Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pẹ̀lú Agbára Ọlọ́run nínú Ògo Nlá
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Pẹ̀lú Agbára Ọlọ́run nínú Ògo Nlá

(1 Néfì 14:14)

Bíbu-ọlá fún awọn májẹ̀mú nmú wa gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.

Mo gbàdúrà pé Ẹmí Mímọ́ yío kọ́ wa yío sì gbé gbogbo wa ga bí a ṣe jùmọ̀ nwo iṣẹ́ ìyanu ti ìgbàlà àti ìgbésókè nínú iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò.

Ìbẹ̀wo Àkọ́kọ́ Mórónì sí Joseph Smith

Ní ìwọ̀n ọdún mẹ́ta lẹ́hìn Ìran àkọ́kọ́, ní alẹ́ Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹsan, 1823, ọ̀dọ́ Joseph Smith ngbàdúrà láti gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti láti mọ ipò rẹ àti ìdúró rẹ níwájú Ọlọ́run.1 Ẹni-nlá kan farahàn ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀, ó pe Joseph ní orúkọ, ó sì kéde pé “òun jẹ́ ìránṣẹ́ tí a rán látọ̀dọ̀ Ọlọ́run … àti pé orúkọ rẹ̀ ni Mórónì.” Ó ṣàlàyé “pé Ọlọ́run ni iṣẹ́ kan fún [Joseph] láti ṣe”2 Ó sì fun ní àṣẹ nípa bíbọ̀ wá Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní pàtàkì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn àkòrí àkọ́kọ́ tí a tọ́ka sí nínú ọ̀rọ̀ Mórónì.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì àti irin-iṣẹ́ nlá ti ìyípadà ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ìdí wa ní pípín ìhìnrere ni láti pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì,3 gba àwọn ìbùkún ti ìhìnrere tí a múpadàbọ̀sípò, ki a si faradà títí dé òpin nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà.4 Ríran àwọn ẹnì-kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti ní ìrírí ìyípada nla ti ọkàn5 àti dídi ara wọn mọ́ Olúwa nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà mímọ́ jẹ́ àwọn èrò-inú ìpìlẹ̀ ti wíwàásù ìhìnrere.

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú Mórónì ti Ìwé Mọ́mọ́nì si Joseph Smith bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga fún àwọn ẹní-kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ti ìbòjú yí nínú iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò.

Ní títẹ̀síwájú ìkọ́ni rẹ̀ sí Joseph, Mórónì ṣe àtúnsọ látinú iwé Málákì nínú Májẹ̀mú Láéláé, pẹ̀lú ìyípada díẹ̀ nínú èdè tí a lò nínú Ẹ̀dà ti Ọba Jákọ́bù:

“Kíyèsĩ, èmi yíò fi Oyè-àlùfáà hàn síi yín, láti ọwọ́ wòlíì Èlíjàh, kí ọjọ́ Olúwa nã èyítí í ṣe nlá tí ó sì ní ẹ̀rù tó dé. …

“… Òun ó sì gbin àwọn ìlérí tí a ṣe sí àwọn bàbá sínú ọkàn àwọn ọmọ, ọkàn àwọn ọmọ yíò sì yí padà sí àwọn baba wọn. Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé yíò ṣòfò pátápátá ní bíbọ̀ rẹ̀.”4

Ìdí wa fún kíkọ àwọn tẹ́mpìlì ni láti pèsè àwọn ibi mímọ́ nínú èyítí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà mímọ́ tí ó wúlò fún ìgbàlà àti ìgbéga ti ẹbí ẹ̀dá ènìyàn ti le jẹ́ síṣe, fún àwọn alãye àti àwọn òkú. Ìkọ́ni Mórónì sí Joseph Smith nípa ipa pàtàkì ti Èlíjàh àti àṣẹ oyè-àlùfáà mú iṣẹ́ ìgbàlà náà àti ìgbéga gbòòrò ní ẹ̀gbẹ́ ti ìbòjú yí àti pé ó mú iṣẹ́ fún àwọn okú ní apa keji ibojú naa wọ inú ìgbà ìríjú wa.

Ní àkópọ̀, àwọn ìkọ́ni Mórónì ní Oṣù Kẹsan ọdún 1823 nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjàh fi ìdí ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ múlẹ̀ fún iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìbòjú náà.

Àwọn ẹ̀kọ́ ti Wòlĩ Joseph Smith.

Àwọn ẹ̀kọ́ tí Joseph Smith kọ́ láti ọwọ́ Moroni ní ipa lórí gbogbo abala iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ. Fún àpẹrẹ, nínú àpéjọ kan tó ní ọ̀wọ̀ tí a ṣe ní Tẹ́mpìlì Kirtland ní Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin,1837, Wòlíì kéde, “Lẹ́hìn gbogbo èyí tí a ti sọ, ojúṣe títóbi àti pàtàkì jùlọ ni láti wàásù Ìhìnrere.”

Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ọdun méje gérégé lẹ́hìnnáà, ní Ọjọ́ Keje Oṣù Kẹ́rin, 1844, Joseph Smith ṣe ìwàásù kan ti a mọ̀ loni bi Ìbánisọ̀rọ̀ Follett King. Wòlíì Joseph Smith sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ náà pé, “Ojúṣe nlá jùlọ nínú ayé yí tí Ọlọ́run tí gbé fún wa ní láti wá àwọn òkú wa.”8

Ṣùgbọ́n báwo ni méjèèjì wíwàásù ìhìnrere àti wíwá àwọn okú wa ṣe lè jẹ́ iṣẹ́ ẹyọkan tí ó tóbi jùlọ ti Ọlọ́run ti gbé sórí wa? Mo gbàgbọ́ pé Wòlíì Joseph Smith ntẹnumọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì òtítọ́ ìpìlẹ̀ pé àwọn májẹ̀mú, tí a wọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìlànà oyè àlúfáà tí ó ní àṣẹ, lè so wá pọ̀ mọ́ Olúwa Jésù Krístì àti pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì ti iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìbòjú náà .

Iṣẹ́-Ìránṣẹ́ ati iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti àkọsílẹ̀-ìtàn ẹbí jẹ́ ìbáramu àti àwọn abala tí ó bára tan nínú iṣẹ́ nla kan tí ó fojúsùn sí àwọn májẹ̀mú mímọ́ àti àwọn ìlànà tí ó fún wa láàyè láti gba agbára ìwà-bí-Ọlọ́run nínú àwọn ìgbésí ayé wa àti, níkẹhìn, padà sí ọ̀dọ̀ Bàbá Ọ̀run. Nítorínáà, àwọn ọ̀rọ̀ meji láti ẹnu Wòlíì tí ó lè kọ́kọ́ farahàn bíi pé wọ́n tako ara wọn, ní òtítọ́, ṣe àfihàn àmì pàtàkì ti iṣẹ́ nla ọjọ́-ìkẹhìn yii.

So mọ́ Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú ati àwọn Ìlànà

Olùgbàlà wípé:

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”9

A ngba àjàgà Olùgbàlà sí ọrùn wa bí a ṣe nkẹ́kọ̀ọ́ nípa, ngbà ní yíyẹ, àti bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà mímọ́ . A njẹ́ sísopọ̀ láìléwu mọ́ àti pẹ̀lú Olùgbàlà bí a ti nfi òtítọ́ rántí tí a sì nṣe dídára jùlọ tí a le ṣe láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ojúṣe tí a ti gbà. Àti pé àsopọ̀ náà pẹ̀lú Rẹ̀ ní orísun okun ti ẹ̀mí ni gbogbo ìgbà àwọn ìgbésí ayé wa.

Àwọn Ènìyàn Májẹ̀mú Olúwa

Mo pè yín láti ṣe àkíyèsí àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí fún àwọn olùpamọ́-májẹ̀mú ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì. Fún àpẹrẹ, Néfì “wo ìjọ ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run [ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn], àti pé iye rẹ̀ kéré, … àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé pẹ̀lú; awọn ijọba wọn sì… jẹ́ kékeré.”10

Òun náà “kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ Ọ̀dọ́-àgùtàn náà, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, … wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.”11

Gbólóhùn náà “gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá” kìí ṣe ìmọ̀ràn tí ó wuyì lásán tàbí àpẹẹrẹ tí èdè ìwé mímọ́ tí ó lẹ́wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìbùkún wọ̀nyí hàn gbangba nínú àwọn ìgbésí ayé àìmọye àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Olúwa ọjọ́ ìkẹhìn.

Àwọn iṣẹ́ ìyànsílẹ̀ mi gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹgbẹ́ Méjìlá gbé mi kiri gbogbo àgbáyé. Àti pé a ti bùkún mi láti pàdé àti láti kọ àwọn ẹ̀kọ́ tí ó yẹ ní ìrántí láti ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín. Mo jẹ̀ri pé àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa loni nítòótọ́ ti gbaradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nla. Mo ti rí ìgbàgbọ́, ìgboyà, ìwòye, ìtẹramọ́, àti ayọ̀ tí ó gbòòrò jìnnà ju ipa ènìyàn kíkú lọ—àti tí Ọlọ́run nìkan lè pèsè.

Mo ti rí òdodo àti agbára Ọlọ́run nínú ògo nla, tí a gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà, ni ìgbésí-ayé ọdọ ọmọ Ìjọ kan tí ó yarọ ní apákan ara nínú ìjàmbá mọ́tò nlá kan. Lẹ́hìn àwọn oṣù síṣoro ti gbígba ìmúláradá àti àtúnṣe sí ìgbésí ayé titun pẹ̀lú àìsí òmìnira láti ṣípòpadà, mo pàde mo sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú akíkanjú ẹ̀mí yii. Lákokò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wa mo béèrè pé, “Kíni ìrírí yii ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́?” Ìdáhùn ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni, “Èmi kò banújẹ́. Èmi kò ya wèrè. Àti pé ohun gbogbo yio dára.”

