Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Mo Gbàdúrà pé Yíò Lò Wá
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Mo Gbàdúrà pé Yíò Lò Wá

Àwọn ìgbìyànjú kékèké lápapọ̀ nmú ipa nlá wá, ní gbígbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kọ̀ọ̀kan tí a nṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì ga.

Àkàra-òyìnbó tí a ṣe nípa fúláwà phyllo àti hòró pistachio ni a dúpẹ́ kan. A ṣe látọ́wọ́ ẹbí Kadado tí wọ́n, ní àwọn ilé-iṣẹ́ búrẹ́dì mẹ́ta ní Damascus, Syria, fún díkédì. Nígbàtí ogun dé, ìdínà dá oúnjẹ àti ìpèsè dúró ní dídé apákan ìlú. Àwọn Kadado npebi. Ní gíga ipò ìtara yí, àwọn Arannilọ́wọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti àwọn òṣìṣẹ́ onígboyà gan ní Rahma Àgbáyé bẹ̀rẹ̀sí nfúnni ní oúnjẹ́ gbígbóná, pẹ̀lú mílíkì fún àwọn ọmọ kékeré. Lẹ́hìn ìgbà ìṣòro, ẹbí náà bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé wọn—bákannáà ilé-iṣẹ́ búrẹ́dì wọn—lẹ́ẹ̀kansi ní orílẹ̀-èdè titun kan.

Láìpẹ́, àpótí àkàrà-òyìnbó kan dé sí ìbi-iṣẹ́ Ìjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Fún jíju oṣù méjì, a tiraka láti gba oúnjẹ láti ilé-ìdáná [Ìrànnilọ́wọ́] àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Láìsí rẹ̀ àwà [ìbá] [ti] pebi kú. Jọ̀wọ́ tẹ́wọ́gba àpẹrẹ èyí … láti ṣọ́ọ̀pù mi bí ọrẹ kékeré kan ti ọpẹ́. Mo ní kí Ọlọ́run Olódùmarè bùkún yín … nínú gbogbo ohun tí ẹ̀ nṣe.”1

Àkàrà-òyìbó kan ti ìmoore àti ìrántí. Ó wà fún yín. Sí gbogbo àwọn tí wọ́n gbàdúrà lẹ́hìn wíwo ìtàn kan lórí ìròhìn, sí gbogbo àwọn tí wọ́n yọ̀ọ̀da nígbàtí kò rọrùn tàbí tí wọ́n dá owó sínú owó arannilọ́wọ́; ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé yíò ṣe rere díẹ̀, ẹ ṣe.

Ojúṣe Àtọ̀runwá láti ṣe Ìtọ́jú fún àwọn Òtòṣì

Ìjọ Jésù Krístì wa lábẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá láti ṣe ìtọ́jú fún àwọn òtòṣì.2 Ó jẹ́ ọ̀kan láti àwọn òpó iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga.3 Ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ ní àwọn ọjọ́ Álmà dájúdájú jẹ́ òtítọ́ fún wa: “Bẹ̃ gẹ́gẹ́, nínú ipò ãsìkí yíi, nwọn kò ta ẹnikẹ́ni ti o wà ni ìhòhònù, tàbí tí ebi npa, tàbí tí òngbẹ ngbẹ, tàbí tí ó ṣàìsàn, tàbí tí kò rí jẹ tó; nwọn kò sì kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀; nítorínã, nwọ́n lawọ́ sí gbogbo ènìyàn; àgbà àti ọmọdé, pẹ̀lú ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin, yálà ní òde ìjọ Ọlọ́run tàbí ní inú ìjọ-Ọlọ́run, tí nwọn kò sì ṣe ojúṣãjú ènìyàn ní ti ẹni tí ó ṣe aláìní.”4

Ìjọ nfèsì sí àṣẹ yí ní onírurú àwọn ìgbòòrò ọ̀nà, pẹ̀lú:

  • iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti a nṣe nípasẹ̀ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àwọn iyejú oyè-àlùfáà, àti àwọn kílásì;

  • Gbígbàwẹ̀ àti ìlò ẹbọ-ọrẹ àwẹ̀;

  • àwọn oko àláfíà àti agolo;

  • àwọn gbàgede ìkìni-káàbọ̀ fún àwọn aṣíkiri.

  • ìnawọ́-jáde fún àwọn tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n.

  • àwọn ìgbìyànjú arannilọ́wọ́ Ìjọ.

  • Ati áàpù JustServe, èyí tí ó bá àwọn ayọ̀ọ̀dà mu pẹ̀lú àwọn ànfàní iṣẹ́-ìsìn.

