Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fífi Ìwàmímọ́ fún Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Fífi Ìwàmímọ́ fún Olúwa

Ìrúbọ dínkù nípa “sísọ nù” àti pùpọ̀ si nípa “fífi fún” Olúwa.

Ní ọdún tó kọjá, nígbàtí mò nsìn nínú Àjọ Ààrẹ Agbègbè Gúsù Asia, mo gba ìpè fóònù kan látọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson tí ó npè mi láti sìn bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Alakoso Bíṣọ́príkì. Ó fi oore-ọ̀fẹ́ pe ìyàwó mi, Lórí, láti darapọ̀ mọ́ ìbárasọ̀rọ̀ náà. Lẹ́hìn tí a parí ìpè, a ṣì wà ní ipò àìgbàgbọ́ nígbàtí ìyàwó mi bèèrè, “Kíni ohun tí Alákóso Bìṣọ́ọ́príkì nṣe ná?” Lẹ́hìn àkokò ìronú díẹ̀, mo fèsì, “Èmi kò mọ̀ ọ́ ní rẹ́gì!”

Ọdún kan lẹ́hìnnáà—àti lẹ́hìn àwọn ìmọ̀lára ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmoore jíjinlẹ̀—mo lè fèsì sí íbééré ìyàwó mi pẹ̀lú ìmọ̀ títóbijù. Ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun míràn, Alákóso Bìṣọ́ọ́príkì nbojútó àláfíà àti ìrànlọ́wọ́ ọmọ-ènìyàn ti Ìjọ. Iṣẹ́ yí nísisìyí káàkiri gbogbo ayé ó sì nbùkún púpọ̀ àwọn ọmọ Ọlọ́run si ju titẹ́lẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́bí Alákóso Bìṣọ́ọ́príkì kan, a nní àtìlẹhìn látọ̀dọ̀ àwọn oníyanu òṣìṣẹ́ Ìjọ àti àwọn ẹlòmíràn, pẹ̀lú Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, tí wọ́n nsìn pẹ̀lú wa lórí Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Àláfíà Ìjọ àti Ìgbẹ́kẹ̀lé-Araẹni. Nínú agbára wa bí ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ náà, Àjọ Ààrẹ Kínní ní kí èmi—bákannáà bí Arábìnrin Eubank, ẹnití ó bá wa sọ̀rọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ àná—ṣe àbápín ìgbéga lórí àwọn ìgbìyànjú tí Ìjọ ti ṣe lórí àwọn ìràn-niyàn-lọ́wọ́ láìpẹ́. Bákannáà nípàtàkì wọ́n ní kí a fi ìmoore ìjìnlẹ̀ wọn hàn—nítorí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀yin ni ẹ̀ nmú kí àwọn ìgbìyànjú ìràn-niyàn-lọ́wọ́ wọnnì ṣeéṣe.

Àwòrán
Àwọn ìdáwó ìrànnìyànlọ́wọ́
Àwòrán
Àfikún àwọn ìdáwó ìrànnìyànlọ́wọ́

Bí a ti ṣàkíyèsí pẹ̀lú àníyàn ní kùtùkùtù ìpalára ọrọ̀-ajé ti ìdààmú COVID-19 káàkiri àgbáyé, a lè ti retí ìrọ̀rùn ìdínkù kan nínú dídá owó èyítí àwọn Ènìyàn Mímọ́ lè fúnni. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, àwọn ọmọ ìjọ wa kò ní àjẹsára sí ìrẹ̀hìn látinú àjàkálẹ̀ àrùn. Ro àwọn ìmọ̀lára wa nígbàtí a kàn ṣàkíyèsí ìdàkejì! Àwọn ìdáwó ìràn-niyàn-lọ́wọ́ ní 2020 ní àbájáde jẹ́ gígajúlọ tí a ti rí láé—àní ó ṣì nlọ sókè si ní ọdún yí. Gẹ́gẹ́bí àyọrísí inúrere yín, Ìjọ ti lè dáhùn sí ìfèsì gígùn látigbà ìbẹ̀rẹ̀ Owó Ìràn-niyàn-lọ́wọ́, pẹ̀lú o ju ẹgbẹ̀rún kan àti ààbọ̀ àwọn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ ní púpọ̀ju orílẹ̀-èdè àádọ́jọ lọ. Àwọn ìdáwó wọ̀nyí, èyí tí ẹ ti fúnni pẹ̀lú àìnímọtaraẹni-nìkan gan sí Olúwa, ni a ti yípadà sí oúnjẹ ìmú-ẹ̀mí-dúró, atẹ́gùn, àwọn ohun-èlò ìlera, àti àwọn àjẹsára fún àwọn bíbẹ́ẹ̀kọ́ tí wọ́n lè ti wà láìní.

