Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àánú Ìbánigbé Olùgbàlà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Àánú Ìbánigbé Olùgbàlà

Ìfihàn àánú fún àwọn ẹlòmíràn ni àkójá ìhìnrere Jésù Krístì.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ tó lámì tí a kọ́ni láti ọwọ́ Olùgbàlà nígbà iṣẹ́-ìránṣẹ ilé-ayé Rẹ̀ ni pàtàkí títọ́jú àwọn ẹ̀lòmíràn pẹ̀lú àánú. Ẹ jẹ́ kí a ronú lorí ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ yí àti rírí ìlò rẹ̀ nípa ríro àkọsílẹ̀ ìbẹ̀wò Jésù sí ilé Símónì, Farisí náà.

Ìhìnrere Lúkù sọ pé obìnrin kan, tí a kà sí ẹlẹ́ṣẹ̀, wọlé Símónì nígbàtí Jésù wà níbẹ̀. Nínú ìròjẹ́ ìrẹ̀lẹ̀, obìnrin náà dé ọ̀dọ̀ Jésù, wẹ ẹsẹ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú omijé rẹ̀, nù wọ́n pẹ̀lú irun rẹ̀, àti nígbànáà ó fẹnukòó ó sì fi àmì òróró yàn wọ́n pẹ̀lú ìkúnra pàtàkì.1 Onígbéraga olùgbàlejò, ẹnití ó ro ararẹ̀ pé ó jẹ́ ọ̀gá sí obìnrin náà, ronú sí ararẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gàn àti ìgbéraga, “Ọkùnrin yí, bí ó bá jẹ́ wòlíì kan, ìbá ti mọ ẹnití àti irú obìnrin tí èyí nṣe tí ó fọwọ́kan án: nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ó jẹ́.”2

Ìwà mojẹ́-mímọ́-jù Farisí náà darí rẹ̀ láti dájọ́ àìtọ́ nípa Jésù àti obìnrin náà. Ṣùgbọ́n nínú òye-nlá Rẹ̀, Olùgbàlà mọ̀ ọkàn Símónì àti, nínú ọgbọ́n títobí, pe ìkẹgàn Símónì níjà, bákannáà ó ṣe ìkìlọ̀ fun nítorí àìní àpọ́nlé rẹ̀ ní gbígba àlejò pàtàkì bíi ti Olùgbàlà sínú ilé rẹ̀. Lootọ́, ìbáwí tààrà Jésù sí Farisí dúró bí ẹ̀rí kan pé Jésù dájúdájú ní ẹ̀bùn àsọtẹ́lẹ̀ àti pé obìnrin yí, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìròbìnújẹ́ ọkàn, ní ìronúpìwàdà a sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jìí.3

Bií ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn nígbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ ilé-ayé ti Jésù, àkọsílẹ̀ yí jẹ́wọ́ jùlọ lẹ́ẹ̀kansi pé Olùgbàlà ṣe ìṣe pẹ̀lú àánú sí gbogbo ẹnití yíò bá wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀—láìsí ìyàtọ̀—àti ní pàtàkì jùlọ sí àwọn ẹnití wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ jùlọ. Ìfẹ́ ìròjẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí obìnrin náà fihan Jésù jẹ́ ẹ̀rí ìrònúpìwàdà òdodo rẹ̀ àti ifẹ́ láti gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bákannáà, ìwà mo ga ju ti Símónì, papọ̀ pẹ̀lú ọkàn líle rẹ̀,4 dẹ́kun rẹ̀ ní fífi ìyọ́nú hàn fún ẹ̀mí tí ó rònúpìwàdà náà, àti pé àní ó tọ́ka sí Olùgbàlà arayé pẹ̀lú àìníyàtọ̀ àti iríra. Ìwà Rẹ̀ fihàn pé ọ̀nà ìgbé-ayé rẹ̀ kò ju alàfo àti àfiyèsí líle ti àkóso àti àwọn ìfihàn ìta ti àwọn ìjẹri nípa ìgbéraẹni-ga àti ìwàmímọ́ ẹ̀tàn lọ.5

