Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Bèèrè, Wá Kiri, sì Kànkù
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Bèèrè, Wá Kiri, sì Kànkù

Apákan pàtàkì ètò ti Bàbá Ọ̀run ni ànfàní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nígbàkugbà tí a bá fẹ́.

Ní oṣù mẹ́rin sẹ́hìn, nínú àṣàrò mi ní ti àwọn ìwé mímọ́, mo nkà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Almà ní Ammoníhàh nígbàtí mo rí àbá yi nínú Wá, Tẹ̀lé Mi: “Bí o ti kà nípa àwọn ìbùkún nlá tí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Néfì (wo Álmà 9:19-23), ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìbùkún nlá tí Ó ti fi fún ọ.”1 Mo pinnu lati to àwọn ìbùkún Ọlọ́run sími ní ẹsẹẹsẹ mo sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ẹ̀dà dígítà ti ìwé ìkọ́ni náà. Ní ààrin àwọn ìṣẹ́jú díẹ̀, mo ti to àwọn ìbùkún mẹ́rìndínlógún.

Èyítí ó léwájú jùlọ ní ààrin wọn ni àwọn ìbùkún nlá ti àánú àti ẹbọ ètùtù ti Olùgbàlà ní ìṣojú fún mi. Bákannáà mo kọ nípa ìbùkún tí mo ní láti ṣojú fún Olùgbàlà bíi ọ̀dọ́ oníṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Portugal àti, lẹ́hìnwá, pẹ̀lú olùfẹ́ni èkejì ayérayé mi, Patricia, ní Mísọ̀n Gúsù Brazil Porto Alegre, níbití a ti sìn pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ alágbára àti oníyanu 522. Ní sísọ̀rọ̀ nípa Patricia, púpọ̀ àwọn ìbùkún tí mo ṣe àkọsílẹ̀ wọn ní ọjọ́ náà jẹ́ àwọn ìbùkún tí a ti jọ gbádùn papọ̀ jákèjádò àwọn ogójì ọdún ti ìgbéyàwó wa—nínú èyítí fífi èdìdi dì wa ní Tẹ́mpìlì São Paulo Brazil wà, àwọn ọmọ wa mẹ́ta oníyanu, àwọn ẹnìkejì wọn, àti àwọn ọmọ-ọmọ wa mẹ́tàlá.

Ìrònú mi tún yí bákannáà sí àwọn olódodo òbí me, tí wọ́n tọ́ mi nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìhìnrere. A rán mi létí ní pàtàkì ti àkókò kan nígbàtí olùfẹ́ni ìyá mi kúnlẹ̀ pẹ̀lú mi láti gbàdúrà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi nígbàti mo wà ní bíi ọdún mẹwa ọjọ́ orí. Ó nílati ti ní ìmọ̀lára pé bí àwọn àdúrà mi yío bá dé ọ̀dọ̀ Baba mi ní Ọ̀run, wọ́n nílò láti gbèrú síi. Nítorínáà ó wí pé, “èmi yío kọ́kọ́ gbàdúrà, àti pé lẹ́hìn àdúrà mi, ìwọ yío gbàdúrà.” Ó tẹ̀síwájú nínú àwòṣe yí fún àwọn alẹ́ púpọ̀, títí tí ó fi ní ìdánilójú pé mo ti kọ́ nípa ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ àti nípa síṣe, bí a ti í sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run. Èmi ó fi ìmore hàn sí i títí láé fún kíkọ́ mi láti gbàdúrà, níotorí mó kọ́ pé Baba mi Ọrun ngbọ́ àdúra mi Ó sì ndáhùn wọn.

Ní tòótọ́, èyíinì ni ìbùkún miràn tí mo fi sí inú títò lẹ́sẹẹsẹ mi—ẹ̀bùn láti le gbọ́ kí a sì kọ́ nípa ìfẹ́ inú Olúwa. Apákan pàtàkì ètò ti Bàbá Ọ̀run ni ànfàní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nígbàkugbà tí a bá fẹ́.