Àwòrán
Àwọn asásálà
Àwòrán
Àwọn asásálà
Àwòrán
Àwọn asásálà

Nípàtàkì gẹ́gẹ́bí ìlọ́wọ́sí àwọn ohun-èlò ni ìtújáde títóbi-púpọ̀ ti àkokò àti okun èyí tí àwọn ọmọ Ìjọ ndá sí àwọn ọ̀ràn ìràn-niyàn-lọ́wọ́. Àní bí àjàkálẹ̀ àrùn ti njà, àwọn àjálù àdánidá, ìjà ìgboro, àti àìdájú ọrọ̀-ajé ti jẹ́ àìní-àánú ó sì tẹ̀síwájú láti lé àwọn míllíọ́nù ènìyàn kúrò ní ile wọn. Nísisìyí àwọn United Nation nròhìn pé ó ju míllíọ́nù méjìlélọ́gọ́rin ènìyàn tí a lékúrò tipátipá ní ayé.1 Ní fífikún èyí àwọn míllíọ́nù ti àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n yàn láti kúrò nínú òṣì tàbí ìninilára ní ìwákiri ìgbé-ayé dídára fún arawọn tàbí àwọn ọmọ wọn, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí nní ìwòye títóbi ipò gbogbo-ayè yí.

Inú mi dùn láti ròhìn pé ọpẹ́ fún àkokò olùyọ̀ọ̀da àti àwọn ẹ̀bùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ́ẹ̀, Ìjọ ní gbàgede ìkíni-káàbọ̀ asásálà àti aṣíkiri ní àwọn ibi púpọ̀ ní United States àti Europe. Àti ọpẹ́ fún àwọn ìlọ́wọ́sí yín, a pèsè àwọn ohun-èlò, nínàwó, àti àwọn olùyọ̀ọ̀da láti ran àwọn ètò irúkannáà lọ́wọ́ tí a nṣe nípasẹ̀ àwọn ìṣètò míràn káàkiri àgbáyé.

Njẹ́ kí nnawọ́ ìmoore àtọkànwá mi sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n ti nawọ́ jáde láti bọ́, wọṣọ, ṣọ̀rẹ́, tí wọ́n sì ran àwọn asásálà wọ̀nyí lọ́wọ́ láti di alágbékalẹ̀ àti ànító-araẹni.

Ní ìrọ̀lẹ́ àná, Arábìnrin Eubank pín díẹ̀ lara ìgbìyànjú àwọn Ènìyàn Mímọ́ oníyanu nípa èyí pẹ̀lú yín. Bí mo ti ronú lórí àwọn ìgbìyànjú wọ̀nyí, àwọn èrò mi nígbàkugbà nyí sí ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ìrúbọ àti ìsopọ̀ tààrà nípa ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ sí àwọn òfin nlá méjì ti fífẹ́ràn Ọlọ́run àti fífẹ́ràn aladugbo wa.

