Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìnílò fún Ìjọ kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ìnílò fún Ìjọ kan

Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni ní àtètèkọ́ṣe àti ìnílò fún ìjọ kan tí a darí nípasẹ̀ àti pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wa, Jésù Krístì.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, Alàgbà Mark E. Petersen, ọmọ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kan pẹ̀lú àpẹrẹ yí.

“Kenneth àti aya rẹ̀, Lucille, jẹ́ ènìyàn rere, olootọ́ àti olódodo. Wọ̀n kìí lọ sílé ìjọsìn, bíótilẹ̀jẹ́pé, wọ́n rò pé wọ́n dára tó láìsí i. Wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òtítọ́ àti ìwàrere wọ́n sì wí fúnra wọn pé ó jẹ́ nípa gbogbo ohun tí Ìjọ yíò ṣe fún wọn.

“Àti, ní ọ̀nàkọnà, wọ́n tẹnumọ pé wọ́n nílò òpin-ọ̀sẹ̀ wọn fún ìṣeré ẹbí … [àti pé] lílọ-sílé ìjọsìn yíò dí wọn lọ́wọ́ dájúdájú.”1

Ní òní, ọ̀rọ̀ mi bá irú àwọn ènìyàn ẹlẹ́sìn-ọkàn tí wọ́n ti dúró ní lílọ sí tàbí kíkópa nínú ìjọ wọn wí.2 Nígbàtí mo wípé “àwọn ìjọ,” mo mú pẹ̀lú àwọn sínágọ́gù, mọ́ṣáláṣí, tàbí àwọn ìṣètò ẹ̀sìn míràn. A ní àníyàn pé wíwásí ní gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ti lọ sílẹ̀ gidi káàkiri agbáyé.3 Bí a bá jáwọ́ ní fífi iyì fún àwọn ìjọ wá fún ìdí kankan, a ndẹ́rù ba ìgbé-ayé ti-ẹ̀mí araẹni wa, àti pé iye àwọn tí wọ́n nya arawọn sọ́tọ̀ gidigidi kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ndín àwọn ìbùkún Rẹ̀ kù sí àwọn orílẹ̀-èdè wa.

Wíwásí àti ṣíṣe ìṣe ní ìjọ kan nràn wá lọ́wọ́ láti di ènìyàn dídárasi àti agbára dídárasi nínú ìgbé-ayé àwọn ẹlòmíràn. Nínú ìjọ a kọ́ wa bí a ó ti lo àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn. A nkẹkọ látọ̀dọ̀ arawa. Àpẹrẹ pípàrọwà kan jẹ́ alágbára si ju ìwàásù lọ. À ngbà ìfúnni-lókun nípa ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bíi tiwa. Ni wíwásí ìjọ àti kíkópa, ọkàn wa, bí Bíbélì ti wí “wà níìrẹ́pọ̀ papọ̀ nínú ìfẹ́.”4

l.

Àwọn ìwé-mímọ́ tí Ọlọ́run ti fún àwọn Krìstẹ́nì nínú Bíbélì àti ìfihàn òde-òní kọ́ni ní ìnílò fún ìjọ kedere. Méjèèjì fihàn pé Jésù Krístì ṣètò ìjọ kan ó sì ronú pé ìjọ kan yíò tẹ̀síwájú lórí iṣẹ́ Rẹ̀ lẹ́hìn Rẹ̀. Ó pe àwọn Àpóstélì Méjìlá ó sì fún wọn ní àṣẹ àti àwọn kọ́kọ́rọ́ láti darí rẹ̀. Bíbélì kọ́ni pé Krístì ni “olórí ìjọ”5 àti pé àwọn olóyè rẹ̀ ni a fún “fún mímú àwọn èníyàn mímọ́ di pípé, fún ìṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìgbéga ara Krístì.”6 Dájúdájú Bíbélì hàn kedere lòrí àtètèkọ́ṣe ìjọ àti ìnílò fún un nísisìyí.

