Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Pe Krístì láti jẹ́ Olùpilẹ̀sẹ̀ Ìtàn Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ẹ Pe Krístì láti jẹ́ Olùpilẹ̀sẹ̀ Ìtàn Yín

Ẹ jẹ́kí ìtàn yín jẹ́ ọ̀kan ti ìgbàgbọ́, ní títẹ̀lé Alápẹrẹ yín, Olùgbàlà Jésù Krístì.

Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú jíju àwọn ìbéèrè púpọ̀, tí ó wà fún ìṣàṣàrò-araẹni.

  • Irú ìtàn ti araẹni wo ni ìwọ nkọ fún ìgbé ayé rẹ?

  • Njẹ́ ipa ọ̀nà tí o júwe nínú ìtàn yín jẹ́ tààrà?

  • Njẹ́ ìtàn rẹ parí sí ibití ó ti bẹ̀rẹ̀, ní ilé rẹ ọ̀run?

  • Njẹ́ àpẹrẹ kan wà nínú ìtàn rẹ—àti pé njẹ́ Olùgbàlà Jésù Krístì wà níbẹ̀?

Mo jẹ́ri pé Olùgbàlà ni “olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.”1 Njẹ́ ìwọ ó pè É láti jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìtàn rẹ bí?

Ó mọ ìbẹ̀rẹ̀ láti òpin. Òun ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé. Ó fẹ́ kí á padà wá sílé lọdọ Rẹ̀ àti Baba wa Ọrun. Ó ti fi ohun gbogbo sínú wa Ó sì fẹ́ kí a ṣe àṣeyege.

Kíni ẹ rò pé ó nmú wa kúrò ní gbígbé àwọn ìtàn wa wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀?

Bóyá àpèjúwe yi yíò ṣe ìrànwọ́ nínú àyẹ̀wò-araẹni yín.

Amòfin ìwádìí tí ó múná-dóko mọ̀ pé nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ó ṣọ̀wọ́n fún ọ láti bi ẹlẹ́ri kan ní ìbéèrè tí ìwọ kò mọ ìdáhùn sí. Bíbèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ jẹ́ pípe ẹlẹ́ri náà láti sọ fún ọ—àti adájọ́ àti ìgbìmọ̀ náà—ohun kan tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. O lè gba ìdáhùn kan tí yíó yà ọ́ lẹ́nu tí ó sì lòdì sí ìtàn tí o ti pèsè sílẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ.

Bíótilẹ̀jẹ́pé bíbi ẹlẹ́ri kan ní ìbéèrè tí ìwọ kò mọ ìdáhùn sí jẹ́ ohun àìgbọ́n ní ìwọpọ̀ fún amòfin ìwádìí, ìdàkejì rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ fún àwa. Àwa le bèèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ olùfẹ́ni Baba wa Ọrun, ní orúkọ alãnú Olùgbàlà wa, àti pé ẹlẹ́rìí tí ó ndáhùn àwọn ìbéèrè wa ni Ẹmí Mímọ́, ẹnití ó nfi ìgbàgbogbo jẹ́ri òtítọ́.2 Nítorípé Ẹmí Mímọ́ nṣiṣẹ́ ní ìṣọkan pípé pẹ̀lú Baba Ọrun àti Jésù Krístì, a mọ̀ pé àwọn ìfarahàn ti Ẹmí Mímọ́ jẹ́ èyítí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. Kíni ìdí, nígbànáà, tí a fi nṣe àtakò nígbàmíràn sí bíbèèrè fún irú ìrànlọ́wọ́ ti ọ̀run yi, òtítọ́ tí a fihàn síwa nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́? Kíni ìdí tí a fi nṣe àgbétì bíbèèrè ìbéèrè tí a kò mọ ìdáhùn sí nígbàtí ẹlẹ́ri náà kìí ṣe pé ó jẹ́ bíi ọ̀rẹ́ nìkan ṣùgbọ́n tí yío fi ìgbàgbogbo sọ òtítọ́?

