Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dídà Bí Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Dídà Bí Rẹ̀

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá Olùgbàlà nìkan ni gbogbo wa fi le tẹ̀síwájú sí dídà bíi Rẹ̀.

Sí àní olùṣọ́ra akẹ́kọ̀ọ́ ti ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì, ìyànjú ti Olùgbàlà láti dà bí “àní bí èmi ti rí”1 jẹ́ ìdàláàmú ó sì dàbí ohun tí kò ṣeéṣe. Bóyá o dàbí èmi—tí o mọ̀ dáadáa nípa àwọn alébù àti àwọn ìkùnà rẹ, nítorínáà o le ríi nínú ọkàn rẹ pé ó tura láti rìn ipa ọ̀nà tí kò tẹ́rí sí òkè àti ìdàgbàsókè díẹ̀. “Dájúdájú, ìkọ́ni yi kò bójúmu ó sì jẹ́ àsọdùn,” a nṣe àwáwí bí a ti nfi ìtura yan ipa tí àtakò rẹ̀ kéré jùlọ, nípa bẹ́ẹ̀ tí a njó àwọn kálórì díẹ̀ ti ìyípadà tí a nílò.

Ṣùgbọ́n báwo ni bí dídà “àní bí [Òun ti rí]” kò bá jẹ́ àpẹrẹ lásán, àní nínú ipò kíkú wa? Báwo ni bí ó bá jẹ́ pé, dé àwọn àyè kan, ó ṣeéṣe ní ìgbé ayé yi àti pé, ní tòótọ́, ó jẹ́ pàtàkì ṣaájú wíwà pẹ̀lú Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi? Báwo ni bí “àní bí èmi ti rí” ni ohun gan an àti pàtó tí Olùgbàlà ní lọ́kàn? Nígbànáà kínni? Irú ìpele aápọn wo ni a ó fẹ́ láti ṣe láti pe agbára ìyànu Rẹ̀ sí inú ayé wa kí a le yí àdánidá wa gan an padà?

Alàgbà Neal A. Maxwell kọ́ni pé: “Bí a ti nronu pé a ti pàṣẹ fúnwa nípasẹ̀ Jésù láti dàbí Òun, a nri pé ipò wa ìsisìnyí jẹ́ ọ̀kan nínú èyítí kìí ṣe pé a burú dájúdájú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ọ̀kan nínú èyítí a wà ní agbedeméjì tóbẹ́ẹ̀ àti tí a ṣe aláìní tóbẹ́ẹ̀ ní ti ìtara fún iṣẹ́ Rẹ̀—èyítí í ṣe iṣẹ́ wa, náà! A nṣe ìgbéga ṣùgbọ́n a ṣọ̀wọ́n ní àfarawé Rẹ̀.”2 Ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan, Charles M. Sheldon, sọ àwọn ìmọ̀lára tí ó jọra ní ọ̀nà yi: Kristiẹ́nítì wa fẹ́ràn ìrọ̀rùn àti ìtura rẹ̀ dáradára jù láti gbé ohunkóhun tí ó ní ìnira tí ó sì wúwo tóbẹ́ẹ̀ bíi àgbélèbú kan.”2

Ní tòótọ́, ẹni gbogbo wà ní abẹ́ ìdarí láti dà bí Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù Krístì ti dà bí Baba.4 Bí a ti ntẹ̀síwájú, a ndi pípé síi, píparí, àti kíkún ní ìdàgbàsókè.5 Irú ìkọ́ni bẹ́ẹ̀ kò dá lé orí àwọn ẹ̀kọ́ ti ẹyọkan ijọ kankan ṣùgbọ́n ó wá tààrà láti ọ̀dọ̀ Olùkọ́ni Fúnra-Rẹ̀ Ó jẹ́ pé nípasẹ̀ iwò ojú yi ni àwọn ìgbé ayé ṣe nílati jẹ́ gbígbé, àwọn ìbásọ̀rọ̀ ní gbígbéyèwò, àti ṣíṣìkẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀. Ní tòótọ́, kò sí ọ̀nà míràn láti wo àwọn ọgbẹ́ ti àwọn ìbáṣepọ̀ dídárú tàbí ti àwùjọ tí ó ti bàjẹ́ sàn ju fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti farawé Ọmọ Aládé Alàáfíà ní kíkún síi lọ,6

Jẹ́kí a ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ ìlépa àníyàn, àmọ̀ọ́mọ̀ṣe, àti àtinúwá ti dídà bí Òun ti rí nípa jíjèrè àwọn àbùdá ti Jésù Krístì gan an.