Àwọn kan wípé lílọsí àwọn ìpàdé ìjọ kìí ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn kan wípé, “èmi ko kọ́ ohunkóhun loni” tàbí “Kò sí ẹni tí ó bá mi ṣọ̀rẹ́” tàbí “A ṣẹ̀ mi.” Àwọn ìjákulẹ̀ araẹni kò gbọ́dọ̀ pa wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀kọ́ Krístì, ẹnití ó kọ́ wá láti sìn, kìí ṣe kí a sìn wá.7 Pẹ̀lú èyí nínú, ọmọ-ìjọ míràn júwe ìdojúkọ lílọ sí Ìjọ rẹ̀.

“Àwọn ọdún sẹ́hìn, mo yí ìwà mi padà nípa lílọ sílé-ìjọsìn. Kìí ṣe pé èmi nlọ sílé-ìjọsìn fún ara mi mọ́, ṣùgbọ́n láti ronú nípa àwọn ẹlòmíràn. Mo nṣe àmì wíwípé báwo sí àwọn ènìyàn sí wọ́n dá joko, láti kí àwọn àlejò káàbọ̀, … láti yọ̀ọ̀da fún ìfúni-níṣẹ kan. …

“Ní kúkúrú, mò nlọ sí ìlé-ìjọsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú èrò-inú tí jíjẹ́ aláápọn, kìí ṣe àìní-aápọn, àti ṣìṣe ìyàtọ̀ dáradára nínú ìgbé-ayé àwọn ènìyàn.”8

Àwòrán
Ìkíni-káàbọ̀ ni ìjọ

Ààrẹ Spencer W. Kimball kọ́ni pé “a kò lọ sí àwọn ìpàdé Sábóáthì láti gbádùn àní tàbí láti gba àṣẹ lásán. À nlọ láti jọ́sìn Olúwa. Ó jẹ́ ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan. … Bí ìsìn bá jẹ́ ìkùnà sí yín, ẹ ti kùnà. Kò sí ẹnìkan tí ó lè jọ́sìn fún yín, ẹ gbọ́dọ̀ ṣe dídúró dé Olúwa funra yín.”9

Wíwásí Ìjọ lè ṣí ọkàn yín kí ó sì ya ẹ̀mí yín sí mímọ́.

Àwòrán
Ìpàdé ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù

Nínú ìjọ kan a kìí dá sìn tàbí nípa yíyàn arawa tàbí ní ìtẹ́lọ́rùn wa. A máa nsìn nínú ẹgbẹ́. Nínú ìsìn à nwá láti rí àwọn ànfàní rírán-láti-ọ̀run láti kọjá jíjẹ́-ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ọjọ́-orí wa, Ìdarí ìsìn Ìjọ nràn wá lọ́wọ́ láti borí ìmọtara-ẹni-nìkan araẹni tí ó lè dí ìdàgbà ti-ẹ̀mí wa dúró.

Àwọn èrè pàtàkì míràn wa láti dárúkọ, àní ní ṣókí. Nínú ìjọ a nbáraṣe pẹ̀lú àwọn oníyanu èníyàn tí wọ́n ntiraka láti sin Ọlọ́run. Èyí rán wa létí pé a kò dá wà nínú àwọn ṣíṣe ẹ̀sìn. Gbogbo wa nílò ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti pé ìbaṣe ìjọ ni ara ìrírí dídárajùlọ tí a lè ní, fún arawa àti àwọn ojúgba wa àti àwọn ọmọ. Láìsí àwọn ìbáṣepọ̀ wọnnì, nípatàkì ní àárín àwọn ọmọ àti olotitọ àwọn òbi, ìwáàdí fi ìṣòrò púpọ̀si hàn fún àwọn òbí láti tọ́ àwọn ọmọ nínú ìgbàgbọ́ wọn.10

ll.

Di àkokò yí, mo ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọ lápọpọ̀. Nísisìyí èmi ó sọ̀rọ̀ àwọn ìdí pàtàkì fún jíjẹ́-ọmọ-ìjọ, wíwá, àti kíkópa nínú ìmúpadàbòsípò Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Salt Lake

Àwa, bẹ́ẹ̀náà, tẹnumọ pé àwọn ìwé mímọ́, àtijọ́ àti òde-òní, kọ́ni ní àtètèkọ́ṣe kedere àti ìnílò fún ìjọ kan tí a darí nípasẹ̀ àti pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wa, Jésù Krístì. Bákannáà a jẹri pé ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì ni ti gbékalẹ̀ láti kọ́ni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀ àti láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ oyè-àlùfáà Rẹ̀ láti ṣe àwọn ìlànà tí ó ní iṣé láti wọ ìjọba Ọlọ́run.11 Àwọn ọmọ ìjọ nfi wíwásí Ìjọ sílẹ̀ wọ́n sì ngbáralé ìkọ̀ọ̀kan ti-ẹ̀mí arawọn nìkan ní yíyàsọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn kókó ìhìnrere wọ̀nyí: agbára àti àwọn ìbùkún oyèàlùfáà, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kọ́, àti àwọn ìwúrí àti ànfàní láti lo ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n pàdánù ànfàní wọn láti yege sí wíwàtítí ẹbí wọn fún ayérayé.

Èrè nlá míràn ti ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ni pé ó nràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà níti-ẹ̀mí. Ìdàgbà túmọ̀ sí ìyípadà. Nínú àwọn ọ̀ràn ti-ẹ̀mí èyí túmọ̀ sí ríronúpìwàdà àti lílépa láti súnmọ́ Oluwa si. Nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ a ní ẹ̀kọ́, ìṣísẹ̀, àti àwọn olùrànlọ́wọ́ onímísí tí wọ́n ntìwálẹ́hìn láti ronúpìwàdà. Èrèdí wọn, àní nínú àwọn ìgbìmọ̀ jíjẹ́-ọmọ-ìjọ, kìí ṣe ìjìyà, bíiti àbájáde kóòtù ọ̀daràn kan. Àwọn ìgbìmọ̀ jíjẹ́-ọmọ Ìjọ fi tìfẹ́tìfẹ́ lépa láti ràn wá lọ́wọ́ fún àánú ìdáríjì mu ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.

Àwòrán
Àwọn tọkọ-taya òjíṣẹ́-ìránṣẹ́
Àwòrán
Rírìn síwájú tẹ́mpìlì

Ipò ti-ẹ̀mí ẹnìkọ̀ọ̀kan lè pèsè ìwúrí àti ètò fún iṣẹ́-ẹ̀sìn àìní-ìmọtara-ẹni-nìkan tí a pèsè nípasẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn àpẹrẹ nlá nípa èyí ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn alàgbà tí wọ́n gbé àwọn ìṣe ikẹkọ tàbí ìfẹ̀hìntì wọn sẹgbẹ láti tẹ́wọ́gba àwọn ìpè iṣẹ́-ìránṣẹ́. Iṣẹ́ wọn bí ìránṣẹ́-ìhìnrere sí àwọn àjèjì ní àwọn ibi àìmọ̀ tí wọn kò yàn. Irúkannáà ni àwọn ọmọ ìjọ onígbàgbọ́ òtítọ́ tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́-ìsìn àìní-ìmọtara-ẹni-nìkan tí a pè ní “iṣẹ́ tẹ́mpìlì.” Kò sí irú iṣẹ́-ìsìn náà tí yíò ṣeéṣe láìsí pé Ìjọ ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, ṣètò rẹ̀, àti láti darí rẹ̀.

Ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ìjọ wa àti iṣẹ́-ìsìn Ìjọ ti kọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ nínú ìgbìyànjú àjùmọ̀ṣe láti jèrè ìletò títóbi. Irú ìrírí náà àti ìdàgbàsókè kìí ṣẹlẹ̀ nínú jíjẹ́-ìkọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú àwọn ìṣe ti àwùjọ wa lọ́wọ́lọ́wọ́. Nínú agbègbè ìṣètò àwọn wọ́ọ̀dù ìbílẹ̀ wa, a nbáraṣe a sì nṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni tí wọ́n lè má tilẹ̀ yan, àwọn ẹni tí wọ́n nkọ́ wa tí wọ́n sì ndán wa wo.

