Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìgbàgbọ́ láti Ṣiṣẹ́ àti láti Dà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ìgbàgbọ́ láti Ṣiṣẹ́ àti láti Dà

Nípasẹ̀ àdúrà, àṣàrò ìwé-mímọ́, àti ìṣe, a lè ṣí àwọn ìbùkún ọ̀run kí a sì di àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì Olùgbàlà dídárasi.

Láìpẹ́ lẹ́hìn tí a pè mí láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin, Mo ní ànfààní láti ṣàbẹ̀wò pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Ó jẹ́ ìpàdé àìròtẹ́lẹ̀ nínú ilé oúnjẹ, ó sì jẹ́ onínúure láti pe Alàgbà S. Mark Palmer àti èmi láti jóko àti gbádùn oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lú rẹ̀.

“Kíni kí a sọ̀rọ̀ nípa lákokò oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lú wòlíì náà?” ni èrò tí ó wá sí ọkàn mi. Nítorínáà mo pinnu láti bèèrè lọ́wọ́ Ààrẹ Nelson bí ó bá ní ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà fún mi nígbàtí ó jẹ́ pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìpè mi. Ìdáhùn rẹ̀ rọrùn púpọ̀ àti tààrà; ó wò mí ó sì wí pé, “Alàgbà Schmeil, a pè ọ́ fún ohun tí o lè dà.” Mo rìn kúrò nínú ìrírí náà ní ríronú nípa ohun tí Olúwa fẹ́ kí ndà. Bí mo ṣe ronú nípa èyí, mo ri pé Ó fẹ́ kí ndi ọkọ, bàbá, àti ọmọ tí ó dára jùlọ, àti ìránṣẹ́ tí ó dára jùlọ. Nígbànáà ni mo ri pé gbogbo èyí ni a lè ṣàṣeparí bí mo ti ṣiṣẹ́ láti di ọmọ-ẹ̀hìn tí ó dára jùlọ ti Olùgbàlà Jésù Krístì.

Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí ó kẹ́hìn, Ààrẹ Nelson sọ pé, “Láti ṣe ohunkóhun dáradára gba ìtiraka. Dída ọmọẹ̀hìn òtítọ́ ti Jésù Krístì kìí ṣe ìyàtọ̀ rárá.”1 Ààrẹ Nelson npè wá láti ṣiṣẹ́ takuntakun láti di ọmọ-ẹ̀hìn tí ó dídárasi ti Jésù Krístì. Ó sọ fún wa pé láti dàbí Olùgbàlà síi, a nílò láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun nípa bíbéèrè, ṣíṣe, àti kíkẹ́kọ̀ọ́, láàrin àwọn ohun míràn.

1. Bèèrè

Ó wì pé, “Bèèrè lọ́wọ́ Baba rẹ Ọ̀run, ní orúkọ Jésù Krístì, fún ìrànlọ́wọ́.”2 Bíbèèrè nípasẹ̀ àdúrà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn kọ́kọ́rọ́ láti mọ bí a ṣe lè di ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì tí ó dídárasi.

Nígbàtí iṣẹ́-ìránṣẹ́ Rẹ̀ nparí lọ láarin àwọn ará Néfì ní Amẹ́ríkà, Jésu Krístì gòkè lọ sí ọ̀run. Lẹ́hìnnáà, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ péjọ papọ̀, “ní ìṣọ̀kan nínú àdúrà nlá àti ãwẹ. Jésù sì tún fi ara rẹ̀ hàn sí wọn, nítorítí wọn ngbàdúrà sí Baba ní orúkọ rẹ̀.”3 Kílódé tí Jésù tún fi ara Rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀? Nítorípé wọ́n ngbàdúrà; wọ́n nbèèrè.

Lẹ́hìnnáà Ó tẹ̀síwájú:

“Nísisìyí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ Baba. Àti lõtọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bẽrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, a ó fi fún yín.

“Nítorínáà, ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín; nítorípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá bèèrè, yíò rí gbà; ẹnití ó bá sì kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.”4

A nílò láti bèèrè nínú ìgbàgbọ́ láti mọ ìfẹ́ Olúwa àti láti gbà pé Olúwa mọ ohun tí ó dárasi fún wa.

