Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àṣà Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Àṣà Krístì

A lè ṣìkẹ́ gbogbo àwọn àṣà ilẹ̀-ayé olúkúlùkù tí ó dárajùlọ kí a ṣì jẹ́ olùkópa kíkún nínú àṣà ayérayé tí ó nwá látinú ìhìnrere ti Jésù Krístì.

Irú ayé ẹlẹ́wà tí à ngbé nínú rẹ̀ tí a sì npin, ilé fún orísiríṣi àwọn ènìyàn, èdè, àṣà, àti ìtàn—ntàn káàkiri lórí ọgọgọ́ọ̀rún àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹgbẹgbẹ̀ẹ̀rún àwọn ẹgbẹ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ọrọ̀ ọ̀làjú. Àwọn ènìyàn ní ohun púpọ̀ láti gbéraga fún àti láti ṣe àjọyọ̀. Ṣùgbọ́n bíó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà kíkọ́—àwọn ohun èyí tí a bá lajú sí nípa ọ̀làjú tí a dàgbà nínú rẹ̀—lè di okun nlá nínú ayé wa, bákannáà ó sì lè, di àtakò pàtàkì, nígbàmíràn.

Ó lè dàbíi pé àṣà ti wọnú ìrònú wa àti ìwà tí kò ṣeéṣe láti yí padà. Lẹ́hìnnáà, ó jẹ́, ọ̀pọ̀ ohun tí à nmọ̀lára túmọ̀ ẹni tí a jẹ́ àtì látinú èyí tí a ti nní ìmọ̀ ọgbọ́n ti ìdánimọ̀. Ó lè jẹ́ irù agbára líle pé a lè ní ìjákulẹ̀ láti rí àwọn àìlera tàbí àṣìṣe àfọwọ́dá nínú àwọn àṣà ti ara wa, tí ó yọrísí ìlọ́ra láti ju àwọn lára àṣà baba wa sọnù. Ìfojúsí-púpọ̀jù lórí ìdánimọ̀ àṣà ẹni lè darí sí ìkọ̀sílẹ̀ tó dára—àní àwọn èrò—bí Ọlọ́run, ìhùwàsí, àti ìwà.

Mo mọ arákùnrin oníyanu jẹ́jẹ́ kan ní àwọn ọdún àìpẹ́ sẹ́hìn ẹnití ó ṣèrànwọ́ láti júwe ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ gbogbo ayé nípa àṣà myópíà. Mo pàdé rẹ̀ lákọ́kọ́ ní Singapore nígbàtí a yan iṣẹ́ fún mi láti jẹ́ olùkọ́ ilé ẹbí rẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n ti Sanskrit àti Tamil tó yàtọ̀, ó wá láti gúsù India. Ìyàwó ìyanu àti àwọn ọmọkùnrin méjì rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìjọ, ṣùgbọ́n òun kò darapọ̀ mọ́ Ìjọ rí tàbí fetísílẹ̀ púpọ́ sí àwọn ìkọ́ni sí ìhìnrere. Inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ọ̀nà tí ìyàwó àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi ndàgbà ó sì tì wọ́n lẹ́hìn ní kíkún nínú àwọn ìṣe àti ojúṣe Ìjọ.

Nígbàtí mo gbà láti kọ ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere àti láti pín ìgbàgbọ́ mi pẹ̀lú rẹ̀, ó kọ́kọ́ bìsẹ́hìn. Ó gbà mí ní ìgbà díẹ̀ láti ro ìdí rẹ̀: ó ní ìmọ̀lárá pé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ òun ó di ọ̀dàlẹ̀ sí ìwà òun tẹ́lẹ̀, ènìyàn òun, àti ìtàn òun! Sí ọ̀nà ríronú tirẹ̀, a ó sẹ nínú ohun gbogbo tí ó jẹ́, ohungbogbo tí ẹbí rẹ ti kọ láti jẹ́, ogun Indian tirẹ̀ gan an. Ní àwọn oṣù díẹ̀ tó tẹ̀le, a ba sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Ó jẹ́ ìyanu (bí kò tilẹ̀ yà mí lẹ́nu!) nípa bí ìhìnrere Jésù Krístì ti ṣí ojú rẹ̀ sí ìwò-àmì kan tó yàtọ̀

