a fúnni nínú èyí tí a bá arawa ní òní, ó jẹ́ nítorí rẹ̀ ni.

Mo ní iyèméjì tí ẹnìkan bá wà tí ó ngbọ́ ohùn mi tàbí ka ọ̀rọ̀ mi tí kò ti faragbá nípasẹ̀ àjàkàlẹ̀ àrùn gbogbo-ayé.

Sí awọn tí wọ́n nṣọ̀fọ̀ àdánù ẹ̀bí àti ọ̀rẹ́, a ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú yín. A bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run láti tunínú àti láti rọ̀ yín nínú.

Àwọn àbájáde ìgbà-pípẹ́ ti àrùn yí kọjá ìlera ti-ara lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí ti pàdánù owó-wíwọle tí ebi, àìnìdánilójú, àti ìjánú sì ndérù bà wọ́n, A fẹ́ràn àwọn ìtiraka àìmọtara-ẹni-nìkan ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti dẹ́kun ìtànká àrùn yí. A ní ìrẹ̀lẹ̀ nípasẹ̀ ìrúbọ jẹ́jẹ́ àti àwọn ìtiraka akọni àwọn tí wọ́n fi ewu ààbò ara wọn ṣe àtìlẹhìn, ìwòsàn, ìránlọ́wọ́ àwọn ènìyàn nínú àìní. Ọkàn wa kúm fún ìmoore fún ìwàrere àti àánú yín.

A gbàdúrà gidigidi pé Ọlọ́run yíò ṣí fèrèsé ọ̀run yíò sì kún ìgbé ayé yín pẹ̀lú àwọn ìbùkún ayérayé Ọlọ́run.

Àwa Ni Irú-ọmọ

Ọpọ̀lọpọ̀ awọn àìmọ̀ ni ó ṣì wà nípa àrùn yí. Ṣùgbọ́n tí ohun kan bá wà tí mo mọ̀, ni pé àrùn yí kò ya Baba Ọ̀run lẹ́nu. Òun kò nílati kó àwọn àfikún ọmọ-ogun ángẹ́lì jọ, pe àwọn ìpàdé pajáwìrì, tàbí ya àwọn ohun èlò sọ́tọ̀ látinú ẹ̀dà ìṣẹ̀dá-ayé láti kojú àìní àìròtẹ́lẹ̀.

Ọ̀rọ̀ mi ní òní ni pé àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ àrun yí kìí ṣe ohun tí a fẹ́ tàbí tí a rò, Ọlọ́run ti múra àwọn ọmọ Rẹ̀ sílẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀ fún Àkokò yí.

A o farada èyí, bẹ́ẹ̀ni. Ṣùgbọ́n a ó ṣe ju kí a kàn rún ẹyín wa lọ, dìí mú, àti kí a dúró fún àwọn ohunkan láti padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀, A ó tẹ̀ síwájú, a ó sí dara si gẹ́gẹ́bí àyọrísí kan.

Ní ọ̀nà kan, a jẹ́ irú-ọmọ. Àti fún irú-ọmọ láti débí agbára wọn, a gbọ́dọ̀ gbìn wọ́n kí wọ́n tó wù jáde. Ó jẹ́ ẹ̀rí mi pé bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ní ìgbà míràn a lè ní ìmọ̀ara gbígbìn nípasẹ̀ àwọn àdánwò ìgbé ayé wa tàbí kí àwọn òkùnkùn ẹ̀dùn-ọkàn yí wa ká, ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì yíò mú ohun kàn tí a kò lérò jáde wá.

Àwọn Ìbùkún Nwá Látinú Ìṣòrò

Gbogbo àkokò iṣẹ́ ìríjú ní ó ti dojúkọ àwọn ìgbà àdánwò àti ìṣòrò rẹ̀.