Bóyá ó jẹ́ nítorípe a kò ní ìgbàgbọ́ láti gba ìdáhùn tí a le gbà. Bóyá ó jẹ́ nítorípé ènìyàn ẹlẹ́ran ara ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó wà nínú wa nṣe àtakò sí gbígbé àwọn nkan wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa pátápátá kí a sì gbẹ́kẹ̀lé E pátápátá. Bóyá ìdí nìyí tí a fi yàn láti wà ní lílẹ̀mọ́ pẹ̀lú ìtàn tí a ti kọ fún ara wa, ẹ̀dà títunilára kan ti ìtàn wa tí kò jẹ́ títúnṣe láti ọwọ́ Olùkọ́ni Olùpilẹ̀sẹ̀. A kò fẹ́ bèèrè ìbéèrè kí a sì gba ìdáhùn tí kò wà ní ìbámu rẹ́gí sí inú ìtàn tí a nkọ fún ara wa.

Ní tòótọ́, bóyá díẹ̀ nínú wa ni yío kọ àwọn àdánwò tí ó tún wa ṣe sínú àwọn ìtàn wa. Ṣùgbọ́n njẹ́ a kìí fẹ́ràn ìparí ológo ti ìtàn kan tí a kà nígbàtí olórí òṣèré bá borí ìjàkadì náà? Àwọn àdánwò ni àwọn èròjà eré ìdárayá tí ó nmú àwọn àyànfẹ́ ìtàn wa jẹ́ dandan, àìlákókò, ìgbéga ìgbàgbọ́, àti yíyẹ fún sísọ. Àwọn ìjàkadì rírẹwà tí a kọ sínú àwọn ìtàn wa ni ohun tó nfà wá súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olùgbàlà síi tí ó sì ntúnwa ṣe, tí ó nmúwa dàbíi Rẹ̀ síi.

Fún Dáfídì láti borí Gòláiátì, ọmọkùnrin náà ní láti gbé òmíràn wọ̀. Ìtàn títunilára fún Dáfídì ìbá ti jẹ́ pípadà sí títọ́jú àwọn àgùtàn. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ó ronú lórí ìrírí rẹ̀ ní kíkó àwọn ọ̀dọ́ àgùtàn yọ kúrò lọ́wọ́ kìnìun àti àmọ̀tẹ́kùn. Àti ní kíkọ́ lóri àwọn ìṣe agbára akọni wọ̀nnì, ó kó ìgbàgbọ́ àti ìgboyà jọ pọ̀ láti jẹ́kí Ọlọ́run kọ ìtàn rẹ̀, ó wípé, “Olúwa tí ó gbà mi kúrò lọ́wọ́ kìnìun, àti kúrò lọ́wọ́ àmọ̀tẹ́kùn, òun náà ni yío gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filístìnì yi.”3 Pẹ̀lú ìfẹ́ inú láti jẹ́kí Ọlọ́run borí, pẹ̀lú etí sí Ẹmí Mímọ́, àti pẹ̀lú ṣíṣetán láti jẹ́kí Olùgbàlà jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìtàn rẹ̀, ọmọkùnrin náà Dáfídì ṣẹ́gun Gòlíátì ó sì kó àwọn ènìyàn rẹ̀ yọ.

Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ gíga ti agbára láti yàn, nítòótọ́ gbà wá láàyè láti kọ àwọn ìtàn ti wa—Dáfídì ìbá ti padà sílé, padà sí ìtọ́jú ẹran. Ṣùgbọ́n Jésù Krístì dúró ní síṣetán láti lò wá bíi ohun èlò àtọ̀runwá, ìkọ̀wé tí a ti gbẹ́ ní ọwọ́ Rẹ̀, láti kọ àṣeparí kan. Ó ṣetán pẹ̀lú àánú láti lò èmi, ohun ìkọ̀wé ẹ̀gàn kan, bíi ohun èlò ní ọwọ́ Rẹ̀, bí mo bá ní ìgbàgbọ́ láti jẹ́kí Ó ṣeé, bí èmi ó bá jẹ́kí Ó jẹ́ ònkọ̀wé ìtàn mi.