Nínú àwọn àṣà àfọwọ́dá-ènìyàn ni a ti rí rere àti búburú, títúnṣẹ àti bíbàjẹ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà ayé wa ni àbájáde ìdarí àwọn àtakò ní àárín àwọn tí èrò wọn yàtọ̀ àti àṣà tí ó dìde látinú ọ̀làjú wọn. Ṣùgbọ́n bíi gbogbo ìjà àti aáwọ̀ yíò parẹ́ kíákíá tí ayé bá tẹ́wọ́gba àṣà àtilẹ̀wá nìkan ọ̀kan tí gbogbo gbà láìpẹ́ jọjọ. Ọ̀làjú yí ti bẹ̀rẹ̀ ṣíwájú wíwà láyé ikú. Ọ̀làjú Ádámù àti Énọ́kì ni. Ó jẹ́ àṣà tí a dásílẹ̀ lórí àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà ní àárín àkokò, tí ó sì wà fún gbogbo obìnrin àti ọkùnrin lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ wa. Ó jẹ́ àlàlékejì. Ó jẹ́ àṣà tí ó ju gbogbo àwọn àṣà lọ tí ó sì wá látinú ètò ìdùnnú nlá, tí a dásílè látọwọ́ Ọlọ́run tí Krístì ṣe ọ̀gágun rẹ̀. Ó mú ìrẹ́pọ̀ wá sàju ìyapa. Ò nwòsàn sànju ìpalára.

Ìhìnrere Jésù Krístì kọ́ wá pé èrèdí wà nínú ayé. Wíwà nihin wa kìí ṣe àwọn ìjàmbá nlá cọ́smíkì tàbí àṣìṣe lásán! A wà nihin fún ìdí kan.

Àṣà yí múlẹ̀ nínú ẹ̀rí pé Baba wa Ọ̀run wà, Ó jẹ́ Òótọ́ ó sì fẹ́ràn olúkúlùkù wa ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àwa ni “iṣẹ́ àti ògo [Rẹ̀].”1 Àṣà yí fi ìrò ti ìbáramu yíyẹ hàn. Kò sí mímọni ti ilé-nlá tàbí ipò. Lẹ́hìnnáà, a jẹ́, arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀mí ọmọ àwọn òbí tọ̀run—níti ọ̀rọ̀. Kò sí ìkóríra tàbí “àwa sí àwọn” làákàyè ni ó tóbi ju gbogbo àwọn àṣà lọ. Gbogbo wa ni “àwa.” Gbogbo wa ni “àwọn.” A gbàgbọ́ pé à ní ojúṣe àti ìjiyìn funrawa, arawa, Ìjọ, àti ayé wa. Ojúṣe àti ìjihìn jẹ́ àwọn ìfọ́síwẹ́wẹ́ pàtàkì nínú ìdàgbà wa.

Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìtọ́jú òtítọ́ bíiti Krístì, ni ìtẹ́lẹ̀ ọ̀làjú yí. A ní ìmọ̀lára òtítọ́ fún àwọn àìní ọmọnìkejì wa, ti ara àti ti ẹ̀mí, àti ìṣe lórí àwọn ìmọ̀lára. Ó nmú ìkóríra àti ẹ̀tanú kúró.

A gbádùn ọ̀làjú ìfihàn, tí ó dá lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí a ṣe gbàá nípasẹ̀ àwọn wòlíì (àti ẹ̀rí ti araẹni sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́). Gbogbo ẹlẹ́ran-ara lè mọ ìfẹ́ àti inú Ọlọ́run

Ọ̀làjú yí ni ọ̀gágun ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ agbára láti yàn. Agbára láti yàn ṣe pàtàkì gidi fún ìdàgbàsokè wa àti ìdùnnú wa. Yíyàn pẹ̀lú ọgbọ́n ṣe pàtàkì.

