Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Máa Ṣọ́ra Nítorínáà, Kí Ẹ sì Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ẹ Máa Ṣọ́ra Nítorínáà, Kí Ẹ sì Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo

Lóni, mo mú ìpè mi fún àdúrà gbòrò dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀ èdè yíká àgbáyé.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ààrin ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀hìn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní ayé kíkú, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ láti “Ẹ máa ṣọ́ra nítorínáà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbàgbogbo, kí a le kà yín yẹ láti yọ nínú gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí tí yío wá sí ìmúṣẹ, àti láti dúró níwájú Ọmọ ènìyàn.”1

Nínú “àwọn ohun tí yío wá sí ìmúṣẹ” ṣaájú Bíbọ̀ Ẹẹ̀kejì Rẹ̀ ni “àwọn ogun àti ìdágìrì ogun[,] … ìyàn, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn, àti ilẹ̀ ríri, ní onírúurú ibi,”2

Nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú Olùgbàlà sọ pé, “Ohun gbogbo yío sì wà ní ìdárúdàpọ̀; … nítorí èrù yío wá sí orí gbogbo ènìyàn.”3

Dájúdájú, a ngbé ní àkókò kan nínú èyítí àwọn ohun wà ní ìdárúdàpọ̀. Púpọ̀ àwọn ènìyàn bẹ̀rù ọjọ́ iwájú, àti pé pùpọ̀ àwọn ọkàn ní wọ́n ti yà kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn sí Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Àwọn àbọ̀ ìròhìn kún fún àwọn àkọsílẹ̀ ti ìwà-ipá. Ìwà àbùkù ndi títẹ̀jáde lórí ayélujára. Àwọn itẹ́ òkú, àwọn ilé ìjọsìn, àwọn mọ́sáláṣí, àwọn sínágọ́gù, àti àwọn ojúbọ ẹ̀sìn ti di bíbàjẹ́.

Àjàkálẹ̀ àrùn kárí ayé ti fẹ́rẹ̀ dé gbogbo origun ilẹ̀ ayé: mílíọ́nù àwọn ènìyàn ti fi ara kó; ẹgbẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọgọ́run ti kú. Àwọn ìkẹ́kọjáde ní ilé ìwé, àwọn ìsìn ìjọ́sìn nínú ìjọ, àwọn ètò ìgbéyàwó, ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti ogunlọ́gọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì miràn ti di dídàrú. Ní àfikún, àwọn ènìyàn tí kò lónkà ni a ti fi sílẹ̀ ní dídáwà àti yíyàsọ́tọ̀.

Ètò ọrọ̀ ajé rúdurùdu ti fa àwọn ìdojúkọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, pàápàá fún àwọn aláìlágbára jùlọ nínú àwọn ọmọ ti Baba wa Ọrun.

A ti rí àwọn ènìyàn tí wọ́n nlo ẹ̀tọ́ wọn sí ẹ̀hónú wọrọ́wọ́, a sì ti rí àwọn jandùkú tí wọ́n da ilú rú.

Ní àkókò kannáà, a tẹ̀síwájú láti rí àwọn ìjà yíká gbogbo àgbáyé.

Nígbà gbogbo mo máa nrò nípa ẹ̀yin wọnnì tí ẹ njìyà, nṣe àníyàn, nbẹ̀rù, tàbí tí nní ìmọ̀lára dídáwà. Mo fi dá ẹnìkọ̀ọ̀kan yín lójú pé Olúwa mọ̀ yín, pé Ó mọ̀ nípa àníyàn àti ìrora yín, àti pé Ó fẹ́ràn yín—tímọ́tímọ́, àti bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan, jinlẹ̀-jinlẹ̀, àti títí láe.

Ní alaalẹ́ nígbàtí mo bá ngbàdúrà, mo máa nbẹ Olúwa láti bùkún gbogbo àwọn tí wọ́n wúwo pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, ìrora, ìdánìkanwà, àti ìbànújẹ́. Mo mọ̀ pé àwọn olórí míràn nínú Ijọ gba irú adúrà kannáà. Okàn wa, bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀, jade lọ sí ọ̀dọ̀ yín àwọn àdúrà wa sì lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìtìlẹhìn yín.

Mo lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ní ọdún tó kọjá ní apá ìhà àríwá-ìlà oòrùn ti United States, ní síṣe àbẹ̀wò sí àwọn ibi ìtàn ti Amẹ́ríkà àti Ìjọ, síṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ wa àti àwọn ọmọ ijọ wa, àti síṣe àbẹ̀wò sí àwọn olórí ìjọba àti ti okòwò.

