Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ ti Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ìfẹ́ ti Ọlọ́run

Baba wa àti Olùràpadà wa ti bùkún wa pẹ̀lú àwọn òfin, àti ní gbígbọ́ran sí àwọn òfin Wọn, a nní ìmọ̀lára ifẹ́ pípé Wọn níkíkún àti jíjinlẹ̀ síi.

Baba wa Ọ̀run nifẹ wa jinjlẹ̀jinlẹ̀ àti ní pipé.1 Nínú ìfẹ́ Rẹ̀, Ó dá ètò kan sílẹ̀, ètò ìràpadà àti ìdùnnú kan láti ṣí gbogbo àwọn ànfàní àti ayọ̀ tí à nfẹ́ láti gba fún wa, títí dé àti pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní àti tí ó jẹ́.2 Láti ṣe àṣeyege èyí, Òun tilẹ̀ nfẹ́ láti fi Olùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ fúnni, bí Olùràpadà wa. “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”3 Tirẹ̀ ni ìfẹ́ mímọ́ ti baba—káàkiri sí ẹni-gbogbo, síbẹ̀síbẹ̀ ti-araẹni sí ẹnìkọ̀ọ̀kan.

Jésù Krístì pín irú ìfẹ́ pípé bákannáà pẹ̀lú baba. Nígbànáà Baba kọ́kọ́ ṣe ètò ìdùnnú Rẹ̀ yékéyéké, Ó pe ọ̀kan láti ṣe-ìṣe bí Olùgbàlà kan láti rà wá padà—pàtàkì ara ẹ̀tò kan náà. Jésù dáhùn, “Èmi nìyí, rán mi.”4 Olùgbàlà “kò ṣe ohunkóhun láì jẹ́ fún èrè gbogbo ayé; nítorí ó fẹ́ aráyé, àní tí ó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorínáà, òun kò pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé wọn kì yío ní ìpín nínú ìgbàlà rẹ̀.”6

Ìfẹ́ tọ̀run yí níláti fún wa ní ọ̀pọ̀ ìtùnú àti ìgbẹ́kẹ̀lé bí a ti ngbàdúrà sí Baba ní orúkọ Krístì. Kò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa tí ó jẹ́ àjèjì sí Wọn. A kò níláti lọ́ra láti ké pé Ọlọ́run, àní nígbàtí a nní ìmọ̀lára àìyẹ. A lè gbáralé àánú àti èrè Jésù Krístì láti gbọ́ wa.8 Bí a bá sì wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó dúró ní ìdínkù àti ìdínkù lórí àṣẹ àwọn ẹlòmíràn làti tọ́wasọ́nà.

Ìfẹ́ ti Ọlọ́run Kìí Gba Ẹ̀ṣẹ̀ Láàyè; Ṣùgbọ́n, Ó Nfúnni Ní Ìràpadà

Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ìkámọ́ni-gbogbo, àwọn kan sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí “àìdiwọ̀n,” àti pé nínú wọn wọ́n lè lérò láti túmọ̀ sí pé àwọn ìbùkún Ọlọ́run jẹ́ “àìdíwọ̀n,” àti pé ìgbàlà jẹ́ “àìdíwọ̀n.” Wọn kò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn kan fẹ́ sọ pé, “Olùgbàlà nifẹ mi bí mo ti wà,” ìyẹn sì jẹ́ òtítọ́ dájúdájú. Ṣùgbọ́n Òun kò lè mú ẹnikẹ́ni lára wa lọ sínú ìjọba Rẹ̀ bí a ti wà, “nítorí ohun àìmọ́ kankan kò lè gbé níbẹ̀, tàbí gbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.”9 Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ wa ní a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yànjú.

Amọ̀ye Hugh Nibley ṣàkíyèsí nígbàkan pé ìjọba Ọlọ́run kò lè nífaradà àní bí ó bá faramọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kékeréjùlọ: “Àmì ìbàjẹ́ tíntínjùlọ túnmọ̀ sí pé ayé míràn kò ní jẹ́ àìbàjẹ́ tàbí ayérayé. Àṣíṣe kíkéré jùlọ, ilé-ẹ̀kọ́, àmì, tàbí ìwà yíò jẹ́wọ́ èyítí ó lóró ní ìgbà-pípẹ́ ayérayé.”10 Àwọn òfin Ọlọ́run jẹ́ “líle”11 nítorí ìjọba Rẹ̀ àti àwọn ọmọ-orílẹ̀-èdè rẹ̀ lè dúró nìkan bí wọ́n bá kọ ibi lemọ́lemọ́ tí wọ́n sì yan rere, láìsí ìyàtọ̀.12

