Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àlàáfíà ti Krístì Mú Ìṣọ̀tá Kúrò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Àlàáfíà ti Krístì Mú Ìṣọ̀tá Kúrò

Nígbàtí ìfẹ́ Krístì bá yí ìgbé ayé wa ká, a ó yanjú àwọn èdèàìyedè pẹ̀lú inútútù, sùúrù, àti inúrere.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ìgbà ìdánwò wàhálà ìdárayá kan, iye iṣẹ́ ṣiṣe ti ọkàn npọ̀ si. Àwọn ọkàn tí ó lè rìn lè tiraka láti ṣe àtìlẹhìn àwọn ìbèère sísáré gun òkè. Ní ọ̀nà yí, ìdánwò wàhàlà lè fi àrùn abẹ́lẹ̀ tí kì bá ti hàn bíbẹ́ẹ̀kọ́. Ọ̀ran kankan tí a bá yẹ̀wò nígbànáà lè di wíwòsàn ṣíwájú kí wọ́n tó fa ìdàmú líle nínú igbé-ayé ojojúmọ́.

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 dájúdájú ti jẹ́ ìdánwò wáhálà gbogbo ayé! Ìdánwò náà ti fi àwọn àbájáde onírurú hàn. Àwọn abẹ́rẹ́-àjẹsára tí kò léwu tí ó sì múna-dóko ni a ti gbé-jáde.1 Àwọn amòye oníṣègùn òyìnbó, olùkọ́ni, olùtọ́jú, àti àwọn míràn ti ṣèrúbọ alákọni—wọ́n sì ntẹ̀síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ti fi ìnúrere ati ìwàrere hàn ní gbangba—wọ́n sì ntẹ̀síwájù láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn àìdára abẹ́lẹ̀ ti farahàn. Àwọn olúkúlùkù tó-faragbá jìyà—wọ́n sì ntẹ̀síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹnití wọ́n nṣiṣẹ́ láti yanjú àwọn àìbáradọ́gbà abẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ni a níláti gbà-níyànjú kí a sì ṣọpẹ́ fún.

Àjàkálẹ̀-àrùn bákannáà jẹ́ ìdánwò wàhálà ti-ẹ̀mí fún Ìjọ Olùgbàlà àti àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀. Àwọn àbájáde bákannáà jẹ́ onírurú. Àwọn ìgbé-ayé wa ti di alábùkúnfún nípa ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ ní “ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù,”2 ìwé Wá, Tẹ̀lé Mi àti ikẹkọ ìhìnrere gbùngbun-ilé, Àtilẹhìn-Ìjọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti pèsè ìrànlọ́wọ́ àánú àti ìtùnú ní àkokò àwọn ìṣòrò wọ̀nyí wọ́n sì ntẹ̀síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀.1

Síbẹ̀síbẹ̀, ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀, wàhálà ti-ẹ̀mí fi àwọn ìkúndùn síwájú ìjà àti yíyapa hàn. Èyí da àwọn àbá pé a ní iṣẹ́ láti ṣe láti yí ọkàn wa padà láti wà ní ìrẹ́pọ̀ bí ọmọẹ̀hìn òtítọ́ Olùgbàlà. Èyí kìí ṣe ìpènijà titun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọkàn tí ó le.2

Nígbàtí Olùgbàlà bẹ àwọn ará Néfì wò, Ó kọ́ni pé, “Kò gbọ́dọ̀ sí èdèàìyedè kankan ní àárin yín. … Ẹnití ó bá ní ẹ̀mí ìjà kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe bàbá asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú.”3 Nígbàtí a bá bá ara wa jà nínú ìbínú, Sátánì nrẹrin àti pé Ọlọ́run ti ọ̀run nsọkún.4

Sátánì nrẹrin àti pé Ọlọ́run nsọkún fún ó kéréjù èrèdí méjì. Àkọ́kọ́, ìjà nmú àìlera bá ẹ̀rí wa lápapọ̀ sí ayé Jésù Krístì àti ìràpadà tí ó nwá nípasẹ̀ Rẹ̀ “èrè, … àánú, àti oore-ọ̀fẹ́.”5 Olùgbàlà wípé: “Òfin titun ni Mo fi fún yín, Pé kí ẹ fẹ́ràn ẹnìkejì yín. … Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”6 Bákannáà ìsọ̀rọ̀ náà jẹ́ òtítọ́—gbogbo ènìyàn mọ̀ pé a kìí ṣe ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ nígbàtí a kò bá fi ìfẹ́ hàn sí arawa. Iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn Rẹ̀ ni a sọ di àdàlù nígbàtí ìjà tàbí ìṣọ̀tá7 bá wà ní àárín àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀.8 Èkejì, ìjà jẹ́ àìlókun ti-ẹ̀mí fún wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. A pàdánù àlàáfíà, ayọ̀, àti ìsimi, àti agbára wa láti ní ìmọ̀lára pé Ẹ̀mí ti bàjẹ́.