Nínú ìlò òde-òní, ọ̀ràn náà ìrúbọ ti wá láti fi èrò ti “sísọnù” àwọn ohun fún Olúwa àti ìjọba Rẹ̀. Bákannáà, ní àwọn ọjọ́ àtijọ, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà ìrúbọ wà ní ìsomọ́ típẹ́típẹ́ sí àwọn gbòngbò Latin rẹ̀ méjì: sákà, túmọ̀ sí “ọ̀wọ̀” tàbí “mímọ́,” àti pé fácérè, túmọ̀ sí “láti ṣe.”2 Báyìí, ìrúbọ àtijọ́ níti-ọ̀rọ̀ tumọ̀ sí mímú ohunkan tàbí ẹnìkan di mímọ́.”3 Ní wíwò bẹ́ẹ̀, ìrúbọ ni ètò kan nípa dídi mímọ́ àti mímọ Ọlọ́run, kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí ọ̀nà-ìsìn “sísọ nù” nípa àwọn ohun fún Olúwa.

Olúwa wípé, “[Ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́] ni mo fẹ́ kì íṣe ìrúbọ; àti ìmọ̀ fún Ọlọ́run ju ọrẹ-ẹbọ.”4 Olúwa nfẹ́ kí a di mímọ́,5 kí a sì ní ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́,6 àti láti mọ̀ Ọ́.7 Bí Àpóstélì Pàùlù ti kọ́ni “Bíótilẹ̀jẹ́pé mo fi gbogbo ohun-ìní mi bọ́ òtòṣì, bíótilẹ̀jẹ́pé mo fi ara mi sílẹ̀ fú jíjó, tí èmi kò ní ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́, kò já mọ́ nkankan fún mi.”8 Nígbẹ̀hìn, Olúwa nfẹ́ ọkàn wa; Ó nfẹ́ kí a di ẹ̀dá titun nínú Krístì.9 Bí ó ti pàṣẹ fún àwọn Néfì, “Ẹ ó fi ẹbọ ìrora ọ̀kàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ fún mi.”10

Àwòrán
Ìwà-mímọ́ sí Olúwa

Ìrúbọ dínkù nípa “sísọ ” àti pùpọ̀ si nípa “fífi fún” Olúwa. Gbígbẹ́ sí orí ìwọlé sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tẹ́mpìlì wa ni àwọn ọ̀rọ̀ “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa; Ilé Olúwa.” Bí a ti nkíyèsí àwọn májẹ̀mú wa nípa ìrúbọ, a nmú wa di mímọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì, àti ní pẹpẹ tẹ́mpìlì mímọ́, pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, a fi ìwà-mímọ́ fún Olúwa. Alàgbà Neal A. Maxwell ti kọ́ni pé: “Fífi ìfẹ́ ti ẹnikàn sílẹ̀ [tàbí ọkàn11] dájúdájú ni ohun araẹni kanṣoṣo tí kò láfiwé tí a níláti fi sí orí pẹpẹ Ọlọ́run. … Bákannáà, nígbàtí ẹ̀yin àti èmi bá fi arawa sílẹ̀ ní òpin, nípa jíjẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run gbé ìfẹ́ wa mi, nígbànáà a nfi ohunkan fún Un dájúdájú!”12

Nígbàtí a bá wo àwọn ìrúbọ wá ní ìtìlẹhìn àwọn ẹlòmíràn látinú ìwò ti “sísọnù,” a lè rí wọn bí àjàgà kí a sì ní ìrẹ̀wẹ̀sì nígbàtí a kó bá dá àwọn ìrúbọ wa mọ̀ tàbí gba èrè. Bákannáà, nígbàtí a bá wo látinú ìwò fifi “fún” Olúwa, àwọn ìrúbọ wa ní ìtìlẹ́hìn àwọn ẹlòmíràn ndi ẹ̀bùn, àti pé fífúnni ayọ̀ inúrere ndi èrè ara rẹ̀. Ní òmìnira kúrò nínú àìní ìfẹ́, àṣẹ, tàbí ìmoore látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, àwọn ìrúbọ wa ndi ìfihàn ìmoore wa mímọ́jùlọ àti jíjinlẹ̀-jùlọ àti ìfẹ́ fún Olùgbàlà àti ọmọnikeji wa. Ọgbọ́n ti ìrúbọ-araẹni kankan pẹ̀lú ìgbéraga nfi ọ̀nà fún ìmọ̀lára ìmoore, pẹ̀lú inúrere, ìtẹ́lọ́rùn, àti ayọ̀13