Ìwọ̀nyí ni gbogbo àwọn ọ̀nà, tí a ṣètò nípasẹ̀ oyè-àlùfáà, níbití àwọn ìgbìyànjú kékèké lápapọ̀ nmú ipa nlá wá, gbígbéga ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kọ̀ọ̀kan tí a nṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Àwọn Wòlíì Ní Ìjíyìn fún Gbogbo Ilẹ̀-ayé

Àwọn wòlíì ní àṣẹ fún gbogbo ilẹ̀-ayé, kìí ṣe fún àwọn ọmọ Ìjọ nìkan. Mo lè ròhìn látinú ìrírí ara mi bí àwọn Àjọ Ààrẹ Kínní tí nní àṣẹ níti-ara àti níti-ìfọkànsìn. Bí àwọn ìnílò ṣe npọ̀, Àjọ Ààrẹ Kínní ti pàṣẹ fún wa láti mú nínawọ́-jáde rírannilọ́wọ́ wa pọ̀ si ní ọ̀nà pàtàkì. Wọ́n ní ìfẹ́ ní lílọ títóbijùlọ àti nínú ètò kíníkíní kíkéréjùlọ.

Láìpẹ́, a mú ọ̀kan lára gáùn ààbò ìlera tí Ilé-iṣẹ́-ẹ̀wù Beehive rán fún àwọn ilé-ìwòsàn láti lò ní ìgbà àjàkálẹ̀-àrùn wá fún wọn. Gẹ́gẹ́bí dókítà ìlera, Ààrẹ Nelson ní ìfẹ́ si gidigidi. Òun kò sì fẹ́ rí i lásán. Ó nfẹ́ láti gbìyànjú rẹ̀ wo lára—yẹ àwọn kọ́ọ̀fù àti gígùn àti ọ̀nà tí ó fi dè ní ẹ̀hìn wò. Ó wí fún wa lẹ́hìnnáà, pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, “Nígbàtí ẹ bá pàdé àwọn ènìyàn níbí ìfúnni-níṣẹ́ yín, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún gbígbàwẹ̀, àwọn ẹbọ-ọrẹ wọn, àti ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ wọn ní orúkọ Olúwa.”

Ìròhìn Arannilọ́wọ́.

Lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Nelson, mo nròhìn padà sí yín nípa bí Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti nfèsì sí ìjì-líle, ìsẹ́lẹ̀, fífọ́nká asásálà—àní àti àjàkálẹ̀ àrùn kan—ọpẹ́ fún inúrere àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́. Nígbàtí o ju ẹgbẹ̀rúnkan ààbọ̀ àwọn iṣẹ́ COVID-19 dájúdájú jẹ́ ìdojúkọ títóbijùlọ ìrànlọ́wọ́ Ìjọ ní àwọn oṣù méjìdínlógún tó kọjá, bákannáà Ìjọ fèsì sí ẹgbẹrùn-dín-laadọ́rin-lé-ní-mẹ́ta ìdààmú àjálù àdánidá àti asásálà ní àwọn orílẹ̀-èdè ọgọrun-le-mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n ìṣirò kìí sọ gbogbo ìtàn. Ẹ jẹ́ kí npín àwọn àpẹrẹ mẹrin ní ṣókí láti júwe ìtọ́wò kíkéréjùlọ nípa ohun tí à nṣe.

Ìrànwọ́ COVID àwọn South Africa

Dieke Mphuti ọmọ ọdún mẹrindinlogun ti Welkom, South Africa, pàdánù àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ọdún sẹ́hìn, wọ́n fi sílẹ̀ láti tọ́jú àwọn àbúrò rẹ kékeré mẹ́ta fúnra rẹ̀. Ó máa nlè nígbàgbogbo fún un láti rí oúnjẹ tí ó tó, ṣùgbọ́n ìdínkù ìpèsè COVID àti ìséra fẹ́rẹ̀ mu di àìlèṣeéṣe. Wọ́n máa npebi léraléra, ní ìdáfò pẹ̀lú ìwàrere àwọn aladugbo nìkan.

Àwòrán
Dieke Mphuti

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan ní Oṣù Kẹjọ 2020, ó ya Dieke lẹ́nu láti gba ìkànkù ní ẹnu-ilẹ̀kùn rẹ̀. Ó ṣí i láti rí àwọn àlejò méjì—ọ̀kan jẹ́ aṣojú Ìjọ láti agbègbè ibi-iṣẹ́ ní Johannesburg àti pé òmíràn jẹ́ òṣìṣẹ́ láti Ẹ̀ka Ìgbèrú Àwùjọ ti South Africa.