Ó jẹ́ Ọ̀làjú kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ṣíṣe àṣàrò. À nwá ìmọ̀ àti ọgbọ́n àti dídára julọ nínú ohun gbogbo.

Ó jẹ́ Ọ̀làjú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ti àṣà wa, àti pé ìgbọràn sí àwọn ìkọ́ni àti òfin Rẹ̀ ni àyọrísí. Ìwọ̀nyí mú ìgòkè sí ìṣẹ́gun-araẹni.

Ó jẹ́ Ọ̀làjú àdúrà kan. A gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kò ní gbọ́ wa nìkan ṣùgbọ́n bákannáà yíò ràn wá lọ́wọ́.

Ó jẹ́ ọ̀làjú àwọn májẹ̀mú àti ìlànà, òṣùwọ̀n ìwà gíga, ìrúbọ, ìdáríjì àti ìrònúpìwàdà, àti ṣíṣé ìtọ́jú tẹ́mpìlì ti ara wa. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí ìfarasìn wa sí Ọlọ́run.

Ó jẹ́ ọ̀làjú tó jọba nípasẹ̀ oyè-àlùfáà, àṣẹ láti ṣiṣẹ́ ní orúkọ Ọlọ́run, agbára Ọlọ́run láti bùkún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó ngbéga ó sì nfún olúkúlùkù ní ààyè láti di ènìyàn dídárasi, olórí, ìyá, baba, àti ojúgbà—ó sì nya ilé wa sí mímọ́.

Iṣẹ́ ìyanu tòótọ́ wà nínú èyí, àgbà jùlọ nínú gbogbo àwọn ọ̀làjú, tí a ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, agbára oyè-àlùfáà, àdúrà, ìtúnṣearaẹni, ìyípadà tòótọ́, àti ìdáríjì.

Ó jẹ́ Àṣà iṣẹ́ ìhìnrere. Oye àwọn ẹ̀mì ṣe kókó.

Nínú àṣà Krístì, a gbé àwọn obìnrin sókè sí ipò tótọ́ àti ayérayé wọn. Wọn kò sí ní ìpamọ́ lábẹ́ àwọn ọkùnrin, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà ní ayé òde òní, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ alábáṣepọ̀ ìdọ́gba nihin àti ní ayé tó nbọ̀.

Àṣà yí dá ìwàmímọ́ ti ẹbí dúró. Ẹbí ni kókó ẹ̀yà ayé-àìlópin. Pípé ẹbí yẹ ju ìrúbọ eyikeyi lọ nítorí, bí a ti kọ́, “ko sí àṣeyege kankan tí ó lè san ìkùnà nínú ilé padà.” Ilé ni ibi tí a ti nṣe iṣẹ́ wa dídára jùlọ àti ibití a ti nrí ìdùnú títóbi jùlọ wa gbà.

Nínú àṣà Krístì, ìrísí wà—àti ìdojúkọ àti ìdarì ayérayé. Àṣà yí ni àníyàn pẹ̀lú àwọn ohun yíyẹ tó pẹ́ títí! Ó wá látinú ìhìnrere Jésù Krístì, èyí tí ó jẹ́ ayérayé tí ó sì ṣàlàyé ìdí, ohun àti ibi ti wíwà láyé wa. (Ó wà pẹ̀lú, kò kúró níbẹ̀.) Nítorí àṣà yí jádé látinú lílò àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà wa, ó nṣèrànwọ́ láti pèsè ìkúnra ìwòsàn irú èyí tí ayé nílò pẹ̀lú ìtara.

Irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti wà ní ara ọ̀nà ìgbé ayé ọlọ́lá àti nlá yí. Láti jẹ́ ara èyí, titóbi jùlọ ti gbogbo àwọn àṣà, yíò bèèrè fún ìyípadà. Àwọn wòlíì ti kọ́ni pé ó ṣe kókó láti fi ohunkóhun nínú àwọn àṣà àtijọ́ tí kò bá àṣà ti Krístì mu. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé a níláti fi ohungbogbo sílẹ̀ sẹ́hìn. Àwọn wòlíì bákannáà ti tunsọ pé a pè wá, ní ọ̀kan àti gbogbo ènìyàn, láti mú ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀bùn àti ìmọ̀—gbogbo ohun tó dára nínú ayé wa àti àwọn àṣà olúkúlùkù wa wá—pẹ̀lú wa, kí a sì jẹ́ kí Ìjọ “fi kun un” nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìhìnrere.3

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kìí fi taratara ṣe ẹgbẹ́ ti Ìwọ̀ oòrùn tàbí àṣà Amẹ́ríkà kan lásán. Ó jẹ́ ìjọ gbogbogbò, bí ó ṣe yẹ kí ó rí. Ju ìyẹn lọ, ó jẹ́ èyí tó lágbára jùlọ. Àwọn ọmọ ìjọ titun láti àyíká ayé nmú ọrọ̀, oríṣiríṣi, àti ìdùnnú sínú ẹbí wa tí ó ndàgbà si láéláé. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níbigbogbo ṣì nṣe àjọyọ̀ àti bu iyì fún ogun ti ara wọn àti àwọn akọni, ṣùgbọ́n nísisìyí wọ́n jẹ́ ara ohun kan tí ó tóbi jùlọ gan an. Àṣà Krístì ràn wá lọ́wọ́ láti rí arawa bí a ṣe wà lódodo, àti ìgbàtí a bá rí wa nínú jígí ayé àìlópin, tí a wà pẹ̀lú òdodo, ó jẹ́ ìsìn láti mú agbára pọ̀si láti mú ètò ìdùnnú nlá pọ̀ si.

Nítorínáà kíni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀rẹ́ mi? Bákannáà, a kọ ní àwọn ẹ̀kọ́ ó sì darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Ẹbí rẹ̀ ti ṣe èdidì látìgbànáà fún ìgbà àti gbogbo ayé àìlópin ní Tẹ́mpìlì Sydney Australia. Ó ti fi ohun kékeré sílẹ̀—ó sì jèrè agbára fún ohungbogbo. Ó ṣe àwárí pé òun ṣì lè ṣe àjọyọ̀ ìtàn rẹ̀, kí ó ṣì gbé àwọn bàbánlá rẹ̀, orin rẹ̀ àti ijó àti ìwé-kíka, oúnjẹ rẹ̀, ilẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ga. Ó ti ri pé kò sí wàhálà ní fífi ọ̀làjú ìbílẹ̀ rẹ̀ dídára jùlọ sínú títóbijùlọ gbogbo àwọn àṣà. Ó ṣe àwárí pé mímú ohun èyí tí ó wà ní ìbámu òtítọ́ àti òdodo wá látinú ìgbé ayé àtijọ́ sínú titun nsìn láti mú jíjọ́sìnrẹ̀ gbòòrò pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ àti láti ṣàtìlẹhìn nínú ìrẹ́pọ̀ gbogbo ènìyàn bí ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Ọ̀run.

Nítòótọ́, a lè, ṣìkẹ́ gbogbo àwọn àṣà ilẹ̀-ayé olúkúlùkù tí ó dárajùlọ kí a ṣì jẹ́ olùkópa kíkún nínú ọ̀làjú àtijọ́ jùlọ gbogbo wọn—Àṣà àtilẹ̀bá, ìgbẹ̀hìn, ayérayé tí ó nwá látinú ìhìnrere ti Jésù Kris´tì. Irú ogun ìyanilẹ́nu tí gbogbo wa npín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Mósè1:39.

  2. J. E. McCulloch, in Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Olùdarí Àgbà ti Ìjọ: David O. McKay (2011), 154.

  3. Wo Ìdánilẹ́kọ́ ti àwọn Ààrẹ Ìjọ: George Albert Smith (2011), xxviii; Gordon B. Hinckley, “The Marvelous Foundation of Our Faith,” Liahona, Nov. 2002, 78–81.