2. Ṣiṣe ìṣe

Ṣíṣe àṣàrò jẹ́ kókó pàtàkì sí dídi ọmọ-ẹ̀hìn dídárajù tí Jésù Krístì. Bí a ṣe nṣiṣẹ́, Òun yíò ṣe ìtọ́niyío sì darí wa ní ọ̀nà. Ó dámi lójú pé Néfì nwá ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti mọ bí ó ṣe lè gba àwọn àwo idẹ láti ọ̀dọ̀ Lábánì, síbẹ̀ òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ gbìyànjú lẹ́ẹ̀mejì láìsí àṣeyọrí. Ṣùgbọ́n wọ́n nṣiṣẹ́, àti pé Olúwa ndarí wọn ní ojú ọ̀nà náà. Ní ìparí, Néfì ṣàṣeyọrí ní ìgbà kẹta. Ó ṣe ìrántí, “Ẹ̀mí ni ó darí mi, láìmọ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun èyí tí èmi ìbá ṣe.” 5

Báyí ni Olúwa ti nṣiṣẹ́ bí a ti ntiraka tí a sì nṣe ìṣè, àní nígbàtí a kò ní òye kedere ohun tí a nílò láti ṣe. Olúwa sọ fún Néfì ohun tí yíò ṣe: lọ kí o sì gba àwọn àwo náà. Ṣùgbọ́n Kò sọ fún Néfì yíó ti ṣe é. Ó fi í sílẹ̀ fún Néfì láti wá ojútùú àti láti wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa—báyí sì ni Olúwa fi nṣe iṣẹ́ nínú ayé wa nígbàkugbà. Bí a ṣe nṣiṣẹ́ nínú ìgbàgbọ́, Olúwa nṣe ìtọ́ni Ó sì ndarí wa.

3. Ṣe Àṣàrò

Ninú 3 Néfì, àwọn ọmọẹ̀hìn mẹ́nuba fún Olùgbàlà pé àwọn àríyànjiyàn wà láarin àwọn ènìyàn nípa orúkọ Ìjọ. Ní ìdáhùn, Olùgbàlà kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nígbàtí Ó béèrè pé, “Ṣé wọn kò ka àwọn ìwé mímọ́ bí?” 6 Síṣe àṣàrò nígbànáà jẹ́ kọ́kọ́rọ́ pàtàkì sí dídi ọmọ-ẹ̀hìn dídárajù tí Jésù Krístì. Àdúrà àti ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́ lọ ní ìfọwọ́-kọ́-ọwọ́. Wọ́n ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ànfààní wa. Gbogbo èÈyí jni ìlànà tí Olúwa ti gbé kalẹ̀. “Ẹ ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsíi, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ ohun gbogbo fún yín èyí tí ẹ̀yin ó ṣe.”7

Olùgbàlà tún kọ́ni pé kí a máṣe ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà kí a kọ́ni láti inú wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe àfihàn fún àwọn ará Néfì: “Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí Jésù ti sọ àsọyé gbogbo àwọn ìwé-mímọ́ nã lápapọ̀, èyítí wọ́n ti kọ, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máa kọ́ni ní àwọn ohun náà èyítí òun ti sọ àsọyé rẹ̀ fún wọn.”8

Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì fún Néfì làti padà lọ gba àwọn àwo idẹ: ìdílé rẹ̀ nílò àwọn ìwé mímọ́ kìí ṣe láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti rin ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ ìlérí nìkan ṣùgbọ́n láti trànwọ́n lọ́wọ́ bákannáà láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Àwa pàápàá gbọ́dọ̀ wá ìtọ́sọ́nà láti inú àwọn ìwé mímọ́ fún ìrìnàjò wa, àti pé a gbọ́dọ̀ kọ́ni láti inú wọn ní àwọn ilé wa àti àwọn ìpè ti Ìjọ.