Jésù Krístì ṣe àlàyé pe ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kìí ṣe “láti rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn; ṣùgbọ́n [pé ẹ̀kọ́ Rẹ̀] [ni] kí a mú irú ohun wọnnì kúrò.”9 Bí èmi bá yára láti bínú tàbí fèsì sí èrò yíyàtọ̀ nípa bíbínú tàbí dídájọ́, èmi ó “kùnà” ìdánwò wàhálà ti ẹ̀mí. Ìkùnà ìdánwò yí kò túmọ̀ sí pé èmi kò nírètí. Dìpo-bẹ́ẹ̀, ó tọ́ka pé mo nílò láti yípadà. Ìyẹn sì dára láti mọ̀.

Lẹ́hìn ìbẹ̀wò Olùgbàlà sí àwọn Amẹ́ríkà, àwọn ènìyàn ní ìrẹ́pọ̀; “kò sí ìjà ní gbogbo ilẹ̀ náà.”10 Njẹ́ o lérò pé àwọn ènìyàn náà ní ìrẹ́pọ̀ nítorí gbogbo wọ́n jẹ́ ọ̀kannáà, tàbí nítorí wọn kò ní èrò yíyàtọ̀? Mo níyèméjì rẹ̀. Dípò-bẹ́ẹ̀, ìjà àti ikorira sálọ nítorí wọ́n gbé jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wọn nípa Olùgbàlà ṣíwájú ohungbogbo. Àwọn ìyàtọ̀ wọn dínkù ní àfiwé sí ìfẹ́ tí wọ́n pín nípa Olùgbàlà, wọ́n sì ní ìrẹ́pọ̀ bí “àwọn ajogún ìjọba Ọlọ́run.”11 Èsì náà ni pé “kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ … ẹnití a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá rí”12

Ìrẹ́pọ̀ nfẹ́ ìgbìyànjú.13 Ó ngbèrú nígbàtí a bá tọ́jú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ọkàn wa14 tí a sì dojúkọ àyànmọ́ ayérayé wa.15 A ní ìrẹ́pọ̀ nípa kókó, ìwọ́pọ̀ ìdánimọ̀ wa bí àwọn ọmọ Ọlọ́run16 àti ìfarasìn sí àwọn òtítọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere. Nígbànáà, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn Jẹ́sù Krístì nmú àníyàn tòótọ́ jáde fún àwọn ẹlòmíràn. A mọ iyi rírí-ẹwà ìwà àwọn ẹlòmíràn, ìrísí, àti àwọn ọrẹ.17 Bí a kò bá lè gbé jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn wa sí Jésu ga ju ìfẹ́ araẹni àti ìwòye lọ, a gbọ́dọ̀ tún àwọn ohun-ààyò wa yẹ̀wò kí a sì yípadà.

A le fẹ́ láti wípé, “Bẹ́ẹ̀ni a lè ní ìrẹ́pọ̀—bí ìwọ ó bá gbà pẹ̀lú mi!” Ọ̀nà dídára ni láti bèèrè, “Kíni mo lè ṣe láti mú ìrẹ́pọ̀ wá? Báwo ni mo ṣe lè ran ẹni yí lọ́wọ́ láti súnmọ́ Krístì síi? Kíni mo lè ṣe láti dín ìjà kù àti láti gbé Ìjọ ìletò àánú àti ìtọ́jú kan sókè?”

Nígbàtí ìfẹ́ Krístì bá yí ìgbé ayé wa ká,18 a ó yanjú àwọn èdèàìyedè pẹ̀lú inútútù, sùúrù, àti inúrere.19 A ó dínkù nínú ìdámú nípa ìkanra ti arawa àti púpọ̀ sí aladugbo wa. A “nlépa láti ṣe ìwọ̀ntún-wọ̀nsì àti ìrẹ́pọ̀.”20 A ko sí ní ṣíṣẹ́ nínú “àwọn àríyànjiyàn iyèméjì,” ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ẹnìtí a ní èdèàìyedè, tàbí gbìyànjú láti mú kí wọ́n kọsẹ̀.21 Dípò-bẹ́ẹ̀, a ròó pé àwọn wọnnì pẹ̀lú ẹnití a ní èdèàìyedè nṣe dídárajùlọ tí wọ́n lè ṣe pẹ̀lú àwọn ìrírí ayé tí wọ́n ní.

