Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pẹ̀lú Ìrọ̀rùn Ẹwà—Pẹ̀lú Ẹwà Ìrọ̀rùn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Pẹ̀lú Ìrọ̀rùn Ẹwà—Pẹ̀lú Ẹwà Ìrọ̀rùn

Njẹ́ kí a pa àwọn ìhìnrere ìrọ̀rùn mọ́ bí a ti ngbé àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá wa lé arawa.

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú

Mo fi ìkíni-káàbọ̀ ìwúrí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tí ẹ̀ nkópa nínú ìpàdé àpapọ̀ yí.

Loni mo nírètí láti júwe àwọn ohun-èlò méjì nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì, tí àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rin tó hàn nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yíká àgbáyé tí ó njúwe ìlò àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ wọ́nyí. Ohun-èlò àkọ́kọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere—iṣẹ́ Ìgbàlà Ọlọ́run àti ìgbéga—dojúkọ àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá. Ohun-èlò èkejì ránwa létí pé ìhìnrere hàn kedere, ó sì rọrùn.

Àwọn Ojúṣe Yíyàn Àtọ̀runwá

Láti gba ìyè ayérayé, a gbọ́dọ̀ “wá sọ́dọ̀ Krístì, kí a sì di pípé nínú rẹ̀.”1 Bí a ti nwá sọ́dọ̀ Krístì tí a sì nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákannáà, a nkópa nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga, èyí tí o´ dojúkọ àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá.2 Àwọn ojúṣe tọ̀run wọ̀nyí wà ní ìbámu arawọn pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Mose, Elias, àti Elijah, tí a kọsílẹ̀ e Ìpín 110 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú,3 àti òfin nlá kejì tí a gbà látọwọ́ Jésù Krístì láti ní ìfẹ́ aladugbo wa gẹ́gẹ́bí arawa.4 A rí wọn ní àwọn ojú-ewé méjì àkọ́kọ́ ti Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbòtí a múdójú-ìwọ̀n, tí ó wà fún gbogbo ọmọ ìjọ.

Bí gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ “Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò” tàbí “àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá” bá mú yín tàgìrì nínú ẹ̀rù dídíjú tàbí ìkápọ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe é. Àwọn ojúṣe wọ̀nyí jẹ́ ìrọ̀rùn, onímísí, wíwúnilórí, àti lílèṣe. Nihin ni wọ́n wà:

  1. Gbígbé Ìhinrere Jésù Krístì.

  2. Títọ́jú àwọn wọnnì nínú àìní

  3. Pípe gbogbo-ènìyàn láti gba ìhìnrere

  4. Dída àwọn ẹbí pọ̀ fún Ayérayé

Ẹ lè wò wọ́n bí èmi ti ṣe: bí àwòrán òpópónà láti padà sí ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba wa Ọ̀run.

Àwòrán
Àwọn ohun-èlò iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbèga.

Ìhìnrere Ni Oníyebíye, Ìrọ̀rùn àti Kedere.

A ti wí pé ìhìnrere Jésù Krístì kàn jẹ́ “rírọ̀rùn dídára àti jíjẹ́ ìrọ̀rùn dídára.”4 Ayé kò rí bẹ́ẹ̀. Ó le, ó díjú, ó sì kún pẹ̀lú ìdálágara àti ìjà. A di alábùkún bí a ti nṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí a máṣe fàyè gba ìdíjú, tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé, láti wọlé sínú ọ̀nà tí a ti gbà àti tí a sì nṣe ìhìnrere.

Ààrẹ Oaks ṣàkíyèsí: “A kọ́ wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kékèké àti ìrọ̀rùn nínú ìhìnrere Jésù Krístì. A nílò láti gba ìránnilétí pé ní àpapọ̀ àti ní ìgbà pípẹ́ gan, àwọn ohun kékèké ni wọ́n dàbí ó nmú àwọn ohun nlá wá sí ìmúṣẹ.”5 Jésù Krístì Fúnrarẹ̀ ṣàpèjúwe pé, àjàgà Rẹ̀ rọrùn, ẹrù Rẹ̀ sì fúyẹ́.6 Gbogbo wa níláti pa ìhìnrere mọ́ ní ìrọ̀rùn—nínú ayé wa, nínú ẹbí wa, nínú kílásì àti iyejú, àti nínú wọ́ọ̀dù àti èèkan wa.

Bí ẹ ti nfetísílẹ̀ sí àwọn ìtàn wọ̀nyí tí èmì ó pín pẹ̀lú yín, ẹ damọ̀ pé wọ́n ti yàn wọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti ní ìmísí lọ́wọ́ kan àti láti wí fún yín ní ọ̀nà kejì. Àwọn ìṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wọ̀nyí di àwòṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, lílo ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà ìrọ̀rùn, iyebíye, kedere nígbàti a nmú ọ̀kàn lára àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fihàn ṣẹ.

Gbígbé Ìhinrere Jésù Krístì.

Àkọ́kọ́, gbígbé ìhinrere Jésù Krístì. Jens ti Denmark ngbàdúrà lójojojúmọ́ láti gbé ìhìnrere àti láti kíyèsí àwọn ìṣílétí látọ́dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Òun ti kọ́ láti ṣe ìṣe kíákíá nígbàtí ó bá nímọ̀lára ìdarí nípasẹ̀ Ẹ̀mí.

Àwòrán
Jens ti Denmark

Jens ṣe àbápín wọ̀nyí:

“À ngbé ní ibi yíyẹ kékeré ìle ààbọ̀-igi pẹ̀lú òrùlé koríko ní gbùngbun ìletò fífarabalẹ̀ kékeré kan, nítòsí adágún-odò ìletò.

Àwòrán
Ìletò Idyllic
Àwòrán
Adágún-odo- Ìletò

“Ní alẹ́ yí pẹ̀lú ìgbà-ooru Danish rírẹwà jùlọ tí a lè rò. Àwọn ìlẹ̀kùn àti fèrèsé wà ní ṣíṣí, ohun-gbogbo sì nmí jẹ́jẹ́ àti àláfíà. Nítorí àwọn alẹ́ ológo dídán àti ìgbà-ooru pípẹ́ wa èmi kò sí ní ìyára láti rọ́pò gílóbù jíjó ní yàrá ohun-èlò wa.

Àwòrán
Iná yàrá ibi-èlò

“Lọ́gán, mo ní ìmọ̀lára líle pé mo níláti rọ́pò rẹ̀ kíákíá! Ní àkokò kannáà, mo gbọ́ tí ìyàwó mi, Mariann, pè mí àti àwọn ọmọ láti wẹ ọwọ́ wa nítorí oúnjẹ alẹ́ ti ṣetán!

“Mo ṣe ìgbeyàwó pípẹ́ tó láti mọ̀ pé èyí kìí ṣe àkokò láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ohun míràn kan ju wíwẹ ọwọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbọ́ tí mòfúnra mi npe Mariann pé èmi yíò kàn lọ sí ilé-ìtajà láti ra gílóbù titun kan. Mo nímọ̀lára ìlọ́ra líle láti kúrò lọ́gán.

“Ilé-ìtajà ohun-jíjẹ́ wà ní ẹgbẹ́ adágún-odò míràn nìkan. À máa nrìn, ṣùgbọ́n ní òní mo gbé kẹ̀kẹ́ mi. Nígbàtí mo nyí-kẹ̀kẹ́ kọjá adágún-odò ní ẹ̀gbẹ́ ojú mi, mo ṣàkíyèsí ọmọdékùnrin kan bí ọmọ ọdún méjì, ó ndá rìn nítòsí etí adágún-odò, sísúnmọ́ omi gan—lọ́gán ó já sínú rẹ̀! Ní ìṣẹ́jú kan ó wà níbẹ̀—ní èkejì ó ti lọ!

“Kò sí ẹnikankan tí ó rí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣùgbọ́n èmi. Mo ju kẹ̀kẹ́ mi sílẹ̀, sáré, mo sì tọ sínú adágún-odò gígùn-dé-ikùn. Lọ́gán ojú omi kún fún ewé-ewúro, tí ó mu ṣòro láti rí inú omi. Nígbànáà mo ní ọgbọ́n rírìn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Mo gbé apá mi sínú omi, di T-ṣẹẹ̀tì rẹ̀ mú, mo sì fa ọmọdékùnrin náà sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nmí-fúlefúle, ó nwúkọ́, ó sì nsọkún. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà ọmọdékùnrin náà tún-dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀.”

Àwòrán
Jens àti ẹbí

Bí arákùnrin Jens ti ngbàdúrà ní òwòwúrọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ láti dá àwọn ìṣílétí mọ̀ látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, àní ohunkan bí àìwọ́pọ̀ bí yíyí gílóbù padà lọ́gán, bákannáà ó ngbàdúrà pé kí òun lè lo ohun-èlò kan láti bùkún àwọn ọmọ Ọlọ́run. Jens ngbé ìhìnrere nípa wíwá ìdarí tọ̀run lójojúmọ́, títiraka láti yẹ, nígbànáà ṣíṣe dídárajùlọ rẹ̀ láti tẹ̀lé ìdarí náà nígbàtí wọ́n bá wá.

Títọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní

Nihin ni àpẹrẹ ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn wọnnì nínú àìní. Ní ọjọ́ kan ààrẹ èèkàn ní èèkàn Cucuta ní Colombia lọ pẹ̀lú ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin èèkàn láti bẹ méjì lára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wò—àti arákùnrin àgbà ọ̀dọ́ wọn—tí wọ́n nla àwọn ìlàkàkà líle kọjá. Láìpẹ́ baba wọn kọjá lọ, ìyá wọn sì ti kọjá lọ ní ọdún kan ṣíwájú. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò mẹ́ta ni a fisílẹ̀ nìkan nínú òrùlé kékeré, ìrẹ̀lẹ̀ wọn. Àwọn ògiri rẹ̀ ni a fi igi rọ̀bì tí ó wà pẹ̀lú àwọn àpò rọ́bà ṣe, àti òrùlé agolo kíká tí ó bo agbègbè ibi tí wọ́n sùn sí nìkan.

Títẹ̀lé ìbẹ̀wò wọn, àwọn olórí wọ̀nyí mọ̀ pé wọ́n nílò láti ṣe ìrànlọ́wọ́. Nínú ìgbìmọ̀ wọ̀ọ̀dù, ètò kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́ bẹ̀rẹ̀ láti jáde. Àwọn olórí èèkàn àti wọ́ọ̀dù—Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, iyejú àwọn alàgbà, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin—àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí gbogbo wọn ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bíbùkún ẹbí yí.

Àwòrán
Ilé tí à nkọ́
Àwòrán
Ilé tí à nkọ́

Àwọn ìṣètò pe olúkúlùkù àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù tí wọ́n nṣiṣẹ́ nínú ìkọ́lé. Àwọn kan ṣèrànwọ́ pẹ̀lú àwòrán, àwọn míràn dá àkokò àti iṣẹ́, àwọn míràn ṣe oúnjẹ, àwọn míràn síbẹ̀ dá àwọn ohun-èlò tí wọ́n nílò.

Àwòrán
Ilé píparí

Nígbàtí ilé kékeré náà parí, ó jẹ́ ọjọ́ aláyọ̀ fún àwọn tí wọ́n ṣèránwọ́ àti fún àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta ọmọ wọ́ọ̀dù. Àwọn ọmọ òrukàn wọ̀nyí ní ìmọ̀lára ìyárí àti ìsopọ̀ títún-dánilójú àwọn ẹbí wọ́ọ̀dù wọn láti mọ̀ pé wọn kò dá wà àti pé Ọlọ́run wà níbẹ̀ fún wa nígbàgbogbo. Àwọn tí wọ́n nawọ́ jáde ní ìmọ̀lára ifẹ́ Olùgbàlà fún ẹbí yí wọ́n sì ṣe ìṣe bí ọwọ́ Rẹ̀ ní sísìn wọ́n.

Pípe Gbogbo-ènìyàn láti gba Ìhìnrere

Mo lérò pé ẹ ó gbádùn àpẹrẹ ti pípe gbogbo-ènìyàn láti gba ìhìnrere yí. Cleiton ti Cape Verde ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kò ní èrò ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ bí àbájáde rírìn sínú kílásì ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ wọ́ọ̀dù rẹ̀ ní ọjọ́ kan. Ṣùgbọ́n ìgbé-ayé rẹ̀ àti ìgbé-ayé àwọn ẹlòmíràn yíò yípadà títí-ayé nítorí ó ṣeé.