Ìpè kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa

Nígbàtí Olùgbàlà bẹ àwọn Amẹ́ríkà wò lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀, Ó ṣe àtúnwí ìpè kan tí Ó ti fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ ní Gálílì. Ó wí pé:

“Ẹ bẽrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.

“Nítorí olukúlùkù ẹni tí ó bá bẽrè, nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri, nrí; àti ẹnití ó bá kànkù, a ò ṣí i sílẹ̀ fún“ (3 Néfì 14:7–8; bákannáà wo Matteu 7:7–8).

Woòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti fi irú ìfipè kan tí ó jọ bẹ́ẹ̀ fúnni ní ìgbà tiwa. Ó sọ pé: “Gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì nípa àwọn àníyàn rẹ, àwọn ẹ̀rù rẹ, àwọn àilera rẹ—bẹ́ẹ̀ni, àwọn ìfẹ́ inú ti ọkàn rẹ gan. Àti nígbànáà tẹ́tísílẹ̀! Kọ àwọn èrò tí ó bá wá sí ọkàn rẹ sílẹ̀. Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀lára rẹ kí o sì tẹ̀lée pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tí o bá ní ìmísí láti gbé. Bí o ti nṣe àṣetúnṣe àwọn nkan yi ní ọjọ́ dé ọjọ́, oṣù dé oṣù, ọdún lẹ́hìn ọdún, ìwọ ó ‘dàgbà sínú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìfihàn.’”2

Ààrẹ Nelson fi kún pé, “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, kò ní ṣeéṣe láti yè níti ẹ̀mí láìsí títọ́nisọ́nà, dídarí, titùnínú, àti ní léraléra ti agbára Ẹ̀mí Mímọ́.”3

Kíni ìdí tí ìfihàn fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ sí ìyè wa ní ti ẹ̀mí? Nítorípé ayé le ní ìdàrúdàpọ̀ àti ariwo, kí ó kún fún ẹ̀tàn àti àwọn ìdààmú. Ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba wa ní Ọrun nmú kí ó ṣeéṣe fúnwa láti ṣà àwọn ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ohun tí ó jẹ́ irọ́, ohun tí ó wúlò sí ètò ti Olúwa fún wa àti ohun tí kò rí bẹ́ẹ̀. Bákannáà ayé lè le kí ó sì jẹ́ bíbanilọ́kànjẹ́. Ṣùgbọ́n bí a ti ṣí ọkàn wa payá nínú àdúrà, a ó ni ìmọ̀lára ìtùnú tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Baba wa ní Ọrun àti ìdánilójú pé Ó fẹ́ràn Ó sì mọ iyì wa.

Bèèrè

Olúwa wí pé “olukúlùkù ẹni tí ó bá bèèrè, nrí gbà.” Bíbèèrè dàbí pé ó rọrùn, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ó ní agbára nítorípé ó nṣe àfihàn àwọn ìfẹ́ inú àti ìgbàgbọ́ wa. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ó ngba àkókò àti sùúrù láti kọ́ láti ní òye ohùn Olúwa. A nfi iyè sí àwọn ìrònú àti àwọn ìmọ̀lára tí wọ́n bá wá sí ọkàn àti inú wa, a sì nkọ wọ́n sílẹ̀ bí wòlíì wa ti gbà wá nímọ̀ràn láti ṣe. “Síṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀lára wa jẹ́ apákan pàtàkì ti rírí gbà. Ó nrànwalọ́wọ́ láti rántí, ṣe àgbéyẹ̀wò, àti láti tún ní ìmọ̀lára ohun tí Olúwa nkọ́ wa.

Ní àìpẹ́ yí àyànfẹ́ kan sọ fún mi pé, “Mo gbagbọ́ pé ìfihàn ti ara ẹni jẹ́ òtítọ́. Mo gbàgbọ́ pé Ẹmí Mímọ́ yío fi gbogbo ohun tí mo nílati ṣe hàn mí.4 Ó rọrùn láti gbàgbọ́ nígbàtí mo bá ní ìmọ̀lára pé oókan àyà mi gbóná pẹ̀lú ìdánilójú tí kò ní iyèméjì.5 Ṣùgbọ́n báwo ni Ẹmí Mímọ́ ṣe le máa bámi sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo bí èyí?”

