Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Awọn Arábìnrin ní Síónì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Awọn Arábìnrin ní Síónì

Ẹ̀yin yíò jẹ́ ipa pàtàkì ní kíkójọ Ísráẹ́lì àti ní dídásílẹ̀ àwọn ènìyàn Síónì.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ Arábìnrin mi, mo di alábùkúnfún láti sọ̀rọ̀ ní ìgbà ìyanu yí nínú ìtàn ayé. Ojojumọ, ni a nsúnmọ́ àkokò ológo nígbàtí Olùgbàlà Jésù Krístì yíò dé sí ayé lẹ́ẹ̀kansi. A mọ ohun kan nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí yíò ṣíwájú bíbọ Rẹ̀, síbẹ̀ ọkàn wa kún fún ayọ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé bákannàà ní mímọ àwọn ìlérí ológo tí yíò wá sí ìmúṣẹ ṣíwájú bíbọ̀ Rẹ̀.

Gẹ́gẹ́bí àwọn àyànfẹ́ ọmọbìnrin ti Baba Ọ̀run, àti bí àwọn ọmọbìnrin Olúwa Jésù Krístì nínú ìjọba Rẹ,1 ẹ ó ṣe ipa pàtàkì nínú àwọn àkókò nlá tí ó wà níwájú. A mọ̀ pé Olùgbàlà yíò wá bá àwọn ènìyàn tí ó ti kórajọ tí ó sì ti múrasílẹ̀ láti gbé bí àwọn ènìyàn ti ṣe ní ìlu-nlá ti Enoch. Àwọn ènìyàn nibẹ ní ìrẹ́pọ̀ nínú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti pé wọ́n ní láti di mímọ́ gidi pátápátá tí a fi gbé wọn sóke ọ̀run.

Nihin ni ìjúwe ìfihàn ti Olúwa nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Enoch àti ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ní àkokò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́ ìríjú tó kẹ́hìn :

“Ọjọ́ náà yíò sì dé tí ayé yíò sinmi, ṣùgbọ́n ṣaájú ọjọ́ náà àwọn ọ̀run ni a ó mú ṣókùnkùn, ìbòjú kan ti òkùnkùn yíò si bo ilẹ̀ ayé; àwọn ọ̀run yíò sì mì tìtì, àti ilẹ̀ ayé pẹ̀lú; awọn ìpọ́njú nlá yíò sì wà laarin àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ni èmi yíò pa mọ́;

“Òdodo ni èmi yíò sì rán sọkalẹ̀ wá láti ọ̀run; àti òtítọ́ ni èmi yíò rán jáde lọ láti ilẹ̀ ayé, láti jẹri Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo; àjinde rẹ̀ láti ipò òkú; bẹ́ẹ̀ni, àti àjínde ti gbogbo ènìyàn bákannáà, àti òdodo àti òtítọ́ ni èmi yíò mú kí wọn ó gba ilẹ̀ ayé bí ìkún omi, láti kó àwọn àyànfẹ́ mi jọ pọ̀ jáde láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, sí ibìkan tí ẹ̀mí yíò pèsè, Ìlú nlá Mímọ́ kan, kí àwọn ènìyàn mi ó lè di àmùrè wọn, kí wọn ó sì máà fojú sọ́nà fún ìgbà bíbọ̀ mi; nitorí níbẹ̀ ni àgọ́ mi yíò wa, èyí ni a ó sì pè ní Síónì, Jerúsálẹ́mù Titun kan.

“Oluwa sì wí fún Enoch: Nígbànáà ni ìwọ àti gbogbo wọn ìlú-nla rẹ̀ yíò pàdé wọn níbẹ̀, a ó sì gbà wá sí oókan àyà wa, wọn yíò sì rí wa; a ó sì dì mọ́ wọn ní ọrùn, àwọn ó sì dì mọ́ wa ni ọrùn, a ó sì fi ẹnu ko ara wa lẹ́nu;

“Ibẹ̀ ni yíò sì jẹ́ ibùgbé mi, yíò sì jẹ́ Síónì, Èyítí yíò jáde wá láti inú gbogbo àwọn ẹ̀dá ti èmi ti dá; àti tí àlàfo ẹgbẹ̀rún ọdún ilẹ̀ yíò simi.”2