Iṣẹ́-ìránṣẹ́ àánú àti ti-araẹni Jésù nínú àkọsílẹ̀ yí fi àwòṣe pípé bí a ṣe nílati báraṣe pẹ̀lú aladugbo wa. Àwọn ìwé-mímọ́ ní àwọn àpẹrẹ àìlónkà bí Olùgbàlà, ṣe nímọ̀lára nípa àánú ìjìnlẹ̀ àti ìbánigbé àánú, ní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn ọjọ́ Rẹ̀ àti láti ran àwọn ẹnití ó njìyà àti àwọn “tí wọ́n nṣubú, tí wọ́n fọ́nká káàkiri, bí agùntàn tí kò ní olùṣọ́.”6 Ó nawọ́ àánú sí àwọn ẹnití wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú àwọn àjàgà wọn, níti ẹ̀mí àti ti-ara.7

Ìwà àánú Jésù ní gbòngbò nínú ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́,8 tí a pè ní, ìfẹ́ mímọ́ àti pípé, èyí tì ó jẹ́ àkójá ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Àánú ni ìpìlẹ̀ ìhùwàsí ti àwọn ẹnití wọ́n ntiraka fún yíyàsímímọ́, àti pé ìwà tọ̀run yí wọnúara pẹ̀lú àwọn ìhùwà Krístẹ́nì bíi ṣíṣe ọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹnití wọ́n nṣọ̀fọ̀ tí wọ́n sì nní ìyọ́nú, àánú, àti inúrere.9 Ìfihàn àánú fún àwọn míràn lotitọ́ ni, àkójá ìhìnrere Jésù Krístì àti àmì ẹ̀rí ti-ẹ̀mí àti ẹ̀dùn ọkàn sísúnmọ́ Olùgbàlà. Síwájú síi, ó fi ipò agbára tí Òun ní ní ọ̀nà ìgbé-ayé wa hàn ó sì júwe títóbi àwọn ẹ̀mí wa.

Ó ní ìtúmọ̀ láti ṣe àkíyèsí pé àwọn ìṣe àánú kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ìfihàn ìfàṣẹsí tí ó dá lé ìtòsílẹ́ àwọn iṣẹ́ láti ṣe parí ṣùgbọ́n àwọn ìfihàn ojojúmọ́ ti òdodo ìfẹ́ mímọ́ Rẹ̀ fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ àti ìfẹ́ ìbánigbé Rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Jésù lè mọ ìyàtọ̀ àìní àwọn ènìyàn àní láti ìbi jíjìn. Báyìí, kò yanilẹ́nú, fún àpẹrẹ, pé ní kété lẹ́hìn wíwo ìránṣẹ́ centurion sàn,10 Jésù rin ìrìnàjò láti Capernaum sí ilú tí à npè ní Nain. Ní ibẹ̀ ni Jésù ti ṣe ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́-ìyanu jẹ́jẹ́ ti iṣẹ́-ìránṣẹ́ ilé-ayé Rẹ̀ nígbàtí Òun pàṣẹ kí okù ọ̀dọ́mọkùnrin, ọmọkùnrin kanṣoṣo ti ìyá opó kan, láti dìde tí ó sì yè. Jésù kò ní òye líle ìjìyà ti otòṣì ìyá náà nìkan ṣùgbọ́n bákannáà àwọn ipò líle ti ìgbé-ayé rẹ̀, Ó sì ní ìmọ̀lára pẹ̀lú àánú òtítọ́ fún un.11

Gẹ́gẹ́ bí obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ àti opó Nain, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú agbo agbára wa nwá ìtùnú, ìtọ́jú, wíwàpẹ̀lú, àti ìrànlọ́wọ́-kírànlọ́wọ́ tí a lè fún wọn. Gbogbo wa lè jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Olúwa àti ìṣe pẹ̀lú àánú sí àwọn tí kò ní gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.