À nmú ohunkan di mímọ́—bóyá nínú ayé wa, ohun ìní wa, àkokò wa, tàbí ọrẹ wa—kìí ṣe nípa sísọ ọ́ nù ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ nípa yíyàá sọ́tọ̀14 sí Olúwa. Iṣẹ́ ìràn-nìyàn-lọ́wọ́ ti Ìjọ ni irú ẹbùn bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ àbájáde àpapọ̀, ẹbọ yíyàsọ́tọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́, ìfihàn kan nípa ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀.15

Àwòrán
Arábìnrin Canfield pẹ̀lú àwọn tí ó nsìn

Steve àti Anita Canfield ni aṣojú àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn káàkiri àgbáyé tí wọ́n ti ní ìrírí ìyípòpadà àwọn ìbùkún ti fífi fún Olúwa fún arawọn. Bí àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ fún àláfíà àti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, àwọn Canfield ni a ní kí wọ́n pèsè ìrànwọ́ ní àwọn ibùdó asásálà àti gbàgede aṣíkiri káàkiri Europe. Nínú ìmòye ìgbé-ayé rẹ̀, Arábìnrin Canfield ti jẹ́ olùtúnṣe inú-ilé gíga, tí àwọn olùbárà ọlọ́rọ̀ ngbà síṣẹ́ láti fún ilé tàbí ilé-ìtura títòbi wọn lẹ́wà. Lọ́gán, ó rí ararẹ̀ tí a jù ú sínú ayé tí ó jẹ́ ìdàkejì pátápátá sí bí ó ti nsìn ní àárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ sọ ohun gbogbo nù ní ọ̀ràn ohun-ìní ilẹ̀-ayé. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣe pàṣípàrọ̀ “àwọn ọ̀nà-rírìn mábù fún ilẹ̀ ìdọ̀tí,” àti ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ó rí ipò àìníwọ̀n ìmúṣẹ bí òun àti ọkọ rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ láti badọrẹ—àti láìpẹ́ làti fẹ́ àti láti dìmọ́—àwọn tí wọ́n nílò ìkẹ́ wọn.

Àwọn Canfield ṣàkíyèsí pé, “A kò ní ìmọ́ bí i pé a ti ‘sọ’ ohunkóhun nù láti sin Olúwa. Ìfẹ́ wa ni láti ‘fi’ àkokò wa àti okun fún Un láti bùkún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ọ̀nàkọnà tí Ó rí pé ó dára láti lò wá. Bí a ti nṣiṣẹ́ lẹgbẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, ìwò-ìtà kankan—ìyàtọ̀ nínú àbínibí tàbí wíwà-pẹ̀lú kankan—kúrò fún wa, a sì rí ọkàn arawa jẹ́jẹ́. Kò sí àṣeyege ipò iṣẹ́ kankan tàbí ohun-ìní tí a jèrè tí ìbá ti bá ọ̀nà ti àwọn ìrìrí wọ̀nyí, sísìn ní àárín àwọn onírẹ̀lẹ̀jùlọ ọmọ Ọlọ́run, tí ó nbùkún wa dọ́gba.”

Ìtàn àwọn Canfield àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn bíi tirẹ̀ ti ràn mi lọ́wọ́ láti moore àwọn ọ̀rọ̀ orin jẹ́jẹ́ Alakọbẹrẹ ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ ti ó jinlẹ̀:

“Fúnni,” ni odo-ṣíṣàn kékeré wí,

Bí ó ti nyára sọ̀kalẹ̀ ní òkè-kékeré;

“Èmi kéré, mo mọ̀, ṣùgbọ́n níbikíbi tí mo bá lọ

Pápá náà ndagba ni àwọ-ewéko síbẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa kéré, ṣùgbọ́n lápapọ̀ bí a ti nyára láti fifún Ọlọ́run àti ọmọnikeji wa, níbikíbi tí a bá lọ̀ à nṣìkẹ́ a sì nbùkún àwọn ìgbé-ayé.

