Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣe Òdodo, Nífẹ Àánú, kí o sì Rìn ní Ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Ṣe Ní Òdodo, Nífẹ Àánú, kí o sì Rì ní Ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run

Láti ṣe dárdára túmọ̀ sí ṣíṣe ìṣe ọlálá. A nṣe ìṣe ọlọ́là pẹ̀lú Ọlọ́run nípa rírìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. À nṣe ìṣe ọlọ́lá pẹ̀lú àwọn míràn nípa ìfẹ́ni àánú.

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọlẹ́hìn ti Jésù Krístì, àti gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a tirakà—a sì gbà wá níyànjú láti tiraka—láti ṣe dáradára jùlọ àti làti dára jùlọ.1 Bóyá o ti yà yín lẹ́nu bí mo ti ṣe, “Ṣé mo nṣe tó?” “Kíni ohun míràn tí ó yẹ kí nmáa ṣe?” tàbí “Báwo ni èmi, gẹ́gẹ́bí ènìyàn tí ó ni àbàwọ́n, ó ti yege láti ‘gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ayọ́ tí kò ní òpin’?”2

Wòlíì Micah ti Májẹ̀mú Láéláé béèrè ìbéèrè ní ọ̀nà yi: “Nípa èwo ni èmi ó fi wá síwájú Olúwa, tí èmi ó tẹríba níwájú Ọlọ́run gíga?”3 Míkà aláròfọ̀ rònú bóyá àwọn ọrẹ tí ó tóbi paapaa lè tó láti san ẹ̀san fún ẹ̀ṣẹ̀, ní sísọ pé: “Inú Olúwa yóò ha dùn sí ẹgbẹgbẹ̀rún àgbò, tàbí pẹ̀lú [ẹgbẹ̀rún] mẹwa … odò òróró? èmi ó hà fi àkọ́bí mi fún … ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?”4

Ìdáhùn náà ni rárá. Àwọn ìṣe rere kò tó. Ìgbàlà kò ṣe gbà.5 Àní kìí ṣe àwọn ìrúbọ títóbi tí a daba láti ẹnu Míkà ni ó lè ra ẹ̀ṣẹ̀ tó kéréjùlọ padà. Tí ó bá jẹ́ ti ẹ̀rọ arawa, àfojúsọ́nà ti pípadà láti gbé ní iwájú Ọlọ́run kò ní ìrètí.6

Láìsí àwọn ìbùkún tí ó nwá látọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, a kò lè ṣe tó tàbí nìkan tó nípasẹ̀ arawa. Bíótilẹ̀jẹ́pé, ìròhìn rere náà, ni pé nítorí ti áti nípasẹ̀ Jésù Krístì a lè di tító.7 Gbogbo ènìyàn ní a ó gbàlà lọ́wọ́ ikú ara nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ ikú àti Àjinde Jésù Krístì.8 Àti pé tí a bá yí ọkàn wa padà sí Ọlọ́run, ìgbàlà látinú ikú ti-ẹ̀mí wà fún gbogbo ènìyàn “nípasẹ̀ Ètùtù [Jésù] Krístì … nípa ìgbọràn sí àwọn àṣẹ àti ìlànà Ìhìnrere.”9 A lè ní ìràpadà kùrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ láti dúró ní mímọ́ àti àìléèrí níwajú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́bí Míkà ti ṣàlàyé pé, “[Ọlọ́run] ti fi hàn ọ́, Ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára; àti ohun tí Olúwa bèèrè lọ́wọ́ rẹ, bíkòṣe kí ó ṣe òtítọ́, kí ó sì fẹ́ àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Rẹ̀?”10

Ìdarí Míkà lórí yíyí ọkàn wa padà sí Ọlọ̀run àti yíyege fún ìgbàlà wà pẹ̀lú ìsopọ̀ àwọn èròjà mẹ́ta. Láti ṣe olódodo túmọ̀ sí ṣíṣe ìṣe ọlọ́lá pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn míràn. A nṣe ìṣe ọlọ́là pẹ̀lú Ọlọ́run nípa rírìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. À nṣe ìṣe ọlọ́lá pẹ̀lú àwọn míràn nípa ìfẹ́ni àánú. Nítorínáà láti ṣe òdodo ni ṣíṣe ìlò ti-ara àwọn òfin àkọ́kọ́ àti ìkejì, láti “fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ … [àti láti] fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

Láti ṣe dáadáa àti láti rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni láti mọ̀ọ́mọ̀ yọ ọwọ́ wa nínú àìṣedédé, rìn nínú àwọn ìlànà Rẹ̀, àti ṣíṣe ní òtítọ́.12 Ènìyàn dídára nyípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀, ó sì npa àwọn májẹ̀mú wọ̀nnì mọ́. Ènìyàn dídára kan yàn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ó ronúpìwàdà nígbàti ó bá kùnà, ó sì ntẹ̀síwájú nínú ìgbìyànjú.