4. Ṣiṣe ìṣe láti Dà

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ìdáhùn sí àdúrà kìí wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ láti tẹ̀síwájú, láti ṣe ìṣe nínú òdodo, kí a sì ní ìtẹramọ́ bíi Néfì nígbàtí ó ngbìyànjú láti gba àwọn àwo idẹ. Olúwa yíò fi díẹ̀ hàn wá ní àkókò kan; bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, Olúwa yíò fún wa ní àwọn ìdáhùn tàbí agbára tí ó ṣeéṣe láti la ọjọ́ kan já síi, ọ̀sẹ̀ kan síi, àti láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan síi. Alàgbà Richard G. Scott sọ pé: “Ẹ dúpẹ́ pé nígbàmíràn Ọlọ́run njẹ́kí ẹ ja ìjàkadì fún ìgbà pípẹ́ kí ìdáhùn náà tó dé. Èyí nnì nmú kí ìgbàgbọ́ yín pọ̀ síi kí ìhùwàsí yín sì dàgbà.”9

Nípasẹ̀ àdúrà àti síṣe àṣàrò ìwé mímọ́, Olúwa ti fi ìgbà gbogbo fún mi ní okun láti ṣe àti láti farada ọjọ́ kan síi, ọ̀sẹ̀ kan síi, àti láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan síi. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àwọn ìdáhùn kìí wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mo ní àwọn ìbéèrè tí kò tíì jẹ́ dídáhùn síbẹ̀síbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi tẹ̀síwájú ní bíbéèrè àti ní síṣe àṣàrò, àti pé inú mi dùn pé Olúwa tẹ̀síwájú láti máa fún mi ní okun láti ṣe bí mo ti ndúró fún àwọn ìdáhùn.

Alàgbà Richard G. Scott bákannáà sọ pé, “Bí ẹ ṣe nrìn lọ sí ààlà òye yín sínú àfẹ̀mọ́jú àìdánilójú, ní lílo ìgbàgbọ́, a ó darí yín láti rí àwọn ìlàdí tí ìwọ kì yíò le gbà ní ọ̀nà míràn.”10

Láti di ọmọlẹ́hìn tí ó dárajù ti Olùgbàlà Jésù Krístì jẹ́ ìrìnàjò ìgbésí ayé kan, gbogbo wa sì wà ní oríṣiríṣi àwọn ipele, tí a nsún ní oríṣiríṣi ìgbésẹ̀. A gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn pé èyí kìí ṣe ìdíje, àti pé a wà níbí láti nífẹ àti láti ran ara wa lọ́wọ́. A nílò láti máa ṣe ìṣe kí a lè gba Olùgbàlà láàyè láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa nínú àwọn ìgbésí ayé wa.

Nígbàtí Ò nbá Sidney Rigdon sọ̀rọ̀, Olúwa sọ àwọn nkàn wọ̀nyí: “Mo ti wò ọ́ àti àwọn iṣẹ́ rẹ. Mo ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ, mo sì ti múra rẹ sílẹ̀ fún iṣẹ́ títóbi jù kanl”11 Mo jẹri pé Olúwa ngbọ́ Ó sì ndáhun àwọn àdúrà wa, Ó mọ wa; Ó ní iṣẹ́ nlá kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Nípasẹ̀ àdúrà, àṣàrò ìwé-mímọ́, àti ìṣer, a lè ṣí àwọn ìbùkún ọ̀run àti dídi àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì Olùgbàlà dídárasi.

Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé “Ìdájọ́ Ìkẹhìn kìí wulẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ti àròpọ̀ àwọn ìṣe rere àti búburú—ohun tí a ti ṣe. Ó jẹ́ ìjẹ́wọ́ àyọrísí ìkẹhìn ti àwọn ìṣe àti àwọn èrò inú wa—ohun tí a ti .”12

Mo dúpẹ́ fún àwọn wòlíì, aríran, àti àwọn olùfihàn; wọ́n jẹ́ olùṣọ́ lórí ilé-ìṣọ́ náà. Wọ́n rí àwọn nkàn tí a kò rí. Mo jẹ́rìí pé nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọn, a lè di ọmọlẹ́hìn tí ó dárajù ti Olùgbàlà Jésù Krístì àti ṣe àṣeyọrí agbára ìleṣe wa. Mo jẹ́rìí pé Jésù Krístì wà láàyè ó sì mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bí ẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín