Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àláfíà, Dákẹ́ Jẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Àláfíà, Dákẹ́ Jẹ́

Olùgbàlà kọ́ wa bí a ṣe le ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ àní nígbàtí àwọn ẹ̀fúfù líle nfẹ́ ní àyíká wa tí àwọn ìgbì omi fífuru nhalẹ̀ láti ri àwọn ìrètí wa mọ́lẹ̀.

Nígbatí àwọn ọmọ wa wà ní ọ̀dọ́, ìdílé wa lo àwọn ọjọ́ díẹ̀ ní adágún dáradára kan. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan díẹ̀ nínú àwọn ọmọdé wọ àwọn jákẹ̀tì ìgbésí ayé ṣáájú kí wọn tó fò kúrò lórí dẹ́kìnì àti sínú omi. Ọmọbìnrin wa kékeré jùlọ wò pẹ̀lú ìṣiyèméjì, ó nfi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kiyèsí àwọn arákùnrin rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ìgboyà tí ó lè kó, ó fi ọwọ́ kan di imú rẹ̀ ó sì fò. Ò farahàn lẹ́sẹ́kẹsẹ̀ àti pẹ̀lú ìjaayà díẹ̀ nínú ohùn rẹ̀ ó kígbe, “Ràn mí lọ́wọ́! Ràn mí lọ́wọ́!”

Báyi, kò si nínú ewu ayé ikú kankan; jákẹ̀tì ìgbésì ayé rẹ̀ nṣe iṣẹ́ rẹ̀ ó sì nfò láìléwu. A lè ti nawọ́ jáde kí a fa ẹ̀hìn rẹ̀ padà lórí dẹ́kìnì pẹ̀lú ìgbìyànjú díẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ láti ojú-ìwòye rẹ̀, ó nílò ìrànlọ́wọ́. Bóyá ó jẹ́ tutù ti omi tàbí titun ti ìrírí náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gùn ún padà sẹ́hìn sórí dẹ́kìnì, níbi tí a ti wé e ní aṣọ ìnura gbígbẹ tí a sì yìn ín fún ìgboyà rẹ̀.

Bóyá a ti wà ní àgbàlagbà tàbí ọ̀dọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ti, ní àwọn àkokò ìpọ́njú, sọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìkánjú bíi “Ràn mí lọ́wọ́!” “Gbà mí!” tàbí “Jọ̀wọ́, dáhùn àdúrà mi!”

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù lákoko ayé-ikú ara Rẹ̀. Nínu Márkù a kà pé Jésù “tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni lẹ́ba òkun: àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.”1 Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Jésù “wọnú ọkọ̀ ojú-omi”2 ó sì sọ̀rọ̀ láti orí dẹ́kìnì rẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ ni Ó kọ́ àwọn ènìyàn ní àwọn òwe bí wọ́n ti jóko ní etí òkun.

“Àti pé … nígbàtí [alẹ́] sì dé,” Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, “Jẹ́kí a kọjá sí apá kejì. Nígbàtí wọ́n sì ti rán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lọ,”3 wọ́n sì ṣí kúrò ní etí òkun wọ́n sì wà ní ọ̀nà wọn ní ìsọdá Ókun ti Gálíllì Ní rírí ààyè kan ní ẹ̀hìn ọkọ̀, Jésù dùbúlẹ̀ ó yára sun. Láìpẹ́ “ìjì líle kan dìde, àwọn ìgbì omi sì rọ̀ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tóbẹ́ẹ̀ tí ó ti [fẹ́rẹ̀ẹ́] kún”4 fún omi.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù ni àwọ̀n apẹja tí ó ní ìrírí tí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe lè di ọkọ̀ ojú-omi kékeré kan mú nínú ìjì. Wọ́n jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀—nítòótọ́, àyànfẹ́ Rẹ́—àwọn ọmọ ẹ̀hìn. Wọ́n ti fi àwọn iṣẹ́ sílẹ̀, àwọn ìfẹ́ ti ara ẹni, àti ẹbí láti tẹ̀lé Jésù. Ìgbàgbọ́ wọn nínú Rẹ̀ hàn nípa wíwá nínú ọkọ̀ oju-omi wọn. Àti pé nísisìyí ọkọ̀ ojú omi wọn wà ní àárín ìji tí ó sì wà ní rírì gan an.

A kò mọ ìgbà tí wọ́n jà pẹ́ tó láti pa ọkọ̀ ojú omi náà mọ́ ní fífò nínú ìji, ṣùgbọ́n wọ́n jí Jésù pẹ̀lú ìjaayà díẹ̀ nínú àwọn ohun wọn, ní sísọ pé:

“Olùkọ́ni, ìwọ̀ kò bìkítà pé àwa yóò ṣègbé?”5

Olúwa gbà wá àwá ṣègbé.”6

Wọ́n pè É ní “Olùkọ́ni,” àti pé Òun ni. Bákannáà òun ni “Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Baba ti ọ̀run àti ayé, Ẹlẹ́da ohun gbogbo láti ìpinlẹ̀ṣẹ̀.”7

Àwòrán
Àláfíà, dúró jẹ́.

