Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ohun Ẹ̀mí Mi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Àwọn Ohun Ẹ̀mí Mi

Kíni ohun tí ẹ̀ njíròrò? Àwọn ohun wò ní ó ṣe pàtàkì sí yín lódodo? Kíni àwọn ohun ẹ̀mí yín?

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, bí mo ti dúró nínú Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò olùfẹ wa lẹ́ẹ̀kansi, a ránmilétí àwọn ọ̀rọ̀ Àpóstélì Pétérù: “Olúwa, ó dára fún wa láti wà nihin.”1

Àwọn èrò mi loni dá lórí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Néfì, ẹnití ó pa àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ títẹ̀lé ikú Léhì Baba rẹ̀. Néfì kọ pé, “Àti lórí ìwọ̀nyí ni mo kọ àwọn ohun ẹ̀mí mi.”2

Mo máa nkọjá lórí ẹsẹ yí, ní ríronú pé ọ̀rọ̀ náà àwọn ohun kìí ṣe ẹlẹ́wà gan tàbí ti-ẹ̀mí “ẹ̀mí mi.” Síbẹ̀síbẹ̀ mo ti kọ́ pé ọ̀rọ̀ náà àwọn ohun ni a lò nínú àwọn ìwé-mímọ́ fún ìgbà ẹgbẹ̀rún àti ọgọrun mẹta ólémẹrinlaadọta.3 Fún àpẹrẹ, nínú ìwé Mósè: “Èmi ni Ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin, Ọlọ́run Elédùmarè; nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí Mi Nìkanṣoṣo ni mo dá àwọn ohun wọ̀nyí.”4 Àwọn ọ̀rọ̀ Néfì sì ni: “Kíyèsíi, ọkan mi yọ̀ nínú àwọn ohun Olúwa; ọkàn mi sì njíròrò títí lórí àwọn ohun èyítí mo ti rí tí mo sì ti gbọ́.”5

Àwọn ọ̀rọ̀ Néfì mú àwọn ìbèerè wá “Àwọn ohun wo ni ẹ̀ njíròró?” “Àwọn ohun wò ní ó ṣe pàtàkì sí yín lódodo?” “Kínni àwọn ohun ẹ̀mí yín?”

Àwọn ohun ẹ̀mí wa ni a nyẹ̀wò léraléra àti jíjinlẹ̀ nípa bíbèèrè àwọn ìbèèrè.

Àwòrán
Alàgbà Rasband nínú ìpàdè orí-afẹ́fẹ́
Àwòrán
Ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́
Àwòrán
Ìtànkiri àwọn ọ̀dọ́ àgbà

Ní ìgbà àjàkálẹ̀-àrùn mo ti pàdé pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ káàkiri àgbáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfọkànsìn, títóbi àti kékeré, nípasẹ̀ àwọn ìtànkiri àti ìbákẹ́gbẹ́ ìrohìn, a sì sọ̀rọ̀ àwọn ìbèèrè wọn.

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá Joseph Smith ní ìbèèrè ìjìnlẹ̀ kan nínú ọkàn rẹ̀, ó sì mu tọ Olúwa lọ. Ààrẹ Russell M. Nelson ti tẹnumọ pe: “Kí a mú àwọn ìbèèrè wa tọ Olúwa àti àwọn orísun òtítọ́ míràn lọ. Ṣe àṣàrò pẹ̀lú ìfẹ́-inú láti gbàgbọ́ sànju pẹ̀lú ìrètí pé ẹ lè rí àṣìṣe nínú híhàn ìgbé ayé wòlíì tàbí àìdáa inú iwé-mímọ́. Ẹ dáwọ́ mímú ìyèmejì yín pọ̀ sí dúró nípa títún wọn sọ pẹ̀lú … àwọn oníyèméjì míràn. Ẹ fi àyè gba Olúwa láti darí yín lórí ìrìnàjò ti-ẹ̀mí ìwárí yín.”6

Àwọn ọ̀dọ́ máa nbi mi léèrè léraléra ohun tí mo gbàgbọ́ àti ìdí tí mo fi gbàgbọ́.

Mo rántí fífẹ́rẹ̀ ṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní ilé wọn. Mo bèèrè bí ó bá jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí Àpóstélì kan ti wá sí ilé rẹ̀. Ó rẹrin kíákíá ó sì fèsì, “Bẹ́ẹ̀ni.” Ìbèèrè fún mi dára: “Kínni àwọn ohun pàtàkì tí ó yẹ kí n mọ̀?”