Nígbàtí Krístì tó jíndé bẹ àwọn ará Néfì wò, Ó ṣàlàyé pé a ti rọ́pò òfin Mósè pẹ̀lú òfin gíga. Ó pàṣẹ fún wọn láti “má ṣe rúbọ … àti …ọrẹ sísun” mọ́ bíkòṣe láti rú ọkàn tí ó ní “ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.” Ó tún ṣèlérí, “Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrònùpíwàdà, òun ni èmi ó baptísì pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.”13 Nígbàtí a gbà láti lo ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́hìn ìrìbọmi, a lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ nígbàgbogbo ti Ẹ̀mí Mímọ́ kí a kọ́ wa ni àwọn ohun gbogbo tí ó yẹ kí a ṣe, pẹ̀lú bí a ṣe lè rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ẹbọ Jésù Krístì fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà kúrò nínú ikú ti ẹ̀mí wà fún gbogbo ẹni tí ó ní ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrònùpíwàdà.15 Ọkàn tí ó bàjẹ́ àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ yíò ṣí wa létí láti ronúpìwàdà tayọ̀tayọ̀ àti láti gbìyànjú láti dàbí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì síi. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, a o gba ìwẹ̀nùmọ́ Olùgbàlà, ìwòsàn, àti agbára ìfúnnilókun. Kìí ṣe kí ṣe dáradára nìkan kí a sì rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run; a tún kọ́ ẹ̀kọ́ láti nífẹ àánú ní ọ̀nà tí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ti ṣe.

Ọlọ́run dunnú sí àánú kò sì bínú sí ìlò rẹ̀. Míkà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Jèhófà, “Tani Ọlọ́run bí ìwọ, tí ó ndárí àìṣedéédé jì, … yíò sàánú fún wa,” àti “yíò sì sọ gbogbo … ẹ̀ṣẹ̀ sínú ibú òkun.” Láti nífẹ àánú gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti ṣe ní àsopọ̀ àìle-yàsọ́tọ̀ ní ṣíṣe òdodo pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti àìṣèbàjẹ́ sí wọn.

Pàtàki àìṣèbàjẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn ni a fihàn nínú àkọsílẹ̀ nípa Alàgbà Hillel náà, ọ̀mọ̀wé Jew kan ẹnití ó gbé ní sẹ́ntúrì àkọ́kọ́ ṣáájú Krístì. Ọ̀kan lára àwọn akẹkọ Hillel ni ó bínú nípasẹ̀ ìdijú ti Torah—àwọn ìwé marun ti Mósè pẹlù àwọn òfin ẹgbẹ̀ta-ó-lé-mẹ́tàlá wọn àti pẹ̀lú awọn àwọn ìwé rábbì tí ójọmọ, Akẹkọ náà pe Hillel níjà láti ṣàlàyé Torah ní lílo àkokò tí Hillel nìkan lè dúró lórí ẹsẹ̀ kanṣoṣo . Hillel le má tilẹ̀ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nlá ṣùgbọ́n ó gba ìpènijà náà. O ṣe àyọsọ látinú Léfítíkù, wípé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san, bẹ́ẹ̀ni kí o máṣe ṣe ìkùnsínú sí àwọn ọmọ ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Lẹ́hìnnáà Hillel parí pé: “Èyí tí ó jẹ́ ìkóríra sí ọ, máṣe ṣe sí ẹnìkeji rẹ. Èyí ni gbogbo Torah; ìyókù jẹ́ àsọyé. Lọ kí ó sì ṣe àṣàrò.”