Láti ipò Rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, Jésù dìde ó bá afẹ́fẹ wí, ó sì sọ fún òkun tí nlù pé, “Àlàfíà, dákẹ́ jẹ́. Afẹ́fẹ́ sì dá dúró, ìdákẹ́jẹ́ nlá sì wà.”8 Láéláé ni Olùkọ́ni Àgbà, Jésù lẹ́hìnnáà kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hin Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìbéèrè méjì ìfẹ́ni síbẹ̀ tí ó rọrùn. Ó bèèrè pé:

“Èéṣe tí ẹ fi bẹ̀rù tóbẹ́ẹ̀?”9

“Níbo ni ìgbàgbọ́ rẹ wà?”10

Ìtẹ́sí ayé ikú wà, àní ìdánwò kan, nígbàtí a bá ri ara wa lárin àwọn àdánwò, àwọn wàhálà, tàbí àwọn ìpọ́njú láti kígbe jáde pé, “Olùkọ́ni, ìwọ kò bìkítà pé èmi parun bí? Gbà mí.” Àní Joseph Smith bẹ̀bẹ̀ láti inú túbú ẹ̀rù kan, “Ọlọ́run, níbo ni o wà? Àti pé níbo ni àgọ́ ti o bo ibi ìkọ̀kọ rẹ?”11

Dájúdájú, Olùgbàlà aráyé lóyé àwọn ìdẹ́kun ti ayé ikú wa, nítorí Ó kọ́ wa bí a ṣe le ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ àní nígbàtí àwọn ẹ̀fúfù líle nfẹ́ ní àyíká wa tí àwọn ìgbì omi fífuru nhalẹ̀ láti ri àwọn ìrètí wa mọ́lẹ̀.

Sí àwọn tó wà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a ti dánwò, ìgbàgbọ́ bí ọmọdé, tàbí àní ohun ìgbàgbọ́ tó kéré jùlọ,12 Jésù npè, ó wípé: “Wá sọ́dọ̀ mi.”13 “Gbàgbọ́ nínú orúkọ mi.”14 “Kọ́ nípa mi, kí ó sì fetísí àwọn ọ̀rọ̀ mi.”15 Ó fi rírọ́nú pàṣẹ, “Ronúpíwàdà, kí [kí a sì] ṣe ìrìbọmi fún yín ní orúkọ mi,”16 “Ẹ fẹ́ràn ara yín; bí mo ti fẹ́ràn yín,” àti kí ẹ “máa rántí mi nígbàgbogbo.” Jésù tún mú dánilójú, ó ṣe àlàyé pé: “Àwọn ohun wọ̀nyí ni mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àláfíà nínú mi. Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”1

Mo le ronú pe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésu nínú ọkọ̀ ojú-omi tí ìjì-omi jẹ, ti ìwúlò, ó nṣiṣẹ́ ní wíwò àwọn ìgbì omi tí ó kọlu orí dẹ́kìnì wọn àti gbígba omi sílẹ̀. Mo lè yàwòrán àwọn tí ntu ọkọ̀ ojú-omi náà tí wọ́n ngbìyànjú láti mu irú ìrísí ìṣàkóso kan dúró lórí iṣẹ́ ọwọ́ kékeré wọn. Ìdojúkọ wọn wá lórí ìwàláàyè àkókò náà, àti pé ẹ̀bẹ̀ wọn fún ìrànlọ́wọ́ jẹ́ òótọ́ àtinúwá.

Ọpọ̀lọpọ̀ wa kò yàtọ̀ ní ọjọ́ wa. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìpẹ́ ní àyíká àgbáyé àti ní àwọn orílẹ̀-èdè wa, àwọn ìletò, àti àwọn ìdílé ti fi àwọn ìdánwò àìròtẹ́lẹ̀ kọlù wá. Ní àwọn àkókò rúdurùdu ìgbàgbọ́ wa le ní ìtara sí àwọn opin ti ìfaradà àti òye wa. Àwọn ìgbì omi ti ìbẹ̀rú lè dàmú wa, kí ó fa kí a gbàgbé ire Ọlọ́run, nítorínáà fi ojú-ìwòye wá sí kúkúrú-ojú àti kúrò ní ìdojúkọ. Síbẹ̀síbẹ̀ ó wà nínú àwọn ìrìn tí ó nira nípa ìrìn-àjò wa ni a lè dán ìgbàgbọ́ wa wò ṣùgbọ́n múle gbọingbọin.