Ìyàwó mi ṣiṣẹ́ òfin fún ogún ọdún ó lé. Bí agbẹjọ́rò, ó nṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn léraléra tí wọ́n nṣe èrò àgbàwí àtakò kedere. Ṣùgbọ́n ó kẹkọ láti ṣe èdè-àìyede láìsí àrífín tàbí ìbínú. Ó lè sọ fún amọ̀ràn alátakò pé, “Mo lè ri pé a kò lè baradọ́gba lórí ọ̀ràn yí. Mo fẹ́ràn rẹ. Mo bọ̀wọ̀ fún èrò rẹ. Mo ní ìrètí pé o lè fún mi ní àpọ́nlé kannáà.” Nígbàkugbà èyí nfi àyè gba ìbáramu ọ̀wọ̀ àní àti ìbáṣọ̀rẹ́ bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ní àwọn ìyàtọ̀.

Àní àwọn ọ̀tá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ lè di ìrẹ́pọ̀ nínú jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn ti Olùgbàlà wọn.22 Ní 2006, mo lọ sí ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Helsinki Finland láti bu-ọlá fún baba mi àti àwọn òbí àgbà, tí wọ́n ti jẹ́ olùyípada ìṣíwájú sí Ìjọ ní Finland. Àwọn Finn, pẹ̀lú baba mi, ti lá àlá nípa tẹ́mpìlì ní Finland fún àwọn díkédì. Ní àkokò náà, Tẹ́mpìlì Ẹ̀kùn yíò wà pẹ̀lú Finland, Estonia, Latvia, Lithuania, Belarus, àti Russia.

Níbi ìyàsímímọ́, mo kọ́ ohunkan tí ó yanilẹnu. Ọjọ́ àkọ́kọ́ ti ìṣe gbogbogbò ni a ti gbé sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ìjọ láti ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì. Ó sì le láti ṣe alàyé lásán bí èyí ṣe yanilẹ́nu sí. Russia àti Finland ti ja àwọn ogun púpọ̀ ní àwọn sẹ́ntúrì pípẹ́. Baba mi kò ṣe aláìní-ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Russia nìkan ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ara Russia. Ó ti fi ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ hàn tifẹ́tìfẹ́, àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ sì ti jọra nípa ikorira Finnish sí Russia. Ó ti kọ́ ewì àkọ́sórí àpọ̀jù tí ó mú ogun sẹ́ntúrì mọ́kàndínlógún wá ní àárín àwọn Finns àti Russia. Àwọn ìrírí rẹ̀ ní ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, nígbàtí Finland àti Russia tún ntakora wọn lẹ́ẹ̀kansi, ko ṣe ohunkóhun láti yí àwọn èrò rẹ̀ padà.

Ọdún kan ṣíwájú ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Helsinki Finland, ìgbìmọ̀ tẹ́mpìlì, tí ó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ìjọ Finnish nìkan, pàdé láti sọ̀rọ̀ àwọn ètò fún ìyàsímímọ́. Ní ìgbà ìpàdé náà, ẹnìkan ṣe àkíyèsí pé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Russia yíò rin ìrìnàjò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láti lọ sí ìyàsímímọ́ àti pé wọn lè ní ìrètí láti gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì ṣíwájú pípadà sílé. Alága ìgbìmọ̀, Arákùnrin Sven Eklund, daba pé kí àwọn Finn dúró díẹ̀, kí àwọn Russia jẹ́ ọmọ-ìjọ àkọ́kọ́ láti ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì nínú tẹ́mpìlì. Gbogbo àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ gbà. Àwọn Olootọ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn sún àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì tiwọn síwájú láti fàyè gba àwọn ènìyàn mìmọ́ Russia.