Àwọn ìṣètò méjèèjì ti kórapọ̀ láti mú oúnjẹ wá fún àwọn ojúlé tó wá nínú-ewu. Ìrànwọ́ bo Dieke mọ́lẹ̀ bí ó wo kọ́míìlì àti àwọn oúnjẹ́ míràn gègèrè, tí a rà pẹ̀lú owó arannilọ́wọ́ Ìjọ. Ìwọ̀nyí yíò ṣèrànwọ́ láti mú ẹbí rẹ̀ dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ títí tí ìrànlọ́wọ́ ìjọba yíò fi bẹ̀erè sí ní ipá lórí rẹ̀.

Ìtàn Dieke jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú àwọn ìrírí tí ó ti ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáyé ní ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn COVID ọpẹ́ fún àwọn ìyàsọ́tọ̀ ìlọ́wọ́sí yín.

Afghan Ṣèrànwọ́ ní Ramstein

A ti rí gbogbo àwòrán àìpẹ́ nínú ìròhìn: ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùyọkúrò tí à nkó kúrò ní Afghanistan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dé ìbùdókọ̀ òfúrufú tàbí àwọn ibi-ìpèsè ránpẹ́ míràn ní Qatar, United States, Germany, àti Spain ṣíwájú kí wọ́n tó tẹ̀síwájú sí ibùgbé ìkẹhìn wọn. Àwọn àìní wọn jẹ́ kíakíá, Ìjọ sì fèsì pẹ̀lú àwọn ípèsè àti ayọ̀ọ̀dà. Ní Ibùdó àwọn Ológun Òfúrufú Ramstein ní Germany, Ìjọ pèsè àwọn ìdáwó títóbi itẹdi, oúnjẹ-ọmọdé, oúnjẹ, àti bàtà.

Àwòrán
Àwọn Ìdáwó Arannilọ́wọ́ sí àwọn asásálà
Àwòrán
Àwọn obìnrin ránṣọ fún àwọn asásálà Afghan

Àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin Afghan nlo àwọn ṣẹ́ẹ̀tì ọkọ wọn làti borí wọn nítorí àṣà bíbo orí tí ó ti kúrò ní ìṣiwèrè ti ìbùdókọ̀-òfúrufú Kabul. Níniú ìṣe ìbáṣọ̀rẹ́ tí ó kọjá ẹ̀sìn kankan tàbí ààlà ọ̀làjú, àwọn arábìnrin Wọ́ọ̀dù Àkọ́kọ́ Ramstein kórajọ láti rán ẹ̀wù àṣà Mùsùlùmí fún àwọn obìnrin Afghan. Arábìnrin Bethani Halls wípé, “A gbọ́ pé àwọn obìnrin wà nínú àìní ẹ̀wù àdúrà, a sì nrán an kí wọ́n lè wà ní [ìtura] fún àdúrà.”5

Ìrànwọ́ Ìsẹ́lẹ̀ Haiti

Ápẹrẹ tó tẹ̀le fihàn pé ẹ kò níláti jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí dàgbà láti jẹ́ ohun-èlò fún rere. Ọmọ ọdún méjìdínlógún Marie “Djadjou” Jacques wá láti Ẹ̀ka Cavaillon ní Haiti. Nígbàtí isẹ́lẹ̀ ìpanirun ṣẹ̀lẹ̀ nítòsí ìlú rẹ̀ ní Oṣù Kẹjọ, ilé ẹbí rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹgbẹ̀ẹ̀rún mẹ́wààwá àwọn ilé tí ó wó. Ó fẹ̀rẹ̀ jẹ́ àìlèṣeéṣe láti ro àìnírètí ti pípàdánù ilé yín . Ṣùgbọ́n sànju jíjuwọ́lẹ̀ sí àìnírètí náà, Djadjou—pẹ̀lú àrà—yí jáde.

Àwòrán
Marie Jacques
Àwòrán
Ìsẹ́lẹ̀ Haiti

Akẹ́gbẹ́ Ìgbéròhìnjáde

Ó rí aladugbo àgbàlagbà kan tí ó nlàkàkà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ntọ́jú rẹ̀. Ó ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kó àwọn ìdọ̀tí kúrò. Pẹ̀lú rírẹ̀ rẹ̀, ó darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ìjọ míràn láti pín oúnjẹ àti àwọn ohun-èlò ìlera fún àwọn ẹlòmíràn. Ìtàn Djadjou kàn jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ alágbára ti iṣẹ́-ìsìn tí a ṣe nípasẹ̀ àwọn ọ̀dọ̀ àti ọ̀dọ́-àgbà bí wọ́n ṣe tiraka láti tẹ̀lé àpẹrẹ Jésù Krístì ni.

Ìrànwọ́ Àgbàrá German

Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣíwájú ìṣẹ́lẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́-àgbà míràn ni a fún ní irú iṣẹ́-ìsìn kannáà káàkiri Atlantic. Àwọn àgbàrá ti ó ṣàn kiri ìwọ̀-oòrùn Europe ní Oṣù Kéje ti jẹ́ olóró jùlọ ní àwọn díkédì.