Cleiton, lẹgbẹ pẹ̀lú ìyá rẹ̀ àti arákùnrin àgbà, ti ṣe ìrìbọmi sínú Ìjọ nígbàkan tẹ́lẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ ẹbí náà dáwọ́ wíwá dúró. Ìṣe wíwásí ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ kanṣoṣo ni yíò jẹ́ igun àmì fún ẹbí náà.

Àwọn ọ̀dọ́ míràn nínú kílásì ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ ní ìyárí wọ́n sì kí-káàbọ̀. Wọ́n mú Cleiton ní ìmọ̀ bíi pé ó wà nílé wọ́n sì gbà á níyànjú láti wásí ṣíṣe míràn. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ láìpẹ́ ó sì bẹ̀rẹ̀sí wásí àwọn ìpàdé Ìjọ míràn. Bísọ́ọ̀pù ọlọgbọ́n kan rí okun ti-ẹ̀mí nínú Cleiton ó sì pè é láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. “Láti àkokò náà lọ,” ni Bishop Pina wí, “Cleiton di àpẹrẹ kan àti agbára sí àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn míràn.”

Ẹni àkọ́kọ́ tí Cleiton pè wá sí ìjọ ni ìyá rẹ̀, lẹ́hìnnáà arákùnrin rẹ̀ àgbà. Lẹ́hìnnáà ó yílọ sí àgbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ̀ wọnnì ni ọ̀dọ́mọkùnrin ọjọ̀ orí kannáà bíi tirẹ̀, Wilson. Ní ìpàdé àkọ́kọ́ gan pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́, Wilson fi ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìrìbọmi hàn. Àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ ní ìtẹ̀mọ́ra àti ìyàlẹ́nu ní bí Cleiton ti ṣe àbápín púpọ́ tẹ́lẹ̀.

Àwòrán
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Cape Verde
Àwòrán
Pípé àwọn ẹlòmíràn láti wá sílé ìjọsìn
Àwòrán
Dídàgbà ẹgbẹ́ aápọn àwọn ọ̀dọ́

Àwọn ìgbìyànjú Cleiton kò dúró níbẹ̀. Ó ran àwọn ọmọ ìjọ tì kìí-wá-déédé lọ́wọ́ láti padà, ní àfikún sí pípín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ti ìgbàgbọ́ míràn. Ní òní wọ́ọ̀dù náà ti ní àwọn ọ̀dọ́ marundinlogoji tí wọ́n nṣe déédé, pẹ̀lú ètò ìdánilẹ́ẹ̀kọ́, ara ọpẹ́ púpọ̀ sí àwọn ìgbìyànjú Cleiton láti ní ìfẹ́, ṣe àbápín, àti láti pè. Cleiton àti arákùnrin rẹ̀ àgbà, Cleber, jìjọ nmúrasílẹ̀ láti sin ní ìṣẹ́-ìránṣẹ́ ìgbà-kíkún.

Dída Àwọn Ẹbí Pọ̀ fún Àìlópin

Nígbẹ̀hìn, ẹ jẹ́ kì npín àpẹrẹ dídára ti dída a`wọn ẹbí pọ̀ fún ayérayé. Lydia láti Kharkiv, Ukraine, kọ́kọ́ kọ́ nípa tẹ́mpìlì látọ̀dọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìránṣẹ́. Lọ́gán, Lydia ní ìmọ̀lára ìfẹ́ tọkàntọkàn láti lọ sí tẹ́mpìlì, lẹ́hìn ìrìbọmi rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ láti gba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì.

Lydia lọ sí Tẹ́mpìlì Freiberg Germany láti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì rẹ̀ àti lẹ́hìnnáà ó lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọjọ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ arọ́pò níbẹ̀. Titẹ̀lé ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kyiv Ukraine, Lydia lọsí tẹ́mpìlì lemọ́lemọ́ si. Òun àti ọkọ rẹ̀, Anatoly, ni a ṣe èdidì fún níbẹ̀ àti lẹ́hìnnáà pè wọ́n láti sìn bí àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ tẹ́mpìlì. Lápapọ̀ wọ́n ti rí jú bí orúkọ ẹgbẹ̀rún-marundinlogun ti àwọn bàbánlá tí wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ láti pèsè àwọn ìlànà tẹ́mpìlì fún wọn.