Ní Ọjọ́ Ìsinmi, 20 Oṣù kẹwa, mo bá àpéjọ nlá kan sọ̀rọ̀ ní ẹ̀bá Boston, Massachusetts. Bí mo ti nsọ̀rọ̀, mo ní ìmọ̀lára láti sọ pé, “Mo bẹ̀ yín … láti gbàdúrà fún orílẹ̀ èdè yí, fún àwọn olórí wa, fún àwọn ènìyàn wa, àti fún àwọn ẹbí tí ngbé ní orílẹ̀ èdè nlá yi tí a dá sílẹ̀ nípa ọwọ́ Ọlọ́run.”4

Mo sọ bákannáà pé Amẹ́ríkà àti púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé, bíi ní àwọn ìgbà tí ó kọjá, wà ní ìkóríta míràn tó léwu àti pé wọ́n nílò àwọn àdúrà wa.5

Ẹ̀bẹ̀ mi kò sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti pèsè tẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì tọ̀ mí wá bí mo ti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí tí ó mí sími láti pe àwọn wọnnì tí wọ́n wà níbẹ̀ láti gbàdúrà fún orilẹ̀ èdè wọn àti àwọn olórí wọn.

Lóni mo mú ìpè mi fún àdúrà gbòrò dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀ èdè yíká àgbáyé. Bí ó ti wù kí o máa gbádúrà tàbí ẹnikẹ́ni tí o ngbàdúrà sí, ẹ jọ̀wọ́ lo ìgbàgbọ́ yín—ohunkóhun tí ìgbàgbọ́ yín le jẹ́—kí ẹ si gbàdúrà fún orílẹ̀ èdè yín àti àti fún àwọn olórí orílẹ̀ èdè yín. Bí mo ti sọ ní Oṣù Kẹwa tí ó kọjá ní Massachusetts, a dúró lóni ní ìkóríta pàtàkì kan nínú ìtàn, àti pé àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé wà nínú ìnílò dandan fún imísí àti ìtọ́ni. Èyí kìí ṣe nípa òṣèlú tàbí ìlànà. Èyí jẹ́ nípa àláàfíà àti ìwòsàn tí ó le wá sí ọkàn kọ̀ọ̀kan àti sí ọkàn àwọn orílẹ̀ èdè—àwọn ìlú nlá, àwọn ìlú kéréje, àti àwọn ìletò wọn—nípasẹ̀ Ọmọ Aládé Alàáfíà àti orísun gbogbo ìwòsàn, Olúwa Jésù Krístì.

Ní ààrin àwọn oṣù díẹ̀ tó kọjá mo ti ní ìmọ̀lára tí ó tọ̀mí wá pé ọ̀nà dídára jùlọ láti ran ipò tí àgbáyé wà nísisìyí lọ́wọ́ ni fún gbogbo ènìyàn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ní kíkún síi àti láti yí ọkàn wọn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ àdúrà tòótọ́. Rírẹ ara wa sílẹ̀ àti wíwá ìmisí ọ̀run láti fi ara dà tàbí borí ohun tí ó wà níwájú wa yío jẹ́ ọ̀nà tí ó ní ààbò jùlọ tí ó sì dájú jùlọ láti sún pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ síwájú la àwọn àkókò ìdààmú wọ̀nyí já.

Àwọn ìwé mímọ́ tọ́ka sí àwọn àdúrà tí Jésù gbà àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ bákannáà nípa àdúrà ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ nínú ara kíkú. Ẹ̀yin yío rántí Àdúrà Olúwa:

“Bàbá wa tí nbẹ ní ọ̀run, Ọwọ̀ ni fún orúkọ rẹ.

“Kí ìjọba Rẹ dé. Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé, bí a ti í ṣe ní ọ̀run.

“Fúnwa ní ounjẹ òòjọ́ wa lóni

“Dárí igbèsè wa jì wá, bí àwa ti ndáríjì àwọn onígbèsè wa.

“Má sì fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ibi: Nítorí tìrẹ ni ìjọba, àti agbára, àti ògo títí láé. Àmín.”6

Àdúrà àfojúsùn, rírẹwà yí, tí a ntúnsọ nígbà gbogbo jákèjádò Kristíẹ́nítì, mú un hàn kedere pé ó ṣe déédé láti darí ẹ̀bẹ̀ tààrà sí “Bàbá wa tí nbẹ ní ọ̀run” fún àwọn ìdáhùn sí ohun tí ó ndààmú wa. Nítorínáà, ẹ jẹkí a gbàdúrà fún ìtọ́ni àtọ̀runwá.

