Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu ti ìhìnrere Jésù Krístì.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu ti ìhìnrere Jésù Krístì.

Mo mọ̀ pé ìhìnrere Rẹ̀ le mú ìrètí, àláàfíà, àti ayọ̀ wá fúnwa, kìí ṣe nísisìyí nìkan, ṣùgbọ́n yío bùkún fún àìníye àwọn ẹlòmíràn nínú àwọn ìran ọjọ́ iwájú.

Mabuhay! Mo mú ìfẹ́ àti àwọn ẹ̀rín-músẹ́ tọ̀ yín wá láti ọ̀dọ̀ ìyanu àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti Philippines. Ọdún yí ṣe àmì ọgọ́ta ọdún láti ìgbà tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere àkọ́kọ́ dé sí àwọn erékùsù ti Philippines. Míṣọ̀n mẹ́tàlélógún àti àwọn ọmọ Ìjọ́ tí ó jú irinwó-méjì lọ ní àwọn èèkàn ọgọ́fà-ó-lé-mẹ́ta ló wà. Nísisìyí àwọn tẹ́mpìlì méje ni wọ́n wà tí wọ́n nṣiṣẹ́, tí a nkọ́ lọ́wọ́, tàbí tí a ti kéde. Èyí jẹ́ iṣẹ́ ìyanu kan nítòótọ́. A nrí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ninú 2 Néfì 10:21: “Títóbi ni àwọn ìlérí Olúwa sí àwọn tí nbẹ lórí àwọn erékùṣù òkun.”

Àwòrán
Ààrẹ Hinckley ní àwọn Philippine

Iṣẹ́ ìyanu yi bákannáà jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí a fifúnni nínú àdúrà kan láti ẹnu Alàgbà-nígbànáà Gordon B. Hinckley ní Manila ní 1961. Nínú àdúrà náà, Alàgbà Hinckley sọ pé: “A pe àwọn ìbùkún Rẹ sórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí, pé kí wọn ó le ní ìwà ọ̀rẹ́ àti aájò àti inúrere àti àánú sí àwọn wọnnì tí yío wá síhĩn, àti pé púpọ̀, béèni, Olúwa, a gbàdúrà pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yío wà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún tí wọn yío gba ọ̀rọ̀ yí tí wọn yío sì di alábùkúnfún nípa rẹ̀. Njẹ́ kí Iwọ ó bùkún wọn pẹ̀lú àyà ìgbà-sínú àti ọkàn òye, àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti gbà, àti pẹ̀lú ìgboyà láti gbé ìgbé ayé àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere náà” (American War Memorial Cemetery, Philippines, Apr. 28, 1961).

Àwòrán
Ẹbí Revillo

Tayọ púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún olódodo àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, iṣẹ́ ìyanu ti ìhìnrere náà ti mú àwọn àyípadà rere wá sí orílẹ̀ èdè náà àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi jẹ́ alààyè ẹlẹ́rí kan ti èyí. Èmi jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà nígbàtí àwọn òbí mi darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní gúúsù erékùsù ti Mindanao. Ní àkókò náà, míṣọ̀n kanṣoṣo ní ó wà ní gbogbo orílẹ̀ èdè náà, kò sì sí àwọn èèkàn. Mo ní ìmoore ayérayé fún ìgboyà àti ìfarajì àwọn obí mi láti tẹ̀lé Olùgbàlà. Mo bu ọlá fún wọn àti gbogbo àwọn olùlànà ìjọ ní Philippines. Wọ́n pa ọ̀nà mọ́ fún àwọn ìran tó tẹ̀lé láti jẹ́ alábùkúnfún.

Ọba Benjamin nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ pé: “Àti pẹ̀lú-pẹ̀lù, èmi yío fẹ́ kí ẹ ro ti ipò alábùkún-fún àti ìdùnnú ti àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorí ẹ kíyèsíi, wọ́n jẹ́ alábùkún-fún nínú ohun gbogbo, méjèèjì ní ti ara àti ti ẹ̀mí” (Mosiah 2:41).