Híhùwà ọlọlá pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nígbàgbogbo ni ara ìfẹni àánú. Ro ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kan tí mo gbọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn ní ẹ̀ka pàjáwìrì Ile-ìwòsàn John Hopkins ní Baltimore, ní Ìlú Amẹ́ríkà. Aláìsàn kan, Arákùnrin Jackson, jẹ́ ọkùnrin onínúre, ọlọ́yàyà ẹnití àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn mọ̀ dáradára. Ó ti wà ní ilé-ìwòsàn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà fún ìtọ́jú àwọn àìsàn ìbámú-ọtí. Ní àyájọ́ yí, Arákùnrin Jackson padà sí ilé-ìwòsàn fún àwọn àrun tí ayẹ̀wò bíi ìgbinnikún ọtí-inú ti fà sí òrónro rẹ̀.

Ní òpin iṣẹ́ rẹ̀, Dókíta Cohen, aláápọn òṣìṣẹ́ àti olùwòsàn tí a fẹ́ràn, wo Arákùnrin Jackson ó sì pinnu pé wíwà ní ilè-ìwòsàn rẹ̀ ní àtìlẹ́hìn. Dókítà Cohen yan Dókítà Jones, olùwòsàn tó tẹ̀le ní àyípo, láti gba Arákùnrin Jackson wọlé kí ó sì bojútó ìtọ́jú rẹ̀.

Dókítà Jones lọ sí ilé-ìwé egbòogi oníyì kan o sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìgboyè rẹ̀. Idanilẹkọ líle yí wà pẹ̀lú àìsùn nígbàkugbà, èyí tí ó lè dàbí ó fa èsì búburú Dókítà Jones. Ní ìdojúkọ pẹ̀lú gbígbà ẹkarun ìdúró ní alẹ́, Dókítà Jones ráhùn sí Dókítà Cohen pẹ̀lú ariwo. Ó rò pé kò dára pé kí òun máa lo àwọn wákàtí fún ìtọ́jú Arákùnrin Jackson, nítorí lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, àrùn rẹ jẹ́, àfọwọ́fà ararẹ̀.

Dókítà Cohen fẹ́rẹ̀ sọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nínú àtẹnumọ́ ìfèsì rẹ̀. Ó wípé, “Dókítà Jones, o di olùwòsàn láti tọ́jú àwọn ènìyàn kí o sì ṣiṣẹ́ láti wò wọ́n sàn. Ìwọ kò di olùwòsàn láti ṣèdájọ́ wọn. Tí o kò bá mọ ìyàtọ̀, ìwọ kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe idanilẹkọ ní ilé-iṣẹ́ yí.” Titẹ̀lé ìbáwí yí, Dókítà Jones fi taratara tọ́jú Arákùnrin Jackson ní igbà to wà nílé ìwòsàn.

Arákùnrin Jackson ti kú láti ìgbà náà. Dókítà Jones àti Cohen ti ni àwọn ìṣẹ́ alárinrin. Ṣùgbọ́n ní àkokò líle níbi idanilẹkọ rẹ, a nílò láti rán Dókítà Jones létí láti ṣe olótítọ́, láti nífẹ àánú, àti láti ṣe ìtọ́jú fún Arákùnrin Jackson láì jẹ́ onídájọ́.19

Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, mo ti jèrè látinú ìránnilétí náà. Ìfẹ́ni àánú túmọ̀sí pé a kò fẹ́ àánú tí Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ síwá lásán; a ní inúdídùn pé Ọlọ́run nawọ́ irú àánú kannáà sí àwọn ẹlòmíràn. A sì ntẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀. “Gbogbo ènìyàn rí bákannáà sí Ọlọ́run,”20 gbogbo wa sì nílò ìtọ́jú ti ẹ̀mí láti gba ìrànlọ́wọ́ àti láti wòsàn. Olúwa ti wípé, “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹlòmiràn, tàbí ẹnìkan kò gbọ́dọ̀ rò pé òun ga ju ẹlòmíràn lọ.”21

Jésù Krístì fi àpẹrẹ ohun tí ó túmọ̀ sí láti ṣe olódodo àti láti nífẹ́ àánú. Ó bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe papọ̀, o hùwá ọlọ́lá sí wọn àti pẹ̀lú ọ̀wọ̀. Ó kọ́ni ní ayọ̀ ti pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ áti wíwá láti gbéga sànju láti dá àwọn tí ó ntiraka lẹ́bi. Ó pa àwọn ẹnití wọ́n nṣe ìdanilẹ́bi sí I tì fún ṣiṣe iṣẹ̀ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ro pé kò yẹ.22 Irú òdodo-araẹni nṣẹ̀ Ẹ́ ó ṣì nṣẹ̀ Ẹ́ síbẹ̀.23