Ésítérì ni àpẹrẹ rírẹwà míràn ti jíjẹ́kí Ọlọ́run borí. Dípò lílẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú ìṣọ́ra ìtàn títọ́jú-araẹni tí ó ṣe, ó lo ìgbàgbọ́, ní yíyí ara rẹ̀ sọ́dọ̀ Olúwa pátápátá. Hámánì npérò ìparun gbogbo àwọn Júù ní Pésíà. Mọ́rdékáì, ìbátan Ésítérì mọ̀ nípa ète náà ó sì kọ̀wé sí i, ó rọ̀ ọ́ láti bá ọba sọ̀rọ̀ ní ìgbẹnusọ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó sọ fún un pé ẹni tí ó bá lọ sí iwájú ọba láìsí ìpè yío yẹ fún ikú. Ṣùgbọ́n nínú ìṣe yíyanilẹ́nu ti ìgbàgbọ́, ó sọ fún Mọ́rdékáì láti kó àwọn Júù jọ papọ̀ kí wọn ó sì gbààwẹ̀ fún un. “Èmi pẹ̀lú ati àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi yío gbààwẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́,” ni ó sọ, “bẹ́ẹ̀ni èmi ó sì wọ ilé tọ ọba lọ, tí ó lòdì sí òfin: bí mo bá ṣègbé, mo ṣègbé.”4

Ésítérì ṣetán láti jẹ́kí Olùgbàlà ó kọ ìtàn òun àní bíótilẹ̀jẹ́pé, nípasẹ̀ ojú ti ayé ikú, òpin rẹ̀ le jẹ́ àjálù. Pẹ̀lú ìbùkún, ọba gba Ésítérì, àwọn Júù ní Pérsíà sì di gbígbàlà.

Ní tòótọ́, irú ìpele ìgboyà Ésítérì ṣọ̀wọ́n láti jẹ́ bíbèèrè lọ́wọ́ wa. Ṣùgbọ́n jíjẹ́kí Ọlọ́run borí, jíjẹ́kí Òun ṣe olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé àwọn ìtàn wa, gba pé kí a pa àwọn òfin Rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú tí a ti dá mọ́ Ó jẹ́ pé pípa àwọn òfin àti àwọn májẹ̀mú mọ́ wa ní yío ṣí ipa ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ fún wa láti gba ìfihàn nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́. Àti pé nípasẹ̀ àwọn ìfarahàn ti Ẹmí ni a ó ní ìmọ̀lára ọwọ́ Olùkọ́ni, tí Ó nkọ àwọn ìtàn wa pẹ̀lú wa.

Ní Oṣù Kẹrin 2021, wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, sọ fún wa láti ro ohun tí a le ṣe bí a bá ní ìgbàgbọ́ síi nínú Jésù Krístì. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ síi nínú Jésù Krístì, a le bèèrè ìbéèrè kan èyítí a kò mọ ìdáhùn sí—kí a bi Baba wa ní Ọrun léèrè, ní orúkọ Jésù Krístì, láti rán ìdáhùn kan wá nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́, ẹnití njẹ́ri ti òtítọ́. Bí a bá ní ìgbàgbọ́ síi, a ó bèèrè ìbéèrè náà àti nígbànáà a ó ṣetán láti gba ìdáhùn tí a bá gbà, àní bí kò tilẹ̀ bá ìtàn wa títunilára mu. Àti ìbùkún tí a ṣèlérí tí yío wá láti inú iṣẹ́ síṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ àlékún ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ bíi olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé wa. Ààrẹ Ne/son sọ pé a “ngba ìgbàgbọ́ síi nípa ṣíṣe ohun kan tí ó bèèrè fún ìgbàgbọ́ síi.”5

Nítorínáà, àwọn tọkọ-taya tí kò ní ọmọ tí wọ́n njìyà àìleṣabiyamọ le bèèrè nínú ìgbàgbọ́ bóyá wọn le gba ọmọ kan kí wọn ó sì ṣetán láti faramọ́ ìdáhùn, àní bíótilẹ̀jẹ́pé ìtàn tí wọ́n ti kọ fún ara wọn ní ìbímọ yíyanilẹ́nu nínú.