Ààrẹ Agbègbè ẹnití ó wà níbi ìgbìmọ̀ ìpàdé tẹ́mpìlì, Alàgbà Dennis B. Neuenschwander, kọ lẹ́hìnwá pé: “Èmi kò tíì ní ìgbéraga ju nípa àwọn Finn rí ju bí mo ti ní ní àkokò yí. Àkọsílẹ̀-ìtàn ìṣòro Finland pẹ̀lú aladugbo ìlà-oòrùn rẹ̀ … àti ìwúrí wọn nípa níní [tẹ́mpìlì kan] tí a kọ́ ní orí ilẹ̀ arawọn ni wọ́n gbé sẹgbẹ pátápátá. Gbígba àwọn Russia láyè láti kọ́kọ́ wọnú tẹ́mpìlì [ni] ẹ̀là-ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àti ìrúbọ.”23

Nígbàtí mo ròhìn inúrere yí sí baba mi, ọkàn rẹ̀ rọ̀ ó sì sọkún, ìṣẹ̀lẹ̀ kan gan tó ṣọ̀wọ́n fún akọni Finn náà. Láti àkokò náà lọ títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọdún mẹ́ta lẹ́hìnnáà, òun kò fi ìtara òdì míràn hàn nípa Russia. Níní ìmísí nípa àpẹrẹ ẹnikeji rẹ̀ àwọn Finn, baba mi yàn láti gbé ipò-ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì rẹ̀ ga ju gbogbo àwọn èrò míràn lọ. Àwọn Finn kò dínkù ju Finish; àwọn Russia kò dínkù ju Russian; kò sí ẹgbẹ́ tí ó pa ọ̀làjú wọn, àkọsílẹ̀-ìtàn, tàbí ìrírí ti láti mú ikorira kúrò. Wọn kò níláti ṣe. Dípò-bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti mú jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì wọn jẹ́ kókó èrò.24

Bí wọ́n bá lè ṣe é, àwa náà lè ṣe. A lè mú ìjogún wa, ọ̀làjú, àti àwọn ìrírí wá sí Ìjọ Jésù Krístì. Sámúẹ́lì kò tijú kúrò nínú ìjogún rẹ̀ bí ará Lámánì,25 tàbí kí Mọ́mọ́nì tijú kúrò nínú tirẹ̀ bí ará Néfì.26 Ṣùgbọ́n ọ̀kọ̀ọ̀kan gbé ipò-ọmọẹ̀hìn rẹ̀ ti Olùgbàlà ṣíwájú.

Bí a kò bá jẹ́ ọ̀kan, a kìí ṣe Tirẹ̀.27 Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ akíkanjú ní gbígbé ìfẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà ga ju gbogbo àwọn èrò míràn.28 Ẹ jẹ́ kí a di májẹ̀mú tí ó wà nínú ipò-ọmọẹ̀hìn mú—kí májẹ̀mú náà jẹ́ ọ̀kannáà.

Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé àpẹrẹ àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti àyíká ayé tí wọ́n tí fi àṣeyege di àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì. A lè gbáralé Jésù Krístì, ẹnití ó jẹ́ “àlàáfíà wa, ẹnití ó … ti já ògiri odi àárín wa sílẹ̀; ní pípa ìṣọ̀tá rẹ́ nínú [ètùtù ìrúbọ] rẹ̀.”29 Ẹ̀rí wa nípa Jésù Krístì sí ayé yíò lókun, a ó sì dúró nínú ìlera ti ẹ̀mí.32 Mo jẹri pé bí a ti “npa ìjà ti” tí à ndi “irúkannáà pẹ̀lú Olúwa nínú ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,” Àláfíà Rẹ̀ yíò jẹ́ tiwa.33 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo “The First Presidency Urges Latter-day Saints to Wear Face Masks When Needed and Get Vaccinated Against COVID-19,” Newsroom, Aug. 12, 2021, newsroom.ChurchofJesusChrist.org; “Vaccines Explained,” World Health Organization, who.int/emergencies/diseases/novel-coronavirus-2019/covid-19-vaccines/explainers; “Safety of COVID-19 Vaccines,” Centers for Disease Control and Prevention, Sept. 27, 2021, cdc.gov/coronavirus/2019-ncov/vaccines/safety/safety-of-vaccines.html; “COVID-19 Vaccine Effectiveness and Safety,” Morbidity and Mortality Weekly Report, Centers for Disease Control and Prevention, cdc.gov/mmwr/covid19_vaccine_safety.html.

  2. Russell M. Nelson, “Sisters’ Participation in the Gathering of Israel,” Liahona, Nov. 2018, 69.

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 81:5.

