Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ọ̀kan Ìṣọ̀kan ní Òdodo àti Ìṣọ̀kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Àwọn Ọ̀kan Iṣọ̀kan ní Òdodo àti Ìṣọ̀kan

Ní ọ̀gangan igba ọdún nínú ìtàn Ìjọ wa, ẹ jẹ́ kí a fi ara wa sílẹ̀ bí ọmọ ìjọ Olúwa láti gbé ní òdodo àti ní ìrẹ́pọ̀ ju titẹ́lẹ rí lọ.

Òdodo àti ìṣọ̀kan jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ pàtàkì1 Nígbàtí àwọn ènìyàn bá nifẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn tí wọ́n sì fi òdodo tiraka láti dàbí Rẹ̀, ìjà àti asọ̀ a dìnkù ní àwùjọ. Ìṣọ̀kan a pọ̀ si. Mo fẹ́ràn àkọsílẹ̀ to fi èyí hàn.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa, Ọ̀gágun Thomas L. Kane tìlẹ́hìn ó sì gbèjà àwọn Ènìyàn Mímọ́ bí a ti ní kí wọ́n sá kúrò ní Nauvoo. Ó jẹ́ alágbàwí fún Ìjọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.2

Ní 1872, Ọ̀gágun Kane, ìyàwó rẹ tó lẹ́bùn, Elizabeth Wood Kane àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjì rin ìrìnàjò láti ile wọn ní Ìlú-nlá Pennsylvania Salt Lake. Wọ́n tẹ̀lé Brigham Young àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lórí ìrìn ní gúsù sí St. George, Utah. Elizabeth ṣe ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ rẹ̀ sí Utah pẹ̀lú ìkùnsínú nípa àwọn obìnrin náà. Ó ní ìyàlẹ́nu nípa àwọn ohun tí ó kọ́. Fún àpẹrẹ, ó ri pé ìṣẹ́kíṣẹ́ nípa èyí tí obínrin lè gba ìgbé ayé ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn ní Utah.3 Bákannáà ó rí àwọn ọmọ Ìjọ onínúúre àti olóye pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí àwọn ọmọ Amẹ́ríkà.4

Ní ìrìnàjò náà wọ́n dúró ní Fillmore ní ilé Thomas R. àti Matilda Robison King.5

Elizabeth kọ pé Matilda nmúra oúnjẹ sílẹ̀ fún Ààrẹ Young àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, Amẹríka Indians marun wá sínú yara náà. Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò pè wọ́n, ó hàn kedere pé wọ́n fẹ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́. Arábìnrin King sọ̀rọ̀ sí wọn “ní èdè wọn.” Wọ́n joko sílẹ̀ pẹ̀lú ìbora wọn pẹ̀lú ìyárí ìwò ojú wọn. Elizabeth bèèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ King, “Kíni ìyá yín wí fún àwọn arákùnrin yẹn?”

Ọmọkùnrin Matilda fèsì “Ó wípé, ‘Àwọn àlejò wọ̀nyí kọ́kọ́ dé, mo sì ti se oúnjẹ tótó fún wọn; ṣùgbọ́n oúnjẹ yín wà lórí iná nísisìyí, èmi ó sì pè yín ní kété tí ó bá ṣetán.’”

Elizabeth bèèrè, “Ṣé òun ó ṣe ìyẹn, tàbí fún wọn ní èérún níbi ìlẹ̀kùn ilé-ìdáná?”6

Ọmọkùnrin maltida dáhùn pé, “Ìyá yíò fún wọn lóunjẹ bí ó ti ṣe fún yín, yíò sì fún wọn ní àyè níbi tábìlì.”

Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe, àti pé “wọ́n sì jẹun pẹ̀lú ìwà dídára pípé.” Elizabeth ṣàlàyé pé olùgbàlejò yí gba ìpín ọgọrun lójú rẹ̀.7 Ìrẹ́pọ̀ ngbòrò si nígbàtí a bá hùwà sí àwọn ènìyàn pẹ̀lú iyì àti ọ̀wọ̀ àní bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n yàtọ̀ ní ìhùwàsí ìta.