Alàgbà Jeffrey R. Holland ṣàkíyèsí pé, “Jésù ní òye kedere ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti gbàgbé nínú ọ̀làjú òde-òní: pé ìyàtọ̀ pàtàkì wà ní àárín òfin láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì (èyítí Òun ní agbára àìlópin láti ṣe) àti ìkìlọ̀ ní ìlòdì sí gbígbà á mọ̀ra (èyítí Kò ṣe rí àní fún ìgbàkan).”13

Pẹ̀lú àwọn àìpé wa lọ́wọ́lọ́wọ́, bákannáà, a ṣì lè ní ìrètí láti débi “orúkọ kan àti ìdúró kan,”14 ibì kan, nínú Ìjọ Rẹ̀ àti nínú ayé sẹ̀lẹ́stíà. Lẹ́hìn mímu hàn kedere pé Òun kò lè fàyè gbà tàbí ṣẹ́jú lórí ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa mu dá wa lójú pé:

“Bíótilẹ̀rìbẹ́ẹ̀, ẹnití ó bá ronúpìwàdà tí ó sì pa àwọn òfin Olúwa mọ́ yíò gba ìdáríjì.”13

“Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ènìyàn mi bá ronúpìwàdà ní èmi yíò dárí gbogbo ìrékọjá wọn sí mi jì wọ́n.”16

Ìrònúpìwàdà àti oore-ọ̀fẹ́ tọ̀run yanjú ìdààmú náà.

“Bákannáà ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ámúlẹ́kì sọ fún Sísrọ́mù, nínú ìlú-nlá Amonáíhà; nítorítí ó wí fún un pé Olúwa mbọ̀ dájúdájú láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ṣùgbọ́n kò lè wá láti rà wọ́n padà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n láti rà nwọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

“À sì ti fi agbára fún un láti ọ̀dọ̀ Baba láti rà wọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìrònúpìwàdà; nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde ìròhìn ayọ̀ nípa ti àwọn ipò ìrònúpìwàdà, èyítí ó mú ènìyàn wá sínú agbára Olùràpadà nã, sí ti ìgbàlà ọkàn wọn.”17

Pẹ̀lú ipò ìrònúpìwàdà,Olúwa lè nawọ́ àánú láìsí mímú ìdáláre kúrò, àti kí “Ọlọ́run máṣe ṣaláìjẹ́ Ọlọ́run mọ́.”16

Ọ̀nà ti ayé, bí ẹ ti mọ̀, ni kòṣe-Krístì, tàbí “ohunkóhun ṣùgbọ́n Krístì.” Ọjọ́ wa jẹ́ títúntẹ̀ àkọsílẹ̀-ìtàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú èyítí àwọn agbára-kan nlépa ìjọba àìṣododo lórí àwọn ẹlòmíràn, ṣe ayẹyẹ ìwé-iṣẹ́ ìbálòpọ̀ , àti gbígbéga ìkójọ ọrọ̀ bí ohun wíwá-láyé wa. Àwọn ìmọ̀ wọn “ṣe ìdáláre ní dídá ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀”18 àní tàbí ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó lè fúnni ní ìràpadà. Ìyẹn nwá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn nìkan. Dídárajùlọ ni “ohunkóhun ṣùgbọ́n Krístì” tàbí “ohunkóhun ṣùgbọ́n ìrònúpìwàdà” àwọn èrò lè fúnni ní gbígbà àìfẹsẹ̀múlẹ̀ pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀, tàbí pé tí ó bà wà, nígbẹ̀hìn kò ní àwọn àbájáde kankan. Èmi kò lè ri kí àríyànjiyàn ní gbígba ọ̀pọ̀ ìsúnkì ní òpin Ìdájọ́.19

A kò ní láti gbìdánwò àìṣeéṣe ní gbígbìyànjú sí yíyọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò. Àti ní ọ̀nà míràn, a kò ní láti gbìdánwò àìṣeéṣe ní nínu àbájáde ti ẹ̀ṣẹ̀ nípa èrè ti arawa nìkan kúrò. Tiwa kìí ṣe ti ẹ̀sìn yíyọkúrò tàbí ẹ̀sìn ní-pípé ṣùgbọ́n ẹ̀sìn kan ti ìràpadà—ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Krístì. Bí a bá wà ní àárín àwọn onírẹ̀lẹ̀, pẹ̀lú Ètùtù Rẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ni a kàn mọ́ àgbélèbú Rẹ̀, àti “pẹ̀lú nínà rẹ ni a wò wá sàn.”19