Ẹ̀yin arábìnrin, àwọn ọmọbìnrin yín, ọmọ-ọmọbìnrin yín, àti àwọn obìnrin tí ẹ ti tọ́ yíò wà ní ọ̀kan dídá àwùjọ náà ti àwọn ènìyàn yíò darapọ̀ mọ́ nínú ìṣepọ̀ ológo pẹ̀lú Olùgbàlà. Ẹ̀yin yíò jẹ́ ipa pàtàkì ní kíkójọ Ísráẹ́lì àti ní dídá àwọn ènìyàn Síónì tí ó ngbé ní àláfíà ní Jerúsálẹ́mù Titun.

Olúwa ti ṣe ìlérí fún yín, nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ. Ní àwọn ọjọ́ ìṣaájú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, Wòlíì Joseph Smith wí fún àwọn arábìnrin, “Bí ẹ bá gbé dáradára sí àwọn ànfàní yín, àwọn ángẹ́lì kò lè dẹ́kun ìbáṣepọ̀.pẹ̀lú yín”3

Agbára ìyanu náà wà nínú yín, a ti nmúra yín sílẹ̀ fún.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley wípé:

“Ẹ̀yin arábìnrin … kò di ipò keji mú nínú ètò Baba wa fún ìdùnnú ayérayé àti ìlera ti àwọn ọmọ Rẹ̀. Ẹ jẹ́ apákan pàtàkì gidi lára ètò náà.

“Láìsí yín ètò náà kò lè ṣiṣẹ́. Láìsí yín gbogbo ètò náà a ní ìjákulẹ̀. …

“Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára yín ni ọmọbìnrin Ọlọ́run, tí a fún ni ẹ̀tọ́-ìbí àtọ̀runwá.”4

Wòlíì wa lọ́wọ́lọ́wọ́, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti fúnni ní ìjúwe yí nípa ipa tí ẹ̀ nkó nínú ìmúrasílẹ̀ fún bíbọ̀ Olùgbàlà:

“Kò ní lè ṣeéṣe láti díwọ̀n ipa tí … àwọn obìnrin ni, kìí ṣe lórí àwọn ẹbí nìkan ṣùgbọ́n lórí Ìjọ Olúwa, bíi àwọn ìyàwó, àwọn ìyá, àti àwọn ìyá-ìyá; bí àwọn arábìnrin àti àwọn àbúrò ìyá obìnrin; bí àwọn olùkọ́ àti olórí; àti ní pàtàkì bíi àpẹrẹ olùfọkànsìn olùgbèjà ìgbàgbọ̀.

“Èyí ti jẹ́ òtítọ́ nínú gbogbo àkokò iṣẹ́ ìríjú láti ìgbà àwọn ọjọ́ Ádámù àti Éfà. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn obìnrin ti àkokò iṣẹ́ ìríjú yàtọ̀ sí àwọn obìnrin èyíkèyí míràn nítorí àkokò iṣẹ́ ìríjú yí yàtọ̀ sí òmíràn. Ìyàtọ̀ yí nmú àwọn ànfàní àti ojúṣe méjèèjì wá.”5

Àkokò iṣẹ́ ìríjú yí yàtọ̀ nítorí Olúwa yíò darí wa láti múrasílẹ̀ láti dàbí Ìlú-nlá ti Enoch. Ó ti ṣàpèjúwe nípasẹ̀ àwọn àpóstélì Rẹ̀ àti wòlíì ohun tí ìyípadà sí àwọn ènìyàn Síónì kan yíò gbà.

Alàgbà Bruce R. McConkie kọ́ni:

“Ti [Enoch] ni ọjọ́ búburú àti ibi kan, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣọ̀tẹ̀ kan, ọjọ́ ogun àti ìdahoro kan, ọjọ́ dídarí sí ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ ayé nípa omi.