Pinnu àti Fi Ara Jì

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ìyàwó mi àti èmi dúró ní ibi tírélíẹẹ̀dì òkè gígajùlọ ti Japan, Òkè Fújì. Bí a ti bẹ̀rẹ̀ òkè gígùn wa, a wòkè sí ibi góngó jíjìnnà réré náà a sì ronú bí a bá le débẹ̀.

Àwòrán
Òkè Fújì

Bí a ti ntẹ̀síwájú, àárẹ̀, ọgbẹ́ iṣan, àti àwọn àyọrísí ibi gíga wọlé wá. Pẹ̀lú ọpọlọ, ó di pàtàkì fúnwa láti fi ojú sùn lórí ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀lé nìkan. A nwí pé, “Mo lè má le dé orí òkè láìpẹ́, ṣùgbọ́n mo le ṣe ìgbésẹ̀ tí ó kàn yí nísisìyí.” Àsìkò lẹ́hìn àsìkò iṣẹ́ dídaniláàmú náà di ohun tí ó ṣeéṣe nígbẹ̀hìn—ní ìgbésẹ̀ sí ìgbésẹ̀.

Ìgbésẹ̀ ìkínní ní ipa ọ̀nà ti dídà bí Jésù Krístì yi ni láti ní ìfẹ́ inú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Níní òye ọ̀rọ̀ ìyànjú láti dàbí Rẹ̀ dára, ṣùgbọ́n òye náà nílò láti jẹ́ fífi pẹ̀lú ìpòngbẹ láti yí ara wa padà, ìgbésẹ̀ kan ní àkókò kan, tayọ àdánidá ènìyàn.7 Láti mú ìfẹ́ inú náà dàgbà, a gbọ́dọ̀ mọ ẹnití Ó jẹ́. A gbọdọ̀ mọ nkan kan nípa ìhùwàsí Rẹ̀,8 a sì gbọdọ̀ wò fún àwọn àbùdá Rẹ̀ nínú ìwé mímọ́, àwọn ìsìn, àti àwọn ibi mímọ́ miràn. Bí a bá ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ̀ Ọ síi, a ó rí àwọn àbùdá Rẹ̀ ní híhàn lára àwọn ẹlòmíràn. Èyí yio gbàwá níyànjú nínú ìwádi tiwa, nítorí bí àwọn ẹlòmíràn bá le ṣe ìwọ̀n àwọn ìhùwàsí Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní àwa náà le ṣe.

Bí a bá ṣe olõtọ́ pẹ̀lú ara wa, Imọ́lẹ̀ Krístì9 nínú wa nsọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé àlàfo wà ní ààrin ibi tí a wà ní àfiwé pẹ̀lú ìhùwàsí Olùgbàlà tí a ní ìfẹ́ inú sí.10 Irú ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe kókó bí a bá fẹ́ tẹ̀síwájú ní dídà bí Rẹ̀. Nítòótọ́, ìsòtítọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àbùdá Rẹ̀.

Àwòrán
Ìparun jígí lé-ìṣeré

Nísisìyí, àwọn wọnnì lára wa tí wọ́n jẹ́ akíkanjú le gbèrò bíbéérè lọ́wọ́ ẹnikan tí wọ́n ní ìgbẹkẹ̀lé nínú rẹ̀, ọmọlẹ́bí, ọkọ tàbí aya, ọ̀rẹ́, tàbí olùdarí ní ti ẹ̀mí àbùdá Jésù Krístì wo ni a nílò—ó sì ṣeéṣe kí a nílò láti gba ara wa dì fún ìdáhùn náà! Nígbàmíràn a nrí ara wa pẹ̀lú àwọn jígí dídàrú ti ilé-àwàdà tí nfi wá hàn bóyá ní títóbi síi tàbí kíkéré síi ju bí a ti rí gan an lọ.