Mo fèsì pẹ̀lú àwọn ohun ẹ̀mí mi, àwọn ohun tí ó nmúra mi sílẹ̀ láti gbọ́ ìṣílétí, tí ó ngbé ìwò mi sókè kọjá àwọn ọ̀nà ayé, tí ó nfi èrò sí iṣẹ́ mi nínú ìhìnrere àti sí ìgbé-ayé mi gan.

Njẹ́ kí n pín àwọn díẹ̀ lára ohun ẹ̀mí mi”? Àwọn ohun wọ̀nyí wúlò sí gbogbo ẹnití wọ́n nwá láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn tòótọ́ Jésù Krístì. Mẹwa yíò jẹ́ iye nọ́mbà déédé kan, dídára. Ní òní mò nfún yín ní méje pẹ̀lú ìrètí pé ẹ ó parí mẹ́jọ, mẹsan, àti mẹwa látinú ìrírí ti ara yín.

Àkọ́kọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì, Olùgbàlà wa.

Jésù pàṣẹ òfin àkọ́kọ́ nlá: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.”7

Àarẹ Nelson kéde ìfọkànsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run, Baba wa ayérayé, àti sí Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nígbàtí a pè é láti darí Ìjọ Olúwa, ó wípé, “Èmi mọ̀ Wọ́n, nifẹ Wọn, mo sì jẹjẹ láti sìn Wọ́n—àti ẹ̀yin—pẹ̀lú gbogbo ìyókù èémí ayé mi.”8

Nítorínáà àkọ́kọ́, ní ìfẹ́ Baba àti Ọmọ.

Èkejì, “Ẹ fẹ́ràn aladugbo yín.”9

Ìyẹn kìí ṣe ìrò rere nìkan, ó jẹ́ òfin nlá kejì. Àwọn aladugbo yín ni tọkọ-taya àti ẹbí yín, àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù, àwọn ẹlẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àwọn alábágbé, àwọn tí kìí ṣe ẹ̀sìn wa, àwọn tí wọ́n nílò ọwọ́ ìrànlọ́wọ́, àti lotitọ́ gbogbo ènìyàn. Àkójá ti “Ìfẹ́ aladugbo yín” ní a sọ nínú orin “Ẹ Nifẹ Ara Yín.”10

Ààrẹ Nelson rán wa létí, “Nígbàtí a bá nifẹ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, Ó nyí ọkàn wa padà sí wíwà-dáadáa àwọn míràn.”11

Ẹ̀kẹ́ta, ẹ nifẹ arayin.

Èyí ni ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti nlàkàkà. Ṣe kò jẹ́-àrà pé níní-ìfẹ́ arawa dàbí ó nwá ní ìdínkù ìrọ̀rùn ju níní-ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn? Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa ti wípé, “Ẹ fẹ́ràn aladugbo yín bí arayín.”12 Ó mọyì àtọ̀runwá tí ó wà nínú wa; bẹ́ẹ̀náà ni àwa. Nígbàtí a bá ní àjàgà wúwo pẹ̀lú àwọn àṣìṣe, ìrora-ọkàn, àwọn ìmọ̀lára àìpé, ìjákulẹ̀, ìbínú, tàbí ẹ̀ṣẹ̀, agbára Ètùtù Olùgbàlà jẹ́, nípa àwòṣe àtọ̀runwá, ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó gbé ẹ̀mí ga.

Ẹ̀kẹ́rin, pa àwọn òfin mọ́.

Olúwa ti mu hàn kedere pé: “Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́.”13 Tiraka lójojúmọ́ láti jẹ́ àti láti ṣe dídára díẹ̀ si àti láti tẹ̀síwájú nínú òdodo.

Ikarun, máa wà ní yíyẹ láti lọ sí tẹ́mpìlì nígbàgbogbo.

Mo pè é ni jíjẹ́ ìkàyẹ sí Olúwa. Bóyá ẹ ní àyè sí t´ẹmpìlì kan tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, jíjẹ́ yíyẹ ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́ npa yín mọ́ dọindọin ní ìdojúkọ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì, ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Ikẹfa, jẹ́ aláyọ̀ àti títújúká.