Enoch àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbé ní ìgbà ìkà, ogun, àti ìtàjẹ̀sìlẹ̀. “Ṣùgbọ́n Olúwa wá ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Ó ní àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ nínú fún wọn. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé Síónì kalẹ̀—ènìyàn kan “pẹ̀lú ọkan kan àti inú kan” tí wọ́n “gbé nínú òdodo.”4

Joseph kékeré , ọmọ Jákọ́bù, ni a jù sínú kòtò, a tàá sóko ẹrú, a dalẹ̀ rẹ̀, a sì paá ti.5 Ó lè ti ya Joseph lẹ́nu bí Ọlọ́run bá ti gbàgbé rẹ̀. Ọlọ́run ní ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan nínú fún Joseph. Ó lo àsìkò yí àdánwò yí láti fún ìwà Joseph lókun àti láti fi sí ipò láti gba ẹbí rẹ̀ lá6

Àwòrán
Joseph nínú Ẹ̀wọn Liberty

Ronú nípa Wòlíì Joseph Smith nígbàtí wọn tì í mọ́lé ní Ẹ̀wọ̀n Líberty, bí ó ṣe bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n njìyà. O gbọ́dọ̀ ti ròó bí a ó ṣe gbé Síónì kalẹ̀ nínú àwọn ipò wọnnì. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ̀rọ̀ àláfíà sí i, ìfihàn ológo tí ó tẹ̀le mú àláfíà wá sọ́dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́—ó sì tẹ̀síwájú láti mú àláfíà wá sọ́dọ̀ yín àti èmi.7

Ìgbà méèló nínú àwọn ọdún ìṣaájú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti ṣe aláìnírètí tí ó sì yà wọ́n lẹ́nu bí Ọlọ́run bá ti gbàgbé wọn? Ṣùgbọ́n nípa àwn inùnibíni, ewu, àti ẹ̀rù pípa, Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì ti ní ohunkan míràn nínù fún àwọn agbo kékeré Rẹ̀. Ohun àìrotẹ́lẹ̀ kan.

Kíni a kọ́ látinú àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí—àti àwọn ọgọgọọrún míràn nínú ìwé mímọ́?

Àkọ́kọ́, a kò fún àwọn olódodo ni ìkọja ọ̀fẹ́ tí ó fàyè gbà wọ́n láti yẹra fún àwọn àfonífojì òjìji. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ rin nínú àwọn ìgbà ìṣòro, nítorí nínú àwọn ìgbà ìpọ́njú wọ̀nyí ni à nkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí yíò fún ìwa wa lágbára àti ìdí láti súnmọ́ Ọlọ́run si.

Èkejì, Baba wa Ọ̀run mọ̀ pé a ó jìyà, àti pé nítorí a jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Òun kò ní fi wá sílẹ̀.8

Ronu nípa ẹni alàánú kan, Olùgbàlà, ẹnití ó lo púpọ̀ nínú ìgbé ayé Rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí aláìsàn, aladáwà, oníyèméjì, àti aláìnírètí.9 Ẹ̀yin ha ro pé Òun kò laniyan nipa yín ní òní bí?

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, Ọlọ́run yíò tọ́jú yíò sì ṣe ìṣọ́ lórí yín ní àwọn ìgbà àìnídánilójú àti ẹ̀rù wọ̀nyí. Ó mọ̀ yín. “Ó ngbọ́ àwọn ẹ̀bẹ̀ yín. Ó jẹ́ olóòótọ́ àti olùgbẹ́kẹ̀lé. Òun yíò mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ.

Ọlọ́run ní ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan nínú fún yín gan an àti Ìjọ lápapọ̀—iṣẹ́ ìyanu kan àti ìyanilẹ́nu.

A Dúpẹ Lọwọ Yín, Áà Ọlọrun, fún Wòlíì kan

Àwọn ọjọ́ dídára si wà níwájú wa, kìí ṣe ní ẹ̀hìn wa. Èyí ni ìdí tí Ọlọ́run fi fún wa ní ìfihàn òde òní! Láìsí i rẹ̀, ìgbé ayé lè dàbí fífò ní àwòṣe dídi nkan mú, dídúró fún ìkukù láti fò kí a lè délẹ̀ láìléwu. Àwọn èrèdí Olúwa fún wa pọ̀ ju iyẹn lọ. Nítorí èyí ni Ìjọ Krístì alààyè, àti nítorí Òun ni ó ndarí àwọn wòlìì Rẹ̀, à nlọ síwájú àti sókè sí àwọn ibi tí a kò dé rí, sí ibi gíga tí a kò lérò rárá.

Nísisìyí, èyí kó túmọ̀ sí pé a kò ní ní ìrírí rúdurùdu nínú fífò wa ní ayé ikú. Kò túmọ̀ sí pé kò ní sí àwọn ìkùnà ohun èlò àìròtẹ́lẹ̀, ìbàjẹ́ ẹ̀rọ̀, àti ìpènijà ojú-ọjọ́ líle. Ní toótọ́, àwọn ohunkan le burú si ṣíwájú kí wọ́n tó dára si.