Láti dàbíi Krístì, ẹnìkan nṣe dáradára, ó nhùwà ọlọ́lá pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn míràn. Ènìyàn òdodo kan dára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ó sì dá àwọn ìyàtọ̀ mọ̀ ní ìwò tàbí ìgbàgbọ́ tí kò yọ inúrere àti ìbáṣọ̀rẹ́ tòótọ́ kúro. Àwọn olúkúlùkù ẹni tí ó bá nṣe dáradára “kò ní ní ọkàn láti pa ara wọn lára, ṣùgbọ́n láti gbé ní àláfíà” sí ara wọn.

Láti dàbí Krístì, ẹnìkan á fẹ́ràn àánú. Àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ràn àánú kìí ṣe ìdájọ́; wọ́n nfi ìyọ́nú hàn fún àwọn ẹlòmíràn, nípàtàkì fún àwọn tí wọ́n dínkù ni òríre; wọ́n jẹ́ aláàánú, onínúrere, àti ọlọ́lá. Àwọn ẹnìkộkan wọ̀nyí nhùwà sí gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìfẹ́ àti òye, láìka àwọn àbùdá gẹ́gẹ́bí ìran, akọ tàbí abo, ìsopọ̀ ẹ̀sìn, ìṣàlàyé ìbálò, ipò àwùjọ, àti ẹ̀yà, ìdílé, tàbí àwọn ìyàtọ̀ orílẹ̀-èdè sí. Ìfẹ́ Krístì ni ó borí ìwọ̀nyí.

Láti dàbíi Krístì, ẹnìkan yan Ọlọ́run,25 ó sì nrìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, ó nwá láti dùn Ún nínú, àti láti pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́. Àwọn ẹnìkộkan ẹnití nrìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rántí ohun tí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ti ṣe Fún wọn.

Ṣe mo nṣe tó? Kíni ohun míràn tí ó yẹ ki nmáa ṣe? Ìṣe tí a bá ṣe ní ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè wọ̀nyí ni àringbùngbun sí ìdùnnú nínú ayé yí àti ní àwọn ayérayé. Olùgbàlà kò fẹ́ kí a mú ìgbàlà wa yẹpẹrẹ. Àní lẹ́hìn tí a ti dá májẹ̀mú mímọ́, ó ṣeéṣe kí a lè “ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́ kí a sì yapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” Nítorínáà, ó yẹ kí a “gbọ́ kí a sì gbàdúrà nígbàgbogbo” láti yẹra fún ṣíṣubú “sínú àdánwò.”26

Ṣùgbọ́n ní àkokò kannáà, Baba wa Ọ̀run àti Jésù Krístì kò fẹ́ kí a dààmú nípa ainidaniloju pípẹ́ nínú ìrìnàjò wa ní ayé ikú, ní ríronú bóyá a ti ṣe to láti ní ìgbàlà àti ìgbéga. Dájúdájú wọ́n kò fẹ́ kí a dá wá lágara nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe látinú èyí tí a ti ronùpìwàdà, ní ìrónú nípa wọn bí ọgbẹ́ tí kò jinná láéláé,27 tàbí ní ìfura púpọ̀ jùlọ pé a lè ṣubú lẹ́ẹ̀kansi.

A lè yẹ ìlọsíwájú ara wa wò. A lè mọ̀ pé “ọ̀nà ìgbé ayé [tí à] nlépa jẹ́ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run”28 nígbàtí a bá ṣe dáradára, nifẹ́ àánú, tí a sì rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. A ó gba àwọn ìhùwàsí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì sínú ìwà wa, a sì fẹ́ràn ara wa.

Nígbàtí ẹ bá ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, ẹ ó tẹ̀lé ipa ọ̀nà májẹ̀mú ẹ ó sì yege láti “gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ìdùnnú àìlópin.” Àwọn ẹ̀mí yín yíò wọnú ògo Ọlọ́run àti pẹ̀lú iyè àìlópin.30 Ẹ ó kún fún ayọ̀ àìláfiwé.31 Mo jẹ́rií pé Ọlọ́run wà láàyè àti pé Jésù ni Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Ó sì fi tayọ̀tayọ̀ àti tìfẹ́tìfẹ́ nawọ́ àánú Rẹ̀ sí gbogbo wa. Ṣé ẹ kò nifẹ rẹ̀ ni? Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.