Láìka àwọn ipò wa sí, a le mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àwọn ìtiraka láti gbéga àti láti mú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì pọ̀ si. Ó nfunní ní okun nígbàtí a bá rántí pé ọmọ Ọlọ́run ni wá àti pé Ò fẹ́ràn wa. Ìgbàgbọ́ wa ndàgbà bí a ṣe nṣe àyẹ̀wò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìrètí àti ìtara, ní ìgbìyànjú wa dídára jùlọ láti tẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Krístì. Ìgbàgbọ́ wa npọ̀ si bí a ṣe yàn láti gbàgbọ́ dípò iyèméjì, dáríjì dípò dídájọ́, ronúpíwàdà dípò ṣíṣọ̀tẹ̀. Ìgbàgbọ́ wa ti wà ní àtúnṣe bí a ṣe fi sùúrù dúró lórí àwọn ẹ̀tọ́ àti àánú àti ore-ọ̀fẹ́ ti Mèssíàh Mimọ.20

“Nígbàtí ìgbàgbọ́ kìí ṣe imọ pipe,” Alàgbà Neal A. Maxwell sọ pé, “ó nmú ìgbẹ́kẹ̀lé ìjìnlẹ̀ nínú Ọlọ́run wá, ẹnití ìmọ̀ rẹ̀ pé!”21 Àní ní àwọn àkókò rúdurùdu, ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì jẹ́ ìlara àti agbára àìyípadà. Ó nṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa nípa yíyẹ àwọn ohun ìdíwọ́ tí kò ṣe pàtàkì wò kíníkíní. Ó gbà wá níyànjú láti máa tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú náà. Ìgbàgbọ́ ntari nípasẹ̀ ìrẹ̀wẹ̀sì àti gbà wá láàyè láti dojúkọ ọjọ́ iwájú pẹ̀lu ìpinnu àti àwọn èjìká onígun mẹ́rin. Ó nṣí wa létí láti bèèrè fún ìgbàlà àti ìrànlọ́wọ́ bí a ṣe ngbàdúrà sí Baba ní orúkọ Ọmọ Rẹ̀. Àti pé nígbàtí ó bá dàbí ẹnipé a gba ìdáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ àdúrà, títẹramọ́ ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì nmú sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, àti agbára jáde láti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni:

“A kò nílò láti jẹ́ kí àwọn ìbẹ̀rù wa rọ́pò ìgbàgbọ́ wa. A le dojúko àwọn ìbẹ̀rù wọ̀nnì nípa fífún ìgbàgbọ́ wa lókun.

“Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ. … Jẹ́ kí wọn nímọ̀lára ìgbàgbọ́ rẹ, àní nígbàtí àwọn àdánwò líle bá dé bá ọ. Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ dojúkọ olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Olúwa Jésù Krístì. … Kọ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìrin iyebíye kọ̀ọ̀kan pé ọmọ Ọlọ́run ni, tí a ṣẹ̀dá ní àwòrán Rẹ̀, pẹ̀lú èrèdí mímọ́ àti agbára. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni a bí pẹ̀lú àwọn ìpènijà láti borí àti ìgbàgbọ́ láti ní ìdàgbàsokè. ”

Láìpẹ́ mo gbọ́ tí àwọn ọmọ ọdún mẹ́rin méjì ṣe àbápín ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésú Krístì nígbàtí wọ́n dáhùn sí ìbéérè “Báwo ni Jésù Krísti ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́?” Ọmọ àkọ́kọ́ sọ pé, “Mo mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn mi nítorí Ó kú fún mi. Bákannáà ó fẹ́ràn àwọn àgbàlagbà.” Ọmọ kejì sọ pé, “Ó nràn mí lọ́wọ́ nígbàtí mo bá ní ìbànújẹ́ tàbí ìgbóná ara. Bákannáà ó nran mi lọ́wọ́ nigbati mo bá nrì.”

Jésù kéde, “Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpíwàdà tí ó sì tọ̀ mí wá bí ọmọdé, òun ni èmi ó gbà, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.”24

“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráiyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”25

Láìpẹ́, Ààrẹ Nelson ṣèlérí “wípé ìdínkù ẹ̀rù àti púpọ̀si igbagbọ yóò tẹ̀le” bí àwa bá “bẹ̀rẹ̀ lọ́tun nítòótọ́ láti gbọ́, fetísí, ati kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ Olugbala. ”

Àwòrán
Jèsù nmú òkun dákẹ̀rọ́rọ́.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, awọn ipò ìpèníjá wa lọ́wọ́lọ́wọ́ kii ṣe ìkẹhìn opin ayeraye wa. Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, a ti gba orúkọ Jésù Krístì lé orí wa nípasẹ̀ májẹ̀mú. A ní ìgbàgbọ́ nínú agbára ìràpadà Rẹ̀ àti ìrètí nínú àwọn ìlérí nlá iyebíye Rẹ̀. A ní gbogbo ìdí láti yọ̀, nítorí Olúwa àti Olùgbàlà wa ní ìfura gan an nípa àwọn ìṣòro wa, àwọn àníyàn, àti àwọn ìkoro wa. Bí Jésù ti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní ìgbàanì, Ó wa ninu ọkọ oju-omi wa! Ó ti fi ẹ̀mi Rẹ̀ fúnni kí ìwọ àti èmi kí o má bàá ṣègbé. Kí a lè gbẹ́kẹ̀le E, pa òfin Rẹ̀ mọ́, àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́ gbọ́ Ọ tí ó nsọ pé, “Alafia, dakẹ jẹ́.” Ní orúkọ ọlọ́wọ̀ àti mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.