Gẹ́gẹ́bí olùja awakọ̀ àti ọ̀gágun ọkọ̀ òfúrufú, mo kọ́ pé nígbàtí èmi kò bá lè yan ìpọ́njú tí èmi ó kojú nígbà fífo kan, mo lè yan bí èmí ó ṣe múrasílẹ̀ àti bí èmi ó ṣe fèsì. Ohun tí mo nílò ní àwọn ìgbà wàhàlà ni láti farabalẹ̀ kí nsì ní ìgbẹ́kẹ̀lé orí pípé.

Báwo ni a ó ti ṣe èyí?

A dojúkọ òtítọ́ kí a sì padà sí àwọn ìpìlẹ̀, sí kókó àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀, sí ohun to ṣe pàtàkì jùlọ. Kí ẹ fún ìwà ẹ̀sìn ìkọ̀kọ̀ yín lókun—bíi gbígbàdúrà áti àṣàrò ìwé mímọ àti pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ẹ jẹ́ kí ìpinnu yín dálé àwọn ìṣe ìyẹ̀wò dídára.

Ẹ dojúkọ àwọn ohun tí ẹ lè ṣe kìí ṣe àwọn ohun tí ẹ kò lè ṣe.

Ẹ kó ìgbàgbá yín jọ. Kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ fún ọ̀rọ̀ ìtọ́nisọ́nà Olúwa àti wòlíì Rẹ̀ láti darí yín sí ààbò.

Ẹ rántí, pe èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì—Ó wà ní Orí rẹ̀.

Ẹ ronú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìmísí ìgòkè tí ó ṣẹlẹ̀ ní díkédì tó kọjá nìkan. Láti kàn sọ díẹ̀:

  • Oúnjẹ Olúwa ni a túnsọ bí gbùgbun ìjọsìn Ọjọ́-ìsinmi.

  • Wá, Tẹ̀lé Mi ni a pèsè bí ohun èlò àtìlẹhìn-Ìjọ gbùngbun-ilé láti fún ẹmìkọ̀ọ̀kan àti ẹbí lókun.

  • A bẹ̀rẹ̀ gígajù kan àti ọ̀nà mímọ́ si nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí gbogbo ènìyàn.

  • Lílo ẹ̀rọ ní pípín ìhìnrere àti ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa ti tàn káàkiri gbogbo Ìjọ.

Ànì àwọn abala ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò wọ̀nyí kò ní ṣeéṣe láìsí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ̀ ìyanu.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arákùnrin, pẹ̀lú Krístì ní orí, ohun gbogbo kò ní dára bẹ́ẹ̀ lásán; wọ́n yíò jẹ́ àìròtẹ́lẹ̀.

Ìṣẹ́ Kíkíjọ́ Ísráẹ́lì Ntẹ̀síwájú

Ní àkọ́kọ́ ó lè dàbí ẹnipé àjàkálẹ̀ àrùn yíò jẹ́ ìdinà sí iṣẹ́ Olúwa. Fún àpẹrẹ, àṣà ti pínpín ìhìnrere tẹ́lẹ̀ kò ṣeéṣe. Bákannáà, àjàkálẹ̀ àrùn nfi àwọn ọ̀nà titun àti ìṣe láti nawọ́ jáde sí olotitọ ní ọkàn. Iṣẹ́ kíkójọ Ísráẹ́lì npọ̀si ní agbára àti ìyárí. Ọgọọgọ́run àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìtàn jẹrí sí èyí.

Ọ̀rẹ́ rere kan tí ó ngbé ní Norway kọ̀wé sí Harriet àti èmi nípa púpọ̀ si àìpẹ́ ní ìrìbọmi. “Nní àwọn ibi tí ìjọ ti kéré,” ó kọ wípé, “ẹ̀ka kékeré yíò di ẹ̀ka, àti pé ẹ̀ka yíò di wọ́ọ̀d!!”

Ní Latvia, inú obìnrin kan tí ó wá Ijọ rí nípa títẹ ìpolówó ayélujára dùn láti kọ́ nípa ìhìnrere Jésù Krístì tí ó sì farahàn fún ìpàdé rẹ̀ ní wákàtí kùtùkùtù kan, ṣíwájú kí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tó parí ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́, ó bèèrè fún ọjọ́ tí òun ó ṣe ìrìbọmi.