Àwòrán
Tọkọ-taya Ukrainian ní tẹ́mpìlì

Nígbàtí a bií nípa i`mọ̀lára rẹ̀ nípa iṣẹ́ tẹ́mpìlì, Lydia wípé, “Kíni ohun tí mo gbà ní tẹ́mpìlì? Mo ti dá àwọn májẹ̀mú titun pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀rí mi ti ní okun. Mo ti kọ́ láti gba ìfihàn araẹni. Mo lè ṣe àwọn ìlànà ìgbàlà fún àwọn olóògbé bàbánlá mi. Mo sì lè ní ìfẹ́ kí n sì sìn àwọn ènìyàn míràn.” Ó parí pẹ̀lú ẹ̀là-ọ̀rọ̀ òtítọ́ yí gan pé: “Olúwa nfẹ́ láti rí wa nínú tẹ́mpìlì léraléra.”

Íparí

Mo ní ìmísí nípa ìwàrere àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wọ̀nyí, ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú onírurú àti olúkúlùkù àbínibí, dálórí àwọn ìtàn mẹ́rin wọ̀nyí. Púpọ̀ ni a lè kọ́ látinú àbájáde ìyanilẹ́nu tí ó wá látinú ìlò ìrọ̀rùn ti àwọn ẹ̀kọ́-ípílẹ̀ ìrọ̀rùn. Gbogbo ohun tí wọ́n ṣe wà ní àárín ìkápá wa bákannáà.

Njẹ́ kí a pa ìhìnrere mọ́ ní ìrọ̀rùn bí a ti ngbé ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá wa lé arawa: Láti gbé ìgbé-ayé ìhìnrere Jésù Krístì kí a ba ní ìfura sí àwọn ìṣílétí bí Jens ní Denmark ti ṣe. Láti ṣetọ́jú fún àwọn tó wà nínú àìní, bí a ti júwe látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ìjọ Èèkàn Cucuta ní Colombia ní pípèsè òrùlé fún àwọn ọmọ òrukàn wọ́ọ̀dù wọn. Láti pe gbogbo ènìyàn láti gba ìhìnrere, ní ọ̀nà tí Cleiton láti orílẹ̀-èdè island Áfríkà ti Cape Verde ti ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ẹbí. Ní ìgbẹ̀hìn, láti da àwọn ẹbí pọ̀ fùn ayérayé, bí àpẹrẹ nípa Arábìnrin Lydia láti Ukraine ti fi hàn, nípasẹ̀ àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ti ararẹ̀, àwọn ìgbìyànjú àkọsílẹ̀-ìtàn, àti iṣẹ́-ìsìn ní tẹ́mpìlì.

Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ dájúdájú yíò mú ayọ̀ àti àláfíà wá. Nípa èyí ni mo ṣèlérí tí mo sì jẹri—àti nípa Jésù Krístì bí Olùgbàlà wa àti Olùràpàdà wa—ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Mórónì 10:32.

  2. Wo Ìwé-ìléwọ́: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 1.2, ChurchofJesusChrist.org.

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 110:11–16. Bákannáà wo Dallin H. Oaks, “The Melchizedek Priesthood and the Keys,” Liahona, May 2020, 70: “Following the dedication of the first temple of this dispensation in Kirtland, Ohio, three prophets—Moses, Elias, and Elijah—restored ‘the keys of this dispensation,’ including keys pertaining to the gathering of Israel and the work of the temples of the Lord.” Bákannáà wo Quentin L. Cook, “Prepare to Meet God,” Liahona, May 2018, 114: “Ancient prophets restored priesthood keys for the eternal saving ordinances of the gospel of Jesus Christ. … These keys provide the ‘agbára láti o`kè wá’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:38] for divinely appointed responsibilities that constitute the primary purpose of the Church.”

  4. Wo Máttéù 22:36–40.

  5. Nínu Matthew Cowley Sọ̀rọ̀: Discourses of Elder Matthew Cowley of the Quorum of the Twelve of The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints (1954), xii.

  6. Dallin H. Oaks, “Small and Simple Things,” LiahonaMay 2018, 90.

  7. Wo Matteu 11:30.