Sí àyànfẹ́ mi ati sí gbogbo yín, mo wí pé èmi náà yío fẹ́ láti ní àwọn ìmọ̀lára líle wọnnì léraléra láti ọ̀dọ̀ Ẹmí kí nsì máa fi ìgbà gbogbo rí ipa ọ̀nà ní kedere láti tẹ̀lé. Ṣùgbọ́n èmi kò ri. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ohun tí a le ní ìmọ̀lára rẹ̀ lemọ́lemọ́ ni ohùn jẹ́jẹ́, kékeré ti Olúwa tí ó nsọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí inú àti ọkàn wa: “Mo wà níhĩn. Mo nifẹ rẹ. Tẹ̀síwájú; ṣa gbogbo ipá rẹ. Èmi ó tì ọ́ lẹ́hìn.” Kìí ṣe gbogbo ìgbà ni a nílò láti mọ ohun gbogbo tàbí rí ohun gbogbo.

Ohùn jẹ́jẹ́, kékeré náà tún nfi ìdi rẹ̀ múlẹ̀, ó ngbani níyànjú, ó sì ntuni nínú—àti pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà èyíinì nìkan ni ohun tí a nílò fún ọjọ́ náà. Ẹmí Mímọ́ dájú, àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ sì dájú—àwọn tí ó tóbi àti àwọn tí ó kéré.

Wá kiri

Olúwa tẹ̀síwájú láti ṣe ìlérí pé, “Ẹni tí ó bá wá kiri, nrí.” Wíwá kiri túmọ̀ sí aápọn ní ti ọpọlọ àti ni ti ẹ̀mí—ní ríronú, dídánwò, gbigbìyànjú, àti kíkọ́ ẹ̀kọ́. A nwákiri nítorípé a gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí Olúwa. “Nítorí ẹnití ó bá wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run níláti gbàgbọ́ pé ó wà, àti pé ó jẹ́ ẹlẹ́san àwọn tí wọ́n wá a pẹ̀lú aápọn” (Hebérù 11:6). Nígbàtí a bá wá kiri, a nfi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ pé a ṣì ní àwọn ohun púpọ̀ láti kọ́, Olúwa yíò sì mú òye wa gbòòrò, ní gbígbaradì fún wa láti gbà síi. Nítorí kíyèsĩ i, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yíò fi fún àwọn ọmọ ènìyàn ní ẹsẹ lé ẹsẹ, ilànà lé ìlànà, díẹ̀ níhin àti díẹ̀ lọ́hún; … nítorí ẹni náà tí ó gbà ni èmi yío fún síi” (2 Néfì 28:30).

Kànkù

Ní ìparí Olúwa wí pé, “Ẹnití ó bá sì kànkùn, ni a ò ṣí i sílẹ̀ fún.” Láti kànkùn jẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Nígbàtí a bá tẹ̀lé E pẹ̀lú akitiyan, Olúwa nṣí ọ̀nà níwájú wa. Orin aládùn kan wà tí ó kọ́ wa láti “tají kí a sì ṣe ohun tí o ju líla àlá ìle [wa] lókè lọ. Síṣe rere ndùn mọ́ni, ayọ̀ kan tí ó kọjá òdiwọ̀n, ìbùkún ti ojúṣe àti ìfẹ́.”6 Alàgbà Gerrit W. Gong ti Iyejú àwọn Méjìlá ṣe àlàyé láìpẹ́ yi pé ìfihàn máa nwá ní ọ̀pọ̀ ìgbà nígbàtí a bá wà nínú ìgbésẹ̀ síṣe rere. Ó wí pé: “Bí a ti ngbìyànjú láti nawọ́ jáde nínú iṣẹ́ ìsìn sí àwọn wọnnì ní àyíká wa, mo rò pé Olúwa nfún wa ní àlékún ìwọ̀n ìfẹ́ Rẹ̀ fún wọn àti fún àwa náà. Mo rò pé a ngbọ́ ohùn Rẹ̀—a nní ìmọ̀lára Rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀—bí a ti ngbàdúrà láti ran àwọn wọnnì ní àyíká wa lọ́wọ́ nítorípé èyíinì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àdúrà tí Ó fẹ́ jùlọ láti dáhùn.”7

Àpẹrẹ ti Álmà

Àbá rírọrùn náà nínú Wá, Tẹ̀lé Mi láti ronú nípa àwọn ìbùkún mi mú ẹ̀mí dídùn kan wá àti àwọn òye àìròtẹ́lẹ̀ ti ẹ̀mí. Bí mo ti tẹ̀síwájú ní kkà nípa Almà àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní Ammoníhà, mo ṣe ìwárí pé Alma pèsè àpẹrẹ rere kan nípa ohun tí ó túmọ̀sí láti bèèrè, wá kiri, àti kànkùn. A kà pé “Álmà ṣe làálàá púpọ̀ nínú ẹ̀mí, ní jíja ìjàkadì pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ àdúrà, pé kí ó le tú Ẹ̀mí rẹ̀ jáde sí orí àwọn ènìyàn náà.” Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, àdúrà náà, kò jẹ́ dídáhùn ní ọ̀nà tí ó retí, Almà sì di líle jáde ní ilú náà. “Ní ìsoríkodò pẹ̀lú ìbànújẹ́,” Almà ti fẹ́ jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀, nígbàtí angẹ́lì kan mú ọ̀rọ̀ yí wá: “Ibùkún ni fún ọ, Almà; nítorínáà, gbé orí rẹ sókè kí o sì yọ̀, nítorí ìwọ ní ìdí púpọ̀ láti yọ̀.” Nígbànáà ni angẹ́lì náà sọ fún un láti padà sí Ammonihàh kí ó sì gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi, Almà sì padà kánkán.”8

Kíni a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Almà nípa bíbèèrè, wíwá kiri, àti kíkànkùn? A kọ́ pé àdúrà nílò làálàá ti ẹ̀mí, àti pé kìí fi ìgbàgbogbo darí sí àbájáde tí a ní ìrètí fún. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí tí a soríkodò pẹ̀lú ìbànújẹ́, Olúwa nfún wa ní ìtùnú àti okun ní àwọn ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Ó le má dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè wa tàbí yanjú gbogbo àwọn wàhálà wa ní ojú ẹsẹ̀; dípò bẹ́ẹ̀, Ó ngbà wá níyànjú láti tẹ̀síwájú ní títiraka. Nígbànáà bí a bá fi pẹ̀lú ìyara fi èrò tiwa kò pẹ̀lú èrò Rẹ̀. Òun yío ṣí ọ̀nà fún wa, bí Ó ti ṣe fún Almà.

Ó jẹ́ ẹ̀rí mi pé èyí ni àkókò iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere. A le gbádùn àwọn ìbùkún ti Ètùtù ti Jésù Krístì nínú ayé wa. A ní àwọn ìwé mímọ́ káàkiri ní àrọ́wọ́tó sí wa. A njẹ́ dídarí nípasẹ̀ àwọn wòlíì tí wọ́n nkọ́wa ní ifẹ́ ti Olúwa fún àwọn àkókò líle tí a ngbé nínú rẹ̀. Ní àfikún, a ní ìwọlé tààrà sí ìfihàn tiwa kí Olúwa ó le tùwá nínú àti tọ́wa sọ́nà fúnra wa. Bí angẹ́lì náà ti sọ fún Almà, àwa ní “ìdí pùpọ̀ láti yọ̀.” (Álmà 8:15). Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún àwọn Ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn Ẹbí: Iwé ti Mọ́mọ́nì 2020 (2019), 91.

  2. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa,” Liahona, May 2018, 95; àyọsọ Àwọn Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith (2007), 132.

  3. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa,” 96.

  4. Wo 2 Néfì 32:5

  5. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 9:8

  6. “Njẹ Mo ti Se Rere Kankan?” Àwọn orin, no. 223

  7. Bí Mo Ti #Gbọ́Tirẹ̀: Alàgbà Gerrit W. Gong” (video), ChurchofJesusChrist.org/media.

  8. Wo Álmà 8:10–18