Ẹsẹ kẹta orin yí ni a kò mọ̀ púpọ̀ ṣùgbọ́n ó parí pẹ̀lú ìpè ìfẹ́ni yí:

Fúnni, nígbànáà, bí Jésù ti fúnni

Ohunkan wà tí gbogbo wa lè fúnni.

Ṣe bí odò-ṣíṣàn kí a sì gbìlẹ̀:

Ẹ gbé ìgbé-ayé fún Ọlọ́run àti fún àwọn míràn.16

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ti ngbé ìgbé-ayé fún Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn nípa fífúnni ní iní wa, àkokò wa, àti bẹ́ẹ̀ni, àní arawa, à nfi ayé sílẹ̀ ní àwọ̀-ewéko díẹ̀ si, a sì nfi àwọn ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀ ní dídunnú díẹ̀ si, àti, nínú ètò náà, a ndi mímọ́ díẹ̀ si.

Njẹ́ kí Olúwa bùkún yín pẹ̀lú ọrọ̀ fún àwọn ìrúbọ tí ẹ̀ nfi fún Un ní ọ̀fẹ́.

Mo mọ̀ pé Ọlọ́run wà láàyè. “Ẹni Ìwàmímọ́ ni orúkọ rẹ̀.”17 Jésù Krístì ni Ọmọ Rẹ̀, Òun sì ni olùfúnni gbogbo àwọn ẹ̀bùn rere.18 Njẹ́ kí àwà, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ àti àkíyèsí ti àwọn májẹ̀mú wa nípa ìrúbọ, di mímọ́ kí a sì fúnni ní ìfẹ́ àti ìwà-mímọ́ síi fún Olúwa títí.19 Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo “Global Trends: Forced Displacement in 2020,” UNHCR report, June 18, 2021, unhcr.org.

  2. Ìrúbọ ni a rí látinú Latin sacrificium, which is comprised of the two Latin roots sacer and facere, according to the Merriam-Webster Dictionary (see merriam-webster.com). Ọ̀rọ̀ náà sacer means“sacred” or “holy,” and the word facere means “to make or do,” according to the Latin-English Dictionary (wo latin-english.com).

  3. Guide to the Scriptures, “Ìrúbọ,”scriptures.ChurchofJesusChrist.org.

  4. Hosea 6:6; see footnote b, indicating that mercy in Hebrew means “charity” or “lovingkindness.” Bákannáà wo Matthew 9:10–13; 12:7.

  5. Wo Leviticus 11:44.

  6. Wo Mórónì 7:47.

  7. Wo Mòsíàh 5:13.

  8. 1 Corinthians 13:3; bákannáà wo Mosiah 2:21.

  9. Wo 2 Kọ́ríntì 5:17.

  10. 3 Nephi 9:20, emphasis added; see also verse 19.

  11. Ọ̀rọ̀ náà ọkàn ni a fikun nihin bí irúkannáà fún ifẹ́.

  12. Neal A. Maxwell, “Gbígbémì nínú Ìfẹ́ Baba,” Ensign, Nov. 1995, 24; emphasis added. Bákannáà wo Omni 1:26; Romans 12:1.

  13. Wo Moroni 10:3.

  14. Yàsọ́tọ̀ túmọ̀ sí “kéde tàbí gbé sọ́tọ̀ bí ohun mímọ́,” gẹ́gẹ́bí American Heritage College Dictionary

  15. Wo Máttéù 22:36–40.

  16. “‘Fúnni,’ Said the Little Stream,” Children’s Songbook, 236.

  17. Mósè 6:57.

  18. Wo Mórónì 07:24.

  19. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 97:8.