Ní apa Ìlà-òòrùn Europe, obìnrin kan tí ó gba ìpè látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kígbè, “Ẹ̀yin arábìnrin kílódé tí ẹ kò ti pè ṣíwájúr? Èmi ti ndúró!”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa nṣiṣẹ́ si ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkọ́ àwọn ènìyàn púpọ̀ ju titẹ́lẹ̀ rí lọ. Ìsopọ̀ npọ̀ si ní àárín àwọn ọmọ ìjọ àti ìránṣẹ́ ìhìnrere.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a lè ti so mọ́ àṣà pé ó gbà àjàkàlẹ̀ àrùn láti la ojú wa. Bóyá a ṣì nkọ́lé pẹ̀lú iyanrìn-òkúta nígbàtí wẹ́rẹ́-òkúta ti wà. Ní pàtàkì, nísisìyí a nkọ́ bí a ó ti lo onírurú ètò, pẹ̀lú ẹ̀rọ, láti pe àwọn ènìyàn—ní ọ̀nà tótọ́ àti àbìnibí—láti wá àti làti rí, wá àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́, àti láti wá àti làti wàpẹ̀lú.

Iṣẹ́ Rẹ, Ọ̀nà Rẹ̀

Èyí ni iṣẹ́ Olùwa. Ó pè wá láti wá ọ̀nà Rẹ̀ láti ṣé, àti kí wọ́n lè yàtọ̀ kúrò ní àwọn ìrírí àtẹ̀hìnwá.

Èyí ṣẹlẹ̀ sí Símónì Pétérù àti àwọn ọmọẹ̀hìn míràn tí wọ́n lọ pẹja ní òkun Tíbéríásì.

“Ní òru wọn kò mú ohunkóhun.

“Ṣùgbọ́n nígbàtí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí [nmọ́], Jésù dúró létí òkun. …

“Ó sì wí fún wọn pé, ẹ sọ àwọ̀n sí [ẹ̀gbẹ́] ọ̀tún ọkọ̀, ẹ ó sì ri.”

Wọ́n sì ju àwọ̀n wọn sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún wọn kò sì “lè fáá jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.”10

Ọlọ́run ti fihàn ó sì ntẹ̀síwájú láti fi ọwọ́ agbára Rẹ̀ hàn. Ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí a ó wo ẹ̀hìn tí a ó sì mọ̀ pé ní àkokò ípọ́njú yí, Ọlọ́run nràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀nà dídára si—Ọ̀nà Rẹ̀—láti kọ́ ìjọba Rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ gbọingbọin.

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé iṣẹ́ Ọlọ́run àti pé Òun yíò tẹ̀síwájú láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ ní àárín àwọn ọmọ Rẹ̀, àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ọlọ́run di àtẹ́lẹwọ́ ti ìtọ́jú àti ọwọ́ àánú wa mú.

Mo jẹri pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì fún ọjọ́ wa.

Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Olúwa, mo pè láti bùkún yí láti fi “ìyárí ṣe àwọn ohun tí ó wà ní agbára [yín] láti ṣe, àti pé nígbànáà [ẹ] lè dúró títí, pẹ̀lú ìdánilójú gíga, láti rí ìgbàlà Ọlọ́run, àti láti fi ọwọ́ rẹ̀ hàn.”11 Mo ṣe ìlérí pé Olúwa yíò fa àwọn ohun àìròtẹ̀lẹ̀ láti wá nínú iṣẹ́ òdodo yín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Quartz monzonite tí ó dàbí wẹ́rẹ́-òkúta tí a mú láti ilẹ̀ ní ẹnu Cottonwood Canyon kékeré, ogún máìlì ìlú-nlá gúsù-ìlà-òòrùn.

  2. Fún ìjìnlẹ̀ si wo àsìkò ìtàn yí, wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ̀ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn, vol. 2, Kò sí ọwọ́ ibi, 1846-1893 (2020), àwọn orí 17, 19, àti 21.

  3. “Bí Ìpìlẹ̀ kan Ṣe Fẹsẹ̀-múlẹ̀ Gọingọin,” Àwọn orin, no. 85.