Àwọn ọ̀rẹ́ àti ọmọlẹ́bí tí a ní ìgbẹkẹ̀lé nínú rẹ̀ le ràn wá lọ́wọ́ láti rí ara wa déédé síi, ṣùgbọ́n àwọn náà, bí wọ́n ti jẹ́ olùfẹ́ni tó àti tí yío wù wọ́n láti ṣe ìrànwọ́, wọ́n le rí àwọn nkan ní àìpé. Bíi àyọrísí, ó ṣe kókó pé bákannáà kí a béèrè lọ́wọ́ Baba wa Ọrun ohun tí a nílò àti ibi tí a nílati da ojú àwọn akitiyan wa kọ. Ó ní ìwò pípé fún wa yío sì fi àìlera wa hàn wá pẹ̀lú ìfẹ́.11 Bóyá ìwọ yío kọ́ pé o nílò sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, ìṣoore, ìfẹ́, ìrètí, aápọn, tàbí ìgbọràn tí ó pọ̀ síi, láti dárúkọ àwọn díẹ̀.12

Ní àìpẹ́ púpọ̀ sẹ́hìn, mo ní ìrírí nínà-ẹ̀mí kan nígbàti olùfẹ́ni adárí Ijọ kan dá àbá kan tààrà gan an pé mo le lo ìwọ̀n títóbi síi ti àbùdá kan pàtó. Pẹ̀lú ìfẹ́ni ní ó njálu èyíkéyi àwáwí. Ní alẹ́ náà, mo ṣe àbápín ìrírí yi pẹ̀lú ìyàwó mi. Ó jẹ́ olùṣerere pẹ̀lú àánú àní bí ó ti fi ara mọ́ àbá rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ sí mi pé ìmọ̀ràn wọn jẹ́ láti ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba Ọrun.

Ó le ṣe ìrànwọ́ bákannáà láti fi pẹ̀lú òtítọ́ parí iṣẹ́ ìdárayá ti àbùdá Ìwàbíi Krístì ní orí 6 ti Wàásù Ìhìnrere Mi.13

Níwọ̀n ìgbàtí o bá ti ṣe àyẹ̀wò nítòótọ́ tí o sì pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò sí orí òkè náà, ìwọ ó nílò láti ronúpìwàdà. Ààrẹ Russell M. Nelson fi tìfẹ́tìfẹ́ kọ́ni pé: “Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti yípadà! A nfi àyè gba Olùgbàlà láti yí wa padà sí ẹ̀dà dídárajùlọ ti ara wa. A yàn láti dàgbà ní ti ẹ̀mí kí a sì gba ayọ̀—ayọ̀ ìràpadà nínú Rẹ̀. Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti dàbí Jésù Krístì síi.”14

Dídà bí Jésù Krístì ti rí yio gba yíyí ọkàn àti inú wa padà, nítòótọ́, ìwà wa gan an, àti pé síṣe bẹ́ẹ̀ ṣeéṣe nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ tí ngbanilà ti Jésù Krístì níkan.15

Ṣe Ìdámọ̀ sì Gbé Ìgbésẹ̀

Nísisìyí tí o ti pinnu láti yípadà kí o sì ronúpìwàdà, tí o sì ti wá ìtọ́ni nípasẹ̀ àdúrà, ríronú pẹ̀lú òtítọ́, àti bóyá dídámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ìwọ yío nílò láti yan àbùdá kan tí yío jẹ́ ìjìnlẹ̀ àfojúsùn rẹ. Iwọ ó nílò láti fi ara mọ́ lílo akitiyan tí ó nítumọ̀. Àwọn àbùdá wọ̀nyí kò ní wá ẹ̀dínwó àti lójijì, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ wọn ó wá ní àlékún nígbàtí a ntiraka.

Àwọn àbúdá Ìwàbíi Krístì jẹ́ àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba láti bùkún wa àti àwọn wọnnì ní àyíka wa. Nítorínáà, àwọn akitiyan wa láti gba àwọn àbùdá wọ̀nyí yío nílò àwọn ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá fún ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá Rẹ̀. Bí a bá lépa àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí láti sin àwọn ẹlòmíràn dáradára síi, Òun yío bùkún wa nínú àwọn akitiyan wa. Fífi ìmọtaraẹni lépa ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yío yọrí sí ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́.

