Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Rántí Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Rẹ Tí Njìyà, Áà Ọlọ́run Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Rántí Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Rẹ Tí Njìyà, Áà Ọlọ́run Wa

Pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nṣí agbára ìrúbọ ètùtù ti Jésù Krístì láti pèsè agbára àti pàápàá ayọ̀ fún ẹ̀yin tí njìyà.

Ètò ìdùnnú ti Bàbá Ọ̀run ní ìrírí ayé ikú nínú níbití gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ yìó ti gba ìdánwò tí wọn yíò sì dojúkọ àwọn ìṣòro.1 Ní ọdún marun sẹ́yìn a ṣe àyẹ̀wò mi pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ. Mo ti ní ìmọ̀lára mo ṣì nní ìmọ̀lára àwọn ìrora láti inú àwọn iṣẹ́-abẹ, àwọn ìtọ́jú àgbénákà, àti àwọn ipa búburú ti òògùn. Mo ti ní ìrírí àwọn ìmọ̀lára ìjàkadì ẹdun lakoko àwọn alẹ́ tí kò sí oorun. Àwọn ìṣirò ìlera tọ́ka pé èmi yio kúrò ni ayé ikú ṣaájú ju bi mo ti rò lọ, ní fífi ẹbí tí ó jẹ́ ohun gbogbo fún mi sílẹ̀ sẹ́hìn, fún àkokò kan.

Láìbìkítà ibití ẹ̀ ngbé, ìjìyà ti ara tàbí ti ìmọ̀lára láti oríṣiríṣi àwọn ìṣòro àti àwọn àìlágbára àìkú ti jẹ́, njẹ́ bayi, tàbí yio jẹ́ apákan ìgbésí ayé yín ní ọjọ́ kan.

Ìjìyà ti ara lè wá láti inú dídi ogbó àdánidá, àwọn àìsàn àìròtẹ́lẹ̀, àti àwọn ìjàmbá alábàpàdé; ebi tàbí àìnì ilé lórí; tàbí ìlòkulò, àwọn ìṣe olóró, àti ogun.

Àwọn ìjìyà ẹ̀dùn-ọkàn lè dìde láti inú àìbalẹ̀ ọkàn tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì; dídalẹ̀ aya tàbí ọkọ, òbí, tàbí olórí tí a gbẹ́kẹ̀lé; àwọn ìfàsẹ́hìn iṣẹ́ tàbí ètò ìsúná; ìdájọ́ àìṣedeédé láti ọ̀dọ̀ àwọn míràn; àwọn yíyàn àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọlẹ́bí míràn; ìlòkulò ní àwọn ọ̀nà púpọ̀; àwọn àlá ìgbéyàwó tàbí àwọn ọmọ tí kò ṣẹ; àìsàn tàbí ikú àwọn olólùfẹ́; tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orísun míràn.

Báwo ni a ṣe lè farada ìjìyà àìlẹ́gbẹ́ àti aláìlágbára ti o wá sí ọ̀dọ̀ olúkúlukú wa nígbà míràn?

Pẹ̀lú ìdúpẹ́, ìrètí wa nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì, àti ìrètí tún lè jẹ́ apákan ìgbésí ayé yín. Loni mo pín àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ mẹ́rin ti ìrètí tí a fà láti inú ìwé-mímọ́, àwọn ìkọ́ni àsọtẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àbẹ̀wò síṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, àti ìdánwò ìlera mi tí nlọ́ lọ́wọ́. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí kìí ṣe wíwúlò jákèjádò nìkan ṣùgbọ́n ti ara ẹni jinlẹ̀-jinlẹ̀.

Ní àkọ́kọ́, ìjìyà kò túmọ̀ sí pé inú Ọlọ́run kò dùn sí ìgbésí ayé yín. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́hìn, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù rí ọkùnrin afọ́jú kan ní tẹ́mpìlì wọ́n bèèrè pé, “Olùkọ́ni, tani dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yii, tàbí àwọn òbí rẹ, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ dàbí ẹni pé wọn kò gbàgbọ́ ní títọ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀nìyàn ti í ṣe loni, pé gbogbo ìnira àti ìjìyà nínú ayé jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n Olùgbàlà dáhùn pé, “Ọkùnrin yii kò ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run lè farahàn nínú ayé rẹ̀.”2

Iṣẹ́ Ọlọ́run ní láti mú àìkú àti ìyè ayérayé wa wá sí ìmúṣẹ.3 Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ìṣoro àti ìjìyà—pàápàá ìjìyà tí ó wá sórí wa nípasẹ̀ kí ẹlòmíràn lo agbára láti yàn tirẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀4—mú ìlọsíwájú bá iṣẹ́ Ọlọ́run nígbẹ̀hìn?