Mo pè yín láti gbàdúrà nígbà gbogbo.7 Gbàdúrà fún ẹbí rẹ. Gbàdúrà fún àwọn olórí àwọn orílẹ̀ èdè. Gbadúrà fún àwọn onígboyà ènìyàn tí wọ́n wà ní ilà iwájú nínú àwọn ogun lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìdojúkọ àwọn àrùn ti ìbákẹgbẹ́, àdúgbò, ìṣèlú, àti àbínibí tí nyọ gbogbo ènìyàn lẹ́nu jákèjádò àgbáyé, olówó àti tálákà, ọ̀dọ́ àti ogbó.

Olùgbàlà kọ́wa láti máṣe díwọ̀n ẹnití a ó gbàdúrà fún. Ó sọ pé, “Ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe oore fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò, tí wọn sì nṣe inúnibíni sí yín.”8

Ní orí àgbélébu ní Kalfárì, níbití Jésù ti kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ó ṣe ohun tí Ó kọ́no nígbàtí Ó gbàdúrà, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ṣe.”9

Gbígbàdúrà nítòótọ́ fún àwọn wọnnì tí a le rí bíi àwọn ọ̀tá wa nṣe àpéjúwe ìgbàgbọ́ wa pé Ọlọ́run le yí ọkàn wa padà àti ọkàn àwọn ẹlòmíràn. Irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ yio fi okun fún ìpinnu wa láti ṣe èyíkéyi àwọn àyípadà tí ó bá ṣe dandan nínú ìgbé ayé, ẹbí, àti àdúgbò tiwa.

Kò já mọ́ nkan ibití o ngbé, èdè tí o nsọ, tàbí àwọn ìpèníjà tí o nkojú, Ọlọ́run ngbọ́ Ó sì ndá ọ lóhùn ní ọ̀nà Tirẹ̀ àti ní àkókò Tirẹ̀. Nítorípé a jẹ́ ọmọ Rẹ̀, a le tọ̀ Ọ́ lọ láti wá ìrànlọ́wọ́, ìtùnú, àti ìfẹ́ inú àkọ̀tun láti mú ìyàtọ̀ dídára wá nínú ayé.

Gbígbàdúrà fún òtítọ́, àlàáfíà, tálákà, àti aláìsàn kò tó nígbà púpọ̀. Lẹ́hìn tí a kúnlẹ̀ nínú àdúrà, a nílò láti dìde kúrò lórí eékún wa kí a sì ṣe ohun ti a bá le ṣe láti ṣe ìrànlọ́wọ́—láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ara wa àti àwọn ẹlòmíràn.10

Àwọn ìwé mímọ́ kún fún àpẹrẹ àwọn onigbàgbọ́ ènìyàn tí wọ́n pa àdúrà pọ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ láti mú ìyàtọ̀ wá nínú ìgbé ayé tiwọn àti ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn. Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, fún àpẹrẹ, a kà nípa Enọ́sì. A ti wòye rẹ̀ pé “bíi ìdá méjì nínú mẹ́ta ti ìwé kúkúrú rẹ̀ ṣe àpèjúwe àdúrà kan, tàbí ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn àdúrà, àti pé èyítí ó kù sọ ohun tí ó ṣe ní ìyọrísí àwọn ìdáhùn tí ó gbà.”11

A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ nípa bí àdúrà ṣe mú ìyàtọ̀ wá nínú ìtàn Ijọ tiwa, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà àwísókè àkọ́kọ́ ti Joseph Smith nínú oko igi kan ní ẹ̀bá ilé onígi àwọn òbí rẹ̀ ní ìgbà ìrúwé 1820. Ní wíwá ìdáríjì àti ìdarí ti ẹ̀mí, àdúrà Joseph ṣí àwọn ọ̀run sílẹ̀. Lóni, àwa ni olùjẹànfàní Joseph Wòlíì náà àti àwọn onígbàgbọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn míràn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n gbàdúrà tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ìránwọ́ gbé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kalẹ̀.

Mo máa nrò nígbà púpọ̀ nípa àdúrà àwọn onígbàgbọ́ obìnrin bíi Mary Fielding Smith ẹnití, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó fi ìgboyà darí ẹbí rẹ̀ láti inú inúnibíni tí ó nbẹ̀rẹ̀ ní Illinois sí ibi àbò ní àfonífojì yí, níbití ẹbí rẹ̀ ti ṣe rere ní ti ẹ̀mí àti ní ti ara. Lẹ́hìn gbígbàdúrà pẹ̀lú ìtara lórí eékún rẹ̀, nígbànáà ó ṣiṣẹ́ kára láti borí àwọn ìdojúkọ rẹ̀ ó sì bùkún ẹbí rẹ̀.