Ní àfikún sí ríràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ìwà ti-ẹ̀mí bíiti ìfẹ́, àánú, ìdáríjì, àti sùúrù, èyí nfún wa ní àwọn ànfàní láti kọ́ bí ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni tí wọ́n yàtọ̀ gan an níti àbínibí àti ààyò ṣiṣẹ́. Èrè yí ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ìjọ wa lọ́wọ́, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣètò sì ti di alábùkúnfún nípa ìkópa wọn. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ògbóntàrìgì fún agbára wọn láti darí àti láti ní ìgbìyànjú ìrẹ́pọ̀. Àṣà náà tilẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn onígboyà olùlànà tí wọ́n tẹ Ìwọ̀-oòrun Àárín-òkè dó tí wọ́n sì gbé àṣà iyì ti jíjùmọ̀ṣe àìní-ìmọtara-ẹni-nìkàn kalẹ̀ fún rere gbogbogbò.

Àwòrán
Iṣẹ́ àwọn Ọwọ́ Rírannilọ́wọ́

Ọ̀pọ̀ ìgbìyànjú ìràn-nìyàn-lọ́wọ́ àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni a nílò láti ṣeyọrí nípa fífà àti ṣíṣe àkóso àwọn ohun-èlò kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n títóbi. Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ nṣe èyí pẹ̀lú ìgbìyànjú ìràn-nìyàn-lọ́wọ́ títóbi rẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ìpèsè ẹ̀kọ́ àti ìlera, bíbọ́ elébi, ṣíṣe ìtọ́jú àwọn asásálà, ṣíṣe ìrànwọ́ láti dá ìpalára àwọn ìwà-bánbákú dúró, àti ọ̀pọ̀ àwọn míràn. Àwọn ọmọ Ìjọ wa jẹ́ ògbóntarìgì fún àwọn iṣẹ́ Ọwọ́ Rírannilọ́wọ́ nínú àwọn àjálù àdánidá. Jíjẹ́ ọmọ Ìjọ fi ààyè gbà wá láti jẹ́ ara irú ìgbìyànjú ìwọ̀n-títóbi bẹ́ẹ̀. Bákannáà àwọn ọmọ ìjọ san ẹbọ-ọrẹ àwẹ̀ láti ran àwọn òtòṣì ní àárín arawọn.

Àwòrán
Ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa.

Ní àfikún láti ní ìmọ̀lára àláfíà àti ayọ̀ nípasẹ̀ ojúgbà Ẹ̀mí, àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nwásí-ìjọ ngbádùn èso gbígbé ìhìnrere, bí irú àwọn íbúkún gbígbé Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n àti ohun-èlò àti àísìkí ti ẹ̀mí tí a ṣèlérí fún gbígbé òfin idamẹwa. Bákannáà a ní ìbùkún àmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn onimisi olórí wa.

Bíborí gbogbo èyí ni àwọn ìlànà àṣẹ oyè-àlùfáà tó ṣeéṣe fún ayé-àìlópin, pẹ̀lú oúnjẹ Olúwa tí à ngbà ní ọjọọjọ́ Sábáóthì. Àwọn àkópọ̀ ìlànà nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ni májẹ̀mú ayérayé ìgbeyàwó, èyí tí ó nmu títẹ̀síwájú ìbáṣepọ̀ ẹbí ológo wà-títí. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni ní ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ yí ní ọ̀nà onírántí. Ó wípé: “A kò lè fi ìfẹ́ wá ọ̀nà ara wa lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A níláti gbọ́ran sí àwọn òfin èyí [tí ìbùkún náà] dálé.”12

