Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Mímúrasílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Mímúrasílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Krístì

Ju bíi èyíkéyi ti ìṣaájú lọ, a pè wá láti dojúkọ òtítọ́ pé a nsúnmọ́ Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì síi.

Bí a ti ṣe àkọsílẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní ọdún mẹ́fà ṣaájú ìbí Jésù Krístì, Sámúẹ́lì, olódodo ará Lámánì kan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn Néfì kan àwọn ẹnití wọn ti fẹ́rẹ̀ di olùyapa ènìyàn tán nígbànáà,1 nípa àwọn àmì tí yío bá ìbí Olùgbàlà wa wá. Pẹ̀lú ìbánújẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Néfì kọ àwọn àmì wọnnì sílẹ̀ nítorípé “kò mú ọgbọ́n wá pé irú ẹ̀dá kan bíi Krístì [yíò] wá.”2

Pẹ̀lú àbámọ̀, ní ìbámu sí àkọsílẹ̀ inú ìwé mímọ́, púpọ̀ nínú àwọn Júù, ní ọ̀nà kannáà, kò le gbà pé ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ̀ jẹ́ Jésù, láti agbègbè tí a kà sí kékeré ní Gálílì, ni Mèsíà náà tí a ti ndúró dè fún ìgbà pípẹ́.3 Jésù, ẹnití ó ti wá nítòótọ́ láti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ tí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì Hébérù,3ni a kọ̀sílẹ̀ tí a sì kàn mọ́ àgbélèbú nítorípé, bí wòlíì Jákọ́bù Ìwé Mọ́mọ́nì ti kọ́ni, àwọn Júù “nwò kọjá àmì náà.” Ní àyọrísí, Jákọ́bù sọtẹ́lẹ̀ pé “Ọlọ́run ti mú ìṣe-kedere rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan tí kò lè yé wọn, nítorípé wọ́n fẹ́ ẹ. Àti nítorítí wọ́n fẹ́ ẹ Ọlọ́run ti ṣe é, kí wọ́n lè kọsẹ̀.”4

Bí ó tilẹ̀ dàbí ohun àjèjì, kò sí ìkọ́ni, kò sí ìṣẹ́ ìyanu, kò sì sí ìfarahàn àní ti angẹ́lì ọ̀run, bí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì ti jẹri,5 dàbí ẹnipé ó ní agbára yíyí ọkàn padà lati mú àwọn ènìyàn kan ṣe àtúnṣe ipa ọ̀nà wọn, ìwoye, tàbí ìgbàgbọ́ wọn pé ohun kan jẹ́ òtítọ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nípàtàkì nígbàtí àwọn ìkọ́ni tàbí àwọn iṣẹ́ ìyanu kò bá wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ inú, àwọn ìfinúrò, àti àwọn èrò orí tí ẹnikan ti rò sínú tẹ́lẹ̀.

Ẹ jọ̀wọ́ fún ìgbà díẹ̀ kan ẹ ṣe àfiwé àwọn ìwé mímọ́ méjì yìí, ìkínní láti ọwọ́ Apóstélì Paulù tí ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, ní síṣe àpèjúwe àwọn ọ̀nà ènìyàn, àti ìkejì láti ọwọ́ wòlíì Álmà tí ó nṣe àfihàn bí Ọlọ́run ti í ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ láàrin ẹ̀dá ènìyàn. Àkọ́kọ́ láti ọwọ́ Páulù.

“Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀, pé ní ìkẹhìn ọjọ́ ìgbà ewu yio dé.

“Nítorí àwọn ènìyàn yío jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, olójúkòkòrò, agbéraga, asọ̀rọ̀ buburú, aṣàìgbọràan sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́,

“Aláìnífẹ, aláìle-daríji-ni, abanijẹ́, aláìle-kó-ara-wọn-níjanu, ònrorò, aláìnífẹ ohun rere,

“Onikúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ;

“Wọ́n nfi ìgbàgbogbo kẹ́kọ, wọn kò sì le dé ojú ìmọ̀ òtítọ́.”6

Àti nísisìyí l’ati ọ̀dọ̀ Álmà, ní sísọ ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀sẹ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì: “Nísisìyí ìwọ lè rò pé ohun aláìgbọ́n ní èyí jẹ́ fún mi láti ṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi wí fún ọ, pé nípa àwọn ohun kékèké tí ó sì rọrùn ní àwọn ohun nlá tí njáde wa; àti pé àwọn ohun kékèké ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa dàmú ọlọgbọ́n.”7

A ngbé nínú ayé ìgbàlódé tí ó kún fún ìmọ̀ nlá àti ìgboyà púpọ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, àwọn ohun wọ̀nyí nfi ìgbàgbogbo bo ìpìllẹ̀ aìledúró lórí èyítí wọ́n jẹ́ kíkọ́ lé. Ní ìyọrísí, wọn kò darí sí òtítọ́ gan àtí síwájú Ọlọ́run àti agbára láti gba ìfihàn, gba ìmọ̀ ti-ẹ̀mí, àti láti gbèrú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì tí ó ndarí sí ìgbàlà.8

A ní ìjìnlẹ̀ ìránniléti ti àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa wa sí Thomásì àti àwọn Àpóstélì míràn ní àṣálẹ́ ẹbọ ètùtù Rẹ̀: “Jésù wí fún un pé, èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.”9

Fún àwọn tí wọ́n ní ojú láti rí, etí láti gbọ́, àti ọkàn láti ní ìmọ̀lára, ju bíi èyíkéyi ìṣaájú lọ, a pè wá láti dojúkọ òtítọ́ pé a nsúnmọ́ Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì si. Lõtọ́, àwọn ìṣoro nlá ṣì ndúró de àwọn wọnnì lórí ilẹ̀ ayé ní ìgbà ìpadàbọ̀ Rẹ̀, ṣùgbọ́n nípa èyí, àwọn olõtọ́ kò nílò láti bẹ̀rù.

Nísisìyí èmi ó ṣe àtúnsọ fúngbà díẹ̀ láti inú àwọn Àkòrí Ìhìnrere ti Ìjọ lábẹ́ àkọlé “Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì”:

“Nígbàtí Olùgbàlà yío padá wá, Òun yío wá nínú agbára àti ògo láti gba ilẹ̀-ayé bíi ìjọba Rẹ̀. Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀ yío ṣe àmì ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún-Ọdún náà.

“Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì náà yío kún ní ẹ̀rù, àkókò ọ̀fọ̀ fún àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n yío jẹ́ ọjọ́ àlàáfíà fún àwọn olódodo. Olúwa kéde pé:

“Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n tí wọ́n sì ti gba òtítọ́, àti tí wọ́n ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe amọ̀nà wọn, tí a kò sì tíì tàn wọ́n jẹ—lõtọ́ ni mo wí fún yín, a kì yíò ké wọn lulẹ̀ kí á sì sọ wọ́n sínú iná, ṣùgbọ́n wọn yíò dúró ní ọjọ́ náà.

“A ó sì fi ilẹ̀ ayé fún wọn bíi ogún ìní; wọn yíò sì máa pọ̀ síi àti ní agbára síi, àti àwọn ọmọ wọn yíò dàgbà sókè sínú ìgbàlà láì lẹ́ṣẹ̀.

“Nítorí Olúwa yíò wà ní ààrin wọn, àti ògo rẹ̀ yíò wà ní orí wọn, òun yíò sì jẹ́ ọba wọn àti aṣòfin wọn.”(Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 45:57–59)”10

Nínú ìmúrasílẹ̀ wa fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì, mo pèsè àkọsílẹ̀ kan tí ó jẹ́ kókó, títuni-nínú fún àwọn olõtọ́ láti inú ìwé wòlíì Ámósì ti Májẹ̀mú Láéláé: “Olúwa Ọlọ́run kò ní ṣe ohunkóhun, ṣùgbọ́n òun yíò fi àṣírí rẹ̀ hàn àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.”11

Nínú ẹ̀mí yìí, wòlíì Olúwa sí àgbáyé lóni, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti fúnwa ní ìmọ̀ràn onímísí ti àìpẹ́ yìí: “Ìhìnrere Jésù Krístì jẹ́ ìhìnrere ìrònúpìwàdà. Nítorí Ètùtù Olùgbàlà, ìhìnrere Rẹ̀ pèsè ìfipè kan láti tẹ̀síwájú ní yíyípadà, dídàgbà, àti dídí mímọ́ síi. Ó jẹ́ ìhìnrere ti ìrètí, ti ìwòsàn, àti ti ìlọsíwájú. Báyìí, ìhìnrere náà jẹ́ ọ̀rọ̀ ayọ̀kan! Àwọn ẹ̀mí wa yọ ayọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìṣìsẹ̀ kékèké tí a gbé síwájú.”12

Láì fi ohun kan pamọ́ mo jẹ́ri sí mo si ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti òtítọ́ Ọlọ́run àti àwọn iṣẹ́-ìyanu nínú ìgbé-ayé ojojúmọ́ ti àkàìníye àwọn ènìyàn láti àwọn ipò tí kò ga àti gíga ti ìgbé ayé. Lõtọ́, púpọ̀ àwọn ìrírí mímọ́ ni ó ṣọ̀wọ́n láti sọ̀rọ̀ wọn, ní apákan nítorípé orísun wọn jẹ́ ti ọ̀run àti nítorí àyọrísí àbùkù tí ó ṣeéṣe láti ọwọ́ àwọn ènìyàn kan tí wọn kò mọ̀ dárajù.

Nípa èyí, ẹnití ó kẹ́hìn nínú àwọn wòlíì inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì rán wa létí pe:

“Àti pẹ̀lú mo bá yin sọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ẹ nsẹ́ àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run, tí ẹ sì wípé a tí dáwọ́ wọn dúró, pé kò sí àwọn ìfihàn mọ, tabi àwọn àsọtẹlẹ, tabi àwọn ẹbun, tabi ìwòsàn, tabi fifi onírúrú èdè fọ̀, àti ìtumọ̀ onírúrú èdè;

“Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹniti ó bá sẹ́ àwọn ohun wọ̀nyí kò mọ̀ ìhìnrere Krístì; bẹ́ẹ̀ni, kò tí ì kà àwọn ìwé-mímọ́; bí ó bá sì ti kà wọ́n, wọn kò yé e.

“Nitori njẹ àwa kò ha rí i kà pé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé, àti nínú rẹ̀ ni kò sì sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà?”13

Mo parí ọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú ìkéde ti wòlíì tí ó ní ìmísí tòótọ́ láti ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith, tí a fi fúnni ní tòsí ìparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ bí ó ti w\p síwájú sí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Jésù Krístì: Ṣé a kò ní tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ nlá bẹ́ẹ̀? Ẹ lọ síwájú kì ẹ má sì ṣe rẹ̀hìn. Ìgboyà, ẹ̀yin arákùnrin [àti, njẹ́ mo le fi kun un, arábìnrin]; àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun naa! … Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín kí ó yọ̀, kí ẹ sì ní ìdùnnú tí ó tayọ.”14 Sí èyítí mo fi ẹ̀rí mi kún ni orúkọ Jésù Krístì, Àmín.