Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Òtitọ́ Mímọ́, Ẹkọ́ Mímọ́, àti Ìfihàn Mímọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Òtitọ́ Mímọ́, Ẹkọ́ Mímọ́, àti Ìfihàn Mímọ́

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìpàdé àpapọ̀ yí ní àkókò ti ṣíṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ lati ọ̀dọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé gbogbogbò! Ó ti jẹ́ ayọ̀ tó láti wà pẹ̀lú yín! Ẹ ti wà lọ́kàn mi ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ léraléra ninú àwọn oṣù mẹ́fà tó kọjá. Èmi ti gbàdúrà nípa yín àti fún yín. Nínú àwọn ọ̀sẹ̀ àìpẹ́ yi mo ti gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí ìpàdé àpapọ̀ yi jẹ́ àkókò ìrònú àti ìfihàn fún gbogbo àwọn ẹnití wọ́n nlépa àwọn ìbùkún wọnnì.

A ní ìdùnnú láti máa báa yín sọ̀rọ̀ láti Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi. Púpọ̀jù àwọn ìjókòó ṣì wà ní òfo, ṣùgbọ́n wíwà níhĩn díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Akọrin Àgọ́ jẹ́ ìgbésẹ̀ ìyanu kan síwájú. A kí gbogbo yín káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ yí tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ti ẹrọ kọ̀mpútà tán, níbi gbogbo tí ẹ wà.

A ṣì nṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìparun ti COVID-19 àti àwọn àìrẹ́pọ̀ rẹ̀. A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún títẹ̀lé ìmọ̀ràn wa àti ìmọ̀ràn àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn òyínbó àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní àwọn agbègbè tiyín.

A npe ìjóko ìpàdé àpapọ̀ kọ̀ọ̀kan bí a bá ti darí wa láti ọwọ́ Olúwa.1 Ìjokòó náà ti yàtọ̀ bí àwọn ọdún ṣe nkọjá Nígbàtí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ gan, ìpàdé àpapọ̀ máa ngùn tó ọjọ́ mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Lẹ́hìnwá, ìpàdé àpapọ̀ jẹ́ dídínkù sí ọjọ́ méjì. Gbogbo ọ̀rọ̀ sísọ—nígbànáà àti nísisìyí—jẹ́ àbájáde àdúrà pẹ̀lú ìtara àti ìpalẹ̀mọ́ púpọ̀ ní ti ẹ̀mí.

Àwọn Aláṣẹ gbogbogbò àti àwọn Olóye Gbogbogbò ti Ìjọ tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ yío mú ọ̀rọ̀ wọn dá lé orí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àánú Rẹ̀, àti agbára ìranipadà Rẹ̀ tí kò lópin. Kò tíì sí àkókò kan láé nínú ìtàn àgbáyé nígbàtí ìmọ̀ Olùgbàlà wa jẹ́ kókó àti wíwúlò ti ara-ẹni sí gbogbo ọkàn ènìyàn. Ẹ fi ojú inú wo bí àwọn ìjà bíbanilẹ́rù káàkiri àgbáyé—àti àwọn wọnnì nínú ìgbé ayé olukúlùkù wa—yío ti jẹ́ yíyanjú bí ẹni gbogbo bá yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì tí wọ́n sì gbọ́ràn sí àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.

Nínú ẹ̀mí náà, mo pè yín láti tẹ́tísílẹ̀ fún àwọn ohun mẹ́ta kan nínú ìpàdé àpapọ̀ yí: òtítọ́ mímọ́, ẹ̀kọ́ mímọ́ ti Krístì, àti ìfihàn mímọ́. Ní ìlòdì sí àwọn ìyèméjì ti àwọn kan, irú nkan bíi títọ́ àti àṣìṣe nítòótọ́. Òtítọ́ pípé—òtítọ́ ayérayé nítòótọ́. Ọ̀kan nínú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ti ìgbà tiwa ni pé àwọn ènìyàn tó kéré púpọ̀ ní iye ni wọ́n mọ ibití wọ́n le yà sí fún òtítọ́.2 Mo le fi dáa yín lójú pé ohun tí ẹ ó gbọ́ lóni àti lọ́la fi ìdí òtítọ́ mímọ́ múlẹ̀.

Ẹkọ́ mímọ́ ti Krístì kún fún agbára. Ó nṣe àyípadà ìgbé ayé olukúlùkù ẹnití ó ní òye rẹ̀ tí ó sì nlépa láti mú un lò. Ẹkọ́ Krístì nrànwá lọ́wọ́ láti rí àti láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Dídúró nínú ipa ọ̀nà tóóró ṣùgbọ́n tí a ṣe àlàyé rẹ̀ dáradára náà yío mú wa yẹ nígbẹ̀hìn láti gba gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní.3 Kò sí ohun tí ó le níyì síi ju gbogbo ohun tí Baba wa ní!

Ní ìparí, ìfihàn mímọ́ fún àwọn ìbéèrè inú ọkàn yín yío mú ìpàdé àpapọ̀ yí jẹ́ èyítí ó ní èrè àti mánigbàgbé. Bí ẹ kò bá tíì lépa fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Ẹmí Mímọ́ láti ràn yín lọ́wọ́ láti gbọ́ ohun tí Olúwa fẹ́ kí ẹ gbọ́ láàrin àwọn ọjọ́ méjì wọ̀nyí, mo pè yín láti ṣe bẹ́ẹ̀ nísisìyí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìpàdé àpapọ̀ yí ní àkókò ti ṣíṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ lati ọ̀dọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ kọ́ bí ẹ ó ti mú wọn lò nínú ayé yín.

Èyí ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwa ni ènìyàn májẹ́mu Rẹ̀. Olúwa ti kéde pe Òun yío mú iṣẹ́ Rẹ̀ yára ní àkókò rẹ̀,4 Òun sì nṣe bẹ́ẹ̀ ní ìgbésẹ̀ tí nlékún síi títí. A ní ànfàní láti kópa nínú iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀.

Mo pe ìbùkún kan sí orí gbogbo àwọn tí wọ́n nwá ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, àti òtítọ́ nlá síi. Mo fi ìfẹ́ mi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín hàn, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.