Àwòrán
Catarina Justinano Menossi and Danilo Menossi

Mo mọ ọmọdébìnrin kan ẹnití a bí pẹ̀lú àrùn ètè líle àti àrùn pálétì. Ó níláti ní àkọ́kọ́ ti onírurú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́-abẹ ní ọjọ́ kejì ayé rẹ̀. Ní ìmọ̀lára nípa àánú òdodo fún àwọn ẹnití wọ́n ní ìrírí irù ìpènijà yí kannáà, ọmọbìnrin yí àti àwọn òbí rẹ̀ wá láti tì í lẹ́hìn, níní òye, àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀dùn-ọkàn sí àwọn míràn ẹnití wọ́n dojúkọ òdodo líle yí. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ ara wọn, wọ́n pín pé: “Nípa ìpènijà ọmọbìnrin wa, a ní àyè láti pàdé àwọn ènìyàn ìyanu tí wọ́n nílò ìtùnú, àtìlẹhìn, àti ìgbani-níyànjú. Ìgbàkan sẹ́hìn, ọmọbìnrin wa, ẹnití ó jẹ́ ọmọ ọdún mọkanla nísisìyí, sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí ọmọ-ọwọ́ kan pẹ̀lú ìpènijà kannáà. Ní inú ìbárasọ̀rọ̀ yí, ọmọbìnrin wa lẹ́ẹ̀kan dédé ṣí ìbòmú tí ó wọ̀ nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kí àwọn òbí náà lè ri pé ìrètí wà, àní bíótilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ-ọwọ́ náà ṣì ní ọ̀nà jíjìn láti lọ ní àwọn ọdún díẹ̀ tí ó nbọ̀ láti tún wàhálà náà ṣe. A ní ìmọ̀lára ìmoore gan fún ànfàní láti nawọ́ ìyọ́nú wa sí àwọn ẹnití wọ́n njìyà, bí Olùgbàlà ti ṣe fún wa. A nímọ̀lára pé à nmú ìrora wa rọ̀ ní gbogbo ìgbà tí a bá ran ìrora àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.”

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, bí a ṣe nmọ̀ọ́mọ̀ tiraka láti fi ìwà àánú kan sí ọ̀nà ìgbé-ayé wa, bí Olùgbàlà ti ṣe àpẹrẹ, a ó di olùfetísílẹ̀ sí àìní àwọn ènìyàn. Pẹ̀lú fífetísílẹ̀ púpọ̀si, àwọn ìfẹ́ ìmọ̀lára òdodo àti ìfẹ́ni yíò wọnú gbogbo iṣe wa. Olúwa yíò dá àwọn ìgbìyànjú wa mọ̀, a ó sì di alábùkún dájúdájú pẹ̀lú àwọn ànfàní láti jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Rẹ̀ ní mímúrọ̀ àwọn ọkàn àti mímú ìrọrùn bá àwọn “ọwọ́ … rírẹlẹ̀.”12

Ìkìlọ̀ Jésù sí Símónì Farisí bakannáà fihàn kedere pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe ìdájọ́ líle àti búburú nípa aladugbo wa, nítorí gbogbo wa ni a nílò lílóye àti àánú fún àwọn àìpé wa láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Ṣe èyí kìí ṣe ohun déédé tí Olùgbàlà kọ́ni ní ọ̀ràn míràn nígbàtí Ó wípé, “Èéṣe tí ìwọ rí èerí-kékeré tí ó wà lóju arákùnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n tí o ko rí éérí nlá tí ó wà ní oju tìrẹ?”12