Olúwa sọ fún àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ pé, “Èmi ti tún ọ́ dá, …; Èmi ti yàn ọ nínú iná ìlérú ìpọ́njú.”5 Ohunkóhun tí o fa àwọn ìjìyà yín, olùfẹ́ni Baba yín Ọ̀run lè darí wọn láti tún ẹ̀mí yín da.6 Àwọn ẹ̀mí tí a ti túndá lè gbé ẹrù àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìtara tòótọ́.7 Àwọn ẹ̀mí ti a ti túndá tí ó ti “jáde kúrò nínú ìpọ́njú nlá” ti múra láti fi tayọ̀tayọ̀ gbé ní iwájú Ọlọ́run láíláí, àti pé ”Ọlọ́run yíò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.”8

Ìkejì Baba Ọ̀run mọ tímọtímọ́ nípa ìjìyà yín. Lákokò tí a wà láàrín àwọn ìṣòro, a lè fi àṣìṣe rò pé Ọlọ́run jìnnà réré àti pé kò bìkítà nípa ìrora wa. Wòlíì Joseph Smith pàápàá ṣàlàyé ìmọ̀lára yí ní ààyè kékeré kan ní ìgbésí ayé rẹ. Nígbàtí ó wà nínú túbú ní Ọgbà Ẹwọ̀n Liberty lakoko tí a lé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Ọjọ-Ìkẹhìn kúrò ní ilé wọn, Joseph wá òye nípasẹ̀ àdúrà: “Áà Ọlọrún, níbo ni ìwọ́ wà? Níbo sì ni ágọ́ tí ó bo ibi ìpamọ́ rẹ̀ wà? Ò parí pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ yi: ”Rántí Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Rẹ Tí Njìyà, Áà Ọlọ́run wa.”9

Ìdáhùn Olúwa ṣe ìdánilójú si fún Joseph àti gbogbo ẹni tí ó njìyà.

“Ọmọ mi, àláfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀;

“Àti nígbànáà, bí o bá fi ara dà á dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga sókè; ìwọ yíò borí gbogbo ọ̀tá rẹ.”10

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí njìyà ti ṣe àbápín pẹ̀lú mi bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run lakoko àwọn ìṣòro wọn. Mo rántí kedere ìrírí ti ara mi ní kété ní ààyè kan nínú ìjàkadì mi pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ nígbàtí àwọn dókítà kò tii ṣe iwadii ìdí ìrora nla náà. Mo joko pẹ̀lú ìyàwó mi, ní èrò láti pèsè ìbùkún déédé lórí oúnjẹ ọ̀sán wa. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tí mo lè ṣe ni pé kí nkàn sunkún, “Baba Ọ̀run, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́. Mo ṣàìsàn púpọ̀.” Fún bíi ogún si ọgbọ̀n ìṣẹ́jú àáyá tí ó tẹ̀lé, a yí mi ká nínú ìfẹ́ Rẹ̀. A kò fún mi ní ìdí fún àìsàn mi, kò sí ìtọ́kasí àbájáde níkẹhìn, àti pé kò sí ìdẹ̀rùn kúrò nínú ìrora náà. Mo kàn ní ìmọ̀lára ìfẹ́ mímọ́ Rẹ̀, èyíinì ti tó ó sì tó.

Mo jẹri pé Baba wa Ọ̀run, tí Ó ṣe àkíyèsí ìsubú àní ológoṣẹ́ kan, mọ̀ nípa ìjìyà yín.11

Ìkẹta, Jésù Krístì fúnni ní agbára mímúniṣe Rẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín ní okun láti farada ìjìyà yín dáradára. Agbára mímúniṣe yii ni ó ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀.12 Mo bẹ̀rù pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ìjọ rò pé ti wọ́n bá jẹ́ líle díẹ̀ síi, wọ́n lè la ìjìyà eyikeyi kọjá láyè ara wọn. Èyí jẹ́ ọ̀nà líle láti gbé ayé. Àkokò okun yín fún ìgbà díẹ̀ kò lè ṣe àfiwé sí ìpèsè agbára àìlópin ti Olùgbala láti mọ odi fún ẹ̀mí yín.13

Ìwé ti Mọ́rmọ́nì kọ́ni pé Jésù Krístì “yíò gbé” ìrora, àìsàn, àti àìlera wa lé orí ara Rẹ̀ kí Ó lè ràn wá lọ́wọ́.14 Báwo ni ẹ ṣe lè fa nínú agbára ti Jésù Krístì nfúnni láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yin àti láti fún yín ní okun ní àwọn àkokò ìjìyà? Kọ́kọ́rọ́ náà ni síso ara yín pọ̀ mọ́ Olu`gbàlà nípasẹ̀ pípa àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti bá A ṣe mọ́. A ṣe àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí bí a ti ngba àwọn ìlànà oyèàlúfàà.15

