Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Aláfíà Araẹni ní àwọn Akókò Ìpènijà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Aláfíà Araẹni ní àwọn Akókò Ìpènijà

Kò tíì jẹ́ pàtàkì jù rí láti wá àláfíà araẹni.

Láìpẹ́ mo gba ìfúnni-níṣẹ́ láti ya apá kan ti Nauvoo onítàn símímọ́. Bí apákan ìfúnni-níṣẹ́, mo ṣe ìbẹ̀wò sí Ẹ̀wọ̀n Liberty ní Missouri. Bí mo ti wò ẹ̀wọ̀n náà, mo gbèrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mu jẹ́ irú apákan pàtàkì àkọsílẹ̀-ìtàn Ìjọ. Ìgbé-ayé àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní ewu gẹ́gẹ́bí àbájáde èrò lílékúrò tí gómìnà Missouri fún wọn. Ní àfikún, Wòlíì Joseph àti díẹ̀ àwọn olùbárìn yíyàn ti wọ àtìmọ́lé nínú ẹ̀wọ̀n Liberty ní àìṣòdodo. Ọ̀kan lára àwọn èrèdí fún àtakò líle náà sí àwọn ọmọ-ìjọ wa ní pé púpọ̀jùlọ lára wọn ntàko kíkólẹ́rú.1 Inúnibíni líle ti Joseph Smith yí àti àwọn àtẹ̀lé rẹ jẹ́ àpẹrẹ kíkọjá-àlà lílo agbára òmìnira àìṣòdodo tí ó lè pa àwọn olódodo ènìyàn lára. Àkokò Joseph ní Ẹ̀wọn Líberty júwe pé ìpọ́njú náà kìí ṣe ẹ̀rí àìkàkún tàbí ìmúkúrò àwọn ìbùkún Olúwa.

Ó wọ̀ mí lọ́kàn jìnlẹ̀ bí mo ti ka ohun tí Wòlíì Joseph kéde bí a ti tì í mọ́ Ẹ̀wọ̀n Liberty: “Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wa? Àti pé níbo ni àgọ́ ti o bo ibi ìpamọ́ rẹ?”2 Joseph bèèrè bí yíò ti pẹ́ tó tí àwọn ènìyàn Olúwa yíò fi “jìyà àwọn àìṣedéédé wọ̀nyí àti ìnilára tí kò bá òfin mu.”3

Àwòrán
Alàgbà Cook nbẹ Ẹ̀wọ̀n Liberty wo

Bí mo ti dúró ní Ẹ̀wọ̀n Liberty, mo ní ìfọwọ́kàn tó jinlẹ̀ bí mo ti ka ìdáhùn Olúwa: “Ọmọ mi, àláfíà ni fún ọkàn rẹ̀; ìdàmú rẹ àti àwọn ìpọ́njú rẹ yíò wà ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀; àti nígbànáà, bí ìwọ bá fi orí tìí dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga lókè.”4 Ó hàn kedere pé àtakò lè tún wa ṣe fún àyànmọ́ ayérayé, sẹ̀lẹ́stíà.5

Àwọn ọ̀rọ̀ iyebíye Olùgbàlà “Ọmọ mi, àláfíà ni fún ọkàn rẹ”6 níbamu pẹ̀lú mi níti-ara ó sì ní pàtàkì íṣe fún ọjọ́ wa. Wọ́n rán mi léti nípa ìkọ́ni Rẹ̀ sí awọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nígbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé-ikú Rẹ̀.

Ṣíwájú sí ìjìyà Krístì nínú Ọgbà Gẹ́tsémánì àti lórí àgbélèbú, Ó pàṣẹ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ “ẹ fẹ́ràn ara yín; bí Èmi ṣe fẹ́ yín”7 bíi ti tẹ́lẹ̀ Ó sì tún tù wọ́n nínú pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fún yín: kìí ṣe bí ayé tií fún ni, ni mo fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”8

Ọ̀kan lára àwọn àkọlé Olúwa àti Olùgbàlà, Jésù Krístì wa tí a ṣìkẹ́ jùlọ, ni “Aládé Àláfíà.”9 Nígbẹ̀hìn ìjọba Rẹ̀ ni a ó gbékalẹ̀ pẹ̀lú àláfíà àti ìfẹ́.10 À nwo iwájú fún ìjọba mìllẹ́níà ti Mèssíàh.