Bí a ti ngbé ìgbé ayé tí a sì ngbọ́ràn sí àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà ìhìnrere, a jẹ́ alábùkúnfún, yíyí padà, a sì nyí ọkàn padà sí dídà bíi Jésù Krístì síi. Báyi ni bí ìhìnrere ti ṣe yíyí padà àti bíbùkún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ará Philippines, nínú èyí tí ẹbí mi wà. Ìhìnrere ni ọ̀nà ní tòótọ́ sí ìgbé ayé ìdùnnú àti ọ̀pọ̀.

Àkọ́kọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì. Púpọ̀ àwọn ará Philippines ní àdánidá ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó rọrùn fúnwa láti gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì kí a sì mọ̀ pé a le gba àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa.

Àwòrán
Ẹbí Obedoza

Ẹbí Obedoza jẹ́ àpẹrẹ nlá kan ti èyí. Arákùnrin Obedoza ni ààrẹ ẹ̀ka mi nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin. Ìfẹ́ inú gígajùlọ ti arákùnrin àti arábìnrin Obedoza ni láti fi èdìdi dì sí ẹbí wọn nínú tẹ́mpìlì Mànílà. Wọ́n ngbé ní ìlú nlá General Santos, ẹgbẹ̀rún kan máìlì láti Mànílà. Fún ẹbí ẹlẹ́ni mẹ́san, síṣe ìrìn àjò náà sí tẹ́mpìlì dábí ẹnipé kò ṣeéṣe. Ṣùgbọ́n bíi ti ọkùnrin oníṣòwò náà ẹnití ó lọ tí ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní láti ra píálì olówó iyebíye kan (wo Matteu 13:45–46), tọkọ-taya yi pinnu lati ta ilé wọn láti sanwó fún ìrìn àjò náà. Ọkàn arábìnrin Obedoza kò balẹ̀ nítorípe wọn kòní ní ilé láti padà sí. Ṣùgbọ́n arákùnrin Obedoza fi dá a lójú pé Olúwa yío pèsè.

Wọ́n ṣe èdìdi bíi ẹbí kan fún àkókò àti gbogbo ayérayé nínú tẹ́mpìlì náà ní 1985. Nínú tẹ́mpìlì wọ́n rí ayọ̀ tí kò ní àfiwé—píálì àìdiyelé wọn. Àti ní tòótọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ arákùnrin Obedoza, Olúwa pèsè. Ní ìpadàbọ̀ wọn láti Mànílà, àwọn onínúure ojúlùmọ̀ fún wọn ní àwọn ibi tí wọn le dúró sí, àti ní ìgbẹ̀hìn wọ́n gba ibùgbé tiwọn. Olúwa máa nṣe ìtọ́jú àwọn wọnnì tí wọ́n bá ṣe àfihàn ìgbágbọ́ wọn nínú Rẹ̀.

Èkejì ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni ìrònúpìwàdà. Ìrònúpìwàdà jẹ́ yíyípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti yíyípadà sí Ọlọ́run fún ìdáríjì. Ó jẹ́ ìyípadà ti inú àti ọkàn. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, ó jẹ́ “síṣe àti jíjẹ́ dídára díẹ̀ síi ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan” (“A Le Ṣe Dáradára Síi Kí A sì Di Dáradára Síi,” Liahona, Oṣù Karũn 2019)

Ǐrònúpìwàdà ní àfijọ púpọ̀ sí ọṣẹ. Bíi ọ̀dọ́ onímọ̀-ẹrọ kẹ́míkà, mo ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ọṣẹ síṣe kan ní Philippines. Mó kọ́ bí a ti nṣe ọṣẹ àti ìlànà bí ó ti nṣiṣẹ́. Nígbàtí ẹ bá da àwọn òróró pọ̀ pẹ̀lú èròjà tó ní álíkáláì nínú tí ẹ wá fi àwọn aṣojú egbòógi kòkòrò kan kún, ó nṣẹ̀dá ohun alágbára kan tí ó le ṣe àmúkúrò kòkòrò àti àwọn kòkòrò-àrùn fáírọ́ọ̀sì. Bíi ti ọṣẹ, ìrònúpìwàdà jẹ́ ohun èlò àfọ̀mọ́ kan. Ó nfúnwa ní ànfàní láti mú àwọn àìmọ́ wa kúrò àti àwọn ìdọ̀tí wa àtijọ́, kí a le yẹ láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run, bí ó ti jẹ́ pé “kò sí ohun àìmọ́ kan tí yío jogún ìjọba [Ọlọ́run]” (Álmà 11:37).

Nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà a nfà nínú agbára àfọ̀mọ́ àti ìyàsímímọ́ ti Jésù Krístì. Ó jẹ́ apákan tí ó ṣe kókó ní ti ìlànà ìyílọ́kànpadà. Èyí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn-ará-Léhì-Aṣòdìsí-Néfì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Wọ́n jẹ́ àwọn ará Lámánì tí a ti yí lọ́kàn padà pátápátá tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣubú kúrò mọ́ láé (wo Álmà 23:6–8). Wọ́n bo àwọn ohun ìjà ogun wọn mọ́lẹ̀ wọn kò sì tún mú wọn jáde mọ́ láé. Wọn ó yà kú dípò dída májẹ̀mú náà. Wọ́n sì fi í múlẹ̀. A mọ̀ pé ìrúbọ wọn mú àwọn iṣẹ́ ìyanu wá, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ẹnití njà dojúkọ wọ́n ju àwọn ohun ìjà wọn sílẹ̀ a sì yíwọn lọ́kàn padà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnwá, àwọn ọmọkùnrin wọn, tí a mọ̀ sí àwọn alágbára ọ̀dọ́ jagun-jagun, jẹ́ dídá ààbò bò nínú ogun ní ìdojúkọ àwọn ewu tó ṣòro láti gbàgbọ́!

Àwòrán
Baba Alàgbà Revillo

Ẹbí mi àti púpọ̀ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ará Philippines la irú ìlànà ìyílọ́kàn-padà bẹ́ẹ̀ kọjá. Nígbàtí a gba ìhìnrere Jésù Krístì tí a sì darapọ̀ mọ́ Ìjọ, a yí àwọn ọ̀nà wa àti àṣà wa padà láti wà ní ìbámu sí ìhìnrere náà. A níláti fi àwọn àṣà tí kò tọ́ sílẹ̀ Mo rí èyí nínú baba mi nígbàtí ó kọ́ nípa ìhìnrere tí ó sì ronúpìwàdà. Ó jẹ́ amusìgá gidi tẹ́lẹ̀rí, ṣùgbọ́n ó ju àwọn sìgá rẹ̀ nù kò sì fi ọwọ́ kan ẹyọkan mọ́ láé. Nítorí ìpinnu rẹ̀ láti yípadà, àwọn ìran mẹ́rin láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti di alábùkúnfún.

Àwòrán
Àwọn ìrandíran Ẹbí Revillo family

Ìrònúpìwàdà ndarí wa láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ nípasẹ̀ àwọn ìlànà mímọ́. Àkọ́kọ́ ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga ni ìrìbọmi nípa rírì-sínú-omi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Ìrìbọmi ngbà wá láàyè láti gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ kí a sì wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa. A le ṣe àtúnṣe májẹ̀mú ìrìbọmi yí ní ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀ bí a ti ngba ounjẹ Olúwa. Èyí náà jẹ́ iṣẹ́ ìyanu kan!.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, mo pè yín láti mú iṣẹ́ ìyanu yí wá sí ìgbé ayé yín. Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì kí ẹ sì yàn láti lo ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ṣe àti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ tí rí nínú àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga. Èyí yío fún yín ní ààyè láti wà ní àsopọ̀ pẹ̀lú Krístì ẹ ó sì gba agbára àti àwọn ìbùkún ti ìwàbí-Ọlọ́run (wo Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:20).

Mo jẹ́ri ti òtítọ́ Jésù Krístì àti pé Ó wà láàyè ó sì fẹ́ràn ẹ́nìkọ̀ọ̀kan wa. Mo mọ̀ pé ìhìnrere Rẹ̀ le mú ìrètí, àláàfíà, àti ayọ̀ wá fúnwa, kìí ṣe nísisìyí nìkan, ṣùgbọ́n yío bùkún fún àìníye àwọn ẹlòmíràn nínú àwọn ìran ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí fún àwọn ẹ̀rín músẹ́ rírẹwà àti tìfẹ́-tìfẹ́ ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ará Philippines. Ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ti ìhìnrere àti ẹ̀kọ́ ti Krístì. Mo jẹ́ri èyí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.