Àdúrà yío gbé wa sókè yío sì fà wá papọ̀ bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan, bíi ẹbí, bíi Ijọ kan, àti bíi àgbáyé. Àdúrà yío ní ipa lórí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yío sì ràn wọ́n lọ́wọ́ sí ìhà àwárí àwọn àjẹsára àti àwọn òògùn tí yío fi òpin sí àjàkálẹ̀ àrùn kárí ayé yi. Àdúrà yío tu àwọn wọnnì nínú tí wọ́n ti pàdánù olùfẹ́ kan. Yío tọ́ wa sọ́nà ní mímọ ohun tí a níláti ṣe fún ààbò ti ara wa.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, mo rọ̀ yín láti fi kún ojúṣe yín sí àdúrà, Mo rọ̀ yín láti gbàdúrà nínú iyẹ̀wù yín, nínú ìrìn yín ojojúmọ́, nínú ibùgbé yín, nínú wọ́ọ̀dù yín, àti, nígbà gbogbo, nínú ọkàn yín.12

Ní ìtìlẹhìn fún àwọn olóri Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Enìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn àdúrà yín fún wa. Mo rọ̀ yín láti tẹ̀síwájú láti máà gbàdúrà pé kí a le gba ìmísí àti ìfihàn láti tọ́ Ijọ sọ́nà la àwọn àkókò síṣòro wọ̀nyí já.

Àdúrà le yí ìgbé àyé tiwa padà. Pẹ̀lú ìwúrí nípa àdúrà tòótọ́, a le gbèrú síi kí a sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ láti ṣe bákannáà/

Mo mọ agbára àdúrà nípa ìrírí ti ara mi. Láipẹ́ yi mo dá nìkan wà nínú ọ́físì mi. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìlànà ìṣègùn òyínbó kan tán ní ọwọ́ mi. Ó dúdú ó sì tún búlúù, ó wú, àti pé ó ndùnni. Bí mo ti jókòó ní ibi dẹ́sìkì mi, nkò le fojúsùn sí orí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kókó àti pàtàkì nítorípé ara mi kò balẹ̀ nípasẹ̀ ìrora yi.

Mo kúnlẹ̀ nínú àdúrà mo sì ní kí Olúwa rànmí lọ́wọ́ fojúsùn kí nle ṣe iṣẹ́ mi yọrí. Mo dìde mo sì padà sí ibi àwọn ewé ìwé gíga ní orí dẹ́sìkì mi. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ lọ́gán, síṣe kedere àti ìfojúsùn wá sí iyè mi, ó sì ṣeéṣe fún mi láti parí àwọn ohun tí ó ṣe dandan ní iwájú mi.

Ipò rúdurùdu tí ayé wà lọ́wọ́lọ́wọ́ le dàbí bíbanilẹ́rù bí a bá wo ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn wàhálà àti ìdojúkọ. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹ̀rí ìtara mi pé bí a bá gbàdúrà tí a sì bẹ Baba Ọrun fún àwọn ìbùkún àti ìtọ́ni tí a nílò, a ó mọ bí a ṣe le bùkún àwọn ẹbí, aládugbò, agbègbè, àní àti orílẹ̀ èdè nínú èyí tí a ngbé.

Olùgbàlà gbàdúrà àti nígbànáà Ó “lọ kiri ní síṣe rere”13 nípa bíbọ́ tálákà, pípèsè ìgboyà àti àtìlẹ́hìn fún àwọn wọnnì nínú àìní, àti nínàwọ́ jáde nínú ìfẹ́, ìdáríjì, àlàáfíà, àti ìsinmi sí gbogbo ẹni tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó ntẹ̀síwájú láti nawọ́ jáde síwa.

Mo pe gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ, àti àwọn aládugbò àti àwọn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú tí wọ́n wà ní àwọn ẹgbẹ́ ìgbàgbọ́ miràn káàkiri àgbáyé, láti ṣe bí Olùgbàlà ti gba àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ nímọ̀ràn: “Ẹ máa ṣọ́ra nítorínáà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbs14 fún àlàáfíà, fún ìtùnú, fún ààbò, àti fún àwọn ànfààní láti sin ara yín.

Báwo ni agbára àdúrà ti tóbi tó àti pé báwo ni a ti nílò àwọn àdúrà ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ tó! Ẹ jẹ́ kí a rántí kí a fi ìmoore agbára àdúrà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.