Bí ó ti wù kí ìran ti ìjọba mìllẹ́níà yí rí, a mọ̀ pé àláfíà àti ìrẹ́pọ̀ ayé kò wọ́pọ̀ ní ọjọ́ wa.11 Ní ìgbà ayé mi, èmi ko rí àìsí ọ̀làjú títóbijù rí-rárá. A bò wá mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìbínú, èdè ìjà àti ìmúni-bínú, àwọn ìṣé ìbàjẹ́ tí ó npa àláfíà àti ìfọkànbalẹ̀ run.

Àláfíà nínú ayé ní a kò ní ìlérí tàbí ìdánilójú títí Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Jésù Krístì. Olùgbàlà pàṣẹ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé Rẹ̀ kò ní mú àláfíà gbogbo-ayé wá. Ó kọ́, “Ẹ máṣe rò pé mo wá láti rán àláfíà wá sórí ilẹ̀-ayé.”12 Àláfíà gbogbo-ayé kìí ṣe ara iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé-ikú Olùgbàlà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Àláfíà gbogbo-ayé kò sí ní òni.

Bákannáà, àláfíà araẹni ni a lè múwá biótilẹ̀jẹ́pé ìbínú, ìjà, àti ìyapa tí ó nbajẹ́ tí ó sì nsọ ayé wa ní òní di asán wà. Kò tíì jẹ́ pàtàkì jù èyí rí láti wá àláfíà araẹni. Ọrin alàrinrin àti àyànfẹ́ titun tí a kọ fún àwọn ọ̀dọ́ òní láti ẹnu Arákùnrin Nik Day, àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àláfíà nínú Krístì” kéde pé, “Nígbàtí kò bá sí àláfíà mọ́ lórí ilẹ̀-ayé, àláfíà wà nínú Krístì.”13 A di alábùkúnfún láti ní orin yí kété ṣíwájú àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 gbogbogbò.

Orin yí hàn nínú ẹ̀ṣọ́ dídára ti lílépa fún àláfíà àti ìtẹnumọ́ déédé pé àláfíà ni ìdákòró nínú ayé àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ Jésù Krístì. Ààrẹ Joseph F. Smith kéde, “Ẹ̀mí àláfíà àti ìfẹ́ náà kò lè wá sí ayé láéláé … àyàfi tí gbogbo-ènìyàn yíò bá gba òtítọ́ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run … kí wọ́n sì dá ìmọ̀ àti àṣẹ Rẹ èyí tí ó jẹ́ tọ̀run mọ̀.”14

Nígbàtí a kò ní padà kúrò nínú ìtiraka láti ṣe àṣeyọrí àláfíà gbogbo-ayé, a ti fi dá wa lójú pé a lè ní àláfíà araẹni, bí Krístì ti kọ́ni. Ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ yí ni a gbékalẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú: “Ṣùgbọ́n kẹkọ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ òdodo yíò gba èrè rẹ̀, àní àláfíà ní ayé yí, àti ìyè ayérayé ní ayé ti nbọ̀.”15

Kíni díẹ̀ lára “àwọn iṣẹ́ òdodo” tí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àríyànjiyàn kí a sì dín ìjà kù kí a sì rí àláfíà nínú ayé yí? Gbogbo àwọn ìkọ́ni Krístì tọ́ka sí ìdárí yí. Èmi yíò dárúkọ díẹ̀ èyítí mo gbàgbọ́ pé wọ́n ṣe kókó nípàtàkì.

Àkọ́kọ́, Ìfẹ́ Ọlọ́run, Ẹ gbé àwọn Òfin Rẹ̀, kí ẹ sì Dáríji Gbogbo-ènìyàn.

Ààrẹ George Albert Smith di Ààrẹ Ìjọ ní 1945. A ti mọ̀ ọ́ nígbà àwọn ọdún rẹ̀ bí Àpóstélì bí olórí olùfẹ́ni-àláfíà. Ní àwọn ọdún mẹẹdogun ṣíwájú ki ó tó di Ààrẹ, àwọn ìpènijà àti àwọn àdánwò ìjákulẹ̀ púpọ̀ ní gbogbo-ayé, tí ikú àti ìparun Ogun Àgbáyé Kejì tẹ̀lé, ti jẹ́ ohunkóhun ṣùgbọ́n àláfíà.