  4. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpóstélì àti wòlíì ti yanjú irẹ́pọ̀ àti ìjà ní àwọn ọdún pípẹ́. Fún àpẹrẹ, wo, Marvin J. Ashton, “No Time for Contention,” Ensign, May 1978, 7–9; Marion G. Romney, “Unity,” Ensign, May 1983, 17–18; Russell M. Nelson, “The Canker of Contention,” Ensign, May 1989, 68–71; Russell M. Nelson, “Children of the Covenant,” Ensign, May 1995, 32–35; Henry B. Eyring, “That We May Be One,” Ensign, May 1998, 66–68; D. Todd Christofferson, “Come to Zion,” Liahona, Nov. 2008, 37–40; Jeffrey R. Holland, “The Ministry of Reconciliation,” Liahona, Nov. 2018, 77–79; Quentin L. Cook, “Hearts Knit in Righteousness and Unity,” Liahona, Nov. 2020, 18–22; Gary E. Stevenson, “Hearts Knit Together,” Liahona, May 2021, 19–23.

  5. 3 Néfì 11:28-29.

  6. Wo Mósè 7:26, 28, 33. Èyí kò dá àbá pé ẹbọ èyùtù Olùgbàlà nlọ lọ́wọ́ tàbí pé Òun ntẹ̀síwájú láti jìyà, Jésù Krístì ti parí Ètùtù. Bákannáà, ìyọ́nú àti àánú pípé tí Òun gbà bí àbájáde píparí ẹbọ ètùtù Rẹ̀ fi ààyè gba Á láti ní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́.

  7. 2 Néfì 2:8.

  8. Jòhánnù 13:34, 35.

  9. Ìkórira ni ipò tàbí níní-ìmọ̀ títakò taratara sí ẹnìkan tàbí ohunkan; Ó fi ìlara, ìtakò, ìṣọ̀tẹ̀, ìjà, àti àìfẹ́ràn jíjìnlẹ̀-pipẹ́ tàbí ìfẹ́-ibi hàn. Ọ̀rọ̀ Greek tí a yípadà bí “ìṣọ̀tá” bákannáà ni a yípadà bí “ìkóríra.” Ó jẹ́ òdìkejì ti ìfẹ́ni, èyí tí a yípadà bí “ìfẹ́.” Wo James Strong, The New Strong’s Expanded Exhaustive Concordance of the Bible (2010), Greek dictionary section, number 2189.

  10. Wo Jòhánnù 17:21, 23.

  11. 3 Nèfì 11:30.

  12. 4 Néfì 1:18.

  13. 4 Néfì 1:17.

  14. 4 Néfì 1:16.

  15. Ààrẹ Russell M. Nelson has said, “The Lord loves effort” (in Joy D. Jones, “An Especially Noble Calling,” Liahona, May 2020, 16).

  16. Wo 4 Néfì 1:15. Àwọn tí ó ti ṣaṣeyege irú ìrẹ́pọ̀ yí wà. Ní ọjọ́ Enọ́kù, “Olúwa sì pè àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nitorí wọ́n wà ní ọkàn kan àti inú kan, wọ́n sì gbé nínú òdodo; kò sì sí òtòṣì kankan ní àárín wọn”(Mósè 7:18

  17. Wo Mòsíàh 18:21.

  18. Wo Ìṣe Àwọn Àpóstélì 17:29; Psalmù 82:6.

  19. Wo 1 Kọ́ríntì 12:12-27.

  20. Wo Mórónì 7:47–48.

  21. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:30–31.

  22. Dallin H. Oaks, “Defending Our Divinely Inspired Constitution,” Liahona, May 2021, 107.

  23. Wo Romu14:1- 3, 13, 21.

  24. Olùgbàlà criticized His “disciples, in days of old, [who] sought occasion against one another and forgave not one another in their hearts; and for this evil they were afflicted and sorely chastened. Wherefore,” Jesus admonished His latter-day disciples, “I say unto you, that ye ought to forgive one another” (Doctrine and Covenants 64:8–9).

  25. Alàgbà Dennis B. Neuenschwander, personal communication.

  26. Ní a typical Finnish fashion, when Brother Eklund discussed this decision, he said it was simply logical. Dípò yiyin Finns’ magnanimity, he expressed appreciation for the Russians. Àwọn Finns were grateful for the significant contribution of the Russians to the work being done in the Helsinki Finland Temple. (Sven Eklund, personal communication.)

  27. Wo Hẹ́lámánì 13:2, 5.

  28. Wo 3 Néfì 5:13, 20.

  29. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:27.

  30. Wo Lúkù 14:25-33.

  31. Efesu 2:14-15.

  32. Wo Éfésù 2:19.

  33. Wo Russell M. Nelson, “Arànkàn ti Ìjà,” Ensign, May 1989, 71.