    Àwọn ẹsẹ orin ìyìn nlá yí lè dà bí àkọlé fún àwọn ìgbà wa àti, nígbàtí a bá fi etí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú etí titun, tí ó pèsè òye sínú àwọn ìpènijà tí a dojúkọ:

    Ní gbogbo ipò—nínú àìsàn, nínú ìlera,

    Nínú òṣì tàbí gbígbé nínú ọrọ̀.

    Ní ilé tàbí òkè òkun, ní ilẹ̀ tàbí òkun—

    Bí ọjọ́ yín ṣe bèèrè … bẹ́ẹ̀ni ìtùnú yíò jẹ́.

    Máṣe bẹ̀rù, èmí wà pẹ̀lú yín; ẹ máṣe fòyà,

    Nítorí èmi ni Ọlọ́run yín èmi ó ṣì fún yín ní ìrànlọ́wọ́,

    Èmi ó fún yín lókun, ràn yín lọ́wọ́, àti mú yín dúró,

    Dì yín mú nínú òdodo … ọwọ́ agbára rẹ̀.

    Nígbàtí ó pè mí láti lọ nínú omi jíjìn,

    Odò ìkorò kò ní borí yín,

    Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín, àwọn ìdàmú yín láti bùkún,

    Àti yà yín sí mímọ́ … ìrẹ̀wẹ̀sì jìjinlẹ̀.

    Nígbàtí nínù àdáwò gbígbóná ipa ọ̀nà dùbúlẹ̀,

    Oorẹ-ọ̀fẹ́ mi, gbogbo tó, láti jẹ́ ìpèsè yín.

    Ìná kò ní pa yín lára; ni mo ṣe ètò

    Ìdárọ yín láti run … àti wúrà yín láti túnṣe.

    Ẹ̀mí yín ní orí Jésù ti bèèrè fún òpin

    Èmi kò ní, èmi kò lè, yà sọ́dọ̀àwọn ọ̀tá rẹ̀;

    Ẹ̀mí náà, bí gbogbo ọ̀run-àpáàdì tilẹ̀ wá rìrì,

    Emi kò ní paátì láéláé, rárá láéláé … rárá láéláé!

  4. Wo Mósè 7:13–318.

  5. Bóyá Joseph jẹ́ ọ̀dọ́mọdé bí ọdún mẹ́tàdínlógún nígbàtí àwọn arákùnrin rẹ̀ tàá sí oko ẹrú (wo Genesis 37:2). Ó jẹ́ ọmọ ọdún ọgbọ̀n nígbàtí ó wọ iṣẹ́-ìsìn Pharaoh (wo Gẹ́nẹ́sísì 41:46). Ṣe ẹ lè rò bí ó ti ṣòro tó fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní ìbẹ̀rẹ̀ láti rí ìdalẹ̀, a tàá sí oko ẹrú, a parọ́ mọ, tí a sì tìí mọ́lé? Joseph dájúdájú ni àwòṣe kan kìí ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọ tí wọ́n fẹ́ láti gbé àgbélèbú náà kí wọ́n sì tẹ̀lé Olùgbàlà.

  6. Wo Genesis 45:4–11; 50:20–21. Nínú Psalm 105:17–18, a kà pé, “Ó rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọn, àní Joseph, ẹnití wọ́n ta fún ọmọ-ọ̀dọ̀: ẹnití a pa ẹsẹ̀ rẹ̀ lára pẹ̀lú ìyẹ́: a tẹ sórí irin.” Ní ìyírọ̀padà míràn, ẹsẹ méjìdínlógún ó ka pé, “Wọ́n pa ẹsẹ rẹ̀ lára pẹ̀lú ìyẹ́, irin ti wọ ẹ̀mí rẹ̀” (Young’s Literal Translation). Fún mi èyí dá àbá pé àwọn ìṣòro Joseph fun ní ẹ̀mí líle àti àìdúró bí irin—ìwà kan tí òun yíò nílò fún ọjọ́ ọ̀la nlá àti àìròtẹ́lẹ̀ tí Olúwa ní ní ìṣúra fún un.

  7. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:23.

  8. Bí Olúwa bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ láti ní ìrura nípa àti àánú síwájú àwọn elébi, aláìní, alàìní aṣọ, aláìsàn, àti tí a pọ́nlójú, dájúdájú Òun yíò ní ìfura àti àánú sí wa, àwa ọmọ Rẹ̀ (wo Mormon 8:39).

  9. Wo Lúkù 7:11-17.

  10. Wo John 21:1–6.

  11. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 123:17.