“Ẹ tújúká, kí ẹ máṣe bẹ̀rù,”14 Olúwa ti wí. Kínìdí? Báwo, nígbàtí àwọn ìpènijà bá dojúkọ wá ní gbogbo ìyípo? Nítorí ìlérí tí Jésù Krístì ṣe: “Èmi Olúwa mo wà pẹ̀lú yín, èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín.”15

Ààrẹ Nelson júwe i`múpadàbọ̀sípò i`hìnrere bí “a message ofọ̀rọ̀ ayọ̀ kan joy!”16 ó sì ṣàlàyé pé, “Ayọ̀ ti´ a ní i`mọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ i´ṣe pẹ̀lú a`wọn ipò i`gbé-ayé wa a`ti ohungbogbo i´ṣe pẹ̀lú i`dojúkọ i`gbé-ayé wa.”17

Ikeje, tẹ̀lé wòlíì alààyè Ọlọ́run.

Èyí lè jẹ́ ìkéje lórí àwọn ohun ìtòsílẹ̀ mi, ṣùgbọ́n ó wà ní òkè inú mi ní ọ̀ràn nípa pàtàkì rẹ̀ loni.

A ní wòlíì Ọlọ́run kan ní ilẹ̀-ayé ní òní! Ẹ máṣe dín ohun tí ìyẹn jẹ́ túmọ̀sí fún yín kù. Ẹ rántí ọ̀dọ́mọbìnrin tí mo dárúkọ ní ìbẹ̀rẹ̀. Ó nfẹ́ láti mọ àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì jùlọ. “Tẹ̀lé wòlíì alààyè,” nígbànáà mo wí mo sì tẹnumọ lẹ́ẹ̀kansi ní òní.

A yà wá sọ́tọ̀ bí Ìjọ láti gba ìdarí nípasẹ̀ àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn tí Ọlọ́run pè fún àkokò yí. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nfi etísílẹ̀ tí ẹ sì ntẹ̀lé àmọ̀ràn wọn, ẹ kò ní gba ìdarí ìṣìnà láéláé. Láéláé!

À ngbé ní àkokò kan nígbàtí a “nyí wa síwájú àti sẹ́hìn,”18 nígbàtí níní-ẹ̀mí, ọmọlúàbí, ìwàtítọ́, àti ọ̀wọ̀ wà lábẹ́ ìkọlù. A níláti ṣe àwọn àṣàyàn. A ní ohun Olúwa nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀ láti rọ àwọn ẹ̀rù wa àti láti gbé ìwò wa ga, nítorí nígbàtí Ààrẹ Nelson bá sọ̀rọ̀, ó nsọ̀rọ̀ fún Olúwa.

A di alábùkún pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ àti àwọn ìkọ́ni tí ó rán wá létí, “Àwọn èrò mi kìí ṣe èrò rẹ, bẹ́ẹ̀ni ọ̀nà mi kìí ṣe ọ̀nà rẹ, ni Olúwa wí.”19

Bẹ́ẹ̀ni ó ti rí pẹ̀lú Naaman, olórí ogun nlá kan ní Syria, síbẹ̀síbẹ̀ adẹ́tẹ̀ kan, ẹnití a wí fún pé Elisha lè wò ó sàn. Elisha rán ìránṣẹ́ rẹ̀ láti wí fún Naaman láti wẹ nínú Odò Jordan ní ẹ̀ẹ̀méje àti pé òun yíò di mímọ́. Naaman ráhùn. Dájúdájú kò sí odò tí ó tóbiju Jordan, kínìdí tí ó fi rán ìránṣẹ́ nígbàtí òun nretí Elisha, wòlíì, láti wò ó sàn fúrnrarẹ̀? Naaman rìn kúrò, ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ìránṣẹ́ rẹ̀ rọ̀ọ́: “Bí wòlíì bá ní kí ìwọ wá ṣe ohun nlá, ṣe ìwọ kìbá ti ṣe?”20 Naaman nígbẹ̀hìn ri ara rẹ̀ bọ Jordan ó sì rí-ìwòsàn.

Àkọsílè Naaman nrán wa létí nípa àwọ ewu mímú àti yíyan àwọn àmọ̀ràn ti-wòlíì tí ó bá àwọn ìrònú, ìrètí wa, tàbí àwọn àṣà òní mu. Wòlíì wa tẹ̀síwájú láti fi wá sójú-àmì sí àwọn Odò Jordan láti gba ìwòsàn.

Àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì jùlọ tí a lè gbọ́, jíròrò, kí a sì tẹ̀lé ni àwọn tí a fihàn nípasẹ̀ wòlíì alààyè wa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé mo ti joko nínú ìgbìmọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ Nelson láti sọ̀rọ̀ àwọn ohun pàtàkì nípa Ìjọ àti ayé, mo sì ti rí ìfihàn tí ó nṣàn nípasẹ̀ rẹ̀. Ó mọ Olúwa, ó sì mọ ọ̀nà Rẹ̀, ó sì nfẹ́ pé kí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ó gbọ́ Tirẹ̀, Olúwa Jésù Krístì.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún a ngbọ́ láti ẹnu wòlíì ní ẹ̀ẹ̀mejì ní ọdún nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn líle ọjọ́ wa, Ààrẹ Nelson nsọ̀rọ̀ púpọ̀ si léralérá nínú àwọn àpérò,21 ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn,22 àwọn ìfọkànsì23 àní àti àwọn ìsọníṣókí oníròhìn.24 Mo ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ tí ó nmúrasílẹ̀ tí ó sì ngbé àwọn ọ̀rọ̀ ìfihàn ìjìnlẹ̀ kalẹ̀ tí ó ti gbani-níyànjú ìmoore si, gbé wíwà-pẹ̀lú gíga ti gbogbo àwọn arákùnrin wa àti arábìnrin lórí ilẹ̀-ayé, àláfíà púpọ̀si, irètí, ayọ̀, ìlera, àti ìwòsàn nínú ayé olúkúlùkù ga.

Ààrẹ Nelson jẹ́ ẹlẹ́bùn olùsọ̀rọ̀ kan, ṣùgbọ́n ní-pàtàki si, òun ni wòlíì Ọlọ́run. Ìyẹn jẹ́ ìtagbọ̀ngbọ̀n nígbàtí ẹ bá ronú nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ó le láti mọ̀ pé ìdarí híhàn-kedere rẹ̀ yíò jẹ́ asà gbogbo wa kúrò nínú ẹ̀tàn, ète, àti ọ̀nà ẹ̀kọ́-ayé tí ó njèrè àkokò kan ní ayé òní.25

Gbogbo ìlékọ́ ti-wòlíì jẹ́ nípa ìfihàn. “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhìnrere Jésù Krísti: Ìkéde Igba Ọdún Kan Sí Àgbáyé,” tí a fúnni nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2020, tẹnumọ pé Olúwa ndarí iṣẹ́ yí. Nínú ìkéde yí, Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá: “A kéde pẹ̀lú ìdùnnú pé ìlérí ìmúpadàbọ̀sípò ntẹ̀síwájú nínú ìfihàn tó nlọsíwájú. Ilẹ̀-ayé kò ní rí bákannáà mọ́ láéláé, bí Ọlọ́run yíò ti ‘kó ohun gbogbo jọ papọ̀ ní ọ̀kan nínú Krístì’ (Éfésì 1:10).”26

“Ohun gbogbo nínú Krístì”27 àti “àwọn ohun ọkàn mi”28 ni ohun tí Ìjọ yí, ìhìnrere yí, àti àwọn ènìyàn yí jẹ́ nípa gbogbo rẹ̀.

Mo parí pẹ̀lú ìpè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín láti yẹ ohun méje “ti ọkàn mi” tí mo ti pín loni wò: ìfẹ́ Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì, Olùgbàlà wa; ìfẹ́ aladugbo yín; ìfẹ́ arayín; pa àwọn òfin mọ́; jẹ́ yíyẹ fún ìkaniyẹ tẹ́mpìlì nígbàgbogbo; jẹ́ aláyọ̀ kí ẹ sì tújúká, kí ẹ sì tẹ̀lé wòlíì alààyè Ọlọ́run. Mo pè yín láti wá mẹ́jọ, mẹsan, àti mẹwa ti arayín rí. Ẹ yẹ àwọn ọ̀nà wò tí ẹ lè fi pín “àwọn ohun” pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kí ẹ sì gbà wọ́n níyànjú láti gbàdúrà, jíròrò, àti láti wá ìtọ́sọ́nà Olúwa.

Àwọn ohun ẹmi mi jẹ́ oníyebíye sí mi bí tiyín ti jẹ́ sí yín. Àwọn ohun wọ̀nyí nfún iṣẹ́-ìsìn wa lókun nínú Ìjọ àti káàkiri gbogbo ìgbé-ayé wa. Wọ́n fi wá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, wọ́n sì nrán wa létí nípa àwọn májẹ̀mú wa, wọ́n sì nrànwálọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ààbò nínú apá Olúwa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìfẹ́-inú ti ẹ̀mí wa “kò ní pebi tàbí pòhùngbẹ, ṣùgbọ́n yíò di kíkún”29 pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀ bí a ti nwá láti di àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́, láti jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀ bí Òun ti jẹ́ pẹ̀lú Baba. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.