Àwọn ènìyàn Álmà wọ inú májẹ̀mú ti ìrìbọmi. Lẹ́hìnwá wọ́n jìyà nínú ìgbèkùn a sì sọọ́di èèwọ̀ fún wọn láti jọ́sìn ní gbangba tàbí láti gbàdúrà sókè pàápàá. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ bí o ti dára jùlọ nípa sísun ẹkún síta ní ìdákẹ́jẹ́ nínú ọ̀kan wọn. Ní àbájáde, agbára àtọ̀runwá dé. “Olúwa fún wọn ní okun pé wọ́n lè farada àwọn ẹrù wọn pẹ̀lú ìrọ̀rùn.”16

Ní ọjọ́ wa, Olùgbàlà pè, “Wò mi nínú gbogbo èrò, máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.”17 Nígbàtí a bá pa májẹ̀mú oúnjẹ Olúwa mọ́ láti ṣèrántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, Ó ṣe ìlérí pé Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. Ẹ̀mí nfún wa ní agbára láti faradà àwọn ìṣòro àti láti ṣe ohun tí a kò lè ṣe fúnrawa. Ẹ̀mí lè wò wá sàn, bíótilẹ̀jẹ́pé bí Ààrẹ James E. Faust ti kọ́ni, “Díẹ̀ lára ​​ìwòsàn yí lè wáyé ní ayé míràn.”18

A tún nbùkún wa pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì , níbi tí “agbára ìwà-bí-Ọlọ́run ti nfarahàn.”19 Mo ṣe àbẹ̀wò sí obìnrin kan tí ó pàdánù ọmọbìnrin ọ̀dọ́ kan nínú ìjàmbá nla kan, lẹ́hìnwá ọkọ rẹ̀ fún àrùn jẹjẹrẹ. Mo bèèrè bí o ṣe le farada irú àdánù àti ìjìyà bẹ́ẹ̀. Ó dáhùn pé okun wá láti inú àwọn ìdánilójú ti ẹ̀mí nípa ẹbí ayérayé, tí a gbà lákokò ìjọ́sìn tẹ́mpìlì déédé. Bí a ti ṣe ìlérí, àwọn ìlànà ilé Olúwa ti fun un ní ohun ìjà pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.20

Ẹ̀kẹ́rin, yàn láti wá ayọ̀ lójoójúmọ́. Àwọn tí wọ́n njìyà máa nní ìmọ̀lára nígbàgbogbo pé alẹ́ kàn ntẹ̀síwájú àti síwájú, àti pé ọ̀sángangan kìí yìó wa. Ó dára láti sunkún.21 Síbẹ̀síbẹ̀, tí ẹ bá rí ara yín ni àwọn alẹ́ dúdú ti ìjìyà, nípa yíyàn ìgbàgbọ́ ẹ lè jí sí àwọn òwúrọ̀ dídán ti ayọ̀.

Fún àpẹẹrẹ, mo ṣàbẹ̀wò sí ọ̀dọ́ ìyá kan tí a nṣe ìtọ́jú rẹ̀ fún àrùn jẹjẹrẹ, tí ó nrẹrin músẹ́ nínú ọlánlá lórí ijoko rẹ̀ láìbìkítà ìrora àti àìní irun lórí. Mo pàdé tọkọtaya kan ẹni agbede méjì ọjọ́ orí tí wọ́n nfi tayọ̀-tayọ̀ ṣiṣẹ́ bíi olùdarí àwọn ọ̀dọ́ bíótilẹ̀jẹ́pé, wọn kò lágbára láti lóyún àwọn ọmọ. Mo joko pẹ̀lú obìnrin ọ̀wọ́n kan—ìyá-ìyá ọ̀dọ́, ìyá, àti ìyàwó—tí yio kọjá lọ laarin ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ laarin àwọn omijé ni ẹ̀rín àti àwọn ìrántí aláyọ̀.

Jíjàyà àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí fi àpẹrẹ ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni hàn.

“Ayọ̀ tí à nní ìmọ̀ rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti ohungbogbo íṣe pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbé ayé wa.

“Nígbàtí ìfojúsùn ti ìgbé ayé wa bá wà ní orí ètò ìgbàlà ti Ọlọ́run … Àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìka ohun tí ó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbé ayé wa sí.”23

Mo jẹ́ri24 pé Baba wa ọ̀run rántí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ tí njìyà, Ó nifẹ yin, Ó sì mọ̀ yín tímọ́tímọ́. Olùgbàlà wa mọ ìmọ̀lára tí ẹ nní. “Lootọ́ ó ti faradà ìbànújẹ́ wa, ó sì ti gbé ìrora-ọkàn wa lọ.”25 Mo mọ̀—bí olùgbà ojoojúmọ́26—pé pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nṣí agbára ẹbọ ètùtù Jésù Krístì láti pèsè okun àti pàápàá ayọ̀ fún ẹ̀yin ti njìyà.

Fún gbogbo àwọn tí njìyà, Mo gbàdúrà, njẹ́ kí Ọlọ́run gbà fún yín kí ẹrù yín lè fúyẹ́, nípasẹ ayọ̀ Ọmọ Rẹ̀.”27 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.