Àwòrán
Àgbàrá ní Germany

Nígbàtí omi náà wálẹ̀, olùṣọ́gbà kan ní ibi-odò ìlú Ahrweiler, Germany, yẹ ìbàjẹ́ náà wò ó sì ní ìbòmọ́lẹ̀ tán-pátápátá. Onírẹ̀lẹ̀ ọkùnrin yí, olùfaọkànsìn Catholic, gba àdúrà jẹ́jẹ́ pé kí Ọlọ́run rán ẹnìkan láti ran òun lọ́wọ́. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji gan, Ààrẹ Dan Hammon ti Míṣọ̀n Frankfurt dé sí òpópónà pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìránṣẹ díẹ̀ tí wọ́n wọ vẹ́ẹ̀stì yẹ́lò àwọn Ọwọ́ Rírannilọ́wọ́. Òmi náà dé ìṣísẹ̀ mẹwa ní ògiri aṣọ́gbà náà, ó sì fi ipele pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ jíjinlẹ̀ sẹ́hìn. Àwọn ayọ̀ọ̀da wá pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ jáde, wọ́n gbé kápẹ́ẹ̀tì àti ògiri-gbígbẹ kúrò , àti ipele gègèrè gbogboohun tí ó wà ní òpópónà fún kíkó kúrò. Aṣọ́gbà tí ìnu rẹ̀ dùnrékọjá ṣiṣẹ́ lẹgbẹ wọn fún àwọn wákàtí, ní ìyàlẹ́nu pé Olúwa ti rán ẹgbẹ́ kan ti àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti dáhùn àdúrà rẹ̀—àti ní àárín wákàtí mẹ́rìnlélógún!6

“Ó Dára, Mo Gbàdúrà Pé Òun Yíò Lò Wá”

Sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbìyànjú arannilọ́wọ́ Ìjọ, Alàgbà Jeffrey R. Holland nígbàkan sọ pé: “Àwọn àdúrà ngbà … ní àkokò jùlọ … ní lílo àwọn ènìyàn míràn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó dára, Mo gbàdúrà pé Òun yíò lò wá. Mo gbàdúrà pé a ó jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà àwọn ènìyàn.”7

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nípasẹ̀ iṣẹ́-ìránṣẹ́ yín, ìdáwó, àkokò, àti ìfẹ́, ẹ ti jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ṣì wà si láti ṣe. Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n ti ṣe iprìbọmi, a wà ní abẹ́ májẹ̀mú láti ṣètọ́jú àwọn wọnnì nínú àìní. Àwọn ìgbìyànjú ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gba owó tàbí ibi jíjìnnà8 wọ́n gba ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́ àti ọkàn fífẹ́ láti wí fún Olúwa pé: “Nihin ni mo wà, rán mi.”9

Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà ti Olúwa

Lúkù 4 ṣe àkọsílẹ̀ pé Jésù wá sí Nazareth, níbití òun ti dàgbà, ó sì dúró nínú synagogue láti kàwé. Èyí ni ìsúnmọ́ bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé-ikú Rẹ̀, ó sì ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ kan látinú ìwé Ísàíàh.

“Ẹ̀mí Olúwa nbẹ lára mi, nítorítí ó fi àmì òróró yàn mi láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì, ó sì rán mi láti ṣe ìwòsàn àwọn ọkàn ìròbìnújẹ́, láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

“Láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà ti Olúwa.…

“… Loni ni ìwé-mímọ́ yí ṣẹ ní etí yín .”10

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ìwé-mímọ́ ndi mímúṣẹ ní àkokò ti ara wa bákannáà. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krísti ti wá láti wo àwọn ọkàn ìròbìnújẹ sàn. Ìhìnrere Rẹ̀ ni láti gba ìtúnríran fún àwọn afọ́jú. Ìjọ Rẹ̀ ni láti gba wàásù ìdásílẹ̀ fùn àwọn ìgbèkùn, àti pé àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ káàkiri àgbáyé ntiraka láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́.

Ẹ jẹ̀ kí nparí nípa titún ìbèèrè tí Jésù bi Àpóstélì Rẹ̀ Símónì Pétérù bèèrè: “Ṣé ẹ ní ìfẹ́ mi?”11 Àkójá ìhìnrere náà wà nínú bí a ṣe dáhùn ìbèèrè náà fún ara wa “bọ́ àwọn àgùntàn [Rẹ̀].”12 Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nlá àti ìfẹ́ fún Jésù Krístì, Olùkọ́ni wa, mo pe ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa láti jẹ́ ara iṣẹ́-ìránṣẹ́ títóbi jùlọ Rẹ̀, mo sì “Gbàdúrà pé Òun yíò lò wá.” Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín