Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kíkàyẹ Kìí Ṣe Àìlábùkù
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Kíkàyẹ Kìí Ṣe Àìlábùkù

Nígbàtí ẹ bá nímọ̀lára bíi pé ẹ ti kùnà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà láti tẹ̀síwájú ní gbígbíyànjú, rántí pé Ètùtù Jésù Krístì àti oore-ọ̀fẹ́ tí ó mu ṣeéṣe dánilójú.

Mo fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbàkan rí sí ọmọbìnrin mi àti ọmọkùnrin-àna-mi ní lílo irinṣẹ́ ohùn-sí-nkan-kíkọ lóri fóònù mi. Mo wípé, “Éè, ẹ̀yin méjèèjì. Dájú mo fẹ́ràn yín.” Wọ́n gba, “Kóríra ẹ̀yin méjèèjì. Níláti fẹ́ràn yín.” Njẹ́ kò yanilẹ́nu bí ọ̀rọ̀ rere àti pẹ̀lú èrò inú dáradára ṣe le fi ìrọ̀rùn di gbígbà sódì? Ohun tí ó máa nṣẹlẹ̀ nígbàmíràn nìyí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ìrònúpìwàdà àti kíkàyẹ

Àwọn kan ngba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àṣìṣe pé ìrònúpìwàdà àti ìyípadà kò ṣe dandan. Ọrọ̀ Ọlọ́run ni pé wọ́n ṣe kókó.1 Ṣùgbọ́n njẹ́ Ọlọ́run kò ha fẹ́ràn wa láìka àìpé wa sí bí? Bẹ́ẹ̀ni! Ó fẹ́ràn wa ní pípé. Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ-ọmọ mi, àwọn àìpé wọn àti gbogbo rẹ̀, ṣùgbọ́n èyínnì kò túmọ̀ sí pé èmi kò fẹ́ kí wọn ó gbèrú kí wọn ó sì dì gbogbo ohun tí wọ́n bá le dà. Ọlọ́run fẹ́ràn wa bí a ti wà, ṣùgbọ́n bákannáà Ó fẹ́ràn wa púpọ̀jù láti fí wá sílẹ̀ ní ọ̀nà yí.2 Dídágbà sókè sí Olúwa ni gbogbo ohun tí ayé-ikú wà fún.3 Ìyípadà ni gbogbo ohun tí Ètùtù Krístì wà fún. Kìí ṣe pé Jésù Krístì le jínde, ṣe ìwẹ̀nùmọ́, tù nínú, àti wòwásàn nìkan, ṣùgbọ́n nínú gbogbo rẹ̀, Ó le yíwa padà láti dàbí Rẹ̀ síi.4

Àwọn kan nfi àṣìṣe gba ọ̀rọ̀ náà pé ìrònúpìwàdà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò-kan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, “Ìrònúpìwàdà … jẹ́ ètò kan.”5 Ìrònúpìwàdà lè gba àkokò àti ìgbìyànjú léraléra,6 nítorínáà pípa ẹ̀ṣẹ̀ ti7 kí a má sì ṣe ní “èrò láti ṣe ibi mọ́, ṣùgbọ́n ki a ṣe rere nígbàgbogbo”8 jẹ́ ìlépa ìgbé-ayé.9

Ìgbé-ayé dàbí ìrìn-àjò ojú-ọ̀nà la orílẹ̀ èdè kan já. A kò le dé ibi tí a nlọ pẹ̀lú epo-ọkọ̀ tánkì kan. A gbọ́dọ̀ tún epo rà sí tánkì náà lẹ́ẹ̀kọkan si. Jíjẹ oúnjẹ Olúwa dàbíi wíwọ inú ilé epo kan. Bí a ti nronúpiwàdà tí a sì ntún àwọn májẹ̀mú wa ṣe, a nṣe ìlérí ṣíṣetán wa láti pa àwọn òfin mọ́, Ọlọ́run àti Jésù Krístì yío sì bùkún wa pẹ̀lú Ẹmí Mímọ́.10 Ní kúkúrú, a ṣèlèrí láti tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò wa, Ọlọ́run àti Krístì sì ṣèlérí láti fikún tánkì wa.

Àwọn kan fi àṣìṣe gba ọ̀rọ̀ náà pé àwọn kò yẹ láti kópa ní kíkún nínú ìhìnrere nítorípé àwọn kò tíi di òmìnira tán pátápátá sí àwọn ìwà ìbàjẹ́ kan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé kíkàyẹ kìí ṣe àìlábùkù.11 Kíkàyẹ ni jíjẹ́ olõtọ́ àti títiraka. A gbọ́dọ̀ jẹ́ olõtọ́ sí Ọlọ́run, àwọn olórí óyè-àlùfáà, àti àwọn míràn tí wọ́n fẹ́ràn wa,12 a sì gbọ́dọ̀ tiraka láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ kí a má sì pẹ̀hìndà láé nítórí pé a ṣubú lásán.13 Alàgbà Bruce C. Hafen sọ pé ṣíṣe ìgbèrú ìwà bíi ti Krístì “gba sùúrù àti ìtẹramọ́ ju bí ó ti gba àìlábùkù lọ.”14 Olúwa ti sọ pé àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí ni a “fifúnni fún ànfàní ti àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ràn mi tí wọ́n sì pa àwọn òfin mi mọ́, àti ẹni náà tí ó nlépa láti ṣe bẹ́ẹ̀.”15

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí èmi ó pe ní Damon kọ sílẹ̀ pé, “Ní dídàgbàsókè, mo jìjàkadì pẹ̀lú pọnógíráfì. Mo máa nní ìmọ̀lára ìtìjú nígbàgbogbo pé èmi kò le ṣe àwọn nkan ní títọ́.” Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí Dámon bá ṣubú, ìrora àbámọ̀ di rírorò tó bẹ́ẹ̀ tí ó máa ndá ara rẹ̀ lẹ́jọ líle láti jẹ́ aláìyẹ fún irú èyíkéyìí oore-ọ̀fẹ́, ìdáríjì, tàbí àfikún àwọn ìgbàláàyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sọ pé, “Mo pinnu pé ó kàn yẹ kí nmáa ní ìmọ̀lára búburú ní gbogbo ìgbà ni. Mo wòye pé bóyá Ọlọ́run kóríra mi nítorípé èmi kò ṣetán láti ṣiṣẹ́ kára kí nsì borí èyí lẹ́ẹ̀kannáà. Èmi ó lọ fún ọ̀sẹ̀ kan àti nígbà míràn àní fún oṣù kan, ṣùgbọ́n nígbànáà èmi a tún rẹ̀wẹ̀sì maa sì ronú pé, “Èmi kò le dára tó láé, nítorínáà àní kíni ìwúlò gbígbìyànjú?”

Ní irú àkókò ìrẹ̀lẹ̀ kan bẹ́ẹ̀, Damon sọ fún olórí oyè-àlùfáà rẹ̀ pé “Bóyá kí èmi ó kàn dá wíwá sí ilé ìjọsìn dúró ni. Mo nkáàrẹ̀ ti jíjẹ́ alágàbàgebè.”

Olórí rẹ̀ fèsì, “Ìwọ kìí ṣe alágàbàgebè nítorípé o ní ìwà burúkú kan tí o ngbìyànjú láti múkúrò. O jẹ́ alágàbàgebè bí ìwọ bá fií pamọ́, bí o bá parọ́ nípa rẹ̀, tàbí tí o gbìyànjú láti yí ara rẹ lọ́kànpadà pé Ìjọ ní ìṣoro fún gbígbé irú àwọn òṣùnwọ̀n gíga bẹ́ẹ̀ kalẹ̀. Jíjẹ́ olõtọ́ nípa àwọn ìṣe rẹ àti gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ láti tẹ̀ síwájú kìí ṣe jíjẹ́ alágàbàgebè. Òhun ni jẹ́ jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn kan.”16 Olórí yi ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ Alàgbà Richard G. Scott ẹnití ó kọ́ni pé, “Olúwa nrí àwọn àìlera yàtọ̀ sí bí Ó ti nrí ìṣọ̀tẹ̀. … Nígbàtí Olúwa bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn àìlera, ó máa nfi ìgbàgbogbo jẹ́ pẹ̀lú àánú.”17

Ìwòye tí a fún Damon ní ìrètí. Ó ríi pé Ọlọ́run kò wà ní òkè níbẹ̀ tí Ó nwípé, “Damon tún ti ṣe é lẹ́ẹ̀kansíi.” Dípò bẹ́ẹ̀, bóyá Ó nwípé, “Wo ibi tí Damon ti rìn jìnnà dé.” Nígbẹ̀hìn ọ̀dọ́mọkùnrin yi dá wíwo ilẹ̀ nínú ìtìjú dúró tàbí wíwo ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ fún àwọn àwáwí àti àwíjàre Ó wo òkè fún ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá ó sì rí i.18

Damon sọ pé, “Ìgbà kanṣoṣo tí èmi ti kọjú sí Ọlọ́run rí jẹ́ láti bééré fún ìdáríjì, ṣùgbọ́n nísisìyí mo bèèrè fún oore-ọ̀fẹ́ bákannáà—‘agbára ìleṣe’ Rẹ̀.’[Ìtumọ̀ Bíbélì, “Oore-ọ̀fẹ́”]. Èmi kò tíì ṣe èyí rí láé. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí mo nlo àkókò tí ó kéré púpọ̀ síi ní kíkóríra ara mi fún àwọn ohun tí mo ti ṣe àti àkókò tí ó pọ̀ púpọ̀ síi ní fífẹ́ràn Jésù fún àwọn ohun tí Ó ti ṣe.”

Ní rírò nípa bí ó ti pẹ́ tó tí Damon fi tiraka, kò ṣe ìrànlọ́wọ́ kò sì ṣeéṣe fún àwọn òbí àti àwọn olórí rẹ̀ láti sọ pé “láé lẹ́ẹ̀kansíi” ní kíákíá jù tàbí láti gbé àwọn òsùnwọ̀n pàjáwìrì ti yíyẹrafún kan kalẹ̀ láti ká sí “yíyẹ.” Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àfojúsùn kékeré, tí ọwọ́ tó. Wọ́n ju àwọn ìrètí gbogbo-tàbí-ìkankan sílẹ̀ wọ́n sì fi ojúsùn sórí ìdàgbà díẹ̀díẹ̀, èyítí ó fún Damon ní ààyè láti gbèsókè lórí oríṣiríṣi àwọn àṣeyọrí dípò àwọn ìkùnà.20 Òun, bíi ti àwọn ènìyàn Límhì ní oko ẹrú, kọ́ pé òun le “ṣe rere ní àwọn ìpele.”21

Alàgbà D. Todd Christofferson ti gbani nímọ̀ràn pé: “Láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ohun kan tí ó tobi [gan], a le nílò láti ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ ní kékèké, lójojúmọ́. … Fífi àwọn ìwà titun àti ìwúrí sínu ìhùwàsí wa tàbí bíborí àwọn ìwà burúkú tàbí àwọn bárakú tí ó nfi ìgbàgbogbo jùlọ túmọ̀ sí ìyànjú kan lóni tí òmíràn tẹ̀lé lọ́la àti nígbànáà òmíràn, bóyá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àní àwọn oṣù àti àwọn ọdún. … Ṣùgbọ́n a le ṣe é nítorípé a le bẹ Ọlọ́run … fún ìrànlọ́wọ́ tí a nílò ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.”22

Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 kò ti rọrùn fún ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n yíyàsọ́tọ̀ tí ó so mọ́ àwọn àlà dídáwà ti mú ìgbé ayé nira ní àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn wọnnì tí wọn tiraka pẹ̀lú àwọn ìwà ìbájẹ́. Ẹ rántí ìyípadà ṣeéṣe, ìrònúpìwàdà jẹ́ èto kan, àti pé kíkàyẹ kìí ṣe àìlábùkù. Pàtàkì jùlọ, ẹ rántí pé Ọlọ́run àti Krístì ti ṣetán láti rànwálọ́wọ́ ní ìhínyí àti nísisìyí.23

Àwọn kan fi àṣìṣe gba ọ̀rọ̀ náà pé Ọlọ́run ndúró láti rànwálọ́wọ́ títí di lẹ̀hìn tí a bá ronúpìwàdà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni pé Òun yío rànwálọ́wọ́ a ti nronúpìwàdà. Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tó sí wa “ibi yíówù kí a wà ní ipa ọ̀nà ìgbọràn.”24 Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti sọ pé: “Ọlọ́run kò nílò àwọn ènìyàn tí wọn kò ní àbùkù. O nwá àwọn wọnnì tí wọn yío fi ‘ọkàn àti àyà síṣetán wọn sílẹ̀’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:34], Òun yío sì sọ wọ́n di ‘pípé nínú Krístì’ [Moroni 10:32–33].”24

Ọpọ̀lọpọ̀ ní wọ́n ti ní ọgbẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí tí wọ́n ti já tàbí tí wọ́n ti fàro tí ó jẹ́ pé ó ṣòro fún wọn láti gbàgbọ́ nínú ìyọ́nú àti ìfaradà ti Ọlọ́run. Wọ́n tiraka láti rí Ọlọ́run bí Òun ti rí—olùfẹ́ni Baba kan tí ó nbáwa pàdé nínú àìní wa26 tí ó sì mọ bí yío ti “fi ohun rere fún àwọn tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀.”27 Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ kìí ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tó yẹ nìkan. Ó jẹ́ “àtìlẹ́hìn àtọrunwá” tí Òun nfúnni tí ó nrànwálọ́wọ́ láti di yíyẹ. Kìí ṣe èrè fún àwọn olódodo nìkan. Ó jẹ́ “ẹ̀bùn ti okun” tí Òun nfúnni tí ó nrànwálọ́wọ́ láti di olódodo.28 Kìí ṣe pé a nrìn sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti Krístì nìkan. A nrìn pẹ̀lú Wọn.29

Jákèjádò Ìjọ, àwọn ọ̀dọ́ máa nṣe àtúnsọ Àwọn Àkòrí ti iyejú Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin àti Òyè-àlùfáà Árọ́nì. Láti New Zealand dé Spain dé Ethiopia dé Japan, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin nsọ pé, “Mo ṣìkẹ́ ẹ̀bùn ti ìrònúpìwàdà.” Láti Chile dé Guatemala dé Morónì, ní Utah, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin máa nsọ pé, “bí mo ṣe nlàkàkà láti sìn, lo ìgbàgbọ́, ronúpìwàdà, kí nsì dára síi ní ojoojúmọ́, èmi ó yege láti gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì àti ayọ̀ pípẹ́-títí tí ìhìnrere.”

Mo ṣe ìlérí àwọn ìbùkún wọnnì àti pé ayọ̀ jẹ́ òdodo ó sì wà ní àrọ́wọ́tó fún àwọn wọnnì tí wọ́n npa gbogbo òfin mọ́ àti àwọn “tí wọ́n nwá láti ṣe bẹ́ẹ̀.”29 Nígbàtí ẹ bá nímọ̀lára bíi pé ẹ ti kùnà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà láti tẹ̀síwájú ní gbígbíyànjú, ẹ rántí Ètùtù Jésù Krístì àti oore-ọ̀fẹ́ tí ó mu ṣíṣeéṣe dánilójú.30 “Ó na ọwọ́ àánú [Rẹ̀] síi yín.”31 A fẹ́ràn yín lóni, ní ogun ọdún, àti títí láé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.