Ní ìparí Ogun Àgbáyé Kejì, nígbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní Oṣù Kẹwa 1945, Ààrẹ Smith rán àwọn Ènìyàn Mímọ́ létí nípa ìpè Olùgbàlà láti nifẹ aladugbo wọn kí wọ́n sì dáríji àwọn ọ̀tá wọn ó sì kọ́ni nígbànáà pé, “Ìyẹn ni ẹ̀mí tí ó yẹ kí gbogbo àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wá láti ní bí wọ́n bá nírètí láti dúró ní iwájú Rẹ̀ kí wọ́n sì gba ìkíni-káàbọ̀ ológo ní ọwọ́ Rẹ̀ níjọ́kan.”16

Ékejì: Wá àwọn Èso Ẹ̀mí

Àpóstélì Páùlù nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Gàlátíà, gbé ìyàtọ̀ ní àárín àwọn iṣẹ́ òdodo tí ó mú wa yẹ láti jogún ìjọba Ọlọ́run àti àwọn iṣẹ́ tí ó lè, mu wa jẹ́ àìyẹ, láìsí ìrònúpìwàdà. Ní àárín àwọn ohun tí ó mú wa yẹ ni àwọn èso ti ẹ̀mí “ìfẹ́, ayọ̀, àláfíà, ìparamọ́ra, sùúrù, ìwàrere, ìgbàgbọ́, inútútù, [àti] ìfaradà.”17 Páùlù bákannáà fi gbígbé àjàgà arawa pẹ̀lú àti kí ó máṣe rẹ̀ wa ní ṣíṣe-rere.18 Ní àárín àwọn iṣẹ́ tí kìí ṣe òdodo ni ó fi ìkórira, asọ̀, àti ìjà sí pẹ̀lú.19

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ nlá ní ìgbà Májẹ̀mú Láéláé bá Baba Ábráhámù mu. Ábráhámù àti Lọ́tì, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ní ọrọ̀ ṣùgbọ́n wọn ri pé wọn kò lè gbé papọ̀. Láti mú ìjà kúrò Ábráhámù gba Lọ́tì láàyè láti yan ilẹ̀ tí ó nfẹ́. Lọ́tì yan pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordan, èyí tí ó ní omi-dáadáa àti ẹwà pẹ̀lú. Ábráhámù mú pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Mamre tí ó dínkù ní ọ̀rá. Àwọn ìwé-mímọ́ kà pé Ábráhámù nìgbànáà tẹ̀dó àgọ́ rẹ̀ ó sì kọ́ “pẹpẹ kan fún Olúwa.”20 Lọ́tì, ní ọ̀nà míràn, “tẹ̀dó pẹpẹ rẹ̀ síwájú Sódómù.”21 Láti ní àwọn ìbáṣepọ̀ àláfíà, ẹ̀kọ́ náà hàn kedere pé: a níláti fẹ́ láti làjà kí a sì mú ìjà kúrò pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí àwọn ọ̀ràn tí kò wà-pẹ̀lú òdodo. Bí Ọba Benjamin ti kọ́ pé, “Ẹ̀yin kò ní ní èrò láti pa arayín lára, ṣùgbọ́n láti gbé ìgbé-ayé alálàáfíà.”22 Ṣùgbọ́n lórí ìwà tí ó ní ìbámu sí òdodo àti ẹ̀kọ́ àìnípá, a nílò láti dúró gbọingbọin àti ṣinṣin.

Bí a bá fẹ́ láti ní àláfíà èyítí ó jẹ́ èrè àwọn iṣẹ́ òdodo, a kò tẹ àwọn àgọ́ wa dó síwájú ayé. A ó tẹ àwọn àgọ́ wa dó síwájú tẹ́mpìlì.

Ẹkẹ́ta: Lo Agbára Òmìnira láti Yan Òdodo

Àláfíà àti agbára òmìnira wa papọ̀ bí àwọn ohun-èlò pàtàkì ti ètò ìgbàlà. Bí a ti júwe nínú àkọlé ìhìnrere lórí “Agbára Òmìnira àti Ìjabọ̀,” “Agbára òmìnira ni agbára àti ànfàní tí Ọlọ́run fún wa láti yàn àti láti ṣe ìṣe fún arawa.”23 Báyìí, agbára òmìnira wà ní oókan ìdàgbà araẹni àti ìrírí tí ó nbùkún wa bí a ti ntẹ̀lé Olùgbàlà.24

Agbára òmìnira ni kókó ọ̀ràn nínú Ìgbìmọ̀ ìṣíwáju-ayé ní Ọ̀run àti ìjà ní àárín àwọn tí wọ́n yàn láti tẹ̀lé Krístì àti àwọn àtẹ̀lé Sátánì.26 Fífi ìgbéraga sílẹ̀ àti dídarí àti yíyan Olùgbàlà yíò fàyè gbà wá láti ní ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ àti àláfíà Rẹ̀. Ṣùgbọ́n àláfíà araẹni ni a ó pè níjà nígbàtí àwọn ènìyàn bá lo agbára òmìnira wọn ní àwọn ọ̀nà ìpalára àti ewu.

Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìdánilójú àláfíà tí a ní ìmọ̀lára nínú ọkàn wa ni a fún lókun nípasẹ̀ ìmọ̀ tí a ní nípa ohun tí Olùgbàlà ayé yíò ṣeyọrí ní ìtìlẹhìn wa. Èyí ni a gbé kalẹ̀ dáradára nínú Wàásù Ìhinrere Mi: “bí a ti ngbọ́kànlé Ètùtù Jésù Krístì, Òun lè ràn wá lọ́wọ́ láti farada àwọn àdánwò, àìsàn, àti ìrora wa. A lè kún fún ayọ̀, àláfíà, àti àrọwà. Gbogbo ohun tí kò dára nípa ìgbé-ayé ni a lè mú yẹ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”3

Ẹ̀kẹ́rin: Gbé Síónì Sókè Nínú Ọkàn àti Ilé Wa

A jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run ara ẹbí Rẹ̀ sì ni wa. Bákannáà a jẹ́ ara ẹbí sínú èyí tí a bí wa sí. Gbígbékalẹ̀ ẹbí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún méjèèjì ìdùnnú àti àláfíà. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa—àti nígbà àjàkálẹ̀ àrùn yí a ti kọ́—pé àkíyèsí ẹ̀sìn gbùngbun-ilé àtìlẹhìn-Ìjọ̀, lè “tú agbára ẹbí jáde … láti yí [àwọn] ile [wa] padà sí ìbi-mímọ́ ìgbàgbọ́.”28 Bí a bá ní àkíyèsí ẹ̀sìn yí nínú ilé wa, bákannáà a ó ní àláfíà Olùgbàlà.29 A ní ìfura pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín kò ní àwọn ìbùkún ilé òdodo ẹ sì njà léraléra pẹ̀lú àwọn tí wọ́n yan àìṣòdodo. Olùgbàlà lè pèsè ààbò àti àláfíà láti tọ́ yín sọ́nà nígbẹ̀hìn sí ìgbàlà àti asà kúrò nínú àwọn ìjì ayé.

Mo mu dá yín lójú pé ayọ̀, ìfẹ́, àti ìrírí ìmúṣẹ nínú ẹbí ìfẹ́ni, òdodo nmú àláfíà àti ìdùnnú jáde pẹ̀lú. Ìfẹ́ àti inúrere jẹ́ gbùngbun níní Síónì nínú ọkàn àti ilé wa.30

Ẹkarun: Tẹ̀lé àwọn Ìkìlọ̀ Wòlíì Wa Lọ́wọ́lọ́wọ́

Àláfíà wa ngbòòrò ní títóbi si nígbàtí a bá tẹ̀lé wòlíì Olúwa, Ààrẹ Russell M. Nelson. Àwa ó ní ànfàní láti gbọ́ ní ẹnu rẹ̀ láìpẹ́. A ti múra rẹ̀ sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ìpè yí. Ìmúrasílẹ̀ araẹni rẹ̀ ti lápẹrẹ jùlọ.31

Ó ti kọ́ wa pé a lè “nìmọ̀lára àláfíà àti ayọ̀ pípẹ́ àní ní àwọn ìgbà rúdurùdu,” bí a ti ntiraka láti dà bíiti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì síi32 Ó ti gbà wá lámọ̀ràn láti “ronúpìwàdà lójojúmọ́” láti gba “ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti agbára ìfúnni-lókun Olúwa.”33 Mó jẹ́ ẹlẹri araẹni kan pé a ti gba ìfihàn a ó sì tẹ̀síwájú láti gbà á láti ọ̀run nípasẹ̀ olólùfẹ́ wòlíì wa.

Nígbàtí a bá bu-ọlá tí a sì ṣe ìmúdúró fun bí wòlíì wa, a njọ́sìn Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà, Jésù Krístì. A ngba iṣẹ́-ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

Mo jẹ́ ẹ̀rí mo sì pèsè ẹ̀rí araẹni jíjẹ́-àpóstélì mi pé Jésù Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà ayé, ndarí ó sì ntọ́ ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀ sọ́nà. Ìgbé ayé Rẹ̀ àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ ètùtù ni orísun àláfíà òtítọ́. Òun ni Aládé Àláfíà. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi dídájú àti ọ̀wọ̀ pé Ó wà láàyè. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “People in Independence did not like that the Saints preached to Indians and disapproved of slavery” (Saints: The Story of the Church of Jesus Christ in the Latter Days, vol. 1, The Standard of Truth, 1815–1846 [2018], 172).

  2. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:1.

  3. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:3.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:7–8.

  5. Wo 2 Néfì 2:11–15.

  6. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:7.

  7. Jòhánnù 13:34.

  8. Johanu 14:27.

  9. Isaiah 9:6; 2 Nephi 19:6. The Savior in His beatitudes also taught, “Blessed are the peacemakers: for they shall be called the children of God” (Matthew 5:9).

  10. “With judgment and with justice … for ever” (see Isaiah 9:6–7; 2 Nephi 19:6–7; see also Galatians 5:22).

  11. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:35. Ààrẹ Wilford Woodruff kéde èyí ní 1894 and again in 1896 (wo The Discourses of Wilford Woodruff, sel. G. Homer Durham [1946], 251–52; bákannáà wo Marion G. Romney, in Conference Report, Apr. 1967, 79–82; Ezra Taft Benson, “The Power of the Word,” Ensign, May 1986, 79–80; Dallin H. Oaks, “Preparation for the Second Coming,” Liahona, May 2004, 9).

  12. Máttéù 10:34.

  13. Nik Day, “Peace in Christ,” 2018 Mutual theme song, Liahona, Jan. 2018, 54–55; New Era, Jan. 2018, 24–25. Orin “Àláfíà nínú Krítì kọ́ni:

    Nígbàtí a bá gbé ní ọ̀nà tí Ó gbé,

    Àláfíà wà nínú Krístì.

    Ó fún wa ní ìrètí

    Nígbàtí ìrètí ti lọ.

    Ó fún wa ní okun

    Nígbàtí a kó lè tẹ̀ síwájú.

    Ó fún wa ní ibùgbé

    Nínú àwọn ìjì ayé

    Nígbàtí kò sí àláfíà ni ilẹ̀-ayé.

    Àláfíà wà nínú Krístì.

  14. Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph F. Smith (1998), 400.

  15. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:23.

  16. Wo Joseph Fielding Smith, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀, Oct. 1945, 169–70.

  17. Galatians 5:22–23.

  18. Wo Galatians 6:2, 9.

  19. Wo Galatians 5:20.

  20. Gẹnẹsisi 13:18.

  21. Gẹnẹsisi 22:12.

  22. Mòsíàh 4:13.

  23. Àwọn Àkọlé Ìhìnrere, “Agbára Òmìnira àti Ìjabọ̀,” topics.ChurchofJesusChrist.org.

  24. A wà “ní ìfẹ́ láti yan òmìnira àti ìyè ayérayé, nípasẹ̀ Olùlàjà nlá gbogbo ènìyàn” (2 Nephi 2:27). Agbára òmìnira bákannáà fàyè gba àwọn yíyàn ibi ìpanirun àwọn míràn láti fa ìrora àti ìjìyà àti nígbàmíràn àní ikú. Àwọn ìwé-mímọ́ mu hàn kedere pé ó dájú pé Olúwa Ọlọ́run fúnni ní agbára òmìnira kí ènìyàn lè yan rere tàbí ibi (wo 2 Nephi 2:16).

  25. Àwọn Àkọlé Ìhìnrere, “Agbára Òmìnira àti Ìjabọ̀,” topics.ChurchofJesusChrist.org.

  26. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìsìn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere (2019), 52, ChurchofJesusChrist.org; emphasis added.

  27. Russell M. Nelson, “Dída àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Alápẹrẹ,” LiahonaNov. 2018, 113.

  28. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:23.

  29. I was fortunate to grow up in a home where peace prevailed. This was primarily due to the influence of our mother, who was a faithful member of the Church. My father was outstanding in every way but was less active. Mother honored our father and avoided contention. She taught us as children to pray and attend Church. She also taught us to love and serve each other (wo Mosiah 4:14–15). Growing up in such a home provided peace and has been a great blessing in my life.

  30. Russell M. Nelson graduated from the University of Utah Medical School first in his class at age 22. He had long desired to be a surgeon and received the best training available at major medical institutions. He faithfully fulfilled military commitments in Korea and Japan. For many years he was a pioneer in open-heart surgery and was recognized worldwide. As remarkable as this preparation was to bless people all over the world with his medical skills, President Nelson’s spiritual preparation was even more important. He is the father of a large family of children, grandchildren, and great-grandchildren. Ó ti fi ìgbàgbọ́ sìn àwọn ẹbí rẹ̀ àti Ìjọ ní gbogbo ayé rẹ̀.

  31. Wo Russell M. Nelson, “Opening Message,” Liahona, May 2020, 6; see also Russell M. Nelson, “Joy and Spiritual Survival,” Liahona, Nov. 2016, 81–84.

  32. Russell M. Nelson, “Ọ̀rọ̀ Íṣaájú,” 6.