Mo rí òdodo àti agbára Ọlọ́run nínú ògo nla, tí a gba nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlàna, ninú àye àwọn kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi tí a sì fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ. Àwọn olùyípadà wọ̀nyí ní ìtara láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti sìn, wọ́n ní ìfẹ́-inú ṣùgbọ́n nígbàgbogbo wọn kò ní ìdánilójú nípa bí a ṣe lè fi àwọn ìwà àtijọ́ àti àwọn àṣà tí ó lágbára sílẹ̀, àti síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ní ìdùnnú láti di “àjùmọ̀kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti ilé Ọlọ́run.”12

Mo rí òdodo àti agbára Ọlọ́run nínú ògo nla, tí a gba nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlàna, ni ìgbé ayé ẹbí kan tí wọ́n ṣe ìtọ́jú fún tọkọ-taya àti òbí kan pẹ̀lú àìsàn pípani. Àwọn akíkanjú ọmọ-ẹ̀hìn wọ̀nyí ṣe àpèjúwe àwọn àkókò ti ìdílé wọn ní ìmọ̀lára pé wọ́n nìkan wa—àti àwọn àkókò tí wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ngbé wọn sókè tí ó sì nfún wọn ní okun. Ẹbí yìí fi ìmoore tòótọ́ hàn fún àwọn ìrírí síṣòro ti ayé ikú tí ó gbà wá láàyè láti dàgbà kí a sì dàbí Baba wa Ọ̀run àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì. Ọlọ́run ìtùnú Ó sì bùkún fún ẹbí yii pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́ Ó sì ṣe ilé wọn bi ibi mímọ́ kan bi ibi ìsádi bíi tẹ́mpìlì.

Mo ti rí òdodo àti agbára Ọlọ́run nínú ògo nla, tí a gba nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ sí àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlàna, ninú àye ọmọ Ìjọ kan tí ó ni ìrírí ìbànújẹ́ ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀. Wàhálà ti ẹ̀mí àti ti ẹ̀dùn ọkàn arábìnrin yii ni ó pọ̀ si nípasẹ̀ àìṣododo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú síṣẹ̀ ti ọkọ rẹ sí àwọn májẹ̀mú tí ó si fa títúká ìgbéyàwó wọn. Ó fẹ́ ìdájọ́ ati ìjiyìn.

Bí obìnrin olõtọ́ yìí ṣe ntiraka pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i, ó kẹ́kọ̀ọ́ ó sì ṣe àṣàrò Ètùtù Olùgbàlà pẹ̀lú ìfọkànsí àti kíkankíkan ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ayé rẹ̀. Díẹ̀díẹ̀, òye tí ó jinlẹ̀ nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ ìràpadà Kristi sun térétéré sí ọkàn rẹ̀—ìjìyà Rẹ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti bákannáà àwọn ìrora wa, àìlera wa, ìjákulẹ̀ wa, àti ìbànújẹ́. Ó ní ìmísí láti bèère ìbéèrè gígúnni kan lọ́wọ́ ara rẹ̀: Níwọ̀n ìgbà tí a ti san ìdíyelé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nnì, njẹ́ ìwọ yio béèrè pé kí a san ìdíyelé náà lẹ́ẹ̀mejì? Ó ríi pé irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kìí yio jẹ́ títọ́ tàbí síṣàánú.

Obìnrín yii kọ́ ẹ̀kọ́ pé síso ara rẹ̀ mọ́ Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà lè ṣe ìwòsàn àwọn ọgbẹ́ tí lílo iwa agbára òminira nínú àìṣòdodo ti ẹlòmíràn ṣe okùnfà rẹ̀,ó sì jẹ́kí ó seese fún un láti rí agbára láti dáríjì àti láti gba àlááfìà, àánú, àti ìfẹ́.

Ìlérí àti Ẹ̀rí

Àwọn ìlérí àti ìbùkún májẹ̀mú ṣeéṣe nípa Olùgbàlà wa, Jésù Krístì nìkan. Ó pè wá láti wo Òun,13 wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀,14 kọ́ nípa Rẹ̀,15 kí á sì so ara wa pọ̀ pẹ̀lú Rẹ16 nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà ìhìnrere Rẹ tí a múpadàbọ̀sípò. Mo jẹ́rì mo sì ṣèlérí pé bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú ndì wá ní ìhámọ́ra pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá. Mo sì jẹ́rì pé Olúwa Jésù Krístì alààyè ní Olùgbàlà wa. Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.