Nípa fífi ojú sùn jinlẹ̀ sí orí àbùdá kan tí a nílò, bí o ti ntẹ̀síwájú ní gbígba àbùdá náà, àwọn àbùdá miràn yío bẹ̀rẹ̀ sí di àfikún fún ọ. Njẹ́ ẹnikan tí ó nfojúsùn jinlẹ̀ lórí ìṣerere kì yío ha lékún ní ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ bí? Njẹ́ ẹnikan tí ó nfojúsùn jinlẹ̀ lórí ìgbọràn kì yío ha jèrè aápọ̀n àti ìrètí títóbi síi bí? Àwọn akitiyan pàtàkì rẹ láti jèrè àbùdá kan á di ìgbì omi tí ngbé gbogbo àwọn ọkọ̀ sókè ní èbúté

Kọ Sílẹ̀ sì Mú Dúró

Ó ṣe pàtàkì fún mi bí mo ti ntiraka láti dàbí Rẹ̀ láti kọ àwọn ìrírí mi sílẹ̀ àti àwọn ohun tí mo nkọ́. Bí mo ti nṣe àsàrò pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn àbùdá Rẹ̀ jinlẹ̀ ní inú mi, àwọn ìwé mímọ́ di titun bí mo ti nrí àwọn àpẹrẹ ti àbúdá yi nínú àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, àti àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀. Ojú mi bákannáà di fífisùn sí orí dídá àbùdá náà mọ̀ nínú àwọn ẹlòmíràn. Mo ti ṣe àkíyèsí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan oníyanu méjéjì nínú àti ní òde Ijọ tí wọ́n ní àwọn àbùdá tí ó fi ara wé E. Wọ́n jẹ́ àpẹrẹ tí ó lágbára ti bí àwọn àbùdá wọnnì ṣe le farahàn nínú àwọn ẹni kíkú lásán nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ ìfẹ́ni Rẹ̀.

Kí o le rí ìtẹ̀síwájú gan an, ìwọ ó nílò láti fi akitiyan tí a mú dúró síi. Gẹ́gẹ́ bí gígun òkè ṣe nílò ìgbaradì ṣaájú àti ìfaradà àti ìpamọ́ra ní ìgbà ìgòkè, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrìnàjò yi ṣe nílò akitiyan òtítọ́ àti ìrúbọ. Kristiẹ́nítì tòótọ́, nínú èyítí a ntiraka láti dàbí Olùkọ́ni wa, ti nfi ìgbà gbogbo nílo àwọn akitiyan wa tí ó dára jùlọ.16

Nísisìyí ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ ní ṣókí. Àṣẹ láti dàbí Rẹ̀ kìí ṣe pẹ̀lú èrò láti mú ọ ní ìmọ̀lára ẹ̀bi, àìyẹ, tàbí àìfẹ́ràn. Gbogbo ìrírí wa ní ayé kíkú jẹ́ nípa títẹ̀síwájú, gbígbìyànjú, kíkùnà, àti yíyege. Bí ó ti le wu ìyàwó mi àti èmi tó pé kí a le di ojú wa kí a sì fi idán gbé ara wa dé ibi góngó òkè náà, ohun tí ayé wà nípa rẹ̀ kọ́ ni èyíinì.

O dára tó, a fẹ́ràn rẹ, ṣùgbọ́n síbẹ̀ èyí kò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ pípé Iṣẹ́ wà láti ṣe ní àyé yi àti ní èyí tí ó kàn. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá Rẹ̀ nìkan ni gbogbo wa fi le tẹ̀síwájú sí ìhà dídà bíi Rẹ̀.

Ní àwọn àkókò wọ̀nyí nígbàtí, “ohun gbogbo [farahàn bí] nínú ìdàrúdàpọ̀; àti … ẹ̀rù [dàbí ẹnipé ó] wà ní orí gbogbo ènìyàn,”17 egbòogi kanṣoṣo, àtúnṣe kanṣoṣo, ni láti tiraka láti dàbí Olùgbàlà,18 Olùrapadà19 ti gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, Ìmọ́lẹ̀ Ayé náà,20 àti láti lépa Ẹni náà tí ó kéde pé, “Èmi ni ọ̀nà.”21

Àwòrán
Olùràpadà

Mo mọ̀ pé dídà bí Rẹ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ àti okun àtọ̀runwá Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣeéṣe ní ìgbésẹ̀ sí ìgbésẹ̀. Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Òun ìbá má ti fúnwa ní òfin yi.22 Mo mọ èyí—ní apákan nítorípé mo rí àwọn àbùdá Rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín. Nípa àwọn ohun wọ̀nyí ni mo jẹ́rìí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. 3 Nífáì 27:27 Fún àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n jọra láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, wo Matteu 5:48 (“Nítorínáà kí ẹ̀yin kí ó pé, àní bí Baba yín tí nbẹ ní ọ̀run ti pé”); 1 John 2:6 (“Ẹnití ó bá wípé òun ngbé nínú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn, àní gẹ́gẹ́ bí òun ti rìn”); Mosiah 3:19 Nítorítí ènìà ẹlẹ́ran ara jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, ó sì ti wà bẹ̃ láti ìgbà ìṣubú Ádámù, yíò sì wà bẹ̃ títí láéláé, bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀, tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa, tí ó sì dà bí ọmọdé, onítẹríba, oníwá-tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísũrù, kíkún fún ìfẹ́, tí ó fẹ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ohun gbogbo èyítí Olúwa ríi pé ó tọ́ láti fi bẹ̃ wò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọdé ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún bàbá rẹ̀”); Alma 5:14 (“Àti nísisìyí kíyèsíi, mo bèrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin mi nínú ìjọ, njẹ́ ní ti ẹ̀mí a ti bíi yín nípa ti Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin ti gba àwòrán rẹ̀ nínú ìrísí yín?”); 3 Nefì 12:48 (“Nítorínã, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí èmi, tàbí Baba yín tí nbẹ ní ọ̀run ti wà ní pípé”).

  2. Neal A. Maxwell, Àní Bí Èmi Ti Rí (1982), 16.

  3. Charles M. Sheldon, In His Steps (1979), 185.

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 93:12–17.

  5. Wo Matteu 5:48, àkọsílẹ̀ ìsàlẹ̀ b.

  6. Wo Isaiah 9:6; 2 Nefì 19:6.

  7. Wo 1 Kọ́ríntì 2:14; Mosiah 3:19.

  8. See Matthew 7:23; 25:12; Mosiah 26:24; bákannáà wo àwọn àkọsílẹ̀ ìsàlẹ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé mímọ́; David A. Bednar, “Bí Ẹ Bá Ti Mọ̀ Mí,” Liahona, Nov. 2016, 102–5.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 93:2

  10. Wo Mórónì 7:12–19

  11. Wo Étérì 12:27

  12. Wo Wàásù Ìhìnrere Mi: Ìtọ́nisọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìsin Ìránṣẹ́ Ìhìnrere, rev. ed. (2019), chapter 6, “How Do I Develop Christlike Attributes?” Àwọn àtọ́ka sí àwọn àbùdá miràn ti Olùgbàlà ní wọ́n fọ́nká ní ààrin ìwé mímọ́. Nínú àwọn àpẹrẹ díẹ̀ ni Mosiah 3:19; Alma 7:23; Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:13.

  13. Wo Wàásù Ìhìnrere Mi, 132.

  14. Russell M. Nelson, “A Lè Ṣe Dáradára àti Jẹ́ Dáradára Si,” Liahona, May 2019, 67.

  15. Wo Bible Dictionary, “Oore-ọ̀fẹ́”; Guide to the Scriptures, “Grace,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org.

  16. Wo Sheldon, Nínú Àwọn Ìgbésẹ̀ Rẹ̀, 246: “Bí àpèjúwe wa ti jíjẹ́ Kristíẹnì bá fi ìrọ̀rùn jẹ́ láti gbádùn àwọn ànfààní jíjọ́sìn, kí a yawọ́ láì ná ara wa ní ohunkóhun, kí a ní àkókò dídára, rírọrùn ní yíyíká pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtura àti àwọn ohun títuninínú, gbé ìgbé ayé títẹríba fún àti ní àkókò kannáà yẹra fún àníyàn nlá ti ayé ti ẹ̀ṣẹ̀ àti wàhálà nítorípé ó jẹ́ ìrora púpọ̀ láti gbé e—bí èyí bá jẹ́ ìjúwe wa fún Kristíẹnì, dájúdájú a wà ní ọ̀nà jíjìn sí títẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ Rẹ̀ ẹni tí ó rin ọ̀nà náà pẹ̀lú àwọn ìkérora àti omijẹ́ àti ẹkún oró fún ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti sọnù; ẹnití ó la òógùn, bí ó ti rí, ìkán nlá ti ẹ̀jẹ̀, ẹnití ó kígbe síta ní orí àgbélébu tí a gbé sókè, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀.”

  17. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 88:91

  18. Wo Isaiah 43:3

  19. Wo Job 19:25.

  20. Wo Jòhánù 8:12

  21. Jòhánù14:6

  22. Wo 1 Néfì 3:7