Ìfẹ́ Ìyọ́nú àwọn Wòlíì Fi Ìfẹ́ Ọlọ́run Hàn

Mo ti ní ìwọnilọ́kàn pípẹ́ nípa, àti bákannáà ní ìmọ̀lára ti ìyọ́nú ìfẹ́ àwọn wòlíì Ọlọ́run nínú àwọn ìkìlọ̀ wọn ní ìlòdì sí ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n kò ní ìwúnilórí nípa ìfẹ́ láti dálẹ́bi. Àwọn ìfẹ́ òtítọ́ wọn fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn; ní òdodo, ó jẹ́ ìfẹ́ ti Ọlọ́run. Wọ́n ní ìfẹ́ àwọn wọnnì sí ẹnití a rán wọn sí, ẹnikẹ́ni tí wọ́n lè jẹ́ àti ohunkóhùn tí wọ́n lè dà bí. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa, àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni jìyà àwọn ìrora ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣàyàn burúkú.20

Álmà ni a rán láti kéde ọ̀rọ̀ ìrònúpìwàdà àti ìràpadà sí àwọn ènìyàn oníríra tí wọ́n nfẹ́ láti ṣe inúnibíni, palára, àní àti láti pa àwọn Krìstẹ́nì onígbàgbọ́, pẹ̀lú Álmà Fúnrarẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ ó nifẹ wọn ó sì ní ìyọ́nú fún ìgbàlà wọn. Lẹ́hìn kíkéde Ètùtù Krístì sí àwọn ènìyàn Ammonihah, Álmà bẹ̀bẹ̀: “Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi nfẹ́ tọkàn-tọkàn, bẹ̃ni, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àníyàn ọkàn títí fi dé ìrora, pé kí ẹ̀yin fi ètí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ̀yin sì fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀; … kí ẹ lè ní ìgbéga ní ọjọ́ ìkẹhìn kí ẹ sì wọnú ìsìmi ti [Ọlọ́run].”21

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Russell M. Nelson, “Ó jẹ́ nítorí a ṣìkẹ́ ìjìnlẹ̀ nípa gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a fi kéde òtítọ́ Rẹ̀.”22

Ọlọ́run Nifẹ Yín; Ṣe Ẹ Nifẹ Rẹ̀?

Ìfẹ́ Baba àti Ọmọ ni a fúnni ní ọfẹ ṣùgbọ́n bákannáà ó wà pẹ̀lú àwọn ìrètí àti ìfojúsọ́nà. Lẹ́ẹ̀kansi, a tún ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson sọ pé, “àwọn òfin Ọlọ́run máa njẹ́ wíwuni tán nipa ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀ fún wa àti ìfẹ́-inú Rẹ̀ fún wa láti di ohun gbogbo tí a bá le dà.”8

Nítorí Wọ́n nifẹ yín, Wọn kò fẹ́ fi yín sílẹ̀ “lásán bí ẹ ti wà.” Nítorí Wọ́n nifẹ yín, Wọ́n fẹ́ kí ẹ ní ayọ̀ àti àṣeyọrí. Nítorí Wọ́n nifẹ yín, Wọ́n fẹ́ kí Ẹ ronúpìwàdà nítorí ìyẹn ni ipá-ọ̀nà sí ìdùnnú. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣàyàn yín—Wọ́n bu-ọlá fún agbára òmìnira yín, Ẹ gbọ́dọ̀ yàn láti nifẹ Wọn, láti sìn Wọ́n, láti pa àwọn òfin Wọn mọ́. Nígbànáà Wọ́n lè bùkún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ bákannáà kí Wọ́n nifẹ yín.

Kókó ìrètí Wọn fún wa ni kí a nifẹ Wọn bákannáà. “Ẹni tí kò bá nifẹ kò mọ Ọlọ́run; nítorí ìfẹ́ ni Ọlọ́run.”24 Bí Jòhánù ti kọ pé, “Olùfẹ́, bí Ọlọ́run bá nifẹ wa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a nifẹ arawa.”28