“Enoch, bákannáà, jẹ́ olotitọ. Ó ‘rí Olúwa,’ ó sì ba sọ̀rọ̀ ‘lójú ko jú’ bí ẹnìkan ti nsọ̀rọ̀ sí ẹlòmíràn. (Mósè 7:4.) Olúwa ran láti kígbe ìrònúpìwàdà sí ayé, ó sì pàṣẹ fun láti ‘ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Baba àti Ọmọ, èyí tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, àti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó jẹri àkọsílẹ̀ Bàbá àti Ọmọ.’’ (Mósè1:39.) Enoch dá májẹ̀mú ó sì kó gbogbo ìjọ àwọn onígbàgbọ́ òtítọ́ pọ, gbogbo àwọn ẹnití ó di olotitọ tó pé ‘Olúwa wá ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, wọ́n sì gbé nínú òdodo,’ wọ́n sì alábùkúnfún láti òkè wá. ‘Olúwa sì pè àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nitorí wọ́n wà ní ọkàn kan àti inú kan, wọ́n sì gbé nínú òdodo; kò sì sí òtòṣì kankan ní àárín wọn.’ (Mósè7:18.) …

“Lẹ́hìn tí Olúwa pe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, ìwé mímọ́ wípé Enoch ‘kọ́ ìlú-nlá tí a pè ní Ìlú-nla ti Ìwàmímọ́, àní Síónì;’ Síónì náà ‘tí a gbà sí òkè’ nibití ‘Ọlọ́run ti gbà á sínú oókan àyà rẹ̀; láti ibẹ̀ lọ ni ọ̀rọ̀ sísọ náà ti jáde lọ wípé, Síóni ti sálọ.’ (Moses 7:19, 21, 69.) …

“Síónì kannáà tí a gbà sí ọ̀run yíò padà wá … nígbàtí Olúwa bá mú Síónì wá lẹ́ẹ̀kansi, àwọn olùgbé rẹ̀ yíò darapọ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù titun, éyí tí a ó gbékalẹ̀ nígbànáà.”6

Tí àtẹ̀hìnwá bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣíwájú, ní ìgbà bíbọ̀ Olùgbàlà, àwọn ọmọbìnrin tí ó farasìn jinlẹ̀-jinlẹ̀ sí májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run yíò ju ìlàjì àwọn tí ó múrasílẹ̀ láti kí I káàbọ̀ nígbà tí Ó bá dé. Ṣùgbọ́n eyikeyi nọ́mba náà, ìfọwọ́sí yín ní didá ìrẹ́pọ̀ sílẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn nmúrasílẹ̀ fún Síónì náà yíò jẹ́ títóbi ju ìlàjì lọ gidi.

Èmi ó wí fún yín ìdí tí mo fi gbàgbọ́ pé èyí yíò rí bẹ́ẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì fúnni ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn ènìyàn Síónì. Ẹ rántí pé lẹ́hìn tí a ti kọ́ wọn, tí a fẹ́ wọn, tí a bùkún wọn látọwọ́ olùjínde Olùgbàlà: “Ko si ìjà ní ilẹ̀ náà mọ́, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó gbé ní ọkàn àwọn ènìyàn.”7

Ìrírí mi ti kọ́ mi pé àwọn ọmọbìnrin Baba Ọ̀run ní ẹ̀bùn kan láti mú ìjà kúrò àti làti gbé òdodo ga pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run àti pẹ̀lú ifẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n fi sínú àwọn tí wọ́n nsìn.

Mo rí i ní ọ̀dọ́ mi nígbàtí ẹ̀ka tírín wa pàdé ní ilé ìgbà èwe mi. Arákùnrin mi àti èmi nìkan ni olùdìmú Oyè-àlùfáà Árónì, baba mi nìkan ni olùdìmú Oyè-àlùfáà Mẹ́lkìsédékì. Ààrẹ Ẹgbẹ́ ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀ka ni olùyípadà ẹnití inú ọkọ rẹ̀ kò dùn sí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní Ìjọ. Gbogbo àwọn ọmọ ìjọ jẹ́ aràbìnrin àgbàlàgbà láìsí olùdìmú oyè-àlùfáà nínú ilé wọn. Mo wóó bí ìfẹ́ ìyá mi àti àwọn arábìnrin wọnnì, ngbé ga, tí ó sì nṣìkẹ́ ara wọn láìkùnà. Mo da mọ̀ nísisìyí pé a fún mi ní ìwò ìṣíwájú nípa Síónì.