Ọ̀kan lára àwọn òfin wọnnì ni láti jọ́sìn nínú ìjọ ní ọjọọjọ́ Sábbóáthì.13 Ìjọ́sìn wa àti lílò àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ayérayé nfà wá súnmọ́ Ọlọ́run si àti gbígbéga agbára wa láti nifẹ. Parley P. Pratt, ọ̀kan lára àwọn Àpóstélì àtijọ́ ti iṣẹ́ ìríjú yí, júwe bí òun ti ní ìmọ̀lára nígbàtí Wòlíì Joseph Smith ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí: “Mo nímọ̀lára pé Ọlọ́run ni Baba ọ̀run nítòótọ́; pé Jésù ni arákùnrin mi, àti pé ìyàwó ìhà mi ni àìkú, ojùgbà ayérayé, onínúrere kan, ángẹ́lì oníṣẹ́-ìránṣẹ́, tí a fún mi bí olùtùnú kan, àti adé ológo kan láé àti títíláé. Ní kúkúrú, mo lè ní ìfẹ́ nísisìyí pẹ̀lú ẹ̀mí àti pẹ̀lú ìmọ̀ bákannáà.”14

Ní ìparí, mo rán gbogbo yín létí pé a kó gbàgbọ́ pé rere ni a lè ṣe nípasẹ̀ ìjọ kan níkan. Láìsí ìjọ kan, a rí àwọn míllíọ́nù ènìyàn tí wọ́n ntìlẹhìn tí wọ́n sì ngbé àwọn ìṣẹ́ rere àìlónkà jáde. Ní ọ`kọ̀ọ̀kan, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nkópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ́ wọn. A rí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí bí ìfarahàn òtítọ́ ayérayé pé “Ẹ̀mí nfi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ènìyàn tí ó wá sí ayé.”15

Pẹ̀lú àwọn iṣẹ̀ rere tí a lè ṣe yọrí láìsí ìjọ, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀kọ́ àti ìgbàlà rẹ̀ àti àwọn ìlànà ìgbéga ni ó wà nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ nìkàn. Ní àfikún, wíwásí Ìjọ nfún wa ní okun àti ìgbéga ìgbàgbọ́ tí ó nwá látinú ìbáṣe pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míràn àti jíjọ́sìn papọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ntiraka bákannáà láti dúró lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú àti láti di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì dídárasi. Mo gbàdúrà pé gbogbo wa yíò dúróṣinṣin nínú àwọn ìrírí Ìjọ wọ̀nyí bí a ti nlépa ìyè ayérayé, tí ó tóbiju gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run lọ, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Mark E. Petersen, “Eternal Togetherness,” Ensign, Nov. 1974, 48.

  2. Wo D. Todd Christofferson, “Why the Church,” Liahona, Nov. 2015, 108–11.

  3. Wo Jeffrey M. Jones, “U.S. Church Membership Falls Below Majority for First Time,” Gallup, Mar. 29, 2021, news.gallup.com/poll/341963/church-membership-falls-below-majority-first-time.

  4. Kólósè 2:2.

  5. Wo Éfésù 5:23–24.

  6. Éfésù 4:12.

  7. Wo Jákọ́bù 1:27.

  8. Mark Skousen sí Dallin H. Oaks, Feb. 15, 2009.

  9. Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ: Spencer W. Kimball (2006), 173–74.

  10. Wo Elizabeth Weiss Ozotak, “Social and Cognitive Influences on the Development of Religious Beliefs and Commitment in Adolescence,” Journal for the Scientific Study of Religion, vol. 28, no. 4 (Dec. 1989), 448–63.

  11. Wo Jòhánnù 3:5.

  12. Russell M. Nelson, “Bayi Ni Akoko Lati Murasilẹ,” LiahonaMay 2005, 18.

  13. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:9.

  14. Ìtàn araẹni ti Parley P. Pratt,, ed. Parley P. Pratt Jr. (1938), 298.

  15. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:46; àtẹnumọ́ àfikún; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58:27–28.