Gẹ́gẹ́bí olórí, a wà ní abẹ́ ìrújú pé látẹ̀hìnwá gbogbo ìbáṣepọ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ìṣe dàbíi ti Krístì, tàbí gbogbo ìpinnu jẹ́ dídára. Bákannáà, ìgbàgbọ́ wa kọ́ni pé a jẹ́ àwọn ọmọ Baba wa ní Ọ̀run, àti pé a njọ́sìn Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹnití ó jẹ́ Olùgbàlà wa. Ìfẹ́ inú wa ni pé ọkàn àti inú wa yíò papọ̀ nínú òdodo àti ìrẹ́pọ̀ àti pé a ó jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Wọn.8

Òdodo ni àsọyé tó gbòrò, ọ̀ràn lílóye ṣùgbọ́n dájúdájú ó wà pẹ̀lú gbígbé àwọn òfin Ọlọ́run julọ.9 Ó mú wa yege fún àwọn ìlànà mímọ́ tí ó wà ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí ó sì nbùkún wa láti ní Ẹ̀mí tí ó nfún ìgbé ayé wa ní ìdarí.10

Jíjẹ́ olódodo kò dálórí kí ẹnìkọ̀ọkan wa nígbogbo ìbùkún ní àkokò yí. A lè má ṣe ìgbeyàwó tàbí gba ìbùkún pẹ̀lú àwọn ọmọ tàbí ní àwọn ìbùkún míràn tí a fẹ́ nísisìyí. Ṣùgbọ́n Olúwa ti ṣèlérí pé àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ “lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ìdùnnú àìlopin.”10

Ìrẹ́pọ̀ bákannáà ni àsọyé tó gbòrò, ọ̀ràn yíyèni ṣùgbọ́n dájúdájú ó fi òfin nlá àkọ́kọ́ àti ìkejì láti fẹ́ Ọlọ́run àti láti fẹ́ ọmọnikejì wa hàn.12 Ó fi àwọn ènìyàn Síónì hàn bí ẹnití ọkàn àti inú wọn “wà papọ̀ ní ìrẹ́pọ̀.”13

Ìṣetò fún ọ̀rọ̀ mi ni ìlòdì àti àwọn ẹ̀kọ́ látinú àwọn ìwé mímọ́.

Ó ti wà ní ìgba ọdún sẹ́hìn látigbà tí Baba àti Ọmọ Rẹ̀ ti kọ́kọ́ farahàn àti ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ní 1820. Àkọsílẹ̀ nínú 4 Néfì nínú nínú Ìwé ti Mọ́mọnì wà pẹ̀lú irú igba ọdún kannáà lẹ́hìn tí Olùgbàlà farahàn tí ó sì gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́.

Akọsílẹ̀ ìwé ìtàn tí a ka ní 4 Nẹfì júwe àwọn ẹ̀nìyàn kan níbi tí kò sí ìlara, asọ̀, ariwo, irọ́, ìpànìyàn, tàbí èyíkéyí irú ìwà wọ̀bìà. Nítorí òdodo yí àkọsílẹ̀ wípé, “dájúdájú kò lè sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ jù wọn lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá.”14

Pẹ̀lú ọ̀wọ́ sí ìrẹ́pọ̀, 4 Néfì kà pé, “Kò sí asọ̀ ní ilẹ̀ nã, nitori ifẹ Ọlọ́run èyítí o ngbé inu ọkàn àwọn ènìyàn nã.”15

Láìlóríre, 4 Néfì nígbànáà júwe ìyípadà tí ó bẹ̀rẹ̀ kíá ní “igba ọdún àti ọdún àkọ́kọ́,”16 nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyapa npa òdodo àti ìrẹ́pọ̀ run. Ìjìnlẹ̀ ìdibàjẹ́ tí ó ṣẹlẹ̀ nígbànáà ni ibi tí wòlíì nlá Mọ́mọ́nì pohùnrere sí ọmọkùnrin rẹ̀ Mórónì:

“Ṣùgbọ́n A! ọmọ mi, báwo ni irú àwọn ènìyàn báyĩ, tí ìdùnnú wọn wà nínú ìwà ìríra púpọ̀—

“Báwo ní àwa ó ṣe retí kí Ọlọ́run o dá ọwọ́ ìdájọ́ rẹ̀ sí wa duro?”17

Ní àkokò iṣẹ́ ìríjú yí, bíótilẹ̀jẹ́pé à ngbé ní àkokò pàtàkì kan, tí a kò bùkún ayé pẹ̀lú òdodo àti ìrẹ́pọ̀ tí a júwe ni 4 Néfì. Nítòótọ́, à ngbé ní àsìkò ìyapa líle ní pàtàkì. Bákannáà, àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún tí wọ́n ti tẹ́wọ́gba ìhìnrere Jésù Krístì ti fi ara wọn sílẹ̀ sí ṣíṣe àṣeyege òdodo àti ìrẹ́pọ̀ méjèèjì. Gbogbo wa nífura pé a lè ṣe dáradára si, àti pé ìyẹn ni ìpenijà wa ní ọjọ́ yí. A lè jẹ́ ipa kan láti gbé sókè àti láti bùkún àwùjọ lápapọ̀. Ní ọ̀gangan igba ọdún nínú ìtàn Ìjọ wa, ẹ jẹ́ kí a fi ara wa sílẹ̀ bí ọmọ ìjọ Olúwa láti gbé ní òdodo àti ní ìrẹ́pọ̀ ju titẹ́lẹ rí lọ. Ààrẹ Russell M. Nelson ti ni kí a “fi ìwà dáadáa hàn gidi, ìbámu ẹ̀yà àti pàṣípàrọ̀ ọ̀wọ̀.”18 Èyí túmọ̀ sí níní ìfẹ́ ara wa àti Ọlọ́run àti títẹ́wọ́gba gbogbo ènìyàn bí arákùnrin àti arábìnrin kí a sì jẹ́ àwọn ènìyàn Síónì nítòótọ́.

Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ wa papọ̀, a lè jẹ́ ìgbilẹ̀ ìrẹ́pọ̀ kí a sì ṣe onírurú ayẹyẹ. Ìrẹ́pọ̀ àti onírurú kìí ṣe ìdàkejì. A lè ṣe àṣeyọrí ìrẹ́pọ̀ títóbi jùlọ bí a ṣe nmú wíwàpẹ̀lú ní àyíká wa àti fún onírurú ọ̀wọ̀. Ní àárín ọdún tí mo sìn ní Àjọ Ààrẹ Èèkàn San Franscisco California, a ní àwọn ọmọ ìjo tí wọ́n-nsọ-èdè Spanish-, Tongan-, Samoan-, Tagalog-, àti Mandarin. Àwọn wọ́ọ̀dù wa tó nsọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà àti ọ̀làjú àtilẹ̀wá. Ìfẹ́, òdodò àti ìrẹ́pọ̀ wà.

Àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ka nínú Ìjọ ti Jésù Krístì ti Ọjọ́-ìkẹhìn ní à nmọ̀ nípasẹ̀ agbègbè tàbí èdè,19 kìí ṣe ìran tàbí àṣà. A ko dà ìran mọ̀ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní bí ẹgbẹ̀ta-din-àádọ́ta ṣíwájú ìbí Krístì, a kọ́ wa ní òfin ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nípa ìbáṣepọ̀ ní àárín àwọn ọmọ Baba ní Ọ̀run. Gbogbo ènìyàn níláti pa òfin Ọlọ́run mọ́, a sì pe gbogbo ènìyàn láti ṣe àbápín inúrere Olúwa; “kò sì kọ sí ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ, dúdú àti funfun, tí ó wà nínú ìdè àti ní òmìnira, akọ àti abo; ó sì rántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run, Júù àti Kèfèrí.”20

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà àti ọ̀rọ̀ ti kéde léraléra pé gbogbo ìran àti àwọ̀ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Gbogbo wa jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin. Nínú ẹ̀kọ́ wa a gbàgbọ́ pé orílẹ̀-èdè ìgbani fún Ìmúpadàbọ̀sípò, United State, Iwé òfin U.S21 àti àwọn ìwé ìbámu,22 tí a kọ láti ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìpé, tí wọ́n gba ìmísí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti bùkún gbogbo ènìyàn. Bí a ti kà nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, àwọn ìwé wọ̀nyí ni a “gbékalẹ̀, tí a nílàti mójútó fún ẹ̀tọ́ àti ààbò ti gbogbo ẹlẹ́ran ara, gẹ́gẹ́bí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ òdodo àti mímọ́.”23 Méjì lára àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ wọ̀nyí ni agbára láti yàn àti ìṣirò fún ẹ̀ṣẹ̀ ara ẹni. Olúwa ti kéde pé:

“Nítorínáà, ko tọ̀nà pé kí ẹnikẹ́ni ó wá sínú ìgbèkùn ẹnìkan sí òmíràn.

“Àti fún ìdí yí ni èmi ṣe àgbékalẹ̀ ìwé òfin ti ilẹ̀ yí, láti ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹnití èmí ti gbé dìde nítorí ìdí yí gan an, àti tí mo sì ra ilẹ̀ náà padà nípa títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”24

Ìfihàn yí ni a gbà ní 1833 nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Missouri njìyà inúnibíni nlá. Ní lílọ sí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101 kà ní apákan pé: “Àwọn ẹni ibi ti lé wọn kúrò nílé wọn ní Jacson County. … Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ikú lòdì sí [ọmọ ẹgbẹ́] Ìjọ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.”25

Àkoko yí ni ìnira wà káàkiri. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Missouri ronú nípa Ará Amẹ́ríkà bí ọ̀tá tí kọ̀ lè jáwọ́ tí wọ́n sì nfẹ́ lé wọn kúrò ní ilẹ̀ náà. Ní àfikún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùgbé Missouri jẹ́ olówó àwọn ẹ̀rú wọ́n sì nbẹ̀rù àwọn tó tako òwò ẹrú.

Ní ìlòsì sí, ẹ̀kọ́ wa bu ọ̀wọ̀ fún àwọn olùgbé Amẹ́ríkà, àti pé ìfẹ́ wa ni láti kọ wọn ní ìhìnrere Jésù Krístì. Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí òwò ẹrú, àwọn ìwé mímọ́ wa ti fi han kedere pé ko sí ẹnìkan tí ó yẹ kó wà nínú ìgbèkùn sí ara wọn.26

Nígbẹ̀hìn, a fi ìjà lé àwọn Ènìyàn Mímọ́ jáde ní Missouri27 a sì fi ipá mú wọn lọ sí Ìwọ̀-oòrùn.28 Àwọn Ènìyàn Mímọ́ là àti rí àláfíà tí ó nwá pẹ̀lú òdodò, ìrẹ́pọ̀, àti gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì.

Mo yọ̀ nínú Àdúrà Ìlàjà Olùgbàlà tí a kọsílẹ̀ nínú ìwé Jòhánnù. Olùgbàlà jẹ́wọ́ pé Baba ti rán Òun àti pé Òun, Olùgbàlà ti parí iṣẹ́ tí a rán An láti ṣe. Nígbànáà ó gbàdúra fùn àwọn ẹnití yíò gbàgbọ́ nínú Krístì: “Kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́bí ìwọ, Baba, ṣe wà nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí wọ́n lè jẹ́ ọkan nínú wa.”29 Ọkannáà ni ohun tí Krístì gbàdúrà fún ṣíwájú ìfihàn àti àjinde Rẹ̀.

Ní ọdún àkọ́kọ́ Ìmúpadàbọ̀sipò ìhìnrere Jésù Krístì, tí a kọsílẹ̀ ní ìpín 38 ti Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, Olùwa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ogun àti ìwà-ìkà ó sì kéde pé, “Mo wí fún yín, ẹ jẹ́ ọ̀kan; bí ẹ̀yin kò bá jẹ́ ọ̀kan ẹ̀yin kìí ṣe tèmi .”30

Ọ̀làjú Ìjọ wá látinú ìhìnrere Jésù Krístì. Ìwé Àpóstéli Páùlù sí àwọn ará Rómù jẹ́ ìjìnlẹ̀.31 Ìjọ àkọ́kọ́ ní Rómù wà ní Júù àti Kèfèrí nínú. Àwọn Júù ìṣíwájú wọ̀nyí ní àṣà Júdà wọn sì ti “jèrè ìtúsílẹ̀ wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí nbí si wọ́n sì gbilẹ̀.”32

Àwọn Kéfèrí ní Rome ní ọ̀lájú pẹ̀lú agbára Hellenístík pàtàkì kan, èyí tí Àpóstélì Páùlù ní òye dáradára nítorí àwọn ìrírí rẹ̀ ní Athens àti Kóríntì.

Páùlù gbé ìhìnrere Jésù kalẹ̀ nínú ọ̀ṣọ́ àsoyé. Ó ṣe àkọsílẹ̀ tí ó bá ìṣe Ọ̀làjú Judaic àti Kèfèrí méjèèjì mu33 ti ó tako ìhìnrere òtítọ́ ti Jésù Krístì. Ní pàtàkì Ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn fi àṣà ìdènà látinú àwọn ìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀làjú tí kò wà pẹ̀lú ìhìnrere Jésù Krístì. Páùlù kìlọ̀ fún àwọn júù àti Kèfèrí láti pa àwọn òfin mọ́ kí wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn àti pé òdodo ndarí sí ìgbàlà.34

Ọ̀làjú ìhìnrere Jésù Krístì kìí ṣe Ọ̀làjú Kèfèrí tàbí ọ̀làjú Judaic. A kò lè pinnu rẹ̀ nípa àwọ̀ ara ẹnìkan tàbí ibi tí ẹnìkan ngbé. Nígbàtí a bá yọ nínú àwọn ọ̀làjú tó tayọ, a gbọ́dọ̀ fi ìṣe àwọn ọ̀làjú tí ó ní àtakò pẹ̀lú ìhìnrere Jésù sílẹ̀ sẹ́hìn. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìjọ àti àwọn ìyípadà tuntun nígbàgbogbo wá láti àwọn ẹ̀yà aláwọ àti àṣà púpọ̀. A níláti tẹ̀lé ìkìlọ̀ Ààrẹ Nelson láti kó àwọn àfọ́nká Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú, a ó rí pé a yàtọ̀ bí ti Júù àti Kèfèrí wà ní àkokò Páùlù. Síbẹ̀síbẹ̀ a lè ní ìrẹ́pọ̀ nínú ìfẹ́ ti àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Lẹ́tà Páúlù sí àwọn ará Rómù gbé ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ kalẹ̀ tí à ntẹ̀lé bí àṣà àti ẹ̀kọ́ ìhìnrere Jésù Krístì. Ó jẹ́ àwòṣe fún wa àní ní òní.35 Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì mú wá ní ìrẹ́pọ̀ ní àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ó fi àyè gbà wá láti jẹ́ ọ̀kan nínú gbogbo ọ̀nà pàtàkì ti ayérayé.

A bu ọlá fún àwọn olùlànà ọmọ ìjọ káàkiri ayé kìí ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ pípé ṣùgbọ́n wọ́n borí ìṣòrò, wọ́n ṣe ìrúbọ, wọ́n gbèrò láti dàbí Krístì, wọ́n sì ntiraka láti gbé ìgbàgbọ́ ga àti láti jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Olùgbàlà. Jíjẹ́-ọ̀kan wọn pẹ̀lú Olùgbàlà mú wọn jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú ara wọn. Ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ yí jẹ́ òtítọ́ fún yín àti èmí ní òní.

Ìpè tó nípọn sí àwọn ọmọ Ìjọ ti Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni láti tiraka láti jẹ́ ènìyàn Síónì tí wọ́n jẹ́ ọkàn kan àti inú kan tí wọ́n sì gbé nínú òdodo.36

Àdúrà mi ni pé a ó jẹ́ olódodo àti ìrẹ́pọ̀ kí a dojúkọ sísìn àti jíjọ́sìn Olùgbàlà wa, Jésù Krístì nípa ẹni tí mo jẹri. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọnMájẹ̀mú 38:27.

  2. Iṣẹ́ ìsìn Thomas Kane ní ìtìlẹhìn àwọn ọmọ ìjọ ti hàn léraléra “ìṣe kan nípa ìrúbọ àìmọtaraẹni-nìkannípasẹ̀ ọ̀dọ́ tó mèrò ẹnití ó jẹri àwọn àìní-ìdálére lórí àwọn ẹlẹ́sìn díẹ̀ tí a nṣe inúnibíni sí nípasẹ̀ àwọn oníkanra àti búburú” (ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí Elizabeth Wood Kane, àwọn Ilé Mọ́mọ́nì Méjìlá ni a Bẹ̀wò ní ìrìnàjò kan nínú Utah lọ sí Arizona, ed. Everett L. Cooley [1974], viii).

  3. Wo Kane, Twelve Mormon Homes, 5.

  4. Wo Kane, Twelve Mormon Homes, 40.

  5. Wo Lowell C. (Ben) Bennion and Thomas R. Carter, “Touring Polygamous Utah with Elizabeth W. Kane, Winter 1872–1873,” BYU Studies, vol. 48, no. 4 (2009), 162.

  6. Ó dàbi ẹni pé, Elizabeth gbà pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ìlú Amẹ́ríkà ní àkókò ìgbànì yóò tí fún àwọn ará India ní àwọn àjekù àti tọ́jú wọ́n yàtọ̀ sí àwọn àlejò wọn miiràn.

  7. Wo Kane, Àwọn Ilé Mọ́mọ́nì Méjìlá, 64–65. Ó jẹ́ noteworthy that many Native Americans, including several chiefs, became members of the Church. Bákannáà John Alton Peterson, Utah’s Black Hawk War (1998) 61; Scott R. Christensen, Sagwitch: Shoshone Chieftain, Mormon Elder, 1822–1887 (1999), 190–95.

  8. Ní àkokò iṣẹ́ ìríjú yí “yío sì ṣe tí a ó kó àwọn olódodo jọ papọ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè, wọn ó sì wá sí Síonì, ní kíkọrin pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:71).

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 105:3–5. Àwọn ìwé-mímọ́ ti singled out caring for the poor and needy as being a necessary element of righteousness.

  10. Wo Alma 36:30; bákannáà wo 1 Nephi 2:20; Mosiah 1:7. Ìparí ara Alma 36:30 kà pé, “Níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ a ó ge yí kúrò níwájú rẹ̀. Nísisìyí this is according to his word.”

  11. Mòsíàh 2:41. Ààrẹ Lorenzo Snow (1814–1901) kọ́ni pé: “Kò sí Ènìyàn Miḿọ Ọjọ́-ìkẹhìn kankan tí ó kú lẹ́hìn gbígbé ìgbé ayé òtítọ́ tí yíò sọ ohun kankan nù nítorí kíkùnà láti ṣe àwọn ohun kan pàtò nígbàtí àwọn ànfàní kò wá fún ọkùnrin tàbí obìnrin náà. Ní ọ̀rọ̀ míràn, bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tàbí ọ̀dọ́mọbìnrin kò bá ní ànfaní ti ṣiṣe ìgbeyàwó, tí wọ́n si gbé ìgbé ayé òdodo dé àkokò ikú wọn, wọn yíò ní gbogbo ìbùkún, ìgbéga àti ògò tí eyikeyi ọkùnrin tàbí obìnrin yíò ní ẹni tí ó ní ànfàní yí tí ó sì tun ṣe. Ìyẹn dájú ó sì jẹ́ rere” (Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ: Lorenzo Snow [2012], 130). Bákannáà wo Richard G. Scott, “Ayọ̀ Gbígbé Ètò Ìdùnnú Nlá,” Ensign, Nov. 1996, 75.

  12. Wo 1 Jòhánù 5:2.

  13. Mosiah 18:21; bákannáà wo Mose 7:18.

  14. 4 Néfì 1:16.

  15. 2 Néfì 1:15.

  16. 2 Néfì 1:24.

  17. Moroni 9:13–14.

  18. Russell M. Nelson, in “First Presidency and NAACP Leaders Call for Greater Civility, Racial HarmonyMay 17, 2018, newsroom.ChurchofJesusChrist.org; see also “President Nelson Remarks at Worldwide Priesthood CelebrationJune 1, 2018, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  19. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 90:11 ka, “Every man shall hear the fulness of the gospel … and in his own language.” Accordingly, language congregations are usually approved.

  20. 2 Néfì 26:33.

  21. Wo Ìwé-òfin ti United States

  22. Wo United States Declaration of Independence, 1776; Constitution of the United States, Amendments I–X (Bill of Rights).

  23. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:77; àfikún àtẹnumọ́.

  24. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:79-80.

  25. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101, àkọlé ìpín.

  26. Wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́-ìkẹhìn, vol. 1, The Standard of Truth, 1815–1846 (2018), 172–74; James B. Allen and Glen M. Leonard, The Story of the Latter-day Saints, 2nd ed. (1992), 93–94; Ronald W. Walker, “Seeking the ‘Remnant’: The Native American during the Joseph Smith Period,” Journal of Mormon History, vol.19, no. 1 (spring 1993): 14–16.

  27. Wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́, 1:359–83; William G. Hartley, “The Saints’ Forced Exodus from Missouri, 1839,” in Richard Neitzel Holzapfel and Kent P. Jackson, eds., Joseph Smith, the Prophet and Seer (2010), 347–89; Alexander L. Baugh, “The Mormons Must Be Treated as Enemies,” in Susan Easton Black and Andrew C. Skinner, eds., Joseph: Exploring the Life and Ministry of the Prophet (2005), 284–95.

  28. Wo Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́-ìkẹhìn, vol. 2, No Unhallowed Hand, 1846–1893 (2020), 3–68; Richard E. Bennett, We’ll Find the Place: The Mormon Exodus, 1846–1848 (1997); William W. Slaughter and Michael Landon, Trail of Hope: The Story of the Mormon Trail (1997).

  29. Jòhánnù17:21.

  30. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:27.

  31. Lẹ́tà sí àwọn Ará Rómù jẹ́ yíyéni ní kíkéde ẹ̀kọ́. Àwọn Ará Rómù ní dídárúkọ Ètutù ní inú Májẹ̀mú Titun lẹ́ẹ̀kan. Mo fi ìmoore hàn fún èpístélì sí àwọn ará Rómù fún mímú ìrẹ́pọ̀ wá sí àárín olúkúlùkù èníyàn nípasẹ̀ ìhìnrere Jésù Kris´tì nígbàtí mò nsìn bí ààrẹ èèkan pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ oríṣiríṣi ẹ̀yà àti àṣà tí wọ́n nsọ onírurú àwọn èdè.

  32. F. W. Farrar, The Life and Work of St. Paul (1898), 67.

  33. Wo Farrar, The Life and Work of St. Paul, 450.

  34. Wo Romans 13.

  35. Wo Dallin H. Oaks, “Àṣà Ìhìnrere,” Liahona, Mar. 2012, 22–25; bákannáà wo Richard G. Scott, “Removing Barriers to Happiness,” Ensign, May 1998, 85–87.

  36. Wo Mósè 7:18.