Àwọn àgbà tọkọ-taya le bèèrè bóyá ó tó àkókò fún wọn láti sìn ní míṣọ̀n kí wọn ó sì ṣetán láti lọ, àní bíótilẹ̀jẹ́pé ìtàn tí wọ́n ti kọ fún ara wọn ní àkókò díẹ̀ síi ní ibi iṣẹ́ nínú. Tàbí bóyá ìdáhùn yío jẹ́ “kò tíì yá,” àti tí wọn ó mọ̀ nínú àwọn orí ìtàn wọn lẹ́hìnwá ìdí tí a fi nílò wọn nílè fún ìgbà díẹ̀ síi.

Ọ̀dọ́ ọmọkùnrin tàbí ọ̀dọ́ ọmọbìnrin kan le bèèrè nínú ìgbàgbọ́ bóyá ìlépa ti àwọn eré ìdárayá tàbí ìwé kíkà tàbí orin ní ó ní iyì jùlọ kí ó sì ṣetán láti tẹ̀lé àwọn ìṣílétí ti ẹlẹ́ri pípé náà, Ẹmí Mímọ́.

Kini ìdí tí a fi fẹ́ kí Olùgbàlà jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé àwọn ìtàn wa? Nítorípé Ó mọ agbára ìleṣe wa ní pípé, Òun yío mú wa lọ sí àwọn ibi tí a kò le fi inú rò fúnrawa láé. Ó le ṣe wa ní Dáfídì tàbí Estérì kan. Òun yío na iṣan wa yío sì túnwa ṣe láti dà bíi Rẹ̀ síi? Àwọn ohun tí a ó ṣeyọrí bí a ti nṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ yío mú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì lékún síi.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, ní ọdún kan péré sẹ́hìn, wòlíì wa ọ̀wọ́n bèèrè pé: “Njẹ́ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín bí? Njẹ́ ẹ nfẹ́ láti jẹ́ kí ohunkóhun tí Ó nílò yín láti ṣe jẹ́ ìṣíwájú lórí gbogbo àwọn ìlépa míràn?”6 Mo fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ṣe àfikún sí àwọn ìbéèrè ti wòlíì wọnnì: “Njẹ́ ìwọ ó jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìtàn rẹ?”

Nínú Ìfihàn a kọ́ pé a ó dúró níwájú Ọlọ́run a ó sì dá wa lẹ́jọ́ láti inú àwọn ìwé ìyè, ní ìbámú sí àwọn iṣẹ́ wa.7

A ó dá wa lẹ́jọ́ nípasẹ̀ ìwé ìyè wa. A lè yàn láti kọ ìtàn títunilára kan fún ara wa. Tàbí a le fi ààyè gba Olùkọ́ni Olùpilẹ̀sẹ̀ àti Aláṣepé láti kọ ìtàn wa pẹ̀lú wa, ní jíjẹ́kí ipa tí ó bá nílò wa láti kó kí ó ṣíwájú lórí àwọn ìlépa míràn.

Ẹ jẹ́kí Krístì ó jẹ́ olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìtàn yín.

Ẹ jẹ́kí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹlẹ́rí yín!

Ẹ kọ ìtàn nínú èyítí ipa ọ̀nà tí ẹ wà jẹ́ híhá, nínú eré ìje tí ó ndarí yín padà sí ilé yín ọ̀run láti gbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ẹ jẹ́kí wàhálà àti ìpọ́njú tí ó jẹ́ apákan gbogbo ìtàn rere jẹ́ àwọn ọ̀nà nípa èyítí ẹ ó fi súnmọ́, àti tí ẹ ó fi dàbíi, Jésù Krístì síi.

Ẹ sọ ìtàn kan nínú èyítí ẹ mọ̀ pé àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀. Ẹ bééré àwọn ìbéèrè èyítí ẹ kò mọ ìdáhùn sí, ní mímọ̀ pé Ọlọ́run ṣetán láti sọ ìfẹ́ Rẹ̀ fún yín di mímọ̀ nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́

Ẹ jẹ́kí ìtàn yín jẹ́ ọ̀kan ti ìgbàgbọ́, ní títẹ̀lé Alápẹrẹ yín, Olùgbàlà Jésù Krístì. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.