Ikẹkọ mi ní ipa tíàwọn obìnrin olóotọ́ tẹ̀síwájú ní ẹ̀ka kékeré ti Ìjọ ní Albuquerque, New Mexico. Mo wo ìyàwó ààrẹ̀ ẹ̀ka, ìyàwó ààrẹ ẹ̀kùn, àti ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nmú ìyárí wá sí ọkàn gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá àti olùyípada. Ní Ọjọ́-ìsinmi tí mo kúrò ní Albuquerque, lẹ́hìn ọdún méjì tí mo ti ṣàkíyèsí agbára àwọn arábìnrin níbẹ̀, a dá èèkàn àkọ́kọ́ sílẹ̀. Nísisìyí Olúwa ti gbé tẹ́mpìlì kalẹ̀ síbẹ̀.

Mo lọ sí Boston tẹ̀le, níbití mo ti sìn nínú àjọ ààrẹ ẹ̀kùn tí ó ṣaájú àwọn ẹ̀ka kékeré tí ó tànkákiri àwọn ìpínlẹ̀ méjì. Àwọn ìjà wà ju ìgbà méjì tí a yanjú làti ọwọ́ àwọn olùfẹ́ni àti olùdáríjì obìnrin tí wọ́n ṣèrànwọ́ láti rọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ní Ọjọ́-ìsinmi tí mo kúrò ní Boston, ọmọ àjọ ààrẹ Ìkínní ṣètò èèkan àkọ́kọ́ ní Massachusetts. Tẹ́mpìlì kan wà níbẹ̀ nísisìyí, ó súnmọ́ ibi tí ààrẹ ẹ̀ka ngbé nígbàkan. A mú wá sí aápọn Ìjọ a sì pè é láti sìn bí ààrẹ èèkàn àti nígbànáà bí ààrẹ míṣọ̀n, ẹnití olùfẹ́ni ìyàwó rẹ nfún lágbára.

Ẹ̀yin arábìnrin, a fún yín ní ìbùkún jíjẹ́ ọmọbìnrin Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn pàtàkì. Ẹ mú okun ti-ẹ̀mí wá pẹ̀lú yín sínú ayé ikú láti tọ́ àwọn ẹlòmíràn àti láti gbé wọn ga síwájú ìfẹ́ àti ìwà mímọ́ tí yíò mú wọn yege láti gbé papọ̀ ní àwùjọ Síónì. Kìí ṣe nípa ìjàmbá pé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ìṣètò àkọ́kọ́ Ìjọ nípàtàkì fún Àwọn ọmọbìnrin Baba Ọ̀run, ni bí àkórí rẹ̀ “Ìfẹ́ Àìlẹ́gbẹ́ Kìí Kùnà.”

Èyí ni ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Jésù Krístì. Ìfẹ́ nínú Rẹ̀ àti èrè kíkún Ètùtù àìlópin Rẹ̀ ni yíò mú yín yege, àti àwọn tí ẹ nifẹ tí ẹ̀ nsìn, nítorí ẹ̀bùn tó tayọ láti gbé ní àwùjọ ti a ti-nretí-tipẹ́ àti ìlérí Síónì. Níbẹ̀ ẹ o jẹ́ àwọn arábìnrin ní Síónì, ẹnítí a fẹ́ nípasẹ̀ Olúwa àti àwọn tí ẹ ti bùkún.

Mo jẹri pé ẹ jẹ́ ọmọ-ìlú ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀-ayé. Ẹ jẹ́ àwọn ọmọbìnrin olùfẹ́ni Baba Ọ̀run, tí ó rán yín wá sí ayé pẹ̀lú ẹ̀bùn àìlékejì tí ẹ ṣèlérí láti lo láti bùkún àwọn ẹlòmíràn. Mo ṣe ìlérí pé Olúwa yíò darí yín ní ọwọ́, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Òun yíò lọ ṣíwájú yín bí ẹ ṣe nràn An lọ́wọ́ láti múra àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ láti di Síónì tí a ṣèlérí. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.