A nílò láti rò pé kò rọrùn láti ní òye gbogbo ipò tí ó dásí ìwà tàbí ìdáhùnsí ẹnikẹ́ni. Àwọn ìwò lè jẹ́ ẹ̀tàn àti pé nígbàmíràn kò rọ́pò ìwọ̀n déédé ti ìwà ẹnìkẹ́ni. Ní àìdàbí ẹ̀yin àti èmi, Krístì lágbára ní rírí gbogbo ipò tí ó wà.13 Àní mímọ́ gbogbo àwọn àìlera wa bí Ó ti ṣe, Olùgbàlà kìí dá wa lẹ́bi wàràwàrà ṣùgbọ́n làti tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa pẹ̀lú àánú ní ìgbà pípẹ́, ní rírànwá lọ́wọ́ láti mú èérí nlá kúrò ní ojú wa. Jésù nwo ọkàn nígbàgbogbo kìí ṣe ní ìwò.14 Ohun funrarẹ̀ kéde, “máṣe fi ìwò ṣe ìdájọ́.”15

Nísisìyí, ro àmọ̀ràn ọgbọ́n ti Olùgbàlà sí àwọn ọmọẹ̀hìn méjìlá ti Olùgbàlà ní ìkàsí ìbèèrè yí:

“Ṣe ẹ̀yin kò mọ̀ pé ẹ̀yin yíò jẹ́ adájọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́bí ìdájọ́ èyí tí èmi yíò fifún un yín, èyítí yíò jẹ́ òdodo. Nítorínáà, irú ènìyàn wo ní ó yẹ kí ẹ jẹ́? Lootọ ni mo wí fún yín, àní gẹ́gẹ́bí èmí ti rí.”16

“Nítorínáà mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí èmi, tàbí Bàbá yín tí mbẹ ní ọ̀run ti wà ní pípé.”17

Ní ọ̀rọ̀ yí, Olúwa ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ẹnití wọ́n fi sórí ara wọn láti dájọ́ èrò àìṣedéédé àwọn ẹlòmíràn ní àìṣòdodo. Ní èrò láti yege fúnra wa láti ṣe àwọn ìdájọ́ òdodo, a gbọ́dọ̀ tiraka láti dàbí Olùgbàlà kí a sì wo àwọn àìpé olúkúlùkù pẹ̀lú àánú, àní nínú ojú Rẹ̀. Ríronú pé a ṣì ní ọ̀nà gígùn láti lọ láti dé ibi-pípé, bóyá yíò dára bí a bá joko ní ẹsẹ̀ Jésù kí a sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn àìpé ti arawa, bí obìnrin onírònúpìwàdà ní ilé Farisí ti ṣe, tí kò lo àkokò púpọ̀ jù àti okun ní dídúrólé ríró àìpé àwọn ẹlòmíràn,

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti ntiraka láti fi àpẹrẹ àánú Olùgbàlà sínú ayé wa, agbára wa láti yìn àwọn ìwàrere ti aladugbo wa yíò pọ̀ si àti pé òye-inú àdánidá wa láti dájọ́ àwọn àìpé wọn yíò dínkú. Ìdàpọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run yíò dàgbà, dájúdájú àwọn ìgbé ayé wa yíò sì di dídùn síi, àwọn ìmọ̀lára wa di rírọ̀ síi, àti pé a ó rí orísun àìlópin ìdùnnú títíláé. A ó mọ̀ wá bí àwọn olúlàjà,18 wọnnì tí àwọn ọ̀rọ̀ wọn wà jẹ́jẹ́ bí ìrì òwúrọ̀ ṣíṣàn kan.

Mo gbàdúrà pé a ó di olùpamọ́ra síi àti lílóye àwọn ẹlòmíràn àti ti ìfẹ́ àánú Olúwa, ní inútútú pípé, rọ àìnísùúrù wa pẹ̀lú àwọn àìpé ẹlòmíràn. Èyí ni ìpè Olùgbàlà sí wa. Mo jẹri pé Ó wà láàyè. Òun ni àwòṣe pípé ti àánú àti sùúrù ipò-ọmọlẹ́hìn. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà Jésù Krístì, àmín.