Ààrẹ Gbogbogbò Alakọbẹrẹ Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ Joy D. Jones rántí pé bí ọ̀dọ́ tọkọ-taya kan, òun àti ọkọ rẹ̀ ni a pè láti bẹ̀wò àti láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí ẹbí kan tí wọ́n kò wá sí ilé-ìjọsìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ó hàn kedere lẹ́sẹ̀lẹsẹ̀ nínú ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ pé a kò fẹ́ wọn. Lẹ́hìn ìjákulẹ̀ ti àfikún àwọn ìkùnà ìgbìyànjú, àti lẹ́hìn ọ̀pọ̀ àdúrà tòótọ́ àti ìjíròrò, Arákùnrin àti Arábìnrin Jones gba ìdáhùn sí ìdí iṣẹ́-ìsìn wọn nínú ẹsẹ yí látinú Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú: “Ìwọ yíò fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo okun rẹ; àti agbára, àti ní orúkọ Jésù Krístì ni ìwọ ó sì sì Ín.29 Arábìnrin Jones wípé:

“A mọ̀ pé à ntiraka lódodo láti sin ẹbí yí àti láti sin bíṣọ́ọ̀pù, ṣùgbọ́n a ní láti bi arawa léèrè bí a bá nsìn lotítọ nínú ìfẹ́ fún Olúwa. …

“… A bẹ̀rẹ̀ sí wo iwájú fún ìbẹ̀wò wa pẹ̀lú ẹbí ọ̀wọ́n yí nítorí ìfẹ́ wa fún Olúwa [wo 1 Néfì 11:22]. A nṣe é fún Un. Ó mú kí ìlàkàkà náà kí ó máṣe jẹ́ ìlàkàkà mọ́. Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oṣù ti dídúró lórí àtẹ̀gún, ẹbí náà bẹ̀rẹ̀ sí njẹ́ kí a wọlé. Nígbẹ̀hìn, a ní àdúrà déédé àti ìbarasọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ ìhìnrere papọ̀. A gbèrú ìbáṣọ̀rẹ́ pípẹ́-títí kan. À njọ́sìn à sì nní ìfẹ́ Rẹ̀ nípa níní ìfẹ́ àwọn ọmọ Rẹ̀.”30

Ní jíjẹ́wọ́ pé Ọlọ́run nifẹ wa ní-pípé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa sì lè bèèrè pe, “Báwo ni mo ṣe nifẹ Ọlọ́run sí? Njẹ́ Òun lè gbáralé ìfẹ́ mi bí mo ṣe lè gbáralé Tirẹ̀?” Ṣe kò ní jẹ́ ìnọ̀gàsí yíyẹ láti gbé ìgbé-ayé nítorínáà kí Ọlọ́run lè ní ìfẹ́ wa kìí ṣe nípa ti àwọn ìkùnà wa lásán ṣùgbọ́n bákannáà nítori ti ohun tí a ndà? Áà, pé Òun lè sọ nípa yín àti èmi bí Òun ti sọ nípa Hyrum Smith, fún àpẹrẹ, “Èmi, Olúwa, nifẹ rẹ̀ nítorí ìwà-titọ́ ọkàn rẹ̀.”31 Ẹ jẹ́ kí a rántí ìkìlọ̀ inúrere ti Jòhánnù: “Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí a pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́: àwọn òfin rẹ̀ kò sì nira.”32

Nítoótọ́, àwọn òfin Rẹ̀ kò nira—ó kàn jẹ́ ìdàkejì Wọ́n tẹ ìpa-ọ̀nà ìwòsàn, ìdùnnú, àláfíà, àti ayọ̀. Baba wa àti Olùràpadà wa ti bùkún wa pẹ̀lú àwọn òfin, àti ní gbígbọ́ran sí àwọn òfin Wọn, a nímọ̀lára ifẹ́ pípé Wọn níkíkún síi àti jíjinlẹ̀.33

Nihin ni ojútú fún àwọn àkoko ìjà wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́—ìfẹ́ Ọlọ́run. Ní àkọsílẹ̀-ìtàn ọjọ́ oníwúra Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní títẹ̀lé ìṣẹ́-ìránṣẹ́ Olùgbàlà, a ròhìn rẹ̀ pẹ́ “kò sí ìjà kankan ní ilẹ̀ náà, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó gbé nínú ọkàn àwọn ènìyàn.”34 Bí a ti ntiraka síwájú Síónì, ẹ rántí ìlérí nínú Ìwe-Ìfihàn: “Alábùkún ni fún àwọn tí wọ́n pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí wọ́n lè ní ẹ̀tọ́ sí igi ìyè, kí wọ́n sì lè wọlé láti inú àwọn ọ̀nà sínú ìlú [mímọ́].”35

Mó jẹ́ ẹ̀rí nípa òdodo Baba wa Ọ̀run àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, àti ìfẹ́ lemọ́lemọ́ àìkú Wọn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.